Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

Ẹ́sítérì 3:1-15

3  Lẹ́yìn nǹkan wọ̀nyí, Ahasuwérúsì Ọba gbé Hámánì+ ọmọkùnrin Hamédátà ọmọ Ágágì+ ga lọ́lá, ó sì tẹ̀ síwájú láti gbé e ga,+ ó sì gbé ìtẹ́ rẹ̀ lékè ti gbogbo àwọn ọmọ aládé yòókù tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀.+  Gbogbo àwọn ìránṣẹ́ ọba tí ó wà ní ẹnubodè ọba+ sì ń tẹrí ba mọ́lẹ̀, wọ́n sì ń wólẹ̀ fún Hámánì, nítorí bẹ́ẹ̀ ni ọba ṣe pàṣẹ nípa rẹ̀. Ṣùgbọ́n ní ti Módékáì, kì í tẹrí ba mọ́lẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni kì í wólẹ̀.+  Àwọn ìránṣẹ́ ọba tí ó wà ní ẹnubodè ọba sì bẹ̀rẹ̀ sí sọ fún Módékáì pé: “Èé ṣe tí ìwọ fi ń yẹ àṣẹ ọba sílẹ̀?”+  Ó sì ṣẹlẹ̀ pé, bí wọ́n ti ń bá a sọ̀rọ̀ láti ọjọ́ dé ọjọ́, tí kò sì fetí sí wọn, nígbà náà ni wọ́n sọ fún Hámánì láti rí i bóyá àwọn àlámọ̀rí Módékáì yóò dúró;+ nítorí ó ti sọ fún wọn pé Júù ni òun.+  Wàyí o, Hámánì ń rí i pé Módékáì kì í tẹrí ba mọ́lẹ̀, kì í sì í wólẹ̀ fún òun,+ Hámánì sì kún fún ìhónú.+  Ṣùgbọ́n ó jẹ́ ohun ìtẹ́ńbẹ́lú ní ojú rẹ̀ láti gbé ọwọ́ lé Módékáì nìkan, nítorí wọ́n ti sọ fún un nípa àwọn ènìyàn Módékáì; Hámánì sì bẹ̀rẹ̀ sí wá ọ̀nà láti pa gbogbo àwọn Júù tí ó wà ní gbogbo ilẹ̀ ọba Ahasuwérúsì rẹ́ ráúráú,+ àwọn ènìyàn Módékáì.+  Ní oṣù kìíní,+ èyíinì ni, oṣù Nísàn, ní ọdún kejìlá+ Ahasuwérúsì Ọba, ẹnì kan ń ṣẹ́ Púrì,+ èyíinì ni, Kèké,+ níwájú Hámánì láti ọjọ́ dé ọjọ́ àti láti oṣù dé oṣù, dé ìkejìlá, èyíinì ni, oṣù Ádárì.+  Hámánì sì bẹ̀rẹ̀ sí sọ fún Ahasuwérúsì Ọba pé: “Àwọn ènìyàn kan wà tí a tú ká,+ tí a sì yà sọ́tọ̀ láàárín àwọn ènìyàn tí ó wà ní gbogbo àgbègbè abẹ́ àṣẹ ilẹ̀ ọba rẹ;+ òfin wọn sì yàtọ̀ sí ti gbogbo àwọn ènìyàn yòókù, wọn kì í sì í pa òfin ọba mọ́,+ kò sì bá a mu fún ọba láti jọ̀wọ́ wọn jẹ́ẹ́.  Bí ó bá dára lójú ọba, jẹ́ kí àkọsílẹ̀ kan wà pé kí á pa wọ́n run; ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá+ tálẹ́ńtì fàdákà ni èmi yóò sì san sí ọwọ́ àwọn tí yóò ṣe iṣẹ́ náà+ nípa mímú un wá sínú ibi ìṣúra ọba.” 10  Látàrí ìyẹn, ọba bọ́ òrùka+ àmì àṣẹ rẹ̀ ní ọwọ́ rẹ̀, ó sì fi í fún Hámánì+ ọmọkùnrin Hamédátà ọmọ Ágágì,+ ẹni tí ó fi ẹ̀tanú hàn sí àwọn Júù.+ 11  Ọba sì ń bá a lọ láti sọ fún Hámánì pé: “Fàdákà+ náà ni a fi fún ọ, àti àwọn ènìyàn náà pẹ̀lú, láti ṣe sí wọn gẹ́gẹ́ bí ó ti dára ní ojú rẹ.”+ 12  Àwọn akọ̀wé+ ọba ni a pè lẹ́yìn náà ní oṣù kìíní ní ọjọ́ kẹtàlá rẹ̀, àkọsílẹ̀+ sì ń bá a lọ gẹ́gẹ́ bí gbogbo èyí tí Hámánì pa láṣẹ fún àwọn baálẹ̀ ọba àti àwọn gómìnà tí wọ́n wà lórí àgbègbè abẹ́ àṣẹ+ ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀, àti àwọn ọmọ aládé àwọn ènìyàn ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀, ti àgbègbè abẹ́ àṣẹ kọ̀ọ̀kan, ní ọ̀nà-ìgbàkọ̀wé tirẹ̀,+ àti olúkúlùkù ènìyàn ní ahọ́n tirẹ̀; ní orúkọ+ Ahasuwérúsì Ọba ni a kọ ọ́, a sì fi òrùka+ àmì àṣẹ ọba ṣe èdìdì sí i. 13  Fífi àwọn lẹ́tà rán àwọn asáréjíṣẹ́+ sí gbogbo àgbègbè abẹ́ àṣẹ ọba sì wáyé, láti pa rẹ́ ráúráú, láti pa àti láti run gbogbo àwọn Júù, ọ̀dọ́kùnrin àti àgbà ọkùnrin, àwọn ọmọ kéékèèké àti àwọn obìnrin, ní ọjọ́ kan,+ ní ọjọ́ kẹtàlá oṣù kejìlá, èyíinì ni, oṣù Ádárì,+ àti láti piyẹ́ ohun ìfiṣèjẹ lọ́dọ̀ wọn.+ 14  Ẹ̀dà ìwé náà tí a ó fi fúnni gẹ́gẹ́ bí òfin+ ní gbogbo àgbègbè abẹ́ àṣẹ+ ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni a kéde fún gbogbo àwọn ènìyàn náà gbọ́, kí wọ́n lè múra sílẹ̀ de ọjọ́ yìí. 15  Àwọn asáréjíṣẹ́ náà jáde lọ, a sún wọn láti yára kánkán+ nítorí ọ̀rọ̀ ọba, òfin náà ni a sì fi fúnni ní Ṣúṣánì+ ilé aláruru. Ní ti ọba àti Hámánì, wọ́n jókòó láti mutí;+ ṣùgbọ́n ní ti ìlú ńlá Ṣúṣánì,+ ó wà nínú ìdàrúdàpọ̀y.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé