Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Éfésù 3:1-21

3  Ní tìtorí èyí, èmi, Pọ́ọ̀lù, ẹlẹ́wọ̀n+ Kristi Jésù nítorí yín, ẹ̀yin ènìyàn àwọn orílẹ̀-èdè+  bí ẹ̀yin, ní ti gidi, bá ti gbọ́ nípa iṣẹ́ ìríjú+ inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí Ọlọ́run tí a fi fún mi nítorí yín,  pé lọ́nà ìṣípayá kan ni a fi sọ àṣírí ọlọ́wọ̀ náà di mímọ̀ fún mi,+ gan-an gẹ́gẹ́ bí mo ti kọ̀wé ní ṣókí ní ìṣáájú.  Lójú èyí, nígbà tí ẹ bá ka èyí, ẹ ó lè mọ ìfinúmòye+ tí mo ní nínú àṣírí ọlọ́wọ̀+ ti Kristi.  Ní àwọn ìran mìíràn, àṣírí+ yìí ni a kò sọ di mímọ̀ fún àwọn ọmọ ènìyàn gẹ́gẹ́ bí a ti ṣí i payá+ nísinsìnyí fún àwọn wòlíì+ àti àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ mímọ́ nípasẹ̀ ẹ̀mí,  èyíinì ni, kí àwọn ènìyàn àwọn orílẹ̀-èdè jẹ́ àwọn ajùmọ̀jogún àti ajùmọ̀ jẹ́ ẹ̀yà ara+ àti alábàápín pẹ̀lú wa nínú ìlérí+ náà ní ìrẹ́pọ̀ pẹ̀lú Kristi Jésù nípasẹ̀ ìhìn rere.  Mo di òjíṣẹ́+ èyí gẹ́gẹ́ bí ẹ̀bùn ọ̀fẹ́ inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí Ọlọ́run tí a fi fún mi gẹ́gẹ́ bí ọ̀nà tí agbára rẹ̀ gbà ń ṣiṣẹ́.+  Èmi, ẹni tí ó kéré ju kékeré jù lọ+ nínú gbogbo ẹni mímọ́, ni a fi inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí+ yìí fún, pé kí n polongo ìhìn rere nípa àwọn ọrọ̀+ tí kò ṣeé díwọ̀n ti Kristi fún àwọn orilẹ̀-èdè,+  kí n sì mú kí àwọn ènìyàn rí bí a ṣe ń bójú tó+ àṣírí ọlọ́wọ̀+ tí a ti fi pa mọ́ tipẹ́tipẹ́ sínú Ọlọ́run, ẹni tí ó dá ohun gbogbo.+ 10  Èyí rí bẹ́ẹ̀ kí ó lè jẹ́ pé nísinsìnyí nípasẹ̀ ìjọ,+ a sọ ọ̀pọ̀ oríṣiríṣi ọgbọ́n Ọlọ́run+ di mímọ̀ fún àwọn alákòóso àti àwọn aláṣẹ+ ní àwọn ibi ọ̀run, 11  ní ìbámu pẹ̀lú ète ayérayé tí ó gbé kalẹ̀ ní ìsopọ̀ pẹ̀lú Kristi,+ Jésù Olúwa wa, 12  nípasẹ̀ ẹni tí àwa ní òmìnira ọ̀rọ̀ sísọ yìí àti ọ̀nà ìwọlé+ pẹ̀lú ìgbọ́kànlé nípasẹ̀ ìgbàgbọ́ wa nínú rẹ̀. 13  Nítorí náà, èmi béèrè pé kí ẹ má ṣe juwọ́ sílẹ̀ ní tìtorí ìpọ́njú+ mi wọ̀nyí nítorí yín, nítorí ìwọ̀nyí túmọ̀ sí ògo fún yín. 14  Ní tìtorí èyí, mo tẹ eékún mi ba+ fún Baba,+ 15  láti ọ̀dọ̀ ẹni tí olúkúlùkù ìdílé+ ní ọ̀run àti lórí ilẹ̀ ayé ti gba orúkọ rẹ̀,+ 16  kí ó bàa lè yọ̀ǹda fún yín ní ìbámu pẹ̀lú àwọn ọrọ̀+ ògo rẹ̀ kí a lè sọ yín di alágbára ńlá nínú ẹni tí ẹ jẹ́ ní inú+ pẹ̀lú agbára nípasẹ̀ ẹ̀mí rẹ̀,+ 17  láti mú kí Kristi máa gbé inú ọkàn-àyà yín pẹ̀lú ìfẹ́ nípasẹ̀ ìgbàgbọ́ yín;+ kí ẹ lè ta gbòǹgbò,+ kí ẹ sì fìdí múlẹ̀ lórí ìpìlẹ̀ náà,+ 18  kí ẹ̀yin pẹ̀lú gbogbo ẹni mímọ́ bàa lè fi èrò orí mòye+ ní kíkún ohun tí ìbú àti gígùn àti gíga àti jíjìn náà jẹ́,+ 19  àti láti mọ ìfẹ́ Kristi+ tí ó tayọ ré kọjá ìmọ̀, kí a lè fi gbogbo ẹ̀kúnrẹ́rẹ́+ tí Ọlọ́run ń fúnni kún yín. 20  Wàyí o, fún ẹni tí ó lè ṣe ju ọ̀pọ̀ yanturu ré kọjá gbogbo ohun tí a béèrè tàbí tí a wòye rò,+ ní ìbámu pẹ̀lú agbára rẹ̀ tí ń ṣiṣẹ́+ nínú wa, 21  òun ni kí ògo wà fún nípasẹ̀ ìjọ àti nípasẹ̀ Kristi Jésù títí dé gbogbo ìran láé àti láéláé.+ Àmín.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé