Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

Ẹ́sítérì 7:1-10

7  Nígbà náà ni ọba àti Hámánì+ wọlé láti bá Ẹ́sítérì Ayaba jẹ àkànṣe àsè.  Wàyí o, ọba tún sọ fún Ẹ́sítérì ní ọjọ́ kejì nígbà àkànṣe àsè wáìnì+ pé: “Kí ni ohun tí ìwọ ń tọrọ,+ Ẹ́sítérì Ayaba? Àní kí a fi fún ọ.+ Kí sì ni ìbéèrè rẹ? Títí dé ìdajì ipò ọba+—àní kí ó di ṣíṣe!”  Látàrí èyí, Ẹ́sítérì Ayaba dáhùn, ó sì wí pé: “Bí mo bá ti rí ojú rere ní ojú rẹ, ọba, bí ó bá sì dára ní ojú ọba, jẹ́ kí a fi ọkàn+ mi fún mi nípa ohun tí mo tọrọ àti àwọn ènìyàn mi+ nípa ìbéèrè mi.  Nítorí a ti tà wá,+ èmi àti àwọn ènìyàn mi, láti pa wá rẹ́ ráúráú, láti pa wá àti láti run wá.+ Wàyí o, ká ní a tà wá láti di ẹrúkùnrin lásán-làsàn+ àti ìránṣẹ́bìnrin lásán-làsàn ni, èmi ì bá dákẹ́. Ṣùgbọ́n wàhálà náà kò bá a mu nígbà tí yóò jẹ́ sí ìpalára ọba.”  Wàyí o, Ahasuwérúsì Ọba sọ, bẹ́ẹ̀ ni, ó ń bá a lọ láti sọ fún Ẹ́sítérì Ayaba pé: “Ta ni ẹni yìí,+ ibo gan-an sì ni ẹni náà wà, tí ó ki ara rẹ̀ láyà+ láti ṣe bẹ́ẹ̀?”  Nígbà náà ni Ẹ́sítérì sọ pé: “Ọkùnrin náà, elénìní+ àti ọ̀tá+ náà, ni Hámánì búburú yìí.” Ní ti Hámánì, ìpayà bá a+ nítorí ọba àti nítorí ayaba.  Ní ti ọba, ó dìde nínú ìhónú+ rẹ̀ kúrò níbi àkànṣe àsè wáìnì láti lọ sí ọgbà ààfin; Hámánì alára sì dìde dúró láti ṣe ìbéèrè fún ọkàn ara rẹ̀ lọ́wọ́ Ẹ́sítérì Ayaba,+ nítorí ó rí i pé ọba+ ti pinnu+ ohun búburú sí òun.  Ọba alára sì padà láti ọgbà ààfin sí ilé àkànṣe àsè wáìnì;+ Hámánì sì ṣubú sórí àga ìrọ̀gbọ̀kú+ lórí èyí tí Ẹ́sítérì wà. Nítorí náà, ọba wí pé: “Ìfipá bá ayaba lòpọ̀ yóò ha tún ṣẹlẹ̀ pẹ̀lú, nígbà tí mo wà nínú ilé?” Ọ̀rọ̀ náà jáde lọ láti ẹnu ọba,+ wọ́n sì bo ojú Hámánì.  Hábónà,+ ọ̀kan lára àwọn òṣìṣẹ́ ààfin+ níwájú ọba, sọ wàyí pé: “Pẹ̀lúpẹ̀lù, òpó igi+ kan wà tí Hámánì ṣe fún Módékáì, ẹni tí ó sọ̀rọ̀ rere nípa ọba,+ ó wà ní òró ní ilé Hámánì—ó ga ní àádọ́ta ìgbọ̀nwọ́.” Látàrí ìyẹn, ọba sọ pé: “Ẹ gbé e kọ́ sórí rẹ̀.”+ 10  Wọ́n sì tẹ̀ síwájú láti gbé Hámánì kọ́ sórí òpó igi+ tí ó ti pèsè sílẹ̀ fún Módékáì;+ ìhónú ọba sì rọlẹ̀.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé