Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

Ẹ́sítérì 1:1-22

1  Wàyí o, ó ṣẹlẹ̀ ní àwọn ọjọ́ Ahasuwérúsì,+ èyíinì ni, Ahasuwérúsì tí ń ṣàkóso gẹ́gẹ́ bí ọba láti Íńdíà títí dé Etiópíà, lórí ẹ̀tà-dín-láàádóje àgbègbè abẹ́ àṣẹ,+  pé ní ọjọ́ wọnnì, bí Ahasuwérúsì Ọba ti jókòó lórí ìtẹ́ ọba rẹ̀,+ èyí tí ó wà ní Ṣúṣánì+ ilé aláruru,+  ní ọdún kẹta ìgbà ìjọba rẹ̀, ó se àkànṣe àsè+ fún gbogbo àwọn ọmọ aládé rẹ̀ àti àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀, ẹgbẹ́ ológun Páṣíà+ àti Mídíà,+ àwọn ọ̀tọ̀kùlú+ àti àwọn ọmọ aládé ti àwọn àgbègbè abẹ́ àṣẹ níwájú ara rẹ̀,+  nígbà tí ó fi àwọn ọrọ̀+ ìjọba rẹ̀ ológo àti ọlá+ àti ẹwà títóbi rẹ̀ hàn fún ọjọ́ púpọ̀, ọgọ́sàn-án ọjọ́.  Nígbà tí ọjọ́ wọ̀nyí sì pé, ọba se àkànṣe àsè fún ọjọ́ méje fún gbogbo àwọn ènìyàn tí a rí ní Ṣúṣánì ilé aláruru, fún ẹni ńlá àti ẹni kékeré, ní àgbàlá ọgbà ààfin ọba.  Aṣọ ọ̀gbọ̀, aṣọ òwú múlọ́múlọ́ àti aláwọ̀ búlúù+ tí a fi ìjàrá aṣọ híhun àtàtà so pinpin ń bẹ, àti irun àgùntàn tí a fi àwọ̀ àlùkò àdàpọ̀-mọ́-pupa pa láró+ nínú àwọn òrùka fàdákà àti lára àwọn ọwọ̀n òkúta mábílì, àwọn àga ìrọ̀gbọ̀kú+ ti wúrà àti ti fàdákà lórí ibi tí a fi òkúta pọ́fírì àti òkúta mábílì àti péálì àti òkúta mábílì dúdú tẹ́.  Fífi àwọn ohun èlò+ tí a fi wúrà ṣe gbé [wáìnì] fúnni mu sì wáyé; àwọn ohun èlò náà sì yàtọ̀ sí ara wọn, wáìnì láti ọ̀dọ̀ ọba+ sì wà ní ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ, ní ìbámu pẹ̀lú àlùmọ́ọ́nì ọba.  Ní ti ìgbà mímu gẹ́gẹ́ bí òfin ti wí, kò sí ẹni tí ń múni lọ́ranyàn, nítorí bí ọba ti ṣètò fún olúkúlùkù ènìyàn ńlá nínú agbo ilé rẹ̀ nìyẹn, láti ṣe gẹ́gẹ́ bí gbogbo wọn lẹ́nì kọ̀ọ̀kan ti fẹ́.  Bákan náà, Fáṣítì+ Ayaba alára se àkànṣe àsè fún àwọn obìnrin ní ilé ọba tí ó jẹ́ ti Ahasuwérúsì Ọba. 10  Ní ọjọ́ keje, nígbà tí wáìnì mú kí ọkàn-àyà ọba wà nínú ipò àríyá,+ ó sọ fún Méhúmánì, Bísítà, Hábónà,+ Bígítà àti Ábágítà, Sétárì àti Kákásì, àwọn òṣìṣẹ́ méje láàfin tí ń ṣe ìránṣẹ́+ fún Ahasuwérúsì Ọba fúnra rẹ̀, 11  pé kí wọ́n mú Fáṣítì Ayaba wá nínú ìwérí ayaba síwájú ọba, láti fi ìdáralẹ́wà rẹ̀ han àwọn ènìyàn àti àwọn ọmọ aládé; nítorí tí ó lẹ́wà ní ìrísí.+ 12  Ṣùgbọ́n Fáṣítì Ayaba ń kọ̀+ ṣáá láti wá nípa ọ̀rọ̀ ọba tí a mú wá nípasẹ̀ àwọn òṣìṣẹ́ ààfin. Látàrí èyí, ìkannú ọba ru gidigidi, àní ìhónú rẹ̀ sì ru ṣùṣù nínú rẹ̀.+ 13  Ọba sì bẹ̀rẹ̀ sí sọ fún àwọn ọlọ́gbọ́n+ ènìyàn tí ó ní ìmọ̀ nípa àwọn àkókò+ (nítorí báyìí ni ọ̀ràn ọba ṣe wá síwájú gbogbo àwọn ògbóǹkangí nínú ìmọ̀ òfin àti àwọn ẹjọ́, 14  àwọn tí ó sì sún mọ́ ọn jù lọ ni Káṣénà, Ṣétárì, Ádímátà, Táṣíṣì, Mérésì, Másénà, àti Mémúkánì, àwọn ọmọ aládé méje+ ti Páṣíà àti Mídíà, tí wọ́n ní àǹfààní láti dé ọ̀dọ̀ ọba,+ tí wọ́n sì ń jókòó ní ipò kìíní nínú ìjọba) pé: 15  “Gẹ́gẹ́ bí òfin, kí ni a ó ṣe sí Fáṣítì Ayaba nítorí pé kò mú àsọjáde Ahasuwérúsì Ọba ṣe láti ẹnu àwọn òṣìṣẹ́ ààfin?” 16  Mémúkánì+ fèsì níwájú ọba àti àwọn ọmọ aládé pé: “Kì í ṣe ọba nìkan ni Fáṣítì Ayaba ṣe àìtọ́ sí,+ bí kò ṣe sí gbogbo àwọn ọmọ aládé àti sí gbogbo àwọn ènìyàn tí ó wà ní gbogbo àgbègbè abẹ́ àṣẹ Ahasuwérúsì Ọba. 17  Nítorí àlámọ̀rí ayaba yìí yóò jáde lọ sọ́dọ̀ gbogbo àwọn aya tó bẹ́ẹ̀ tí wọn yóò fi tẹ́ńbẹ́lú+ àwọn olúwa+ wọn ní ojú ara wọn, nígbà tí wọn yóò sọ pé, ‘Ahasuwérúsì Ọba alára sọ pé kí a mú Fáṣítì Ayaba wọlé wá síwájú òun, kò sì wọlé wá.’ 18  Lónìí yìí, àwọn ọmọbìnrin ọba Páṣíà àti Mídíà, tí ó sì ti gbọ́ àlámọ̀rí ayaba, yóò bá gbogbo àwọn ọmọ aládé ọba sọ̀rọ̀, ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ ìfojú tín-ín-rín àti ìkannú+ yóò sì wà. 19  Bí ó bá dára lójú ọba,+ jẹ́ kí ọ̀rọ̀ ọba jáde lọ láti ọ̀dọ̀ òun fúnra rẹ̀, sì jẹ́ kí a kọ ọ́ sára àwọn òfin+ Páṣíà àti Mídíà, kí ó má bàa kọjá lọ,+ pé Fáṣítì kò gbọ́dọ̀ wọlé wá síwájú Ahasuwérúsì Ọba; kí ọba sì fi ipò ọlá ayaba rẹ̀ fún ọ̀gbà rẹ̀, obìnrin tí ó sàn jù ú lọ. 20  Àṣẹ àgbékalẹ̀ ọba tí òun yóò ṣe sì ni kí a gbọ́ ní gbogbo ilẹ̀ ọba rẹ̀ (nítorí ó pọ̀ jaburata), gbogbo àwọn aya yóò sì fi ọlá+ fún olúwa+ wọn, ẹni ńlá àti ẹni kékeré.” 21  Nǹkan náà sì dára lójú ọba+ àti àwọn ọmọ aládé, ọba sì tẹ̀ síwájú láti ṣe gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ Mémúkánì. 22  Nítorí náà, ó fi àwọn ìwé àkọsílẹ̀+ ránṣẹ́ sí gbogbo àgbègbè abẹ́ àṣẹ ọba, sí àgbègbè abẹ́ àṣẹ+ kọ̀ọ̀kan ní ọ̀nà-ìgbàkọ̀wé tirẹ̀ àti sí olúkúlùkù ènìyàn ní ahọ́n tirẹ̀, kí olúkúlùkù ọkọ máa bá a lọ ní ṣíṣe bí ọmọ aládé nínú ilé+ tirẹ̀, kí ó sì máa sọ̀rọ̀ ní ahọ́n àwọn ènìyàn tirẹ̀.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé