Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Ẹ́sítérì 8:1-17

8  Ní ọjọ́ yẹn, Ahasuwérúsì Ọba fún Ẹ́sítérì Ayaba ní ilé Hámánì,+ ẹni tí ń fi ẹ̀tanú hàn sí àwọn Júù;+ Módékáì alára sì wọlé wá síwájú ọba, nítorí pé Ẹ́sítérì ti sọ bí ó ti jẹ́ sí òun.+  Nígbà náà ni ọba bọ́ òrùka àmì àṣẹ+ rẹ̀ tí ó gbà kúrò lọ́wọ́ Hámánì, ó sì fi í fún Módékáì; Ẹ́sítérì sì tẹ̀ síwájú láti fi Módékáì ṣolórí ilé Hámánì.+  Jù bẹ́ẹ̀ lọ, Ẹ́sítérì tún sọ̀rọ̀ níwájú ọba, ó sì wólẹ̀ níwájú ẹsẹ̀ rẹ̀, ó sì sunkún, ó sì fi taratara bẹ̀bẹ̀+ fún ojú rere rẹ̀ láti mú búburú+ Hámánì ọmọ Ágágì kúrò àti ìpètepèrò+ rẹ̀ tí ó ti ṣe sí àwọn Júù.+  Nígbà náà ni ọba na ọ̀pá aládé wúrà+ sí Ẹ́sítérì, látàrí èyí tí Ẹ́sítérì dìde, ó sì dúró níwájú ọba.  Wàyí o, ó sọ pé: “Bí ó bá dára lójú ọba, bí mo bá sì ti rí ojú rere+ níwájú rẹ̀, tí nǹkan náà sì bẹ́tọ̀ọ́ mu níwájú ọba, jẹ́ kí a kọ̀wé láti yí àwọn ìwé àkọsílẹ̀ náà padà,+ ìpètepèrò Hámánì ọmọkùnrin Hamédátà ọmọ Ágágì,+ èyí tí ó kọ pé kí a pa àwọn Júù+ tí ó wà ní gbogbo àgbègbè abẹ́ àṣẹ ọba run.+  Nítorí báwo ni mo ṣe lè mú un mọ́ra nígbà tí mo ní láti wo ìyọnu àjálù tí yóò wá sórí àwọn ènìyàn mi, báwo sì ni mo ṣe lè mú un mọ́ra nígbà tí mo ní láti wo ìparun àwọn ìbátan mi?”  Nítorí náà, Ahasuwérúsì Ọba sọ fún Ẹ́sítérì Ayaba àti fún Módékáì tí í ṣe Júù pé: “Wò ó! Ilé Hámánì ni mo ti fi fún Ẹ́sítérì,+ òun ni wọ́n sì ti gbé kọ́ sórí òpó igi,+ nítorí ìdí náà pé ó ti na ọwọ́ rẹ̀ jáde láti gbéjà ko àwọn Júù.  Kí ẹ̀yin fúnra yín sì kọ̀wé nítorí àwọn Júù gẹ́gẹ́ bí ohun tí ó dára ní ojú ara yín ní orúkọ+ ọba, kí ẹ sì fi òrùka àmì àṣẹ ọba ṣe èdìdì sí i; nítorí ìwé tí a kọ ní orúkọ ọba, tí a sì fi òrùka àmì àṣẹ ọba ṣe èdìdì sí kò ṣée ṣe láti yí i padà.”+  Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, àwọn akọ̀wé+ ọba ni a pè ní àkókò yẹn ní oṣù kẹta, èyíinì ni, oṣù Sífánì, ní ọjọ́ kẹtàlélógún rẹ̀; ìwé kíkọ sì bẹ̀rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí gbogbo èyí tí Módékáì pa láṣẹ fún àwọn Júù àti fún àwọn baálẹ̀+ àti àwọn gómìnà àti àwọn ọmọ aládé àgbègbè abẹ́ àṣẹ tí ó wà láti Íńdíà títí dé Etiópíà, ẹ̀tà-dín-láàádóje àgbègbè abẹ́ àṣẹ,+ sí àgbègbè abẹ́ àṣẹ kọ̀ọ̀kan ní ọ̀nà-ìgbàkọ̀wé+ tirẹ̀ àti sí olúkúlùkù ènìyàn ní ahọ́n+ tirẹ̀, àti sí àwọn Júù ní ọ̀nà-ìgbàkọ̀wé tiwọn àti ní ahọ́n+ tiwọn. 10  Ó sì tẹ̀ síwájú láti kọ ọ́ ní orúkọ Ahasuwérúsì Ọba,+ ó sì fi òrùka àmì àṣẹ+ ọba dì í ní èdìdì,+ ó sì fi àwọn ìwé àkọsílẹ̀ ránṣẹ́ nípa ọwọ́ àwọn asáréjíṣẹ́ lórí ẹṣin,+ tí wọ́n ń gun ẹṣin-agangan tí a ń lò nínú iṣẹ́ ìsìn ọba, àwọn ọmọ abo ẹṣin asárétete, 11  pé ọba yọ̀ǹda fún àwọn Júù tí ó wà ní gbogbo ìlú ńlá ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ láti kó ara wọn jọpọ̀,+ kí wọ́n sì dìde dúró fún ọkàn wọn, láti pa rẹ́ ráúráú àti láti pa, kí wọ́n sì run gbogbo agbo àwọn ènìyàn náà+ àti àgbègbè abẹ́ àṣẹ tí ń fi ẹ̀tanú hàn sí wọn, àwọn ọmọ kéékèèké àti àwọn obìnrin, àti láti piyẹ́ ohun ìfiṣèjẹ wọn,+ 12  ní ọjọ́ kan ṣoṣo,+ ní gbogbo àgbègbè abẹ́ àṣẹ Ahasuwérúsì Ọba, ní ọjọ́ kẹtàlá+ oṣù kejìlá, èyíinì ni, oṣù Ádárì.+ 13  Ẹ̀dà+ ìwé náà ni a ó fi fúnni gẹ́gẹ́ bí òfin jákèjádò gbogbo àgbègbè abẹ́ àṣẹ ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀, tí a kéde fún gbogbo àwọn ènìyàn gbọ́, pé kí àwọn Júù múra sílẹ̀ de ọjọ́ yìí láti gbẹ̀san+ ara wọn lára àwọn ọ̀tá wọn. 14  Àwọn asáréjíṣẹ́ náà,+ tí wọ́n gun ẹṣin-agangan tí a ń lò nínú iṣẹ́ ìsìn ọba, jáde lọ, bí ọ̀rọ̀ ọba ti ń ta wọ́n síwájú,+ tí ó sì ń sún wọn láti sáré tete; òfin náà ni a sì gbé jáde ní Ṣúṣánì+ ilé aláruru. 15  Ní ti Módékáì, ó jáde lọ kúrò níwájú ọba nínú aṣọ ọ̀ṣọ́ ọba+ aláwọ̀ búlúù àti aṣọ ọ̀gbọ̀, pẹ̀lú adé ńlá tí a fi wúrà ṣe, àti ẹ̀yà aṣọ ìlékè àtàtà,+ àní ti irun àgùntàn tí a fi àwọ̀ àlùkò àdàpọ̀-mọ́-pupa pa láró.+ Ìlú ńlá Ṣúṣánì sì ké jáde lọ́nà híhan gan-an-ran, ó sì kún fún ìdùnnú.+ 16  Àwọn Júù sì ní ìmọ́lẹ̀ àti ayọ̀ yíyọ̀ àti ayọ̀ ńláǹlà àti ọlá. 17  Àti ní gbogbo àgbègbè abẹ́ àṣẹ ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ àti ní gbogbo ìlú ńlá ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ní ibikíbi tí ọ̀rọ̀ ọba àti òfin rẹ̀ bá dé, ayọ̀ yíyọ̀+ àti ayọ̀ ńláǹlà wà fún àwọn Júù, àkànṣe àsè+ àti ọjọ́ rere sì wà; púpọ̀ nínú àwọn ènìyàn+ ilẹ̀ náà sì ń polongo ara wọn ní Júù,+ nítorí ìbẹ̀rùbojo+ àwọn Júù ti mú wọn.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé