Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Éfésù 5:1-33

5  Nítorí náà, ẹ di aláfarawé Ọlọ́run,+ gẹ́gẹ́ bí àwọn ọmọ tí í ṣe olùfẹ́ ọ̀wọ́n,  kí ẹ sì máa bá a lọ ní rírìn nínú ìfẹ́,+ gan-an gẹ́gẹ́ bí Kristi pẹ̀lú ti nífẹ̀ẹ́ yín,+ tí ó sì jọ̀wọ́ ara rẹ̀ lọ́wọ́ fún yín gẹ́gẹ́ bí ọrẹ ẹbọ+ àti ẹbọ sí Ọlọ́run fún òórùn tí ń run dídùn.+  Kí a má tilẹ̀ mẹ́nu kan àgbèrè+ àti ìwà àìmọ́ onírúurú gbogbo tàbí ìwà ìwọra+ láàárín yín,+ gẹ́gẹ́ bí ó ti yẹ àwọn ènìyàn mímọ́;+  bẹ́ẹ̀ náà ni ìwà tí ń tini lójú+ tàbí ọ̀rọ̀ òmùgọ̀ tàbí ìṣẹ̀fẹ̀ rírùn,+ àwọn ohun tí kò yẹ, ṣùgbọ́n kàkà bẹ́ẹ̀ ìdúpẹ́.+  Nítorí ẹ mọ èyí, ní mímọ̀ ọ́n dájú fúnra yín, pé kò sí àgbèrè kankan+ tàbí aláìmọ́ tàbí oníwọra+—èyí tí ó túmọ̀ sí jíjẹ́ abọ̀rìṣà—tí ó ní ogún èyíkéyìí nínú ìjọba Kristi àti ti Ọlọ́run.+  Ẹ má ṣe jẹ́ kí ènìyàn kankan fi ọ̀rọ̀ òfìfo tàn yín jẹ,+ nítorí pé nítorí àwọn nǹkan tí a ti sọ ṣáájú wọ̀nyí ni ìrunú Ọlọ́run ṣe ń bọ̀ wá sórí àwọn ọmọ àìgbọ́ràn.+  Nítorí náà, ẹ má ṣe di alábàápín pẹ̀lú wọn;+  nítorí pé ẹ jẹ́ òkùnkùn nígbà kan rí,+ ṣùgbọ́n ẹ jẹ́ ìmọ́lẹ̀+ nísinsìnyí ní ìsopọ̀ pẹ̀lú Olúwa. Ẹ máa bá a lọ ní rírìn gẹ́gẹ́ bí ọmọ ìmọ́lẹ̀,  nítorí pé èso ìmọ́lẹ̀ ní gbogbo onírúurú ohun rere àti òdodo àti òtítọ́ nínú.+ 10  Ẹ máa bá a nìṣó ní wíwádìí ohun tí ó ṣe ìtẹ́wọ́gbà+ fún Olúwa dájú; 11  ẹ sì jáwọ́ nínú ṣíṣàjọpín+ pẹ̀lú wọn nínú àwọn iṣẹ́ aláìléso tí ó jẹ́ ti òkùnkùn,+ ṣùgbọ́n, kàkà bẹ́ẹ̀, àní kí ẹ máa fi ìbáwí tọ́ wọn sọ́nà,+ 12  nítorí pé ó ń tini lójú pàápàá láti ṣèròyìn àwọn ohun tí ń ṣẹlẹ̀ ní ìkọ̀kọ̀ láti ọwọ́ wọn.+ 13  Wàyí o, gbogbo nǹkan tí a ń fi ìbáwí tọ́ sọ́nà+ ni ìmọ́lẹ̀ ń fi hàn kedere, nítorí pé gbogbo ohun tí a ń fi hàn kedere+ jẹ́ ìmọ́lẹ̀. 14  Nítorí náà ni ó ṣe wí pé: “Jí,+ ìwọ olóorun, sì dìde láti inú òkú,+ Kristi yóò sì tàn+ sórí rẹ.” 15  Nítorí náà, ẹ máa ṣọ́ra lójú méjèèjì pé bí ẹ ṣe ń rìn+ kì í ṣe gẹ́gẹ́ bí aláìlọ́gbọ́n ṣùgbọ́n gẹ́gẹ́ bí ọlọ́gbọ́n, 16  ní ríra àkókò tí ó rọgbọ+ padà fún ara yín, nítorí pé àwọn ọjọ́ burú.+ 17  Ní tìtorí èyí, ẹ ṣíwọ́ dídi aláìlọ́gbọ́n-nínú, ṣùgbọ́n ẹ máa bá a lọ ní ríróye+ ohun tí ìfẹ́+ Jèhófà jẹ́. 18  Pẹ̀lúpẹ̀lù, ẹ má ṣe máa mu wáìnì ní àmupara,+ nínú èyí tí ìwà wọ̀bìà wà,+ ṣùgbọ́n ẹ máa kún fún ẹ̀mí,+ 19  ẹ máa fi àwọn sáàmù+ àti ìyìn+ sí Ọlọ́run àti àwọn orin ẹ̀mí bá ara yín sọ̀rọ̀, kí ẹ máa kọrin,+ kí ẹ sì máa fi ohùn orin+ gbè é nínú ọkàn-àyà yín sí Jèhófà, 20  ní orúkọ Olúwa wa Jésù Kristi kí ẹ máa fi ọpẹ́+ fún Baba àti Ọlọ́run wa nígbà gbogbo nítorí ohun gbogbo. 21  Ẹ wà ní ìtẹríba fún ara yín lẹ́nì kìíní-kejì+ nínú ìbẹ̀rù Kristi. 22  Kí àwọn aya wà ní ìtẹríba+ fún àwọn ọkọ wọn gẹ́gẹ́ bí fún Olúwa, 23  nítorí pé ọkọ ni orí aya rẹ̀+ gẹ́gẹ́ bí Kristi pẹ̀lú ti jẹ́ orí ìjọ,+ bí òun ti jẹ́ olùgbàlà ara yìí. 24  Ní ti tòótọ́, gẹ́gẹ́ bí ìjọ ti wà ní ìtẹríba fún Kristi, bẹ́ẹ̀ ni kí àwọn aya pẹ̀lú wà fún àwọn ọkọ wọn nínú ohun gbogbo.+ 25  Ẹ̀yin ọkọ, ẹ máa bá a lọ ní nínífẹ̀ẹ́ àwọn aya yín,+ gan-an gẹ́gẹ́ bí Kristi pẹ̀lú ti nífẹ̀ẹ́ ìjọ, tí ó sì jọ̀wọ́ ara rẹ̀ lọ́wọ́ fún un,+ 26  kí ó lè sọ ọ́ di mímọ́,+ ní wíwẹ̀ ẹ́ mọ́ pẹ̀lú ìwẹ̀ omi nípasẹ̀ ọ̀rọ̀ náà,+ 27  kí ó lè mú ìjọ wá síwájú ara rẹ̀ nínú ìdángbinrin rẹ̀,+ láìní èérí kan tàbí ìhunjọ kan tàbí èyíkéyìí nínú irúfẹ́ nǹkan bẹ́ẹ̀, ṣùgbọ́n pé kí ó lè jẹ́ mímọ́ àti láìsí àbààwọ́n.+ 28  Lọ́nà yìí, ó yẹ kí àwọn ọkọ máa nífẹ̀ẹ́ àwọn aya wọn gẹ́gẹ́ bí ara àwọn fúnra wọn. Ẹni tí ó bá nífẹ̀ẹ́ aya rẹ̀ nífẹ̀ẹ́ ara rẹ̀, 29  nítorí pé kò sí ènìyàn kankan tí ó jẹ́ kórìíra ara òun fúnra rẹ̀; ṣùgbọ́n a máa bọ́ ọ, a sì máa ṣìkẹ́ rẹ̀,+ gẹ́gẹ́ bí Kristi pẹ̀lú ti ń ṣe sí ìjọ, 30  nítorí àwa jẹ́ ẹ̀yà ara rẹ̀.+ 31  “Fún ìdí yìí, ọkùnrin yóò fi baba rẹ̀ àti ìyá rẹ̀ sílẹ̀, yóò sì fà mọ́ aya rẹ̀, àwọn méjèèjì yóò sì di ara kan.”+ 32  Àṣírí ọlọ́wọ̀+ yìí ga lọ́lá. Wàyí o, èmi ń sọ̀rọ̀ nípa Kristi àti ìjọ.+ 33  Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, pẹ̀lúpẹ̀lù, kí olúkúlùkù yín lẹ́nì kọ̀ọ̀kan máa nífẹ̀ẹ́ aya rẹ̀+ bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ó ṣe nífẹ̀ẹ́ ara rẹ̀; ní ọwọ́ kejì ẹ̀wẹ̀, kí aya ní ọ̀wọ̀ jíjinlẹ̀+ fún ọkọ rẹ̀.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé