Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

Ẹ́sírà 7:1-28

7  Àti lẹ́yìn nǹkan wọ̀nyí, ní ìgbà ìjọba Atasásítà+ ọba Páṣíà, Ẹ́sírà+ ọmọkùnrin Seráyà+ ọmọkùnrin Asaráyà ọmọkùnrin Hilikáyà+  ọmọkùnrin Ṣálúmù+ ọmọkùnrin Sádókù ọmọkùnrin Áhítúbù+  ọmọkùnrin Amaráyà+ ọmọkùnrin Asaráyà+ ọmọkùnrin Méráótì+  ọmọkùnrin Seraháyà+ ọmọkùnrin Úsáì+ ọmọkùnrin Búkì+  ọmọkùnrin Ábíṣúà+ ọmọkùnrin Fíníhásì+ ọmọkùnrin Élíásárì+ ọmọkùnrin Áárónì+ olórí àlùfáà+  Ẹ́sírà tí a wí yìí alára gòkè lọ láti Bábílónì; ó sì jẹ́ ọ̀jáfáfá adàwékọ+ nínú òfin Mósè,+ èyí tí Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì fi fúnni, ọba sì yọ̀ǹda gbogbo ìbéèrè rẹ̀ fún un, ní ìbámu pẹ̀lú ọwọ́ Jèhófà Ọlọ́run rẹ̀ lára rẹ̀.+  Nítorí náà, àwọn kan lára àwọn ọmọ Ísírẹ́lì àti lára àwọn àlùfáà+ àti àwọn ọmọ Léfì+ àti àwọn akọrin+ àti àwọn aṣọ́bodè+ àti àwọn Nétínímù+ gòkè lọ sí Jerúsálẹ́mù ní ọdún keje Atasásítà+ Ọba.  Níkẹyìn, ó wá sí Jerúsálẹ́mù ní oṣù karùn-ún, èyíinì ni, ní ọdún keje ọba.  Nítorí pé ní ọjọ́ kìíní oṣù kìíní ni òun fúnra rẹ̀ ṣètò gígòkè lọ kúrò ní Bábílónì, ọjọ́ kìíní oṣù karùn-ún sì ni ó wá sí Jerúsálẹ́mù, ní ìbámu pẹ̀lú ọwọ́ rere Ọlọ́run rẹ̀ lára rẹ̀.+ 10  Nítorí pé Ẹ́sírà fúnra rẹ̀ ti múra ọkàn-àyà rẹ̀ sílẹ̀+ láti ṣe ìwádìí nínú òfin Jèhófà+ àti láti pa á mọ́+ àti láti máa kọ́ni+ ní ìlànà+ àti ìdájọ́ òdodo+ ní Ísírẹ́lì. 11  Èyí sì ni ẹ̀dà lẹ́tà tí Atasásítà Ọba fi fún Ẹ́sírà àlùfáà tí í ṣe adàwékọ,+ olùṣe àdàkọ ọ̀rọ̀ àwọn àṣẹ Jèhófà àti ti àwọn ìlànà rẹ̀ fún Ísírẹ́lì: 12  “Atasásítà,+ ọba àwọn ọba,+ sí Ẹ́sírà àlùfáà, olùṣe àdàkọ òfin Ọlọ́run ọ̀run:+ Kí àlàáfíà pípé+ wà. Wàyí o, 13  mo ti gbé àṣẹ ìtọ́ni+ kan jáde pé kí olúkúlùkù ẹni tí ó wà ní ilẹ̀ ọba+ mi, tí ó jẹ́ ara àwọn ènìyàn Ísírẹ́lì àti àwọn àlùfáà wọn àti àwọn ọmọ Léfì tí ó bá fẹ́ bá ọ lọ sí Jerúsálẹ́mù, kí ó lọ.+ 14  Níwọ̀n ìgbà tí ó jẹ́ pé láti iwájú ọba àti àwọn agbani-nímọ̀ràn+ rẹ̀ méje ni a ti fi àṣẹ ìtọ́ni kan ránṣẹ́ pé kí a ṣe àyẹ̀wò+ nípa Júdà àti Jerúsálẹ́mù nínú òfin+ Ọlọ́run+ rẹ tí ń bẹ ní ọwọ́ rẹ, 15  kí a sì kó fàdákà àti wúrà wá, èyí tí ọba àti àwọn agbani-nímọ̀ràn rẹ̀ ti fínnú-fíndọ̀ fi fún+ Ọlọ́run Ísírẹ́lì, ẹni tí ibùgbé rẹ̀ wà ní Jerúsálẹ́mù,+ 16  pẹ̀lú gbogbo fàdákà àti wúrà tí ìwọ bá rí ní gbogbo àgbègbè abẹ́ àṣẹ Bábílónì pa pọ̀ pẹ̀lú ẹ̀bùn àwọn ènìyàn+ náà àti àwọn àlùfáà tí ń fínnú-fíndọ̀ fi fún ilé Ọlọ́run+ wọn, èyí tí ó wà ní Jerúsálẹ́mù; 17  bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, kánmọ́kánmọ́ ni kí o fi owó yìí ra àwọn akọ màlúù,+ àwọn àgbò,+ àwọn ọ̀dọ́ àgùntàn+ àti àwọn ọrẹ ẹbọ+ ọkà wọn àti àwọn ọrẹ ẹbọ+ ohun mímu wọn, kí o sì kó wọn wá sórí pẹpẹ nínú ilé Ọlọ́run+ yín, èyí tí ó wà ní Jerúsálẹ́mù.+ 18  “Ohun yòówù tí ó bá sì dára lójú rẹ àti lójú àwọn arákùnrin rẹ láti fi ìyókù fàdákà àti wúrà+ náà ṣe, ní ìbámu pẹ̀lú ohun tí Ọlọ́run yín fẹ́+ ni kí ẹ ṣe.+ 19  Àwọn ohun èlò+ tí a ó sì kó fún ọ fún iṣẹ́ ìsìn ilé Ọlọ́run rẹ ni kí o fi jíṣẹ́ lẹ́kùn-ún-rẹ́rẹ́ níwájú Ọlọ́run ní Jerúsálẹ́mù.+ 20  Àti ìyókù àwọn ohun kòṣeémánìí ilé Ọlọ́run rẹ, tí ó já lé ọ léjìká láti pèsè ni ìwọ yóò pèsè láti inú ilé àwọn ìṣúra+ ọba. 21  “Èmi tìkára mi, Atasásítà Ọba, sì ti gbé àṣẹ ìtọ́ni+ kan jáde fún gbogbo àwọn olùtọ́jú ìṣúra+ tí ń bẹ ní ìkọjá Odò,+ pé ohun gbogbo tí Ẹ́sírà+ àlùfáà, olùṣe àdàkọ òfin Ọlọ́run ọ̀run, bá béèrè lọ́wọ́ yín, a ó ṣe é kánmọ́kánmọ́, 22  àní títí dé ọgọ́rùn-ún tálẹ́ńtì+ fàdákà àti ọgọ́rùn-ún òṣùwọ̀n kọ́ọ̀+ àlìkámà àti ọgọ́rùn-ún òṣùwọ̀n báàfù+ wáìnì+ àti ọgọ́rùn-ún òṣùwọ̀n báàfù òróró,+ àti iyọ̀+ láìní ìwọ̀n. 23  Kí a fi ìtara+ fún ilé Ọlọ́run ọ̀run ṣe gbogbo ohun tí ó jẹ́ àṣẹ ìtọ́ni+ Ọlọ́run ọ̀run,+ kí ìrunú kankan má bàa dé sí ilẹ̀ àkóso ọba àti àwọn ọmọ rẹ̀.+ 24  A sì sọ ọ́ di mímọ̀ fún yín pé, ní ti èyíkéyìí lára àwọn àlùfáà+ àti àwọn ọmọ Léfì,+ àwọn olórin,+ àwọn olùṣọ́nà,+ àwọn Nétínímù,+ àti àwọn òṣìṣẹ́ ilé Ọlọ́run yìí, a kò yọ̀ǹda kí a gbé owó orí, owó òde+ tàbí owó ibodè+ kankan kà wọ́n lórí. 25  “Àti ìwọ, Ẹ́sírà, ní ìbámu pẹ̀lú ọgbọ́n+ Ọlọ́run rẹ tí ó wà ní ọwọ́ rẹ, kí o yan àwọn agbófinró àti àwọn onídàájọ́ sípò, kí wọ́n lè máa ṣe ìdájọ́+ gbogbo ènìyàn tí ó wà ní ìkọjá Odò, àní gbogbo àwọn tí ó mọ àwọn òfin Ọlọ́run rẹ; ẹnikẹ́ni tí kò bá sì mọ̀ wọ́n ni ẹ óò fún ní ìtọ́ni.+ 26  Gbogbo ẹni tí kò bá sì di olùpa òfin Ọlọ́run+ rẹ mọ́ àti òfin ọba, kánmọ́kánmọ́ ni kí a mú ìdájọ́ ṣẹ ní kíkún lé e lórí, yálà sí ikú+ tàbí sí ìlékúrò láwùjọ,+ tàbí sí owó ìtanràn+ tàbí sí ìfisẹ́wọ̀n.” 27  Ìbùkún ni fún Jèhófà Ọlọ́run àwọn baba ńlá+ wa, ẹni tí ó fi irú nǹkan bẹ́ẹ̀ sínú ọkàn-àyà+ ọba, láti ṣe ilé Jèhófà, èyí tí ó wà ní Jerúsálẹ́mù, lẹ́wà!+ 28  Ó sì ti nawọ́ inú-rere-onífẹ̀ẹ́+ sí mi níwájú ọba àti àwọn agbani-nímọ̀ràn+ rẹ̀ àti ní ti gbogbo alágbára ńlá ọmọ aládé ọba. Èmi, ní tèmi, fún ara mi lókun ní ìbámu pẹ̀lú ọwọ́+ Jèhófà Ọlọ́run mi lára mi, mo sì bẹ̀rẹ̀ sí kó àwọn olórí jọ láti inú Ísírẹ́lì láti gòkè lọ pẹ̀lú mi.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé