Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Ẹ́sírà 4:1-24

4  Nígbà tí àwọn elénìní+ Júdà àti Bẹ́ńjámínì gbọ́ pé àwọn ọmọ Ìgbèkùn+ ń kọ́ tẹ́ńpìlì kan fún Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì,  lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, wọ́n tọ Serubábélì+ àti àwọn olórí+ àwọn ìdí ilé baba wá, wọ́n sì wí fún wọn pé: “Ẹ jẹ́ kí a jọ+ kọ́lé; nítorí pé, gan-an gẹ́gẹ́ bí ẹ̀yin, àwa ń wá Ọlọ́run+ yín, òun sì ni àwa ń rúbọ sí láti àwọn ọjọ́ Esari-hádónì+ ọba Ásíríà, ẹni tí ó kó wa gòkè wá síhìn-ín.”+  Àmọ́ ṣá o, Serubábélì àti Jéṣúà+ àti ìyókù àwọn olórí+ àwọn ìdí ilé baba ní Ísírẹ́lì wí fún wọn pé: “Kò sí nǹkan kan tí ó pa àwa àti ẹ̀yin pọ̀ ní kíkọ́ ilé fún Ọlọ́run+ wa, nítorí pé àwa tìkára wa ni yóò para pọ̀ kọ́lé fún Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì, gan-an gẹ́gẹ́ bí Kírúsì+ Ọba tí í ṣe ọba Páṣíà ti pàṣẹ fún wa.”  Látàrí ìyẹn, àwọn ènìyàn ilẹ̀ náà ń bá a lọ ní sísọ ọwọ́ àwọn ènìyàn Júdà di aláìlera,+ wọ́n sì ń sọ ọkàn wọn domi láti má ṣe kọ́lé,+  wọ́n sì ń háyà+ àwọn agbani-nímọ̀ràn lòdì sí wọn láti mú kí ìmọ̀ràn wọn já sí pàbó ní gbogbo ọjọ́ Kírúsì ọba Páṣíà títí di ìgbà ìjọba Dáríúsì+ ọba Páṣíà.  Àti ní ìgbà ìjọba Ahasuwérúsì, ní ìbẹ̀rẹ̀ ìgbà ìjọba rẹ̀, wọ́n kọ̀wé ẹ̀sùn+ lòdì sí àwọn olùgbé Júdà àti Jerúsálẹ́mù.  Pẹ̀lúpẹ̀lù, ní àwọn ọjọ́ Atasásítà, Bíṣílámù, Mítírédátì, Tábéélì àti àwọn ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ yòókù kọ̀wé sí Atasásítà ọba Páṣíà, ọ̀nà ìkọ̀wé tí a lò nínú lẹ́tà náà sì jẹ́ àwọn àmì ìkọ̀wé Árámáíkì, tí a sì tú sí èdè Árámáíkì.+  Réhúmù+ olórí ìjòyè ìjọba àti Ṣímúṣáì akọ̀wé òfin kọ lẹ́tà kan sí Atasásítà Ọba lòdì sí Jerúsálẹ́mù, lọ́nà yìí:  Nígbà náà ni Réhúmù olórí ìjòyè ìjọba àti Ṣímúṣáì akọ̀wé òfin àti àwọn ẹlẹgbẹ́ wọn yòókù, àwọn onídàájọ́ àti àwọn gómìnà kékeré tí ó wà ní òdì-kejì Odò,+ àwọn akọ̀wé,+ àwọn ènìyàn Érékì,+ àwọn ará Babilóníà,+ àwọn olùgbé Súsà,+ èyíinì ni, àwọn ọmọ Élámù,+ 10  àti àwọn orílẹ̀-èdè+ yòókù tí Ásénápárì+ ńlá àti ọlọ́lá kó lọ sí ìgbèkùn, tí ó sì tẹ̀ wọ́n dó sí àwọn ìlú ńlá Samáríà,+ àti àwọn yòókù tí ó wà ní ìkọjá Odò, ——; wàyí o 11  èyí ni ẹ̀dà lẹ́tà tí wọ́n fi ránṣẹ́ nípa rẹ̀: “Sí Atasásítà+ Ọba, àwa ìránṣẹ́ rẹ, àwa ènìyàn tí a wà ní ìkọjá Odò: Wàyí o, 12  kí ó di mímọ̀ fún ọba pé àwọn Júù tí ó gòkè wá síhìn-ín láti ọ̀dọ̀ rẹ sí ọ̀dọ̀ wa ti dé Jerúsálẹ́mù. Wọ́n ń kọ́ ìlú ńlá ọ̀tẹ̀ àti ìlú ńlá búburú náà, wọ́n sì tẹ̀ síwájú ní píparí àwọn ògiri+ rẹ̀ àti ní títún àwọn ìpìlẹ̀ rẹ̀ ṣe. 13  Wàyí o, kí ó di mímọ̀ fún ọba pé, bí a bá tún ìlú ńlá yìí kọ́, tí a sì parí àwọn ògiri rẹ̀, wọn kì yóò mú owó orí+ tàbí owó òde+ tàbí owó ibodè wá, yóò sì fa àdánù wá bá àwọn ibi ìṣúra+ àwọn ọba. 14  Wàyí o, níwọ̀n ìgbà tí ó jẹ́ pé àwa ń jẹ iyọ̀ ààfin, tí kò sì bẹ́tọ̀ọ́ mu fún wa láti rí títú ọba sí borokoto, ní tìtorí èyí ni àwa fi ránṣẹ́, tí a sì sọ ọ́ di mímọ̀ fún ọba, 15  kí a lè ṣe àyẹ̀wò ìwé àkọsílẹ̀ àwọn baba ńlá rẹ ìgbàanì. Ìwọ yóò wá rí i nínú ìwé àkọsílẹ̀,+ ìwọ yóò sì mọ̀ pé ìlú ńlá yẹn jẹ́ ìlú ńlá ọ̀tẹ̀ àti èyí tí ń fa àdánù wá bá àwọn ọba àti àwọn àgbègbè abẹ́ àṣẹ, àti pé àwọn tí ń dìtẹ̀ ń bẹ nínú rẹ̀ láti àwọn ọjọ́ láéláé. Fún ìdí yìí ni ìlú ńlá yẹn ṣe di ahoro.+ 16  Àwa ń sọ ọ́ di mímọ̀ fún ọba pé, bí a bá tún ìlú ńlá yẹn kọ́, tí a sì parí àwọn ògiri rẹ̀, ó dájú pé ìwọ pẹ̀lú kì yóò ní ìpín kankan ní ìkọjá Odò.”+ 17  Ọba fi ọ̀rọ̀ ránṣẹ́ sí Réhúmù+ olórí ìjòyè ìjọba àti Ṣímúṣáì akọ̀wé òfin àti àwọn ẹlẹgbẹ́+ wọn yòókù tí ń gbé ní Samáríà àti àwọn yòókù tí ó wà ní ìkọjá Odò pé: “Mo kí+ yín! Wàyí o, 18  ìwé àṣẹ tí ẹ fi ránṣẹ́ sí wa ni a ti kà níwájú mi ketekete. 19  Nítorí náà, mo ti gbé àṣẹ ìtọ́ni kan jáde, wọ́n sì ti ṣe àyẹ̀wò,+ wọ́n sì rí i pé láti àwọn ọjọ́ láéláé ni ìlú ńlá yẹn ti jẹ́ èyí tí ń dìde sí àwọn ọba àti inú èyí tí a ti ń ṣọ̀tẹ̀ tí a sì ti ń dìtẹ̀.+ 20  Àwọn ọba+ tí ó lágbára sì jẹ lórí Jerúsálẹ́mù, wọ́n sì ń ṣàkóso gbogbo àwọn tí ó wà ní ìkọjá Odò,+ àti pé owó orí, owó òde àti owó ibodè ni a ń fi fún wọn.+ 21  Wàyí o, ẹ gbé àṣẹ ìtọ́ni kan jáde fún àwọn abarapá ọkùnrin wọ̀nyí pé kí wọ́n dáwọ́ dúró, pé a kò gbọ́dọ̀ tún ìlú ńlá yẹn kọ́, títí èmi yóò fi gbé àṣẹ ìtọ́ni kan jáde. 22  Nítorí náà, ẹ kíyè sára kí ó má ṣe sí ìwà àìnáání kankan nípa gbígbé ìgbésẹ̀ lórí ọ̀ràn yìí, kí ìpalára má bàa pọ̀ sí i, sí èṣe àwọn ọba.”+ 23  Wàyí o, lẹ́yìn tí a ka ẹ̀dà ìwé àṣẹ Atasásítà Ọba níwájú Réhúmù+ àti Ṣímúṣáì+ akọ̀wé òfin àti àwọn ẹlẹgbẹ́+ wọn, wàrà-wéré ni wọ́n lọ sí Jerúsálẹ́mù sí ọ̀dọ̀ àwọn Júù, wọ́n sì fi ohun ìjà dá wọn dúró.+ 24  Ìgbà yẹn ni iṣẹ́ lórí ilé Ọlọ́run, èyí tí ó wà ní Jerúsálẹ́mù, dáwọ́ dúró; a sì dáwọ́ rẹ̀ dúró títí di ọdún kejì ìgbà ìjọba Dáríúsì+ ọba Páṣíà.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé