Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

Ẹ́sírà 8:1-36

8  Wàyí o, ìwọ̀nyí ni àwọn olórí àwọn ìdí ilé baba+ wọn àti àkọsílẹ̀ orúkọ+ ní ìbámu pẹ̀lú ìtàn ìlà ìdílé àwọn tí ó gòkè lọ pẹ̀lú mi kúrò ní Bábílónì ní ìgbà ìjọba Atasásítà+ Ọba:  Lára àwọn ọmọ Fíníhásì,+ Gẹ́ṣómù; lára àwọn ọmọ Ítámárì,+ Dáníẹ́lì;+ lára àwọn ọmọ Dáfídì,+ Hátúṣì;  lára àwọn ọmọ Ṣẹkanáyà, lára àwọn ọmọ Páróṣì,+ Sekaráyà, àti pẹ̀lú rẹ̀, àkọsílẹ̀ orúkọ àádọ́jọ ọkùnrin;  lára àwọn ọmọ Pahati-móábù,+ Elieho-énáì ọmọkùnrin Seraháyà, àti pẹ̀lú rẹ̀, igba ọkùnrin;  lára àwọn ọmọ Sátù,+ Ṣẹkanáyà ọmọkùnrin Jahasíẹ́lì, àti pẹ̀lú rẹ̀, ọ̀ọ́dúnrún ọkùnrin;  àti lára àwọn ọmọ Ádínì,+ Ébédì ọmọkùnrin Jónátánì, àti pẹ̀lú rẹ̀, àádọ́ta ọkùnrin;  àti lára àwọn ọmọ Élámù,+ Jeṣáyà ọmọkùnrin Ataláyà, àti pẹ̀lú rẹ̀, àádọ́rin ọkùnrin;  àti lára àwọn ọmọ Ṣẹfatáyà,+ Sebadáyà ọmọkùnrin Máíkẹ́lì, àti pẹ̀lú rẹ̀, ọgọ́rin ọkùnrin;  lára àwọn ọmọ Jóábù, Ọbadáyà ọmọkùnrin Jéhíélì, àti pẹ̀lú rẹ̀, igba ọkùnrin ó lé méjìdínlógún; 10  àti lára àwọn ọmọ Bánì,+ Ṣẹ́lómítì ọmọkùnrin Josifáyà, àti pẹ̀lú rẹ̀, ọgọ́jọ ọkùnrin; 11  àti lára àwọn ọmọ Bébáì, Sekaráyà ọmọkùnrin Bébáì,+ àti pẹ̀lú rẹ̀, ọkùnrin méjìdínlọ́gbọ̀n; 12  àti lára àwọn ọmọ Ásígádì,+ Jóhánánì ọmọkùnrin Hákátánì, àti pẹ̀lú rẹ̀, àádọ́fà ọkùnrin; 13  àti lára àwọn ọmọ Ádóníkámù,+ àwọn tí ó kẹ́yìn, ìwọ̀nyí sì ni orúkọ wọn: Élífélétì, Jéélì àti Ṣemáyà, àti pẹ̀lú wọn, ọgọ́ta ọkùnrin; 14  àti lára àwọn ọmọ Bígífáì,+ Útáì àti Sábúdì, àti pẹ̀lú wọn, àádọ́rin ọkùnrin. 15  Mo sì bẹ̀rẹ̀ sí kó wọn jọ níbi odò+ tí ń ṣàn wá sí Áháfà;+ a sì dó sí ibẹ̀ fún ọjọ́ mẹ́ta, kí n lè ṣàyẹ̀wò àwọn ènìyàn+ náà àti àwọn àlùfáà+ fínnífínní, ṣùgbọ́n n kò rí ìkankan lára àwọn ọmọ Léfì+ níbẹ̀. 16  Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, mo ránṣẹ́ pe Élíésérì, Áríélì, Ṣemáyà àti Élínátánì àti Járíbù àti Élínátánì àti Nátánì àti Sekaráyà àti Méṣúlámù, àwọn olórí, àti Jóyáríbù àti Élínátánì, àwọn olùkọ́ni.+ 17  Mo wá pa àṣẹ fún wọn nípa Ídò tí í ṣe olórí ní ibi tí a ń pè ní Kásífíà, mo sì fi ọ̀rọ̀+ sí wọn lẹ́nu pé kí wọ́n bá Ídò àti àwọn arákùnrin rẹ̀ tí í ṣe àwọn Nétínímù+ sọ̀rọ̀ ní ibi tí a ń pè ní Kásífíà, pé kí wọ́n mú àwọn òjíṣẹ́+ wá fún wa, fún ilé Ọlọ́run wa. 18  Nítorí náà, ní ìbámu pẹ̀lú ọwọ́+ rere Ọlọ́run wa lára wa, wọ́n mú ọkùnrin kan tí ó ní ọgbọ́n inú+ wá fún wa, láti ara àwọn ọmọ Máhílì+ ọmọ-ọmọ Léfì+ ọmọkùnrin Ísírẹ́lì, èyíinì ni, Ṣerebáyà+ àti àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ àti àwọn arákùnrin rẹ̀, méjìdínlógún; 19  àti Haṣabáyà, àti pẹ̀lú rẹ̀, Jeṣáyà láti ara àwọn ọmọ Mérárì,+ àwọn arákùnrin rẹ̀, àti àwọn ọmọkùnrin wọn, ogún. 20  Àti láti ara àwọn Nétínímù, àwọn tí Dáfídì àti àwọn ọmọ aládé fi fún iṣẹ́ ìsìn àwọn ọmọ Léfì, okòó-lérúgba àwọn Nétínímù, gbogbo àwọn tí a yàn sọ́tọ̀ nípa orúkọ wọn. 21  Nígbà náà ni mo pòkìkí ààwẹ̀ níbẹ̀ níbi Odò Áháfà, láti rẹ ara wa sílẹ̀+ níwájú Ọlọ́run wa, láti wá ọ̀nà títọ́+ láti ọ̀dọ̀ rẹ̀ fún àwa àti fún àwọn ọmọ wa kéékèèké+ àti fún gbogbo ẹrù wa. 22  Nítorí pé ó tì mí lójú láti béèrè fún ẹgbẹ́ ológun+ àti àwọn ẹlẹ́ṣin+ lọ́wọ́ ọba láti ràn wá lọ́wọ́ láti dojú kọ ọ̀tá lójú ọ̀nà, nítorí àwa ti sọ fún ọba pé: “Ọwọ́+ Ọlọ́run wa ń bẹ lára gbogbo àwọn tí ń wá a fún rere,+ ṣùgbọ́n okun rẹ̀ àti ìbínú+ rẹ̀ ń bẹ lòdì sí gbogbo àwọn tí ó fi í sílẹ̀.”+ 23  Nítorí náà, a gbààwẹ̀,+ a sì ṣe ìbéèrè+ lọ́dọ̀ Ọlọ́run wa nípa èyí, bẹ́ẹ̀ ni ó sì jẹ́ kí a pàrọwà+ sí òun. 24  Mo wá ya àlùfáà méjìlá sọ́tọ̀ kúrò lára àwọn olórí, àwọn wọ̀nyí ni, Ṣerebáyà,+ Haṣabáyà,+ àti pẹ̀lú wọn, mẹ́wàá lára àwọn arákùnrin wọn. 25  Mo sì tẹ̀ síwájú láti wọn fàdákà àti wúrà àti àwọn nǹkan èlò+ fún wọn, ọrẹ fún ilé Ọlọ́run wa, èyí tí ọba+ àti àwọn agbani-nímọ̀ràn+ rẹ̀ àti àwọn ọmọ aládé rẹ̀ àti gbogbo ọmọ Ísírẹ́lì+ tí a rí ti fi ṣe ìtọrẹ. 26  Nípa báyìí, mo wọn àádọ́ta-lé-lẹ́gbẹ̀ta tálẹ́ńtì fàdákà+ sí ọwọ́ wọn àti ọgọ́rùn-ún nǹkan èlò fàdákà tí ó tó tálẹ́ńtì méjì, àti ọgọ́rùn-ún tálẹ́ńtì wúrà, 27  àti ogún àwokòtò kéékèèké tí a fi wúrà ṣe, tí ó tó ẹgbẹ̀rún owó dáríkì àti nǹkan èlò méjì tí a fi bàbà dáradára ṣe, tí ń pọ́n yòò, tí ó fani mọ́ra bí wúrà. 28  Nígbà náà ni mo wí fún wọn pé: “Ẹ̀yin jẹ́ ohun mímọ́+ lójú Jèhófà, àwọn nǹkan èlò+ náà sì jẹ́ ohun mímọ́, fàdákà àti wúrà náà sì jẹ́ ọrẹ àfínnúfíndọ̀ṣe sí Jèhófà Ọlọ́run àwọn baba ńlá yín. 29  Ẹ wà lójúfò, kí ẹ sì máa ṣọ́ra títí ẹ ó fi wọ̀n+ wọ́n níwájú àwọn olórí àwọn àlùfáà àti àwọn ọmọ Léfì àti àwọn ọmọ aládé àwọn baba Ísírẹ́lì ní Jerúsálẹ́mù, nínú àwọn gbọ̀ngàn+ ìjẹun ti ilé Jèhófà.” 30  Àwọn àlùfáà àti àwọn ọmọ Léfì sì gba ìwọ̀n fàdákà àti wúrà àti àwọn nǹkan èlò náà, láti kó wọn wá sí Jerúsálẹ́mù sí ilé Ọlọ́run+ wa. 31  Níkẹyìn, a ṣí kúrò níbi Odò Áháfà+ ní ọjọ́ kejìlá oṣù kìíní+ láti lọ sí Jerúsálẹ́mù, àní ọwọ́ Ọlọ́run wa sì wà lára wa, tí ó fi jẹ́ pé, ó dá wa nídè+ kúrò ní àtẹ́lẹwọ́ ọ̀tá àti abadeni ní ọ̀nà. 32  Nítorí náà, a dé Jerúsálẹ́mù,+ a sì gbé níbẹ̀ fún ọjọ́ mẹ́ta. 33  Àti ní ọjọ́ kẹrin, a bẹ̀rẹ̀ sí wọn fàdákà àti wúrà+ àti àwọn nǹkan èlò+ nínú ilé Ọlọ́run wa sí ọwọ́ Mérémótì+ ọmọkùnrin Úríjà àlùfáà àti pẹ̀lú rẹ̀ Élíásárì ọmọkùnrin Fíníhásì àti pẹ̀lú wọn Jósábádì+ ọmọkùnrin Jéṣúà àti Noadáyà ọmọkùnrin Bínúì+ àwọn ọmọ Léfì, 34  nípa iye àti nípa ìwọ̀n ni gbogbo rẹ̀, lẹ́yìn èyí tí a kọ gbogbo ìwọ̀n náà sílẹ̀ ní àkókò yẹn. 35  Àwọn tí ń jáde bọ̀ láti oko òǹdè,+ àwọn ìgbèkùn tẹ́lẹ̀ rí, àwọn tìkára wọn mú àwọn ẹbọ+ sísun wá fún Ọlọ́run Ísírẹ́lì, akọ+ màlúù méjìlá fún gbogbo Ísírẹ́lì, àgbò+ mẹ́rìn-dín-lọ́gọ́rùn-ún, akọ+ ọ̀dọ́ àgùntàn mẹ́tàdínlọ́gọ́rin, òbúkọ méjìlá gẹ́gẹ́ bí ọrẹ ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀, gbogbo rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọrẹ ẹbọ sísun sí Jèhófà. 36  Nígbà náà ni a fi àwọn òfin+ ọba fún àwọn baálẹ̀+ ọba àti àwọn gómìnà+ tí ó wà ní ìkọjá Odò,+ wọ́n sì ṣèrànwọ́ fún àwọn ènìyàn+ náà àti ilé Ọlọ́run tòótọ́.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé