Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

Ẹ́sítérì 2:1-23

2  Lẹ́yìn nǹkan wọ̀nyí, nígbà tí ìhónú Ahasuwérúsì+ Ọba ti rọlẹ̀, ó rántí Fáṣítì+ àti ohun tí ó ṣe+ àti ohun tí a ti pinnu lòdì sí i.+  Nígbà náà ni àwọn ẹmẹ̀wà ọba, àwọn òjíṣẹ́+ rẹ̀, sọ pé: “Jẹ́ kí wọ́n wá+ àwọn ọ̀dọ́bìnrin, àwọn wúńdíá,+ tí ó lẹ́wà ní ìrísí, fún ọba,  kí ọba sì yan àwọn kọmíṣọ́nnà sípò ní gbogbo àgbègbè abẹ́ àṣẹ+ tí ń bẹ ní ilẹ̀ ọba rẹ̀, kí wọ́n sì kó gbogbo àwọn ọ̀dọ́bìnrin, àwọn wúńdíá, tí ó lẹ́wà ní ìrísí jọpọ̀, sí Ṣúṣánì ilé aláruru,+ sí ilé àwọn obìnrin tí ó wà lábẹ́ àbójútó Hégáì+ ìwẹ̀fà+ ọba, olùṣètọ́jú àwọn obìnrin; kí ṣíṣe ìwọ́ra fún wọn sì wáyé.  Ọ̀dọ́bìnrin tí ó bá sì dára lójú ọba ni yóò jẹ́ ayaba dípò Fáṣítì.”+ Nǹkan náà sì dára lójú ọba, ó sì tẹ̀ síwájú láti ṣe bẹ́ẹ̀.  Ó ṣẹlẹ̀ pé, ọkùnrin kan, tí í ṣe Júù, wà ní Ṣúṣánì+ ilé aláruru, orúkọ rẹ̀ sì ni Módékáì+ ọmọkùnrin Jáírì, ọmọkùnrin Ṣíméì, ọmọkùnrin Kíṣì, ọmọ Bẹ́ńjámínì,+  ẹni tí a mú lọ sí ìgbèkùn+ láti Jerúsálẹ́mù pẹ̀lú àwọn ènìyàn tí a kó lọ, àwọn tí a kó lọ sí ìgbèkùn pẹ̀lú Jekonáyà+ ọba Júdà, ẹni tí Nebukadinésárì+ ọba Bábílónì mú lọ sí ìgbèkùn.  Ó sì wá jẹ́ olùtọ́jú+ Hádásà, èyíinì ni, Ẹ́sítérì, ọmọbìnrin arákùnrin+ baba rẹ̀, nítorí kò ní baba, bẹ́ẹ̀ ni kò ní ìyá; ọ̀dọ́bìnrin náà sì rẹwà ní wíwò,+ ó sì lẹ́wà ní ìrísí, nígbà tí baba rẹ̀ àti ìyá rẹ̀ kú, Módékáì sì mú un ṣe ọmọbìnrin rẹ̀.  Ó sì ṣẹlẹ̀ pé, nígbà tí a gbọ́ ọ̀rọ̀ ọba àti òfin rẹ̀, nígbà tí a sì kó àwọn ọ̀dọ́bìnrin púpọ̀ jọpọ̀ sí Ṣúṣánì+ ilé aláruru lábẹ́ àbójútó Hégáì,+ nígbà náà, a mú Ẹ́sítérì lọ sí ilé ọba lábẹ́ àbójútó Hégáì olùṣètọ́jú àwọn obìnrin.  Wàyí o, ọ̀dọ́bìnrin náà dára lójú rẹ̀, tó bẹ́ẹ̀ tí ó fi jèrè inú-rere-onífẹ̀ẹ́+ níwájú rẹ̀, ó sì ṣe kánkán láti ṣe ìwọ́ra+ rẹ̀ fún un àti láti fún un ní oúnjẹ rẹ̀ ṣíṣe wẹ́kú, ó sì fún un ní àwọn àṣàyàn ọ̀dọ́bìnrin méje láti ilé ọba, ó sì tẹ̀ síwájú láti ṣí òun àti àwọn ọ̀dọ́bìnrin rẹ̀ nípò lọ sí ibi tí ó dára jù lọ ní ilé àwọn obìnrin. 10  Ẹ́sítérì kò tíì sọ nípa àwọn ènìyàn rẹ̀+ tàbí nípa àwọn ìbátan rẹ̀, nítorí Módékáì fúnra rẹ̀ ti gbé àṣẹ kalẹ̀ fún un pé kí ó má sọ.+ 11  Ní ọjọ́ dé ọjọ́, Módékáì sì ń rìn níwájú àgbàlá ilé àwọn obìnrin láti mọ̀ nípa àlàáfíà Ẹ́sítérì àti ohun tí a ń ṣe sí i. 12  Nígbà tí ó bá sì yí kan ọ̀dọ́bìnrin kọ̀ọ̀kan láti wọlé lọ bá Ahasuwérúsì Ọba lẹ́yìn tí ó ti ṣẹlẹ̀ sí i gẹ́gẹ́ bí ìlànà àwọn obìnrin fún oṣù méjìlá, nítorí bí àwọn ọjọ́ ọ̀nà-ìgbàwọ́ra wọn ṣe ń pé ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀ nìyẹn, oṣù mẹ́fà pẹ̀lú òróró òjíá+ àti oṣù mẹ́fà pẹ̀lú òróró básámù+ àti pẹ̀lú ìwọ́ra obìnrin; 13  lẹ́yìn náà, nínú àwọn ipò yìí, ọ̀dọ́bìnrin náà alára a wọlé lọ bá ọba. Ohun gbogbo tí ó bá mẹ́nu kàn ni a ó fi fún un, láti bá a wá láti ilé àwọn obìnrin sí ilé ọba.+ 14  Ní ìrọ̀lẹ́, òun alára a wọlé, àti ní òwúrọ̀, òun alára a padà sí ilé kejì ti àwọn obìnrin lábẹ́ àbójútó Ṣááṣígásì ìwẹ̀fà ọba,+ olùṣètọ́jú àwọn wáhàrì. Òun kì yóò wọlé mọ́ sọ́dọ̀ ọba àyàfi bí ọba bá ní inú dídùn sí i, tí a sì fi orúkọ pè é.+ 15  Nígbà tí ó sì yí kan Ẹ́sítérì ọmọbìnrin Ábíháílì arákùnrin òbí Módékáì, ẹni tí ó ti mú ṣe ọmọbìnrin rẹ̀,+ láti wọlé lọ bá ọba, kò béèrè ohunkóhun+ àyàfi ohun tí Hégáì+ ìwẹ̀fà ọba, olùṣètọ́jú àwọn obìnrin, tẹ̀ síwájú láti mẹ́nu kàn (ní gbogbo àkókò yìí, Ẹ́sítérì ń bá a lọ ní jíjèrè ojú rere ní ojú gbogbo àwọn tí ó bá rí i).+ 16  Nígbà náà ni a mú Ẹ́sítérì lọ sọ́dọ̀ Ahasuwérúsì Ọba ní ilé ọba ní oṣù kẹwàá, èyíinì ni, oṣù Tébétì, ní ọdún keje+ ìgbà ìjọba rẹ̀. 17  Ọba sì wá nífẹ̀ẹ́ Ẹ́sítérì ju gbogbo àwọn obìnrin yòókù lọ, bẹ́ẹ̀ ni ó sì jèrè ojú rere àti inú-rere-onífẹ̀ẹ́ púpọ̀ sí i níwájú rẹ̀ ju gbogbo àwọn wúńdíá yòókù.+ Ó sì tẹ̀ síwájú láti fi ìwérí ayaba sí i ní orí, ó sì fi í ṣe ayaba+ dípò Fáṣítì. 18  Ọba sì bẹ̀rẹ̀ sí se àkànṣe àsè ńlá fún gbogbo àwọn ọmọ aládé rẹ̀ àti àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀, àkànṣe àsè Ẹ́sítérì; ó sì yọ̀ǹda ìdáríjì ọba+ fún àwọn àgbègbè abẹ́ àṣẹ, ó sì ń fúnni ní àwọn ẹ̀bùn ní ìbámu pẹ̀lú àlùmọ́ọ́nì ọba. 19  Wàyí o, nígbà tí a kó àwọn wúńdíá+ jọpọ̀ ní ìgbà kejì, Módékáì ń jókòó ní ẹnubodè ọba.+ 20  Ẹ́sítérì kò sọ nípa àwọn ìbátan rẹ̀ àti àwọn ènìyàn rẹ̀,+ gan-an gẹ́gẹ́ bí Módékáì+ ti gbé àṣẹ kalẹ̀ fún un;+ Ẹ́sítérì sì ń mú àsọjáde Módékáì ṣe, gan-an gẹ́gẹ́ bí ìgbà tí ó ṣẹlẹ̀ pé ó wà lábẹ́ àbójútó rẹ̀.+ 21  Ní ọjọ́ wọnnì, nígbà tí Módékáì ń jókòó ní ẹnubodè ọba, Bígítánì àti Téréṣì, méjì nínú àwọn òṣìṣẹ́ ààfin ọba, àwọn olùṣọ́nà, ni ìkannú wọn ru, wọ́n sì ń wá ọ̀nà láti gbé ọwọ́+ lé Ahasuwérúsì Ọba. 22  Nǹkan náà sì wá di mímọ̀ fún Módékáì, lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, ó sọ+ fún Ẹ́sítérì Ayaba. Ẹ̀wẹ̀, Ẹ́sítérì bá ọba sọ̀rọ̀ ní orúkọ Módékáì.+ 23  Nítorí náà, a wádìí ọ̀ràn náà àti ní àsẹ̀yìnwá-àsẹ̀yìnbọ̀, a rídìí rẹ̀, àwọn méjèèjì ni a sì gbé kọ́+ sórí òpó igi;+ lẹ́yìn èyí tí a kọ ọ́ sínú ìwé àlámọ̀rí+ àwọn ọjọ́ náà níwájú ọba.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé