Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Éfésù 6:1-24

6  Ẹ̀yin ọmọ, ẹ jẹ́ onígbọràn sí àwọn òbí yín+ ní ìrẹ́pọ̀+ pẹ̀lú Olúwa, nítorí èyí jẹ́ òdodo:+  “Bọlá fún baba rẹ àti ìyá rẹ”;+ èyí tí í ṣe àṣẹ kìíní pẹ̀lú ìlérí:+  “Kí nǹkan lè máa lọ dáadáa fún ọ, kí ìwọ sì lè wà fún àkókò gígùn lórí ilẹ̀ ayé.”+  Àti ẹ̀yin, baba, ẹ má ṣe máa sún àwọn ọmọ yín bínú,+ ṣùgbọ́n ẹ máa bá a lọ ní títọ́ wọn dàgbà+ nínú ìbáwí+ àti ìlànà èrò orí+ Jèhófà.  Ẹ̀yin ẹrú, ẹ jẹ́ onígbọràn sí àwọn tí í ṣe ọ̀gá yín nípa ti ara,+ pẹ̀lú ìbẹ̀rù àti ìwárìrì+ nínú òtítọ́ ọkàn-àyà yín, gẹ́gẹ́ bí sí Kristi,  kì í ṣe lọ́nà àrójúṣe gẹ́gẹ́ bí àwọn olùwu ènìyàn,+ ṣùgbọ́n gẹ́gẹ́ bí ẹrú Kristi, ní ṣíṣe ìfẹ́ Ọlọ́run tọkàntọkàn.+  Ẹ jẹ́ ẹrú pẹ̀lú àwọn ìtẹ̀sí èrò rere, gẹ́gẹ́ bí fún Jèhófà,+ kì í ṣe fún àwọn ènìyàn,  nítorí ẹ mọ̀ pé, ohun rere yòówù tí olúkúlùkù ì báà ṣe, yóò gba èyí padà láti ọ̀dọ̀ Jèhófà,+ yálà ó jẹ́ ẹrú tàbí òmìnira.+  Pẹ̀lúpẹ̀lù, ẹ̀yin ọ̀gá, ẹ máa ṣe ohun kan náà fún wọn, ní fífa ọwọ́ ìhalẹ̀mọ́ni sẹ́yìn,+ nítorí ẹ mọ̀ pé Ọ̀gá wọn àti tiyín+ ń bẹ ní ọ̀run, kò sì sí ojúsàájú+ kankan lọ́dọ̀ rẹ̀. 10  Lákòótán, ẹ máa bá a lọ ní gbígba agbára+ nínú Olúwa àti nínú agbára ńlá+ okun rẹ̀. 11  Ẹ gbé ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ìhámọ́ra ogun+ láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wọ̀, kí ẹ bàa lè dúró gbọn-in gbọn-in lòdì sí àwọn ètekéte+ Èṣù; 12  nítorí àwa ní gídígbò kan,+ kì í ṣe lòdì sí ẹ̀jẹ̀ àti ẹran ara, bí kò ṣe lòdì sí àwọn alákòóso,+ lòdì sí àwọn aláṣẹ,+ lòdì sí àwọn olùṣàkóso ayé+ òkùnkùn yìí, lòdì sí àwọn agbo ọmọ ogun ẹ̀mí burúkú+ ní àwọn ibi ọ̀run. 13  Ní tìtorí èyí, ẹ gbé ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ìhámọ́ra ogun láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run,+ kí ẹ bàa lè dúró tiiri ní ọjọ́ burúkú náà, lẹ́yìn tí ẹ bá ti ṣe ohun gbogbo kínníkínní, kí ẹ sì lè dúró gbọn-in gbọn-in.+ 14  Nítorí náà, ẹ dúró gbọn-in gbọn-in pẹ̀lú abẹ́nú yín ti a fi òtítọ́+ dì lámùrè,+ kí ẹ sì gbé àwo ìgbàyà ti òdodo wọ̀,+ 15  àti pẹ̀lú ẹsẹ̀ yín+ tí a fi ohun ìṣiṣẹ́ ìhìn rere àlàáfíà wọ̀ ní bàtà.+ 16  Lékè ohun gbogbo, ẹ gbé apata ńlá ti ìgbàgbọ́,+ èyí tí ẹ ó lè fi paná gbogbo ohun ọṣẹ́ oníná ti ẹni burúkú náà.+ 17  Pẹ̀lúpẹ̀lù, ẹ tẹ́wọ́ gba àṣíborí+ ìgbàlà, àti idà+ ẹ̀mí,+ èyíinì ni, ọ̀rọ̀ Ọlọ́run,+ 18  lẹ́sẹ̀ kan náà, pẹ̀lú gbogbo oríṣi àdúrà+ àti ìrawọ́ ẹ̀bẹ̀, kí ẹ máa bá a lọ ní gbígbàdúrà ní gbogbo ìgbà nínú ẹ̀mí.+ Àti pé fún ète yẹn, ẹ wà lójúfò pẹ̀lú gbogbo àìyẹsẹ̀ àti pẹ̀lú ìrawọ́ ẹ̀bẹ̀ nítorí gbogbo ẹni mímọ́, 19  àti fún èmi pẹ̀lú, kí a lè fún mi ní agbára láti sọ̀rọ̀+ pẹ̀lú líla ẹnu mi, pẹ̀lú òmìnira ọ̀rọ̀ sísọ+ láti sọ àṣírí ọlọ́wọ̀ ti ìhìn rere di mímọ̀,+ 20  èyí tí mo tìtorí rẹ̀ ń ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí ikọ̀+ tí a fi ẹ̀wọ̀n dè; kí n lè máa sọ̀rọ̀ ní ìsopọ̀ pẹ̀lú rẹ̀ láìṣojo bí ó ti yẹ kí n máa sọ̀rọ̀.+ 21  Wàyí o, kí ẹ̀yin pẹ̀lú lè mọ̀ nípa àwọn àlámọ̀rí mi, ní ti bí mo ti ń ṣe, Tíkíkù,+ arákùnrin olùfẹ́ ọ̀wọ́n àti olùṣòtítọ́ òjíṣẹ́ nínú Olúwa, yóò sọ ohun gbogbo di mímọ̀ fún yín.+ 22  Èmi ń rán an sí yín fún ète yìí gan-an, kí ẹ lè mọ̀ nípa àwọn ohun tí ó kàn wá, kí ó sì lè tu ọkàn-àyà yín nínú.+ 23  Kí àwọn ará ní àlàáfíà àti ìfẹ́ pẹ̀lú ìgbàgbọ́ láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run Baba àti Jésù Kristi Olúwa. 24  Kí inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí+ wà pẹ̀lú gbogbo àwọn tí ó nífẹ̀ẹ́ Olúwa wa Jésù Kristi nínú ìwà àìdíbàjẹ́.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé