Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Ẹ́sítérì 6:1-14

6  Ní òru yẹn, oorun dá lójú ọba.+ Nítorí náà, ó ní kí a mú ìwé àkọsílẹ̀+ àlámọ̀rí àwọn àkókò wá. Nípa báyìí, a wá kà wọ́n níwájú ọba.  Níkẹyìn, a rí i pé a kọ ohun tí Módékáì ròyìn+ nípa Bígítánà àti Téréṣì, òṣìṣẹ́ méjì láàfin+ ọba, àwọn olùṣọ́nà, tí wọ́n wá ọ̀nà láti gbé ọwọ́ lé Ahasuwérúsì Ọba.  Nígbà náà ni ọba wí pé: “Kí ni ọlá àti ohun ńláǹlà tí a ti ṣe fún Módékáì nítorí èyí?” Àwọn ẹmẹ̀wà ọba, àwọn òjíṣẹ́ rẹ̀, fèsì pé: “A kò tíì ṣe nǹkan kan fún un.”+  Lẹ́yìn náà, ọba wí pé: “Ta ni ó wà ní àgbàlá?” Wàyí o, Hámánì alára ti dé sí àgbàlá ìta+ ti ilé ọba láti sọ fún ọba pé kí ó gbé Módékáì kọ́ sórí òpó igi+ tí òun pèsè sílẹ̀ fún un.  Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, àwọn ẹmẹ̀wà ọba sọ fún un pé: “Hámánì+ rèé tí ó dúró ní àgbàlá.” Nítorí náà, ọba sọ pé: “Ẹ jẹ́ kí ó wọlé.”  Nígbà tí Hámánì wọlé, ọba tẹ̀ síwájú láti sọ fún un pé: “Kí ni a ó ṣe fún ọkùnrin tí ọba tìkára rẹ̀ ní inú dídùn sí láti bọlá fún?”+ Látàrí èyí, Hámánì sọ nínú ọkàn-àyà rẹ̀ pé: “Ta ni ọba yóò ní inú dídùn láti fún ní ọlá ju èmi lọ?”+  Nítorí náà, Hámánì sọ fún ọba pé: “Ní ti ọkùnrin tí ọba tìkára rẹ̀ ní inú dídùn sí láti bọlá fún,  jẹ́ kí wọ́n mú aṣọ ọ̀ṣọ́ ọba+ wá, èyí tí ọba fi máa ń wọ ara rẹ̀ àti ẹṣin tí ọba máa ń gùn,+ ní orí èyí tí a sì ti fi ìwérí ọba sí.  Sì jẹ́ kí fífi aṣọ ọ̀ṣọ́ àti ẹṣin náà sábẹ́ àbójútó ọ̀kan nínú àwọn ọ̀tọ̀kùlú ọmọ aládé ọba+ wáyé; kí wọ́n sì fi wọ ọkùnrin tí ọba tìkára rẹ̀ ní inú dídùn sí láti bọlá fún, kí wọ́n sì mú kí ó gun ẹṣin náà ní ojúde+ ìlú ńlá,+ kí wọ́n sì máa ké jáde níwájú rẹ̀ pé, ‘Bí a ti ń ṣe nìyí sí ọkùnrin tí ọba tìkára rẹ̀ ní inú dídùn sí láti bọlá fún.’”+ 10  Lójú-ẹsẹ̀, ọba sọ fún Hámánì pé: “Yára, mú aṣọ ọ̀ṣọ́ àti ẹṣin náà, gan-an gẹ́gẹ́ bí o ti wí, kí o sì ṣe bẹ́ẹ̀ fún Módékáì tí í ṣe Júù, tí ń jókòó ní ẹnubodè ọba. Má ṣe jẹ́ kí ohunkóhun lọ láìní ìmúṣẹ nínú gbogbo ohun tí o sọ.”+ 11  Hámánì sì tẹ̀ síwájú láti mú aṣọ ọ̀ṣọ́+ àti ẹṣin náà, ó sì fi wọ Módékáì,+ ó sì mú kí ó gun ẹṣin ní ojúde+ ìlú ńlá náà, ó sì ń ké jáde níwájú rẹ̀+ pé: “Bí a ti ń ṣe nìyí sí ọkùnrin tí ọba tìkára rẹ̀ ní inú dídùn sí láti bọlá fún.”+ 12  Lẹ́yìn náà, Módékáì padà sí ẹnubodè ọba.+ Ní ti Hámánì, ó lọ sí ilé rẹ̀ wéréwéré, ó ń ṣọ̀fọ̀, ó sì bo orí rẹ̀.+ 13  Hámánì sì bẹ̀rẹ̀ sí ṣèròyìn ohun gbogbo tí ó ti ṣẹlẹ̀ sí i fún Séréṣì+ aya rẹ̀ àti fún gbogbo ọ̀rẹ́ rẹ̀. Látàrí èyí, àwọn ọlọ́gbọ́n+ rẹ̀ àti Séréṣì aya rẹ̀ wí fún un pé: “Bí ó bá jẹ́ láti inú irú-ọmọ àwọn Júù ni Módékáì, iwájú ẹni tí ìwọ ti bẹ̀rẹ̀ sí ṣubú, ìwọ kì yóò borí rẹ̀, ṣùgbọ́n ìwọ yóò ṣubú níwájú rẹ̀ láìsí àní-àní.”+ 14  Bí wọ́n ti ń bá a sọ̀rọ̀ lọ́wọ́, àwọn òṣìṣẹ́ ààfin ọba dé, wọ́n sì fi ìkánjú+ tẹ̀ síwájú láti mú Hámánì lọ síbi àkànṣe àsè+ tí Ẹ́sítérì ti sè.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé