Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

Ẹ́sírà 5:1-17

5  Hágáì+ wòlíì àti Sekaráyà+ ọmọ-ọmọ Ídò+ wòlíì, sọ tẹ́lẹ̀ fún àwọn Júù tí ń bẹ ní Júdà àti ní Jerúsálẹ́mù, ní orúkọ+ Ọlọ́run Ísírẹ́lì, ẹni tí ó wà lórí wọn.+  Ìgbà náà ni Serubábélì+ ọmọkùnrin Ṣéálítíẹ́lì+ àti Jéṣúà+ ọmọkùnrin Jèhósádákì dìde, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí tún ilé Ọlọ́run kọ́, èyí tí ó wà ní Jerúsálẹ́mù; àwọn wòlíì+ Ọlọ́run tí ń ṣe àrànṣe fún wọn sì ń bẹ pẹ̀lú wọn.  Ní àkókò yẹn, Táténáì+ gómìnà tí ó wà ní ìkọjá Odò+ àti Ṣetari-bósénáì àti àwọn ẹlẹgbẹ́ wọn wá bá wọn, èyí sì ni ohun tí wọ́n ń sọ fún wọn: “Ta ní gbé àṣẹ ìtọ́ni jáde fún yín pé kí ẹ kọ́ ilé yìí, kí ẹ sì parí ohun yìí tí ẹ ń fi ìtì igi kọ́?”+  Nígbà náà ni wọ́n sọ èyí fún wọn: “Kí ni orúkọ àwọn abarapá ọkùnrin tí ń kọ́ ilé yìí?”  Ojú+ Ọlọ́run wọn sì wà lára+ àwọn àgbà ọkùnrin àwọn Júù, wọn kò sì dá wọn dúró títí ìròyìn fi lọ sọ́dọ̀ Dáríúsì, lẹ́yìn tí a ó lè fi ìwé àṣẹ nípa èyí ránṣẹ́ padà.  Èyí ni ẹ̀dà+ lẹ́tà tí Táténáì+ gómìnà tí ó wà ní ìkọjá Odò+ àti Ṣetari-bósénáì+ àti àwọn ẹlẹgbẹ́ rẹ̀,+ àwọn gómìnà kékeré tí ó wà ní ìkọjá Odò, fi ránṣẹ́ sí Dáríúsì Ọba;  wọ́n fi ọ̀rọ̀ ránṣẹ́ sí i, ìwé tí wọ́n sì kọ sínú rẹ̀ kà báyìí: “Sí Dáríúsì Ọba: “Àlàáfíà+ gbogbo!  Kí ó di mímọ̀ fún ọba pé àwa lọ sí àgbègbè+ abẹ́ àṣẹ Júdà, sí ilé Ọlọ́run+ ńlá, wọ́n sì ń fi àwọn òkúta tí a ń yí sí àyè wọn kọ́ ọ, wọ́n sì ń to àwọn ẹ̀là gẹdú sí àwọn ògiri; wọ́n sì ń fi ìháragàgà ṣe iṣẹ́ yẹn, ó sì ń tẹ̀ síwájú ní ọwọ́ wọn.  Nígbà náà ni a béèrè lọ́wọ́ àwọn àgbà ọkùnrin wọ̀nyí. Èyí ni ohun tí a wí fún wọn: ‘Ta ní gbé àṣẹ ìtọ́ni jáde fún yín pé kí ẹ kọ́ ilé yìí, kí ẹ sì parí ohun yìí tí ẹ ń fi ìtì igi kọ́?’+ 10  A sì tún béèrè orúkọ wọn lọ́wọ́ wọn, láti lè jẹ́ kí o mọ̀, kí a lè kọ orúkọ àwọn abarapá ọkùnrin tí ó jẹ́ olórí+ wọn. 11  “Èyí sì ni ọ̀rọ̀ tí wọ́n fi fèsì fún wa, pé: ‘Àwa ni ìránṣẹ́ Ọlọ́run ọ̀run àti ilẹ̀ ayé,+ a sì ń ṣe àtúnkọ́ ilé tí a ti kọ́ ní ọ̀pọ̀ ọdún ṣáájú èyí, tí ọba ńlá kan ní Ísírẹ́lì kọ́, tí ó sì parí.+ 12  Bí ó ti wù kí ó rí, nítorí pé àwọn baba wa sún Ọlọ́run ọ̀run bínú,+ ó fi wọ́n lé+ ọwọ́ Nebukadinésárì+ Ọba Bábílónì, ará Kálídíà,+ ó sì wó ilé+ yìí palẹ̀, ó sì kó àwọn ènìyàn náà lọ sí ìgbèkùn ní Bábílónì.+ 13  Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, ní ọdún kìíní Kírúsì+ ọba Bábílónì, Kírúsì Ọba gbé àṣẹ ìtọ́ni kan jáde pé kí a tún ilé Ọlọ́run+ yìí kọ́. 14  Pẹ̀lúpẹ̀lù, àwọn ohun èlò+ wúrà àti fàdákà ilé Ọlọ́run, èyí tí Nebukadinésárì kó jáde kúrò nínú tẹ́ńpìlì, tí ó wà ní Jerúsálẹ́mù, tí ó sì kó wá sínú tẹ́ńpìlì Bábílónì,+ ìwọ̀nyí ni Kírúsì Ọba+ kó jáde kúrò nínú tẹ́ńpìlì Bábílónì, a sì kó wọn fún Ṣẹṣibásà,+ orúkọ ẹni tí ó fi jẹ gómìnà.+ 15  Ó sì wí fún un pé: “Kó ohun èlò+ wọ̀nyí. Lọ, kó wọn sínú tẹ́ńpìlì tí ó wà ní Jerúsálẹ́mù, kí a sì tún ilé Ọlọ́run kọ́ sí àyè rẹ̀.”+ 16  Nígbà tí Ṣẹṣibásà yẹn dé, ó fi àwọn ìpìlẹ̀ ilé Ọlọ́run lélẹ̀,+ èyí tí ó wà ní Jerúsálẹ́mù; láti ìgbà yẹn títí di ìsinsìnyí ni a ti ń tún un kọ́, ṣùgbọ́n a kò tíì parí rẹ̀.’+ 17  “Wàyí o, bí ó bá dára lójú ọba, jẹ́ kí a ṣe àyẹ̀wò+ nínú ilé àwọn ìṣúra ọba, èyí tí ó wà níbẹ̀ ní Bábílónì, bóyá bẹ́ẹ̀ ni ó rí, pé Kírúsì Ọba gbé àṣẹ ìtọ́ni+ kan jáde pé kí a tún ilé Ọlọ́run yẹn kọ́ ní Jerúsálẹ́mù; ìpinnu ọba nípa ọ̀ràn yìí sì ni kí òun fi ránṣẹ́ sí wa.”

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé