Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Ẹ́sírà 6:1-22

6  Ìgbà náà ni Dáríúsì Ọba gbé àṣẹ ìtọ́ni kan jáde, wọ́n sì ṣe àyẹ̀wò nínú ilé àkọsílẹ̀+ àwọn ìṣúra tí a kó síbẹ̀ ní Bábílónì.  Àti ní Ekibátánà, ní ibi olódi tí ó wà ní àgbègbè abẹ́ àṣẹ Mídíà,+ a rí àkájọ ìwé kan, ìwé ìrántí kan nípa èyí ni a sì kọ sínú rẹ̀ pé:  “Ní ọdún kìíní Kírúsì Ọba,+ Kírúsì Ọba gbé àṣẹ ìtọ́ni kan jáde nípa ilé Ọlọ́run ní Jerúsálẹ́mù: Kí a tún ilé náà kọ́ gẹ́gẹ́ bí ibi tí a ó ti máa rú àwọn ẹbọ,+ kí a sì fi àwọn ìpìlẹ̀ rẹ̀ sọlẹ̀, gíga rẹ̀ jẹ́ ọgọ́ta ìgbọ̀nwọ́, fífẹ̀ rẹ̀ jẹ́ ọgọ́ta ìgbọ̀nwọ́,+  pẹ̀lú ipele mẹ́ta òkúta tí a yí+ sí àyè wọn àti ipele kan àwọn ẹ̀là gẹdú;+ kí a sì pèsè ìnáwó láti ilé+ ọba.  Pẹ̀lúpẹ̀lù, àwọn ohun èlò wúrà+ àti fàdákà ilé Ọlọ́run, tí Nebukadinésárì+ kó jáde kúrò nínú tẹ́ńpìlì tí ó wà ní Jerúsálẹ́mù, tí ó sì kó wá sí Bábílónì ni kí a dá padà, kí wọ́n lè dé inú tẹ́ńpìlì tí ó wà ní Jerúsálẹ́mù ní àyè rẹ̀, kí a sì kó wọn sínú ilé Ọlọ́run.+  “Wàyí o, Táténáì+ tí í ṣe gómìnà tí ó wà ní ìkọjá Odò,+ Ṣetari-bósénáì+ àti ẹ̀yin ẹlẹgbẹ́ wọn, ẹ̀yin gómìnà+ kékeré tí ẹ wà ní ìkọjá Odò, kí ẹ jìnnà sí ibẹ̀.+  Ẹ jọ̀wọ́ iṣẹ́ lórí ilé Ọlọ́run yẹn jẹ́ẹ́.+ Gómìnà àwọn Júù àti àwọn àgbà ọkùnrin àwọn Júù yóò tún ilé Ọlọ́run kọ́ sí àyè rẹ̀.  Mo sì ti gbé àṣẹ ìtọ́ni+ kan jáde ní ti ohun tí ẹ ó ṣe fún àwọn àgbà ọkùnrin àwọn Júù wọ̀nyí, fún títún ilé Ọlọ́run yẹn kọ́; láti inú ibi ìṣúra+ ọba ti owó orí láti ìkọjá Odò ni a ó ti pèsè+ ìnáwó ní kánmọ́kánmọ́ fún àwọn abarapá ọkùnrin wọ̀nyí láìdáwọ́ dúró.+  Ohun tí a sì nílò, àwọn ẹgbọrọ akọ+ màlúù àti àwọn àgbò+ àti àwọn ọ̀dọ́ àgùntàn+ fún àwọn ọrẹ ẹbọ sísun sí Ọlọ́run ọ̀run, àlìkámà,+ iyọ̀,+ wáìnì+ àti òróró,+ gan-an gẹ́gẹ́ bí àwọn àlùfáà tí ó wà ní Jerúsálẹ́mù ṣe sọ, kí a máa bá a lọ ní fífún wọn láti ọjọ́ dé ọjọ́ láìkùnà; 10  kí wọ́n lè máa bá a lọ+ ní mímú àwọn ọrẹ ẹbọ+ amáratuni pẹ̀sẹ̀ wá fún Ọlọ́run ọ̀run, kí wọ́n sì máa gbàdúrà fún ìwàláàyè ọba àti àwọn ọmọ rẹ̀.+ 11  Mo sì ti gbé àṣẹ ìtọ́ni kan jáde pé, ní ti ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣẹ̀+ sí àṣẹ àgbékalẹ̀ yìí, ẹ̀là gẹdú+ ni a ó fà yọ lára ilé rẹ̀, a ó sì kan+ ẹni náà mọ́ ọn, a ó sì sọ ilé rẹ̀ di ilé ìgbọ̀nsẹ̀ gbogbo ènìyàn ní tìtorí+ èyí. 12  Kí Ọlọ́run tí ó ti mú kí orúkọ+ rẹ̀ máa gbé níbẹ̀ bi ọba àti àwọn ènìyàn èyíkéyìí ṣubú tí ó bá na ọwọ́ rẹ̀ jáde láti rú ìlànà àti láti pa ilé Ọlọ́run yẹn run,+ èyí tí ó wà ní Jerúsálẹ́mù. Èmi, Dáríúsì, gbé àṣẹ ìtọ́ni kan jáde. Kí a ṣe é ní kánmọ́kánmọ́.” 13  Nígbà náà ni Táténáì tí í ṣe gómìnà tí ó wà ní ìkọjá Odò,+ Ṣetari-bósénáì+ àti àwọn ẹlẹgbẹ́ wọn, gan-an gẹ́gẹ́ bí Dáríúsì Ọba ti fi ọ̀rọ̀ ránṣẹ́, bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ṣe ní kánmọ́kánmọ́. 14  Àwọn àgbà ọkùnrin+ àwọn Júù sì ń kọ́lé,+ wọ́n sì ń tẹ̀ síwájú nítorí ìsọtẹ́lẹ̀ Hágáì+ wòlíì àti Sekaráyà+ ọmọ-ọmọ Ídò,+ wọ́n sì kọ́lé, wọ́n sì parí rẹ̀ nítorí àṣẹ ìtọ́ni Ọlọ́run Ísírẹ́lì+ àti nítorí àṣẹ ìtọ́ni Kírúsì+ àti Dáríúsì+ àti Atasásítà+ ọba Páṣíà. 15  Wọ́n sì parí ilé yìí nígbà tí ó fi máa di ọjọ́ kẹta oṣù òṣùpá Ádárì,+ èyíinì ni, ní ọdún kẹfà ìgbà ìjọba Dáríúsì Ọba. 16  Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, àwọn àlùfáà àti àwọn ọmọ Léfì+ àti ìyókù àwọn ìgbèkùn+ tẹ́lẹ̀ rí sì fi ìdùnnú ṣe ayẹyẹ ṣíṣí+ ilé Ọlọ́run yìí. 17  Wọ́n sì mú ọgọ́rùn-ún akọ màlúù, igba àgbò, irínwó ọ̀dọ́ àgùntàn, àti akọ ewúrẹ́ méjìlá gẹ́gẹ́ bí ọrẹ ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ fún gbogbo Ísírẹ́lì, ní ìbámu pẹ̀lú iye ẹ̀yà Ísírẹ́lì+ wá fún ayẹyẹ ṣíṣí ilé Ọlọ́run yìí. 18  Wọ́n sì yan àwọn àlùfáà sípò ní ìsọ̀rí-ìsọ̀rí+ wọn, àti àwọn ọmọ Léfì ní ìpín-ìpín wọn, fún iṣẹ́ ìsìn Ọlọ́run, èyí tí ó wà ní Jerúsálẹ́mù, ní ìbámu pẹ̀lú ohun tí a là sílẹ̀ nínú ìwé Mósè.+ 19  Àwọn ìgbèkùn tẹ́lẹ̀ rí sì bẹ̀rẹ̀ sí ṣe ìrékọjá+ ní ọjọ́ kẹrìnlá oṣù+ kìíní. 20  Níwọ̀n bí àwọn àlùfáà àti àwọn ọmọ Léfì ti wẹ ara wọn mọ́+ gẹ́gẹ́ bí àwùjọ kan ṣoṣo, gbogbo wọn ni ó mọ́, wọ́n sì tipa báyìí pa ẹran ẹbọ+ ìrékọjá fún gbogbo àwọn ìgbèkùn tẹ́lẹ̀ rí àti fún àwọn arákùnrin wọn àlùfáà àti fún ara wọn. 21  Nígbà náà ni àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tí wọ́n padà dé láti Ìgbèkùn jẹun,+ àti olúkúlùkù tí ó ti ya ara rẹ̀ sọ́tọ̀ sọ́dọ̀ wọn kúrò nínú ohun àìmọ́+ àwọn orílẹ̀-èdè ilẹ̀ náà, láti wá Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì.+ 22  Wọ́n sì ń bá a lọ ní fífi ayọ̀ yíyọ̀ ṣe àjọyọ̀ àwọn àkàrà+ aláìwú fún ọjọ́ méje; nítorí pé Jèhófà mú kí wọ́n máa yọ̀, ó sì yí ọkàn-àyà ọba Ásíríà padà+ síhà ọ̀dọ̀ wọn láti fún ọwọ́ wọn lókun nínú iṣẹ́ ilé Ọlọ́run tòótọ́, Ọlọ́run Ísírẹ́lì.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé