Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Ìṣípayá 1:1-20

1  Ìṣípayá+ kan láti ọ̀dọ̀ Jésù Kristi, èyí tí Ọlọ́run fi fún un,+ láti fi han àwọn ẹrú rẹ̀,+ àwọn ohun tí ó gbọ́dọ̀ ṣẹlẹ̀ láìpẹ́.+ Ó sì rán áńgẹ́lì+ rẹ̀ jáde, ó sì gbé e kalẹ̀ nípa àwọn àmì+ nípasẹ̀ rẹ̀ fún ẹrú rẹ̀ Jòhánù,+  ẹni tí ó jẹ́rìí sí ọ̀rọ̀ tí Ọlọ́run fúnni+ àti sí ẹ̀rí tí Jésù Kristi jẹ́,+ àní sí gbogbo ohun tí ó rí.  Aláyọ̀+ ni ẹni tí ń ka àwọn ọ̀rọ̀ àsọtẹ́lẹ̀+ yìí sókè+ àti àwọn tí ń gbọ́, tí wọ́n sì ń pa àwọn ohun tí a kọ sínú rẹ̀ mọ́;+ nítorí àkókò tí a yàn kalẹ̀ ti sún mọ́lé.+  Jòhánù sí àwọn ìjọ méje+ tí ó wà ní àgbègbè Éṣíà: Kí ẹ ní inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí àti àlàáfíà láti ọ̀dọ̀ “Ẹni náà tí ń bẹ, tí ó ti wà, tí ó sì ń bọ̀,”+ àti láti ọ̀dọ̀ ẹ̀mí méje+ tí ó wà níwájú ìtẹ́ rẹ̀,  àti láti ọ̀dọ̀ Jésù Kristi, “Ẹlẹ́rìí Aṣeégbíyèlé,”+ “Àkọ́bí nínú àwọn òkú,”+ àti “Olùṣàkóso àwọn ọba ilẹ̀ ayé.”+ Fún ẹni tí ó nífẹ̀ẹ́ wa,+ tí ó sì tú wa kúrò nínú àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa nípasẹ̀ ẹ̀jẹ̀ òun fúnra rẹ̀+  ó sì mú kí a jẹ́ ìjọba+ kan, àlùfáà+ fún Ọlọ́run àti Baba rẹ̀—bẹ́ẹ̀ ni, òun ni kí ògo àti agbára ńlá jẹ́ tirẹ̀ títí láé.+ Àmín.  Wò ó! Ó ń bọ̀ pẹ̀lú àwọsánmà,+ gbogbo ojú ni yóò sì rí i,+ àti àwọn tí ó gún un lọ́kọ̀;+ gbogbo ẹ̀yà ilẹ̀ ayé yóò sì lu ara wọn nínú ẹ̀dùn-ọkàn nítorí rẹ̀.+ Bẹ́ẹ̀ ni, Àmín.  “Èmi ni Ááfà àti Ómégà,”+ ni Jèhófà Ọlọ́run wí, “Ẹni náà tí ń bẹ, tí ó ti wà, tí ó sì ń bọ̀,+ Olódùmarè.”+  Èmi Jòhánù, arákùnrin yín àti alájọpín pẹ̀lú yín nínú ìpọ́njú+ àti ìjọba+ àti ìfaradà+ ní ìbákẹ́gbẹ́pọ̀ pẹ̀lú Jésù,+ wá wà ní erékùṣù tí a ń pè ní Pátímọ́sì nítorí sísọ̀rọ̀ nípa Ọlọ́run àti jíjẹ́rìí Jésù.+ 10  Nípa ìmísí,+ mo wá wà+ ní ọjọ́ Olúwa,+ mo sì gbọ́ ohùn líle+ bí ti kàkàkí lẹ́yìn mi, 11  tí ó wí pé: “Kọ+ ohun tí ìwọ rí sínú àkájọ ìwé, kí o sì fi í ránṣẹ́ sí ìjọ méje,+ ní Éfésù+ àti ní Símínà+ àti ní Págámù+ àti ní Tíátírà+ àti ní Sádísì+ àti ní Filadéfíà+ àti ní Laodíkíà.”+ 12  Mo sì yí padà láti wo ohùn tí ń bá mi sọ̀rọ̀, bí mo sì ti yí padà, mo rí ọ̀pá fìtílà méje oníwúrà,+ 13  àti ní àárín àwọn ọ̀pá fìtílà náà, ẹnì kan tí ó dà bí ọmọ ènìyàn,+ tí a wọ̀ ní ẹ̀wù tí ó balẹ̀ dé ẹsẹ̀, a sì fi àmùrè wúrà di igẹ̀ rẹ̀. 14  Jù bẹ́ẹ̀ lọ, orí rẹ̀ àti irun rẹ̀ funfun+ bí irun àgùntàn funfun, bí ìrì dídì, àti ojú rẹ̀ bí ọwọ́ iná ajófòfò;+ 15  ẹsẹ̀ rẹ̀ sì dà bí bàbà àtàtà+ nígbà tí ó bá pọ́n yòò nínú ìléru; ohùn+ rẹ̀ sì dà bí ìró omi púpọ̀. 16  Ó sì ní ìràwọ̀ méje+ ní ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀, idà+ gígùn olójú méjì mímú sì yọ jáde láti ẹnu rẹ̀, ìrísí ojú rẹ̀ sì dà bí oòrùn nígbà tí ó bá ń ràn nínú agbára rẹ̀.+ 17  Nígbà tí mo sì rí i, mo ṣubú bí òkú lẹ́bàá ẹsẹ̀ rẹ̀. Ó sì gbé ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ lé mi, ó sì wí pé: “Má bẹ̀rù.+ Èmi ni Ẹni Àkọ́kọ́+ àti Ẹni Ìkẹyìn,+ 18  àti alààyè;+ mo sì ti di òkú tẹ́lẹ̀,+ ṣùgbọ́n, wò ó! mo wà láàyè títí láé àti láéláé,+ mo sì ní kọ́kọ́rọ́ ikú+ àti ti Hédíìsì+ lọ́wọ́. 19  Nítorí náà, kọ àwọn ohun tí ìwọ rí sílẹ̀, àti àwọn ohun tí ó wà àti àwọn ohun tí yóò ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn ìwọ̀nyí.+ 20  Ní ti àṣírí ọlọ́wọ̀ ti ìràwọ̀ méje+ tí ìwọ rí ní ọwọ́ ọ̀tún mi, àti ti ọ̀pá fìtílà méje oníwúrà náà:+ Ìràwọ̀ méje náà túmọ̀ sí àwọn áńgẹ́lì ìjọ méje, ọ̀pá fìtílà méje náà sì túmọ̀ sí ìjọ méje.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé