Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

Ẹ́sírà 10:1-44

10  Wàyí o, gbàrà tí Ẹ́sírà ti gbàdúrà,+ tí ó sì ti jẹ́wọ́+ bí ó ti ń sunkún tí ó sì wólẹ̀+ búrúbúrú níwájú ilé+ Ọlọ́run tòótọ́, àwọn ènìyàn Ísírẹ́lì kó ara wọn jọpọ̀ sọ́dọ̀ rẹ̀, ìjọ ńlá gan-an, àwọn ọkùnrin àti àwọn obìnrin àti àwọn ọmọdé, nítorí pé àwọn ènìyàn náà ti sunkún pẹ̀rẹ̀pẹ̀rẹ̀.  Nígbà náà ni Ṣẹkanáyà ọmọkùnrin Jéhíélì+ lára àwọn ọmọ Élámù+ dáhùn, ó sì wí fún Ẹ́sírà pé: “Àwa—àwa ti ṣe àìṣòótọ́ sí Ọlọ́run wa, tí ó fi jẹ́ pé a fi ibùgbé fún àwọn aya ilẹ̀ òkèèrè láti inú àwọn ènìyàn ilẹ̀+ náà. Síbẹ̀ náà, ìrètí+ ṣì ń bẹ fún Ísírẹ́lì ní ti èyí.  Ǹjẹ́ nísinsìnyí, ẹ jẹ́ kí a bá Ọlọ́run wa dá májẹ̀mú+ láti lé gbogbo àwọn aya náà lọ+ àti àwọn ọmọ tí wọ́n bí, ní ìbámu pẹ̀lú ìmọ̀ràn Jèhófà àti ti àwọn tí ń wárìrì+ sí àṣẹ+ Ọlọ́run wa, kí a lè ṣe é ní ìbámu pẹ̀lú òfin.+  Dìde, nítorí ọ̀ràn náà já lé ọ léjìká, àwa sì ń bẹ pẹ̀lú rẹ. Jẹ́ alágbára, kí o sì gbé ìgbésẹ̀.”  Látàrí ìyẹn, Ẹ́sírà dìde, ó sì mú kí àwọn olórí àwọn àlùfáà, àwọn ọmọ Léfì àti gbogbo Ísírẹ́lì búra+ láti ṣe gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ yìí. Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, wọ́n búra.  Ẹ́sírà dìde wàyí kúrò níwájú ilé Ọlọ́run tòótọ́, ó sì lọ sínú gbọ̀ngàn+ ìjẹun Jèhóhánánì ọmọkùnrin Élíáṣíbù. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ó lọ sí ibẹ̀, kò jẹ oúnjẹ,+ bẹ́ẹ̀ ni kò mu omi, nítorí pé ó ń ṣọ̀fọ̀+ lórí ìwà àìṣòótọ́ àwọn ìgbèkùn.  Nígbà náà ni wọ́n mú kí ìpè kan la gbogbo Júdà àti Jerúsálẹ́mù já, pé kí gbogbo àwọn ìgbèkùn+ tẹ́lẹ̀ rí kó ara wọn jọpọ̀ sí Jerúsálẹ́mù;  ẹnikẹ́ni tí kò bá sì wá+ níwọ̀n ọjọ́ mẹ́ta, gẹ́gẹ́ bí ìmọ̀ràn àwọn ọmọ aládé+ àti àwọn àgbà ọkùnrin—gbogbo ẹrù rẹ̀ ni a ó fi òfin dè,+ òun fúnra rẹ̀ ni a ó sì yà sọ́tọ̀+ kúrò nínú ìjọ àwọn ìgbèkùn.  Nítorí náà, gbogbo àwọn ènìyàn Júdà àti Bẹ́ńjámínì kó ara wọn jọpọ̀ sí Jerúsálẹ́mù láàárín ọjọ́ mẹ́ta, èyíinì ni, ní oṣù kẹsàn-án+ ní ogúnjọ́ oṣù náà, gbogbo àwọn ènìyàn náà sì jókòó sí ibi gbayawu ilé Ọlọ́run tòótọ́, wọ́n ń gbọ̀n nítorí ọ̀ràn náà àti ní tìtorí ọ̀wààrà òjò.+ 10  Níkẹyìn, Ẹ́sírà àlùfáà dìde, ó sì wí fún wọn pé: “Ẹ̀yin fúnra yín ti ṣe àìṣòótọ́ ní ti pé ẹ fi ibùgbé fún àwọn aya+ ilẹ̀ òkèèrè láti lè fi kún ẹ̀bi Ísírẹ́lì.+ 11  Ǹjẹ́ nísinsìnyí, ẹ jẹ́wọ́+ fún Jèhófà Ọlọ́run àwọn baba ńlá yín, kí ẹ sì ṣe ohun tí ó jẹ́ ìdùnnú+ rẹ̀, kí ẹ sì ya ara yín sọ́tọ̀ kúrò nínú àwọn ènìyàn ilẹ̀ náà àti kúrò lọ́dọ̀ àwọn aya+ ilẹ̀ òkèèrè.” 12  Gbogbo ìjọ sì dáhùn, wọ́n sì fi ohùn rara sọ pé: “Gan-an gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ rẹ, bẹ́ẹ̀ ni ó já lé wa léjìká láti ṣe.+ 13  Àmọ́ ṣá o, àwọn ènìyàn náà pọ̀, àsìkò ọ̀wààrà òjò sì ni, kò sì ṣeé ṣe láti dúró lóde; kì í sì í ṣe iṣẹ́ ọjọ́ kan tàbí méjì, nítorí tí àwa ti ṣọ̀tẹ̀ gidi gan-an nínú ọ̀ràn yìí. 14  Nítorí náà, jọ̀wọ́, jẹ́ kí àwọn ọmọ aládé+ wa ṣojú fún gbogbo ìjọ; àti pé, ní ti gbogbo àwọn tí ó wà nínú àwọn ìlú ńlá wa, tí wọ́n ti fi ibùgbé fún àwọn aya ilẹ̀ òkèèrè, jẹ́ kí wọ́n wá ní àwọn àkókò tí a yàn kalẹ̀, ti àwọn ti àgbà ọkùnrin ìlú ńlá kọ̀ọ̀kan àti àwọn onídàájọ́ rẹ̀, títí àwa yóò fi yí ìbínú jíjófòfò Ọlọ́run wa padà kúrò lórí wa, ní tìtorí ọ̀ràn yìí.” 15  (Bí ó ti wù kí ó rí, Jónátánì ọmọkùnrin Ásáhélì àti Jaseáyà ọmọkùnrin Tíkífà tìkára wọn dìde dúró lòdì+ sí èyí, Méṣúlámù àti Ṣábétáì+ tí í ṣe àwọn ọmọ Léfì sì ni àwọn tí ó ràn wọ́n lọ́wọ́.) 16  Àwọn ìgbèkùn+ tẹ́lẹ̀ rí sì bẹ̀rẹ̀ sí ṣe bẹ́ẹ̀; Ẹ́sírà àlùfáà àti àwọn ọkùnrin tí í ṣe olórí àwọn baba fún ilé ìdí ilé baba+ wọn, àní gbogbo wọn ní orúkọ-orúkọ, sì ya ara wọn sọ́tọ̀ wàyí, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí jókòó ní ọjọ́ kìíní oṣù+ kẹwàá láti ṣe ìwádìí ọ̀ràn náà;+ 17  ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀, wọ́n parí pẹ̀lú gbogbo àwọn ọkùnrin tí ó fi ibùgbé fún àwọn aya ilẹ̀ òkèèrè+ nígbà tí ó máa fi di ọjọ́ kìíní oṣù kìíní. 18  A sì wá rí àwọn kan lára àwọn ọmọ àlùfáà+ tí wọ́n ti fi ibùgbé fún àwọn aya ilẹ̀ òkèèrè; lára àwọn ọmọ Jéṣúà+ ọmọkùnrin Jèhósádákì+ àti àwọn arákùnrin rẹ̀, Maaseáyà àti Élíésérì àti Járíbù àti Gẹdaláyà. 19  Ṣùgbọ́n wọ́n ṣèlérí nípasẹ̀ bíbọwọ́, láti lé àwọn aya wọn lọ, àti pé, nítorí pé wọ́n jẹ̀bi,+ àgbò+ kan láti inú agbo ẹran ní láti wà fún ẹ̀bi wọn. 20  Àti lára àwọn ọmọ Ímérì+ ni Hánáánì àti Sebadáyà; 21  àti lára àwọn ọmọ Hárímù,+ Maaseáyà àti Èlíjà àti Ṣemáyà àti Jéhíélì àti Ùsáyà; 22  àti lára àwọn ọmọ Páṣúrì,+ Élíóénáì, Maaseáyà, Íṣímáẹ́lì, Nétánélì, Jósábádì àti Éléásà. 23  Àti lára àwọn ọmọ Léfì, Jósábádì àti Ṣíméì àti Keláyà, (èyíinì ni, Kélítà), Petaháyà, Júdà àti Élíésérì; 24  àti lára àwọn akọrin, Élíáṣíbù; àti lára àwọn aṣọ́bodè, Ṣálúmù àti Télémù àti Úráì. 25  Àti lára Ísírẹ́lì, lára àwọn ọmọ Páróṣì+ ni Ramáyà àti Isáyà àti Málíkíjà àti Míjámínì àti Élíásárì àti Málíkíjà àti Bẹnáyà; 26  àti lára àwọn ọmọ Élámù,+ Matanáyà, Sekaráyà àti Jéhíélì+ àti Ábídì àti Jérémótì àti Èlíjà; 27  àti lára àwọn ọmọ Sátù,+ Élíóénáì, Élíáṣíbù, Matanáyà àti Jérémótì àti Sábádì àti Ásísà; 28  àti lára àwọn ọmọ Bébáì,+ Jèhóhánánì, Hananáyà, Sábáì, Átíláì; 29  àti lára àwọn ọmọ Bánì, Méṣúlámù, Málúkù àti Ádáyà, Jáṣúbù àti Ṣéálì àti Jérémótì; 30  àti lára àwọn ọmọ Pahati-móábù,+ Ádúnà àti Kélálì, Bẹnáyà, Maaseáyà, Matanáyà, Bẹ́sálẹ́lì àti Bínúì àti Mánásè; 31  àti lára àwọn ọmọ Hárímù,+ Élíésérì, Isiṣíjà, Málíkíjà,+ Ṣemáyà, Ṣíméónì, 32  Bẹ́ńjámínì, Málúkù àti Ṣemaráyà; 33  lára àwọn ọmọ Háṣúmù,+ Máténáì, Mátáátà, Sábádì, Élífélétì, Jérémáì, Mánásè àti Ṣíméì; 34  lára àwọn ọmọ Bánì, Máádáì, Ámúrámù àti Yúẹ́lì, 35  Bẹnáyà, Bedeáyà, Kélúhì, 36  Fanáyà, Mérémótì, Élíáṣíbù, 37  Matanáyà, Máténáì àti Jáásù; 38  àti lára àwọn ọmọ Bínúì, Ṣíméì 39  àti Ṣelemáyà àti Nátánì àti Ádáyà, 40  Makinádébáì, Ṣáṣáì, Ṣáráì, 41  Ásárẹ́lì àti Ṣelemáyà, Ṣemaráyà, 42  Ṣálúmù, Amaráyà, Jósẹ́fù; 43  lára àwọn ọmọ Nébò, Jéélì, Matitáyà, Sábádì, Sébínà, Jádáì àti Jóẹ́lì àti Bẹnáyà. 44  Gbogbo àwọn wọ̀nyí ni wọ́n tẹ́wọ́ gba àwọn aya+ ilẹ̀ òkèèrè, wọ́n sì tẹ̀ síwájú láti rán àwọn aya lọ tọmọ-tọmọ.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé