Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

Éfésù 4:1-32

4  Nítorí náà, èmi, ẹlẹ́wọ̀n+ nínú Olúwa, pàrọwà fún yín láti máa rìn lọ́nà tí ó yẹ+ ìpè tí a fi pè yín,+  pẹ̀lú ìrẹ̀lẹ̀ pátápátá ti èrò inú+ àti ìwà tútù, pẹ̀lú ìpamọ́ra,+ ní fífaradà á fún ara yín lẹ́nì kìíní-kejì nínú ìfẹ́,+  kí ẹ máa fi taratara sakun láti máa pa ìṣọ̀kanṣoṣo ẹ̀mí mọ́ nínú ìdè asonipọ̀ṣọ̀kan ti àlàáfíà.+  Ara kan+ ní ń bẹ, àti ẹ̀mí kan,+ àní gẹ́gẹ́ bí a ti pè yín nínú ìrètí kan ṣoṣo+ tí a pè yín sí;  Olúwa kan,+ ìgbàgbọ́ kan,+ ìbatisí kan;+  Ọlọ́run kan+ àti Baba gbogbo ènìyàn, tí ń bẹ lórí ohun gbogbo, tí ó sì la ohun gbogbo já, tí ó sì ń bẹ nínú ohun gbogbo.  Wàyí o, olúkúlùkù wa ni a fún ní inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí+ ní ìbámu pẹ̀lú bí Kristi ṣe díwọ̀n ẹ̀bùn ọ̀fẹ́ náà fúnni.+  Nítorí náà ni ó ṣe wí pé: “Nígbà tí ó gòkè lọ sí ibi gíga lókè, ó kó àwọn òǹdè lọ; ó fúnni ní àwọn ẹ̀bùn [tí ó jẹ́] ènìyàn.”+  Wàyí o, gbólóhùn ọ̀rọ̀ náà “ó gòkè,”+ kí ni ó túmọ̀ sí bí kò ṣe pé ó tún sọ̀ kalẹ̀ sí àwọn ẹkùn ilẹ̀ ìsàlẹ̀, èyíinì ni, ilẹ̀ ayé?+ 10  Ẹni náà gan-an tí ó sọ̀ kalẹ̀ ni ẹni tí ó tún gòkè+ jìnnà ré kọjá gbogbo ọ̀run,+ kí ó lè fi ẹ̀kúnrẹ́rẹ́+ fún ohun gbogbo. 11  Ó sì fúnni ní àwọn kan gẹ́gẹ́ bí àpọ́sítélì,+ àwọn kan gẹ́gẹ́ bí wòlíì,+ àwọn kan gẹ́gẹ́ bí ajíhìnrere,+ àwọn kan gẹ́gẹ́ bí olùṣọ́ àgùntàn àti olùkọ́,+ 12  láti lè ṣe ìtọ́sọ́nàpadà+ àwọn ẹni mímọ́, fún iṣẹ́ òjíṣẹ́, fún gbígbé ara Kristi ró,+ 13  títí gbogbo wa yóò fi dé ìṣọ̀kanṣoṣo nínú ìgbàgbọ́ àti nínú ìmọ̀ pípéye nípa Ọmọ Ọlọ́run, tí a ó fi di géńdé+ ọkùnrin, tí a ó fi dé orí ìwọ̀n ìdàgbàsókè tí ó jẹ́ ti ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ Kristi;+ 14  kí a má bàa tún jẹ́ ìkókó mọ́, tí a ń bì kiri+ gẹ́gẹ́ bí nípasẹ̀ àwọn ìgbì òkun, tí a sì ń gbé síhìn-ín sọ́hùn-ún nípasẹ̀ gbogbo ẹ̀fúùfù ẹ̀kọ́+ nípasẹ̀ ìwà àgálámàṣà+ àwọn ènìyàn, nípasẹ̀ àlùmọ̀kọ́rọ́yí nínú dídọ́gbọ́n hùmọ̀ ìṣìnà. 15  Ṣùgbọ́n ní sísọ òtítọ́,+ ẹ jẹ́ kí a fi ìfẹ́ dàgbà sókè+ nínú ohun gbogbo sínú ẹni tí í ṣe orí,+ Kristi. 16  Láti ọ̀dọ̀ rẹ̀ ni gbogbo ara náà,+ nípa síso wọ́n pọ̀ ní ìṣọ̀kan àti mímú kí wọ́n fọwọ́ sowọ́ pọ̀ nípasẹ̀ gbogbo oríkèé tí ń pèsè ohun tí a nílò, ní ìbámu pẹ̀lú ìṣiṣẹ́ olúkúlùkù ẹ̀yà ara kọ̀ọ̀kan ní ìwọ̀n yíyẹ, ń mú kí ara náà dàgbà fún gbígbé ara rẹ̀ ró nínú ìfẹ́.+ 17  Nítorí náà, èyí ni mo ń wí, tí mo sì ń jẹ́rìí sí nínú Olúwa, pé kí ẹ má ṣe máa bá a lọ mọ́ ní rírìn gẹ́gẹ́ bí àwọn orílẹ̀-èdè+ pẹ̀lú ti ń rìn nínú àìlérè èrò inú wọn,+ 18  bí wọ́n ti wà nínú òkùnkùn ní ti èrò orí,+ tí a sì sọ wọ́n di àjèjì+ sí ìyè tí ó jẹ́ ti Ọlọ́run, nítorí àìmọ̀kan+ tí ń bẹ nínú wọn, nítorí yíyigbì+ ọkàn-àyà wọn. 19  Níwọ̀n bí wọ́n ti wá ré kọjá gbogbo agbára òye ìwà rere,+ wọ́n fi ara wọn fún ìwà àìníjàánu+ láti máa fi ìwà ìwọra+ hu onírúurú ìwà àìmọ́ gbogbo.+ 20  Ṣùgbọ́n ẹ̀yin kò kẹ́kọ̀ọ́ Kristi bẹ́ẹ̀,+ 21  bí ó bá jẹ́ pé, ní tòótọ́ ni ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀, tí a sì tipasẹ̀ rẹ̀ kọ́ yín,+ gan-an gẹ́gẹ́ bí òtítọ́+ ti wà nínú Jésù, 22  kí ẹ bọ́ ògbólógbòó àkópọ̀ ìwà sílẹ̀,+ èyí tí ó bá ipa ọ̀nà ìwà yín àtijọ́ ṣe déédéé, tí a sì ń sọ di ìbàjẹ́+ ní ìbámu pẹ̀lú àwọn ìfẹ́-ọkàn rẹ̀ atannijẹ;+ 23  ṣùgbọ́n kí ẹ di tuntun nínú ipá tí ń mú èrò inú yín ṣiṣẹ́,+ 24  kí ẹ sì gbé àkópọ̀ ìwà tuntun+ wọ̀,+ èyí tí a dá+ ní ìbámu pẹ̀lú ìfẹ́ Ọlọ́run nínú òdodo tòótọ́+ àti ìdúróṣinṣin. 25  Nítorí náà, nísinsìnyí tí ẹ ti fi èké ṣíṣe sílẹ̀,+ kí olúkúlùkù yín máa bá aládùúgbò rẹ̀ sọ òtítọ́,+ nítorí ẹ̀yà ara tí ó jẹ́ ti ara wa lẹ́nì kìíní-kejì ni wá.+ 26  Ẹ fi ìrunú hàn, síbẹ̀ kí ẹ má ṣẹ̀;+ ẹ má ṣe jẹ́ kí oòrùn wọ̀ bá yín nínú ipò ìbínú,+ 27  bẹ́ẹ̀ ni kí ẹ má ṣe fi àyè sílẹ̀ fún Èṣù.+ 28  Kí ẹni tí ń jalè má jalè mọ́,+ ṣùgbọ́n kàkà bẹ́ẹ̀, kí ó máa ṣe iṣẹ́ àṣekára, kí ó máa fi ọwọ́ rẹ̀ ṣe ohun tí ó jẹ́ iṣẹ́ rere,+ kí ó lè ní nǹkan láti pín fún ẹni tí ó wà nínú àìní.+ 29  Kí àsọjáde jíjẹrà má ti ẹnu yín jáde,+ bí kò ṣe àsọjáde yòówù tí ó dára fún gbígbéniró bí àìní bá ṣe wà, kí ó lè fi ohun tí ó ṣeni lóore fún àwọn olùgbọ́.+ 30  Pẹ̀lúpẹ̀lù, ẹ má ṣe máa kó ẹ̀dùn-ọkàn bá ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run,+ èyí tí a fi fi èdìdì dì yín+ fún ọjọ́ ìtúsílẹ̀ nípasẹ̀ ìràpadà.+ 31  Kí ẹ mú gbogbo ìwà kíkorò onínú burúkú+ àti ìbínú àti ìrunú àti ìlọgun àti ọ̀rọ̀ èébú+ kúrò lọ́dọ̀ yín pa pọ̀ pẹ̀lú gbogbo ìwà búburú.+ 32  Ṣùgbọ́n kí ẹ di onínúrere+ sí ara yín lẹ́nì kìíní-kejì, ní fífi ìyọ́nú oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ hàn,+ kí ẹ máa dárí ji ara yín fàlàlà gan-an gẹ́gẹ́ bí Ọlọ́run pẹ̀lú ti tipasẹ̀ Kristi dárí jì yín fàlàlà.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé