Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Ẹ́sítérì 5:1-14

5  Ó sì ṣẹlẹ̀ ní ọjọ́ kẹta+ pé Ẹ́sítérì wọ aṣọ ayaba,+ lẹ́yìn èyí tí ó mú ìdúró rẹ̀ ní àgbàlá inú lọ́hùn-ún+ ti ilé ọba ní òdì-kejì ilé ọba, nígbà tí ọba jókòó sórí ìtẹ́ ọba nínú ilé ọba tí ó wà ní òdì-kejì ẹnu ọ̀nà ilé náà.  Ó sì ṣẹlẹ̀ pé, gbàrà tí ọba rí Ẹ́sítérì Ayaba tí ó dúró ní àgbàlá, ó jèrè ojú rere+ ní ojú rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni ọba sì na ọ̀pá aládé wúrà+ tí ó wà ní ọwọ́ rẹ̀ sí Ẹ́sítérì. Wàyí o, Ẹ́sítérì sún mọ́ tòsí, ó sì fọwọ́ kan orí ọ̀pá aládé náà.  Nígbà náà ni ọba wí fún un pé: “Kí ni ìwọ ń fẹ́, Ẹ́sítérì Ayaba, kí sì ni ìbéèrè rẹ?+ Títí dé ìdajì ipò ọba+—àní kí a fi fún ọ!”  Ẹ̀wẹ̀, Ẹ́sítérì sọ pé: “Bí ó bá dára ní ojú ọba, kí ọba àti Hámánì+ wá lónìí síbi àkànṣe àsè+ tí mo ti sè fún un.”  Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, ọba sọ pé: “Ẹ mú kí Hámánì gbé ìgbésẹ̀ kíákíá+ lórí ọ̀rọ̀ Ẹ́sítérì.” Lẹ́yìn náà, ọba àti Hámánì wá síbi àkànṣe àsè tí Ẹ́sítérì sè.  Nígbà tí ó ṣe, ọba wí fún Ẹ́sítérì nígbà àkànṣe àsè wáìnì pé: “Kí ni ohun tí ìwọ ń tọrọ?+ Àní kí a yọ̀ǹda rẹ̀ fún ọ! Kí sì ni ìbéèrè rẹ? Títí dé ìdajì ipò ọba—àní kí ó di ṣíṣe!”  Ẹ́sítérì dáhùn, ó sì wí pé: “Ohun tí mo ń tọrọ àti ìbéèrè mi ni pé,  Bí mo bá rí ojú rere+ ní ojú ọba, bí ó bá sì dára lójú ọba láti yọ̀ǹda ohun tí mo ń tọrọ fún mi àti láti gbé ìgbésẹ̀ lórí ìbéèrè mi, kí ọba àti Hámánì wá síbi àkànṣe àsè tí èmi yóò sè fún wọn lọ́la, ọ̀la ni èmi yóò sì ṣe gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ ọba.”+  Nítorí náà, Hámánì jáde lọ ní ọjọ́ yẹn pẹ̀lú ìdùnnú+ àti àríyá ọkàn-àyà; ṣùgbọ́n gbàrà tí Hámánì rí Módékáì ní ẹnubodè ọba+ àti pé kò dìde,+ kò sì wárìrì ní tìtorí òun,+ Hámánì kún fún ìhónú+ lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ sí Módékáì. 10  Bí ó ti wù kí ó rí, Hámánì ń bá a nìṣó ní kíkó ara rẹ̀ níjàánu, ó sì wá sí ilé rẹ̀. Nígbà náà ni ó ránṣẹ́, ó sì sọ pé kí a mú àwọn ọ̀rẹ́ òun àti Séréṣì+ aya òun wọlé; 11  Hámánì sì bẹ̀rẹ̀ sí polongo ògo ọrọ̀+ rẹ̀ fún wọn àti bí àwọn ọmọ rẹ̀ ti pọ̀ tó níye+ àti ohun gbogbo tí ọba fi gbé e ga lọ́lá àti bí ó ṣe gbé e ga lórí àwọn ọmọ aládé àti àwọn ìránṣẹ́ ọba.+ 12  Hámánì sì ń bá a lọ láti sọ pé: “Jù bẹ́ẹ̀ lọ, Ẹ́sítérì Ayaba kò mú kí ẹnì kankan bá ọba wá síbi àkànṣe àsè tí ó ti sè bí kò ṣe èmi,+ àti lọ́la+ pẹ̀lú a ké sí èmi àti ọba láti wá sọ́dọ̀ rẹ̀. 13  Ṣùgbọ́n gbogbo èyí—kò sí ìkankan tí ó bá mi lára mu, níwọ̀n ìgbà tí mo bá ń rí Módékáì tí í ṣe Júù tí ń jókòó ní ẹnubodè ọba.” 14  Látàrí èyí, Séréṣì aya rẹ̀ àti gbogbo ọ̀rẹ́ rẹ̀ wí fún un pé: “Jẹ́ kí wọ́n ṣe òpó igi+ kan tí ó ga ní àádọ́ta ìgbọ̀nwọ́. Lẹ́yìn náà, ní òwúrọ̀,+ sọ fún ọba pé kí wọ́n gbé Módékáì kọ́ sórí rẹ̀.+ Nígbà náà, kí o bá ọba wọlé lọ síbi àkànṣe àsè náà pẹ̀lú ìdùnnú.” Nítorí náà, nǹkan yìí jọ pé ó dára+ lójú Hámánì, ó sì tẹ̀ síwájú láti mú kí a ṣe òpó igi náà.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé