Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Éfésù 1:1-23

1  Pọ́ọ̀lù, àpọ́sítélì+ Kristi Jésù nípasẹ̀ ìfẹ́ Ọlọ́run,+ sí àwọn ẹni mímọ́ tí ń bẹ ní Éfésù àti àwọn olùṣòtítọ́+ ní ìrẹ́pọ̀+ pẹ̀lú Kristi Jésù:  Kí ẹ ní inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí+ àti àlàáfíà+ láti ọ̀dọ̀ Baba wa Ọlọ́run àti Jésù Kristi Olúwa.  Ìbùkún ni fún Ọlọ́run àti Baba Olúwa wa Jésù Kristi,+ nítorí ó ti fi gbogbo ìbùkún ti ẹ̀mí ní àwọn ibi ọ̀run+ bù kún wa+ ní ìrẹ́pọ̀ pẹ̀lú Kristi,  gan-an gẹ́gẹ́ bí ó ti yàn+ wá ní ìrẹ́pọ̀ pẹ̀lú rẹ̀ ṣáájú ìgbà pípilẹ̀+ ayé, kí a lè jẹ́ mímọ́ àti láìní àbààwọ́n+ níwájú rẹ̀ nínú ìfẹ́.+  Nítorí ó yàn wá ṣáájú+ sí ìsọdọmọ+ fún ara rẹ̀ nípasẹ̀ Jésù Kristi, ní ìbámu pẹ̀lú ìdùnnú rere ìfẹ́ rẹ̀,+  nínú ìyìn+ inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí rẹ̀+ ológo èyí tí ó fi dá wa lọ́lá pẹ̀lú inú rere nípasẹ̀ olólùfẹ́ rẹ̀.+  Nípasẹ̀ rẹ̀ àwa ní ìtúsílẹ̀ nípa ìràpadà nípasẹ̀ ẹ̀jẹ̀+ ẹni yẹn, bẹ́ẹ̀ ni, ìdáríjì+ àwọn àṣemáṣe wa, ní ìbámu pẹ̀lú ọrọ̀ inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí rẹ̀.+  Èyí ni ó mú kí ó pọ̀ gidigidi sọ́dọ̀ wa nínú ọgbọ́n+ àti agbára ìmòye rere gbogbo,  ní ti pé ó sọ àṣírí ọlọ́wọ̀+ ìfẹ́ rẹ̀ di mímọ̀ fún wa. Ó jẹ́ ní ìbámu pẹ̀lú ìdùnnú rere rẹ̀ èyí tí ó pète nínú ara rẹ̀+ 10  fún iṣẹ́ àbójútó+ kan ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ àwọn àkókò tí a yàn kalẹ̀,+ èyíinì ni, láti tún kó ohun gbogbo jọpọ̀+ nínú Kristi,+ àwọn ohun tí ń bẹ ní ọ̀run+ àti àwọn ohun tí ń bẹ lórí ilẹ̀ ayé.+ Bẹ́ẹ̀ ni, nínú rẹ̀, 11  ní ìrẹ́pọ̀ pẹ̀lú ẹni tí a tún yàn wá fún gẹ́gẹ́ bí àwọn ajogún,+ ní ti pé a yàn wá ṣáájú gẹ́gẹ́ bí ète ẹni tí ń mú ohun gbogbo ṣiṣẹ́ ní ìbámu pẹ̀lú ọ̀nà tí ìfẹ́ rẹ̀ pinnu,+ 12  kí àwa lè sìn fún ìyìn ògo rẹ̀,+ àwa tí a jẹ́ àkọ́kọ́ láti nírètí nínú Kristi.+ 13  Ṣùgbọ́n ẹ̀yin pẹ̀lú nírètí nínú rẹ̀ lẹ́yìn tí ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ òtítọ́ náà,+ ìhìn rere nípa ìgbàlà yín.+ Nípasẹ̀ rẹ̀ pẹ̀lú, lẹ́yìn tí ẹ gbà gbọ́, a fi èdìdì dì yín+ pẹ̀lú ẹ̀mí mímọ́ tí a ṣèlérí,+ 14  èyí tí ó jẹ́ àmì ìdánilójú+ ṣáájú ogún wa,+ fún ète ìtúsílẹ̀ nípasẹ̀ ìràpadà+ ohun ìní [ti Ọlọ́run],+ sí ìyìn ológo rẹ̀. 15  Ìdí nìyẹn tí èmi pẹ̀lú, láti ìgbà tí mo ti gbọ́ nípa ìgbàgbọ́ tí ẹ ní nínú Jésù Olúwa àti sí gbogbo àwọn ẹni mímọ́,+ 16  èmi kò ṣíwọ́ dídúpẹ́ nítorí yín. Mo ń bá a lọ ní dídárúkọ yín nínú àwọn àdúrà mi,+ 17  pé kí Ọlọ́run Olúwa wa Jésù Kristi, Baba ògo, fún yín ní ẹ̀mí ọgbọ́n+ àti ti ìṣípayá nínú ìmọ̀ pípéye nípa rẹ̀;+ 18  bí a ti la ojú+ ọkàn-àyà yín lóye,+ kí ẹ lè mọ ohun tí ìrètí+ náà jẹ́ èyí tí ó pè yín sí, ohun tí ọrọ̀ ológo+ náà jẹ́ èyí tí ó dì mú gẹ́gẹ́ bí ogún fún àwọn ẹni mímọ́,+ 19  àti ohun tí títóbi agbára rẹ̀+ títayọ ré kọjá jẹ́ sí àwa onígbàgbọ́. Ó jẹ́ gẹ́gẹ́ bí ìṣiṣẹ́+ agbára ńlá okun rẹ̀, 20  èyí tí ó ti fi ṣiṣẹ́ nínú ọ̀ràn ti Kristi nígbà tí ó gbé e dìde kúrò nínú òkú,+ tí ó sì mú un jókòó ní ọwọ́ ọ̀tún+ rẹ̀ ní àwọn ibi ọ̀run,+ 21  lókè fíofío ré kọjá gbogbo ìjọba àti ọlá àṣẹ àti agbára àti ipò olúwa+ àti gbogbo orúkọ tí a ń dá,+ kì í ṣe nínú ètò àwọn nǹkan yìí nìkan,+ ṣùgbọ́n nínú èyí tí ń bọ̀ pẹ̀lú.+ 22  Ó tún fi ohun gbogbo sábẹ́ ẹsẹ̀ rẹ̀,+ ó sì fi í ṣe orí lórí ohun gbogbo+ fún ìjọ, 23  èyí tí ó jẹ́ ara rẹ̀,+ ẹ̀kúnrẹ́rẹ́+ ẹni tí ó kún ohun gbogbo nínú ohun gbogbo.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé