Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

Ẹ́kísódù 9:1-35

9  Nítorí náà, Jèhófà wí fún Mósè pé: “Wọlé lọ bá Fáráò kí o sì sọ fún un pé,+ ‘Èyí ni ohun tí Jèhófà Ọlọ́run àwọn Hébérù wí: “Rán àwọn ènìyàn mi lọ kí wọ́n lè sìn mí.  Ṣùgbọ́n bí ìwọ bá ń bá a lọ ní kíkọ̀ láti rán wọn lọ, tí o sì ń dá wọn dúró síbẹ̀,+  wò ó! ọwọ́ Jèhófà+ ń bọ̀ wá sára àwọn ohun ọ̀sìn+ rẹ tí ó wà nínú pápá. Àjàkálẹ̀ àrùn bíbùáyà+ yóò wà lára àwọn ẹṣin, àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, àwọn ràkúnmí, ọ̀wọ́ ẹran àti agbo ẹran.  Dájúdájú, Jèhófà yóò sì fi ìyàtọ̀ sáàárín àwọn ohun ọ̀sìn Ísírẹ́lì àti àwọn ohun ọ̀sìn Íjíbítì, kò sì sí ohun kan tí yóò kú nínú gbogbo ohun tí ó jẹ́ ti àwọn ọmọ Ísírẹ́lì.”’”+  Jù bẹ́ẹ̀ lọ, Jèhófà dá àkókò àyànkalẹ̀, pé: “Ọ̀la ni Jèhófà yóò ṣe nǹkan yìí ní ilẹ̀ yìí.”+  Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, Jèhófà ṣe nǹkan yìí ní ọjọ́ kejì, gbogbo onírúurú àwọn ohun ọ̀sìn Íjíbítì sì bẹ̀rẹ̀ sí kú;+ ṣùgbọ́n kò sí ọ̀kan tí ó kú nínú àwọn ohun ọ̀sìn àwọn ọmọ Ísírẹ́lì.  Nígbà náà ni Fáráò ránṣẹ́, sì wò ó! kò tilẹ̀ sí ẹyọ kan pàápàá tí ó kú nínú àwọn ohun ọ̀sìn Ísírẹ́lì. Síbẹ̀síbẹ̀, ọkàn-àyà Fáráò ń bá a lọ láti gíràn-án,+ kò sí rán àwọn ènìyàn náà lọ.  Lẹ́yìn ìyẹn, Jèhófà sọ fún Mósè àti Áárónì pé: “Ẹ fi ọwọ́ méjèèjì bu ẹ̀kúnwọ́ màjàlà fún ara yín láti inú ẹbu,+ kí Mósè sì fọ́n ọn sí ojú ọ̀run ní ojú Fáráò.  Yóò sì di ekuru lórí gbogbo ilẹ̀ Íjíbítì, yóò sì di oówo tí ń sọ jáde pẹ̀lú ìléròrò+ lára ènìyàn àti ẹranko ní gbogbo ilẹ̀ Íjíbítì.” 10  Nítorí náà, wọ́n bu màjàlà ẹbu, wọ́n sì dúró níwájú Fáráò, Mósè sì fọ́n ọn sí ojú ọ̀run, ó sì di oówo líléròrò,+ tí ń sọ jáde lára ènìyàn àti ẹranko. 11  Àwọn àlùfáà pidánpidán kò lè dúró níwájú Mósè nítorí oówo náà, nítorí pé oówo ti yọ lára àwọn àlùfáà pidánpidán àti lára gbogbo ará Íjíbítì.+ 12  Ṣùgbọ́n Jèhófà jẹ́ kí ọkàn-àyà Fáráò di èyí tí ó ṣoríkunkun, kò sì fetí sí wọn, gan-an gẹ́gẹ́ bí Jèhófà ti sọ fún Mósè.+ 13  Nígbà náà ni Jèhófà wí fún Mósè pé: “Dìde ní kùtùkùtù òwúrọ̀, kí o sì mú ìdúró ní iwájú Fáráò,+ kí o sì wí fún un pé, ‘Èyí ni ohun tí Jèhófà Ọlọ́run àwọn Hébérù wí: “Rán àwọn ènìyàn mi lọ kí wọ́n lè sìn mí.+ 14  Nítorí lọ́tẹ̀ yìí, èmi yóò rán gbogbo ìyọnu àgbálù mi sí ọkàn-àyà rẹ àti sára àwọn ìránṣẹ́ rẹ àti àwọn ènìyàn rẹ, kí ìwọ bàa lè mọ̀ pé kò sí ẹnì kankan bí èmi ní gbogbo ilẹ̀ ayé.+ 15  Nítorí pé, nísinsìnyí, èmi ì bá ti na ọwọ́ mi kí n lè fi àjàkálẹ̀ àrùn kọlu ìwọ àti àwọn ènìyàn rẹ, kí n sì pa ọ́ rẹ́ kúrò lórí ilẹ̀ ayé.+ 16  Ṣùgbọ́n, ní ti tòótọ́, fún ìdí yìí ni mo ṣe mú kí o máa wà nìṣó,+ nítorí àtifi agbára mi hàn ọ́ àti nítorí kí a lè polongo orúkọ mi ní gbogbo ilẹ̀ ayé.+ 17  Ìwọ ha ṣì ń hùwà lọ́nà ìrera sí àwọn ènìyàn mi ní ṣíṣàìrán wọn lọ bí?+ 18  Kíyè sí i, èmi yóò mú kí òjò yìnyín bíbùáyà rọ̀ ní nǹkan bí àkókò yìí ní ọ̀la, irú èyí tí kò tíì wáyé rí ní Íjíbítì láti ọjọ́ tí a ti fi ìpìlẹ̀ rẹ̀ sọlẹ̀ títí di ìsinsìnyí.+ 19  Wàyí o, ránṣẹ́, mú gbogbo ohun ọ̀sìn rẹ àti gbogbo ohun tí ó jẹ́ tìrẹ nínú pápá wá sábẹ́ ibi ààbò. Ní ti ènìyàn àti ẹranko èyíkéyìí tí a bá rí nínú pápá tí a kò sì kó jọ sínú ilé, yìnyín+ yóò bọ́ lù wọ́n, wọn yóò sì kú.”’” 20  Ẹnikẹ́ni tí ó bẹ̀rù ọ̀rọ̀ Jèhófà láàárín àwọn ìránṣẹ́ Fáráò mú kí àwọn ìránṣẹ́ tirẹ̀ àti àwọn ohun ọ̀sìn rẹ̀ sá sínú ilé,+ 21  ṣùgbọ́n ẹnì yòówù tí kò mú kí ọkàn-àyà rẹ̀ ka ọ̀rọ̀ Jèhófà sí nǹkan kan fi àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ àti àwọn ohun ọ̀sìn rẹ̀ sílẹ̀ nínú pápá.+ 22  Wàyí o, Jèhófà wí fún Mósè pé: “Na ọwọ́ rẹ+ sí ọ̀run, kí yìnyín+ lè wá sórí gbogbo ilẹ̀ Íjíbítì, sára ènìyàn àti ẹranko àti gbogbo ewéko pápá ní ilẹ̀ Íjíbítì.” 23  Nítorí náà, Mósè na ọ̀pá rẹ̀ jáde sí ọ̀run; Jèhófà sì pèsè ààrá àti yìnyín,+ iná a sì tú dà sí ilẹ̀ ayé, Jèhófà sì ń bá a lọ láti mú kí òjò yìnyín rọ̀ sórí ilẹ̀ Íjíbítì. 24  Báyìí ni yìnyín dé, tí iná sì ń gbọ̀n wìrìwìrì láàárín yìnyín náà. Ó bùáyà, tí ó fi jẹ́ pé èyíkéyìí bí irú rẹ̀ kò ṣẹlẹ̀ rí ní gbogbo ilẹ̀ Íjíbítì láti ìgbà tí ó ti di orílẹ̀-èdè.+ 25  Yìnyín náà sì bẹ̀rẹ̀ sí bọ́ lu gbogbo ilẹ̀ Íjíbítì. Yìnyín náà bọ́ lu ohun gbogbo tí ó wà nínú pápá, láti orí ènìyàn dórí ẹranko, àti gbogbo onírúurú ewéko pápá; ó sì fa gbogbo onírúurú igi pápá ya pẹ́rẹpẹ̀rẹ.+ 26  Kìkì ilẹ̀ Góṣénì, níbi tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì wà, ni yìnyín kankan kò ti bọ́.+ 27  Ní àsẹ̀yìnwá-àsẹ̀yìnbọ̀, Fáráò ránṣẹ́, ó sì pe Mósè àti Áárónì, ó sì wí fún wọn pé: “Mo ti ṣẹ̀ lọ́tẹ̀ yìí.+ Olódodo ni Jèhófà,+ èmi àti àwọn ènìyàn mi sì ṣe àìtọ́. 28  Pàrọwà sí Jèhófà kí ààrá tí ń sán àti yìnyín tí ń bọ́ láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run lè tó gẹ́ẹ́.+ Nígbà náà, èmi múra tán láti rán yín lọ, ẹ kì yóò dúró mọ́.” 29  Nítorí náà, Mósè wí fún un pé: “Gbàrà tí mo bá ti jáde kúrò ní ìlú ńlá yìí, èmi yóò tẹ́ ọwọ́ mi sí Jèhófà.+ Ààrá náà yóò dáwọ́ dúró, yìnyín náà kò sì ní máa bá a lọ mọ́, kí ìwọ bàa lè mọ̀ pé ilẹ̀ ayé jẹ́ ti Jèhófà.+ 30  Ní ti ìwọ àti àwọn ìránṣẹ́ rẹ, mo ti mọ̀ tẹ́lẹ̀ pé, nígbà náà pàápàá, ẹ kì yóò bẹ̀rù Jèhófà Ọlọ́run.”+ 31  Gẹ́gẹ́ bí ó ti jẹ́, ọ̀gbọ̀ àti ọkà bálì ni a kọlù, nítorí pé ọkà bálì wà nínú ṣírí, ọ̀gbọ̀ sì ti ní ìrudi òdòdó.+ 32  Ṣùgbọ́n àlìkámà àti ọkà sípẹ́ẹ̀tì+ ni a kò kọlù, nítorí pé a kò gbìn wọ́n lásìkò. 33  Wàyí o, Mósè jáde kúrò ní ìlú ńlá náà kúrò lọ́dọ̀ Fáráò, ó sì tẹ́ ọwọ́ rẹ̀ sí Jèhófà, ààrá àti yìnyín náà sì bẹ̀rẹ̀ sí dáwọ́ dúró, òjò kò sì rọ̀ sí ilẹ̀.+ 34  Nígbà tí Fáráò sì wá rí i pé òjò àti yìnyín àti ààrá ti dáwọ́ dúró, ó tún bẹ̀rẹ̀ sí dẹ́ṣẹ̀, ó sì ń mú kí ọkàn-àyà rẹ̀ gíràn-án,+ òun àti àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀. 35  Ọkàn-àyà Fáráò sì ń bá a lọ láti jẹ́ èyí tí ó ṣoríkunkun, kò sì rán àwọn ọmọ Ísírẹ́lì lọ, gan-an gẹ́gẹ́ bí Jèhófà ti sọ nípasẹ̀ Mósè.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé