Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Ẹ́sírà 2:1-70

2  Ìwọ̀nyí sì ni àwọn ọmọkùnrin àgbègbè+ abẹ́ àṣẹ tí ó gòkè lọ kúrò ní oko òǹdè àwọn ìgbèkùn+ tí Nebukadinésárì ọba Bábílónì kó lọ sí ìgbèkùn+ ní Bábílónì, tí wọ́n sì padà+ lẹ́yìn náà sí Jerúsálẹ́mù àti Júdà,+ olúkúlùkù sí ìlú ńlá tirẹ̀;  àwọn tí wọ́n bá Serubábélì+ wá ni, Jéṣúà,+ Nehemáyà, Seráyà,+ Reeláyà, Módékáì, Bílíṣánì, Mísípárì, Bígífáì, Réhúmù, Báánáhì. Iye àwọn ọkùnrin nínú àwọn ènìyàn Ísírẹ́lì:  Àwọn ọmọkùnrin Páróṣì,+ ẹgbọ̀kànlá ó dín méjìdínlọ́gbọ̀n;  àwọn ọmọkùnrin Ṣẹfatáyà,+ òjì-dín-nírínwó ó lé méjìlá;  àwọn ọmọkùnrin Áráhì,+ ẹgbẹ̀rin ó dín mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n;  àwọn ọmọkùnrin Pahati-móábù,+ ti àwọn ọmọ Jéṣúà àti Jóábù,+ ẹgbẹ̀rìnlá ó lé méjìlá;  àwọn ọmọkùnrin Élámù,+ ọ̀tà-lé-lẹ́gbẹ̀fà ó dín mẹ́fà;  àwọn ọmọkùnrin Sátù,+ òjì-lé-lẹ́ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rún ó lé márùn-ún;  àwọn ọmọkùnrin Sákáì,+ òjì-dín-lẹ́gbẹ̀rin; 10  àwọn ọmọkùnrin Bánì,+ òjì-lé-lẹ́gbẹ̀ta ó lé méjì; 11  àwọn ọmọkùnrin Bébáì,+ ẹgbẹ̀ta ó lé mẹ́tàlélógún; 12  àwọn ọmọkùnrin Ásígádì,+ ẹgbẹ̀fà ó lé méjìlélógún; 13  àwọn ọmọkùnrin Ádóníkámù,+ ọ̀tà-lé-lẹ́gbẹ̀ta ó lé mẹ́fà; 14  àwọn ọmọkùnrin Bígífáì,+ ẹgbàá ó lé mẹ́rìndínlọ́gọ́ta; 15  àwọn ọmọkùnrin Ádínì,+ àádọ́ta-lé-nírínwó ó lé mẹ́rin; 16  àwọn ọmọkùnrin Átérì,+ ti Hesekáyà, méjì-dín-lọ́gọ́rùn-ún; 17  àwọn ọmọkùnrin Bísáì,+ ọ̀ọ́dúnrún ó lé mẹ́tàlélógún; 18  àwọn ọmọkùnrin Jórà, méjì-lé-láàádọ́fà; 19  àwọn ọmọkùnrin Háṣúmù,+ okòó-lérúgba ó lé mẹ́ta; 20  àwọn ọmọkùnrin Gíbárì,+ márùn-dín-lọ́gọ́rùn-ún; 21  àwọn ọmọkùnrin Bẹ́tílẹ́hẹ́mù,+ mẹ́tàlélọ́gọ́fà; 22  àwọn ọkùnrin Nétófà,+ mẹ́rìndínlọ́gọ́ta; 23  àwọn ọkùnrin Ánátótì,+ méjì-dín-láàádóje; 24  àwọn ọmọkùnrin Ásímáfẹ́tì,+ méjìlélógójì; 25  àwọn ọmọkùnrin Kiriati-jéárímù,+ Kéfírà àti Béérótì, òjì-lé-lẹ́ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rin ó lé mẹ́ta; 26  àwọn ọmọkùnrin Rámà+ àti Gébà,+ ẹgbẹ̀ta ó lé mọ́kànlélógún; 27  àwọn ọkùnrin Míkímásì,+ méjìlélọ́gọ́fà; 28  àwọn ọkùnrin Bẹ́tẹ́lì+ àti Áì,+ okòó-lérúgba ó lé mẹ́ta; 29  àwọn ọmọkùnrin Nébò,+ méjì-lé-láàádọ́ta; 30  àwọn ọmọkùnrin Mágíbíṣì, mẹ́rìndínlọ́gọ́jọ; 31  àwọn ọmọkùnrin Élámù+ kejì, ọ̀tà-lé-lẹ́gbẹ̀fà ó dín mẹ́fà; 32  àwọn ọmọkùnrin Hárímù,+ okòó-lé-lọ́ọ̀ọ́dúnrún; 33  àwọn ọmọkùnrin Lódì,+ Hádídì+ àti Ónò,+ ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rin ó lé márùndínlọ́gbọ̀n; 34  àwọn ọmọkùnrin Jẹ́ríkò,+ òjì-lé-lọ́ọ̀ọ́dúnrún ó lé márùn-ún; 35  àwọn ọmọkùnrin Sénáà,+ egbèjìdínlógún ó lé ọgbọ̀n. 36  Àwọn àlùfáà:+ Àwọn ọmọkùnrin Jedáyà+ ti ilé Jéṣúà,+ ẹgbẹ̀rún ó dín mẹ́tàdínlọ́gbọ̀n; 37  àwọn ọmọkùnrin Ímérì,+ àádọ́ta-lé-lẹ́gbẹ̀rún ó lé méjì; 38  àwọn ọmọkùnrin Páṣúrì,+ ẹgbẹ̀fà ó lé mẹ́tà-dín-láàádọ́ta; 39  àwọn ọmọkùnrin Hárímù,+ ẹgbẹ̀rún ó lé mẹ́tàdínlógún. 40  Àwọn ọmọ Léfì:+ Àwọn ọmọkùnrin Jéṣúà+ àti Kádímíélì,+ ti àwọn ọmọkùnrin Hodafáyà,+ mẹ́rìn-lé-láàádọ́rin. 41  Àwọn akọrin, àwọn ọmọkùnrin Ásáfù,+ méjì-dín-láàádóje. 42  Àwọn ọmọkùnrin àwọn aṣọ́bodè, àwọn ọmọkùnrin Ṣálúmù,+ àwọn ọmọkùnrin Átérì,+ àwọn ọmọkùnrin Tálímónì,+ àwọn ọmọkùnrin Ákúbù,+ àwọn ọmọkùnrin Hátítà,+ àwọn ọmọkùnrin Ṣóbáì, gbogbo wọn lápapọ̀, mọ́kàndínlógóje. 43  Àwọn Nétínímù:+ Àwọn ọmọkùnrin Síhà, àwọn ọmọkùnrin Hásúfà, àwọn ọmọkùnrin Tábáótì,+ 44  àwọn ọmọkùnrin Kérósì, àwọn ọmọkùnrin Síáhà, àwọn ọmọkùnrin Pádónì,+ 45  àwọn ọmọkùnrin Lébánà, àwọn ọmọkùnrin Hágábà, àwọn ọmọkùnrin Ákúbù, 46  àwọn ọmọkùnrin Hágábù, àwọn ọmọkùnrin Sálímáì,+ àwọn ọmọkùnrin Hánánì, 47  àwọn ọmọkùnrin Gídélì, àwọn ọmọkùnrin Gáhárì,+ àwọn ọmọkùnrin Reáyà, 48  àwọn ọmọkùnrin Résínì,+ àwọn ọmọkùnrin Nékódà, àwọn ọmọkùnrin Gásámù, 49  àwọn ọmọkùnrin Úúsà, àwọn ọmọkùnrin Páséà,+ àwọn ọmọkùnrin Bésáì, 50  àwọn ọmọkùnrin Ásínà, àwọn ọmọkùnrin Méúnímù, àwọn ọmọkùnrin Néfúsímù;+ 51  àwọn ọmọkùnrin Bákíbúkì, àwọn ọmọkùnrin Hákúfà, àwọn ọmọkùnrin Háhọ́rì,+ 52  àwọn ọmọkùnrin Básílútù, àwọn ọmọkùnrin Méhídà, àwọn ọmọkùnrin Háṣà,+ 53  àwọn ọmọkùnrin Bákósì, àwọn ọmọkùnrin Sísérà, àwọn ọmọkùnrin Téémà,+ 54  àwọn ọmọkùnrin Nesáyà, àwọn ọmọkùnrin Hátífà.+ 55  Àwọn ọmọkùnrin àwọn ìránṣẹ́ Sólómọ́nì:+ Àwọn ọmọkùnrin Sótáì, àwọn ọmọkùnrin Sóférétì, àwọn ọmọkùnrin Pérúdà,+ 56  àwọn ọmọkùnrin Jálà, àwọn ọmọkùnrin Dákónì, àwọn ọmọkùnrin Gídélì,+ 57  àwọn ọmọkùnrin Ṣẹfatáyà, àwọn ọmọkùnrin Hátílì, àwọn ọmọkùnrin Pokereti-hásébáímù, àwọn ọmọkùnrin Ámì.+ 58  Gbogbo Nétínímù+ àti àwọn ọmọkùnrin àwọn ìránṣẹ́ Sólómọ́nì jẹ́ irínwó ó dín mẹ́jọ.+ 59  Ìwọ̀nyí sì ni àwọn tí ó gòkè lọ láti Tẹli-mélà, Tẹli-háṣà, Kérúbù, Ádónì àti Ímérì, wọn kò sì lè sọ ilé baba wọn àti orírun wọn,+ yálà wọ́n jẹ́ ara Ísírẹ́lì: 60  àwọn ọmọkùnrin Deláyà, àwọn ọmọkùnrin Tobáyà, àwọn ọmọkùnrin Nékódà,+ àádọ́ta-lé-lẹ́gbẹ̀ta ó lé méjì. 61  Àti lára àwọn ọmọkùnrin àwọn àlùfáà:+ àwọn ọmọkùnrin Habáyà, àwọn ọmọkùnrin Hákósì,+ àwọn ọmọkùnrin Básíláì,+ tí ó fẹ́ ọ̀kan lára àwọn ọmọbìnrin Básíláì,+ ọmọ Gílíádì ṣe aya, tí a sì wá ń fi orúkọ wọn pè é. 62  Ìwọ̀nyí ni àwọn tí ó wá àkọsílẹ̀ orúkọ wọn, láti fi ìdí ìtàn ìlà ìdílé wọn múlẹ̀ ní gbangba, wọn kò sì rí tiwọn, a sì dènà wọn láti má ṣe wọ inú iṣẹ́ àlùfáà+ nítorí a kà wọ́n sí eléèérí. 63  Nítorí náà, ẹni tí ó jẹ́ Tíṣátà+ wí fún wọn pé wọn kò lè jẹ+ nínú àwọn ohun mímọ́ jù lọ títí àlùfáà kan yóò fi dìde dúró pẹ̀lú Úrímù+ àti Túmímù. 64  Gbogbo ìjọ náà pátá gẹ́gẹ́ bí àwùjọ+ kan ṣoṣo jẹ́ ẹ̀gbàá mọ́kànlélógún ó lé òjì-dín-nírínwó,+ 65  yàtọ̀ sí àwọn ẹrúkùnrin wọn àti àwọn ẹrúbìnrin wọn, àwọn wọ̀nyí jẹ́ ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀tà-dín-lógójì ó lé mẹ́tàdínlógójì; wọ́n sì ní igba ọkùnrin akọrin+ àti obìnrin akọrin. 66  Ẹṣin wọn jẹ́ òjì-lé-lẹ́ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rin ó dín mẹ́rin, ìbaaka wọn jẹ́ òjìlúgba ó lé márùn-ún,+ 67  ràkúnmí wọn jẹ́ irínwó ó lé márùndínlógójì, kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ wọn jẹ́ ẹgbẹ̀rìnlélọ́gbọ̀n ó dín ọgọ́rin.+ 68  Àwọn kan báyìí lára àwọn olórí+ ìdí ilé baba,+ nígbà tí wọ́n wá sínú ilé Jèhófà,+ èyí tí ó wà ní Jerúsálẹ́mù,+ wọ́n ṣe àwọn ìtọrẹ àfínnúfíndọ̀ṣe+ fún ilé Ọlọ́run tòótọ́, láti mú kí ó dúró ní àyè rẹ̀.+ 69  Gẹ́gẹ́ bí agbára wọn, wọ́n mú wúrà+ wá fún àwọn ìpèsè àfiṣiṣẹ́, ọ̀kẹ́ mẹ́ta ó lé ẹgbẹ̀rún owó dírákímà, àti fàdákà,+ ẹgbẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n mínà, àti ọgọ́rùn-ún aṣọ+ àwọn àlùfáà. 70  Àwọn àlùfáà àti àwọn ọmọ Léfì àti àwọn kan lára àwọn ènìyàn náà,+ àti àwọn akọrin àti àwọn aṣọ́bodè àti àwọn Nétínímù sì bẹ̀rẹ̀ sí gbé nínú ìlú ńlá wọn, àti gbogbo Ísírẹ́lì nínú ìlú ńlá wọn.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé