Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

Ẹ́sírà 9:1-15

9  Gbàrà tí a sì parí nǹkan wọ̀nyí, àwọn ọmọ aládé+ tọ̀ mí wá, wọ́n wí pé: “Àwọn ènìyàn Ísírẹ́lì àti àwọn àlùfáà àti àwọn ọmọ Léfì kò ya ara wọn sọ́tọ̀+ kúrò lọ́dọ̀ àwọn ènìyàn ilẹ̀ wọnnì ní ti àwọn ohun ìṣe-họ́ọ̀-sí+ wọn, èyíinì ni, àwọn ọmọ Kénáánì,+ àwọn ọmọ Hétì,+ àwọn Pérísì,+ àwọn ará Jébúsì,+ àwọn ọmọ Ámónì,+ àwọn ọmọ Móábù,+ àwọn ará Íjíbítì+ àti àwọn Ámórì.+  Nítorí pé wọ́n ti tẹ́wọ́ gba àwọn kan lára àwọn ọmọbìnrin wọn fún ara wọn àti fún àwọn ọmọkùnrin wọn;+ àti pé àwọn, tí í ṣe irú-ọmọ+ mímọ́, ti dà pọ̀+ mọ́ àwọn ènìyàn ilẹ̀ wọnnì, ọwọ́ àwọn ọmọ aládé àti ti àwọn ajẹ́lẹ̀ sì ni ó wà ní iwájú pátápátá+ nínú ìwà àìṣòótọ́ yìí.”  Wàyí o, gbàrà tí mo gbọ́ nípa nǹkan yìí, mo gbọn ẹ̀wù+ mi àti aṣọ àwọ̀lékè mi tí kò lápá ya, mo sì bẹ̀rẹ̀ sí fà lára irun orí+ mi àti irùngbọ̀n mi tu, mo sì jókòó tìyàlẹ́nu-tìyàlẹ́nu.+  Pẹ̀lúpẹ̀lù, wọ́n kó ara wọn jọ sọ́dọ̀ mi, tí olúkúlùkù ń wárìrì+ nítorí ọ̀rọ̀ Ọlọ́run Ísírẹ́lì lòdì sí ìwà àìṣòótọ́ àwọn ìgbèkùn, bí mo ti jókòó tìyàlẹ́nu-tìyàlẹ́nu títí di ìgbà ọrẹ ẹbọ ọkà àṣálẹ́.+  Nígbà tí ó sì di ìgbà ọrẹ ẹbọ+ ọkà àṣálẹ́, mo dìde dúró kúrò nínú ìtẹ́lógo mi, tèmi ti ẹ̀wù mi àti aṣọ àwọ̀lékè mi tí kò lápá tí ó ya sọ́tọ̀ọ̀tọ̀, mo sì wá kúnlẹ̀ lórí eékún+ mi, mo sì tẹ́ àtẹ́lẹwọ́ mi sí Jèhófà Ọlọ́run+ mi.  Mo sì bẹ̀rẹ̀ sí wí pé:+ “Ìwọ Ọlọ́run mi, ojú ń tì+ mí, ara sì ń tì+ mí láti gbé ojú mi sókè sí ọ, ìwọ Ọlọ́run mi, nítorí pé àwọn ìṣìnà+ wa pàápàá ti di púpọ̀ sí i ní orí wa, ẹ̀bi wa sì ti di ńlá, àní títí dé ọ̀run.+  Láti ọjọ́ àwọn baba ńlá+ wa ni a ti wà nínú ẹ̀bi ńláǹlà títí di òní yìí;+ ní tìtorí àwọn ìṣìnà wa sì ni a ṣe fi àwa, àní àwa fúnra wa, àwọn ọba+ wa, àwọn àlùfáà+ wa, lé àwọn ọba ilẹ̀ wọnnì lọ́wọ́ pẹ̀lú idà,+ pẹ̀lú oko òǹdè+ àti pẹ̀lú ohun tí a piyẹ́+ àti pẹ̀lú ìtìjú,+ gan-an gẹ́gẹ́ bí ó ti rí lónìí yìí.  Ǹjẹ́ nísinsìnyí, fún ìṣẹ́jú díẹ̀, ojú rere+ láti ọ̀dọ̀ Jèhófà Ọlọ́run wa ti dé, nípa ṣíṣẹ́ àwọn tí ó sá àsálà+ kù fún wa àti nípa fífún wa ní èèkàn kan ní ibi mímọ́ rẹ̀, láti mú kí ojú wa tàn,+ ìwọ Ọlọ́run wa, àti láti fún wa ní ìmúsọjí díẹ̀ nínú ipò ìsìnrú+ wa.  Nítorí pé ìránṣẹ́+ ni wá; àti pé nínú ipò ìsìnrú wa,+ Ọlọ́run wa kò fi wá sílẹ̀, ṣùgbọ́n ó nawọ́ inú-rere-onífẹ̀ẹ́ sí wa níwájú àwọn ọba Páṣíà,+ láti fún wa ní ìmúsọjí láti lè gbé ilé Ọlọ́run+ wa dìde àti láti tún àwọn ibi+ ahoro rẹ̀ ṣe àti láti fún wa ní ògiri+ òkúta ní Júdà àti ní Jerúsálẹ́mù. 10  “Ǹjẹ́ nísinsìnyí, ìwọ Ọlọ́run wa, kí ni àwa yóò wí lẹ́yìn èyí? Nítorí tí àwa ti fi àwọn àṣẹ+ rẹ sílẹ̀, 11  èyí tí ìwọ pa láṣẹ nípasẹ̀ àwọn ìránṣẹ́ rẹ wòlíì, pé, ‘Ilẹ̀ tí ẹ ń wọlé lọ láti gbà jẹ́ ilẹ̀ ìdọ̀tí nítorí ohun ìdọ̀tí àwọn ènìyàn ilẹ̀+ náà, nítorí àwọn ohun ìṣe-họ́ọ̀-sí+ wọn, èyí tí wọ́n fi kún un láti ìpẹ̀kun dé ìpẹ̀kun+ nípasẹ̀ ìwà àìmọ́+ wọn. 12  Ǹjẹ́ nísinsìnyí, àwọn ọmọbìnrin yín ni kí ẹ má ṣe fún àwọn ọmọkùnrin+ wọn, àwọn ọmọbìnrin wọn ni kí ẹ má sì tẹ́wọ́ gbà fún àwọn ọmọkùnrin yín; àti pé fún àkókò tí ó lọ kánrin, ẹ kò gbọ́dọ̀ ṣiṣẹ́ fún àlàáfíà+ wọn àti aásìkí wọn, kí ẹ bàa lè di alágbára,+ kí ẹ sì máa jẹ ire ilẹ̀ náà dájúdájú, kí ẹ sì gbà á ní tòótọ́ fún àwọn ọmọ yín fún àkókò tí ó lọ kánrin.’+ 13  Lẹ́yìn gbogbo ohun tí ó sì ti dé bá wa nítorí àwọn iṣẹ́+ búburú wa àti ẹ̀bi ńláǹlà wa—nítorí pé ìwọ fúnra rẹ, ìwọ Ọlọ́run wa, ti ka ìṣìnà+ wa sí kékeré ju bí ó ti yẹ lọ, ìwọ sì ti fún wa ní àwọn tí ó sá àsálà, bí àwọn wọ̀nyí+ 14  ǹjẹ́ ó yẹ kí a tún máa rú àwọn àṣẹ rẹ, kí a sì máa bá àwọn ènìyàn tí ń ṣe àwọn ohun ìṣe-họ́ọ̀-sí+ wọ̀nyí dána?+ Ìbínú rẹ kì yóò ha ru sókè sí wa dójú ààlà,+ tí kì yóò fi sí ẹnì kankan tí yóò ṣẹ́ kù,+ tí kì yóò sì fi sí ẹnì kankan tí yóò sá àsálà? 15  Ìwọ Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì, olódodo+ ni ìwọ, nítorí pé a ti ṣẹ́ wa kù gẹ́gẹ́ bí olùsálà bí ó ti rí lónìí yìí. Àwa rèé níwájú rẹ nínú ẹ̀bi+ wa, nítorí pé kò ṣeé ṣe láti dúró níwájú rẹ ní tìtorí èyí.”+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé