Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Ẹ́kísódù 8:1-32

8  Nígbà náà ni Jèhófà wí fún Mósè pé: “Wọlé lọ bá Fáráò, kí o sì sọ fún un pé, ‘Èyí ni ohun tí Jèhófà wí: “Rán àwọn ènìyàn mi lọ kí wọ́n lè sìn mí.+  Bí ìwọ bá sì ń bá a nìṣó ní kíkọ̀ láti rán wọn lọ, kíyè sí i, èmi yóò fi àwọn àkèré kọlu gbogbo ìpínlẹ̀ rẹ.+  Odò Náílì yóò sì kún fún àwọn àkèré tìrìgàngàn, dájúdájú, wọn yóò sì jáde wá, wọn yóò sì wọ inú ilé rẹ àti yàrá ibùsùn rẹ inú lọ́hùn-ún àti orí àga ìrọ̀gbọ̀kú rẹ àti inú ilé àwọn ìránṣẹ́ rẹ àti ara àwọn ènìyàn rẹ àti inú àwọn ààrò rẹ àti inú àwọn ọpọ́n ìpo-nǹkan rẹ.+  Àkèré yóò sì jáde wá sára rẹ àti sára àwọn ènìyàn rẹ àti sára gbogbo ìránṣẹ́ rẹ.”’”+  Lẹ́yìn náà, Jèhófà wí fún Mósè pé: “Sọ fún Áárónì pé, ‘Na ọwọ́ rẹ pẹ̀lú ọ̀pá rẹ+ sórí àwọn odò, àwọn ipa odò Náílì àti àwọn odò adágún tí ó kún fún esùsú, kí o sì mú kí àwọn àkèré jáde wá sórí ilẹ̀ Íjíbítì.’”  Látàrí èyí, Áárónì na ọwọ́ rẹ̀ sórí omi Íjíbítì, àwọn àkèré sì bẹ̀rẹ̀ sí jáde wá, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí bo ilẹ̀ Íjíbítì.  Bí ó ti wù kí ó rí, àwọn àlùfáà pidánpidán fi iṣẹ́ òkùnkùn wọn ṣe ohun kan náà, wọ́n sì mú àwọn àkèré jáde wá sórí ilẹ̀ Íjíbítì.+  Lẹ́yìn-ọ̀-rẹ̀yìn, Fáráò pe Mósè àti Áárónì, ó sì wí pé: “Pàrọwà sí Jèhófà+ kí ó lè mú àwọn àkèré kúrò lọ́dọ̀ èmi àti àwọn ènìyàn mi, bí ó ti jẹ́ pé mo fẹ́ rán àwọn ènìyàn náà lọ kí wọ́n lè rúbọ sí Jèhófà.”+  Nígbà náà ni Mósè wí fún Fáráò pé: “Kí ìwọ fi mí gba ògo láti sọ ìgbà tí èmi yóò pàrọwà nítorí rẹ àti àwọn ìránṣẹ́ rẹ àti àwọn ènìyàn rẹ kí a lè ké àwọn àkèré náà kúrò ní ọ̀dọ̀ rẹ àti ní àwọn ilé rẹ. Inú Odò Náílì nìkan ni wọn yóò ṣẹ́ kù sí.” 10  Ó fèsì pé: “Ní ọ̀la.” Nítorí náà, ó wí pé: “Yóò rí gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ rẹ, kí o lè mọ̀ pé kò sí ẹlòmíràn bí Jèhófà Ọlọ́run wa,+ 11  ní ti pé, dájúdájú, àwọn àkèré náà yóò lọ kúrò ní ọ̀dọ̀ rẹ àti ní àwọn ilé rẹ àti kúrò ní ọ̀dọ̀ àwọn ìránṣẹ́ rẹ àti àwọn ènìyàn rẹ. Inú Odò Náílì nìkan ni wọn yóò ṣẹ́ kù sí.”+ 12  Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, Mósè àti Áárónì jáde kúrò lọ́dọ̀ Fáráò, Mósè sì ké jáde sí Jèhófà+ nítorí àwọn àkèré tí Ó ti fi sára Fáráò. 13  Nígbà náà ni Jèhófà ṣe gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ Mósè,+ àwọn àkèré náà sì bẹ̀rẹ̀ sí kú kúrò nínú àwọn ilé, àwọn àgbàlá àti àwọn pápá. 14  Wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí kó wọn jọ pelemọ, ní òkìtì-òkìtì, ilẹ̀ náà sì bẹ̀rẹ̀ sí ṣíyàn-án.+ 15  Nígbà tí Fáráò wá rí i pé ìtura ti dé, ó mú ọkàn-àyà rẹ̀ gíràn-án;+ kò sì fetí sí wọn, gan-an gẹ́gẹ́ bí Jèhófà ti wí.+ 16  Wàyí o, Jèhófà wí fún Mósè pé: “Sọ fún Áárónì pé, ‘Na ọ̀pá rẹ+ jáde, kí o sì lu ekuru ilẹ̀, yóò sì di kòkòrò kantíkantí ní gbogbo ilẹ̀ Íjíbítì.’” 17  Wọ́n sì tẹ̀ síwájú láti ṣe èyí. Nítorí náà, Áárónì na ọwọ́ rẹ̀ pẹ̀lú ọ̀pá rẹ̀ jáde, ó sì lu ekuru ilẹ̀, àwọn kòkòrò kantíkantí sì wá wà lára ènìyàn àti ẹranko. Gbogbo ekuru ilẹ̀ di kòkòrò kantíkantí ní gbogbo ilẹ̀ Íjíbítì.+ 18  Àwọn àlùfáà pidánpidán sì gbìyànjú láti fi iṣẹ́ òkùnkùn+ wọn ṣe ohun kan náà, kí wọ́n bàa lè mú kòkòrò kantíkantí jáde, ṣùgbọ́n wọn kò lè ṣe é.+ Àwọn kòkòrò kantíkantí sì wá wà lára ènìyàn àti ẹranko. 19  Nítorí èyí, àwọn àlùfáà pidánpidán náà wí fún Fáráò pé: “Ìka+ Ọlọ́run+ ni èyí!” Ṣùgbọ́n ọkàn-àyà Fáráò ń bá a lọ láti jẹ́ èyí tí ó ṣoríkunkun,+ kò sì fetí sí wọn, gan-an gẹ́gẹ́ bí Jèhófà ti wí. 20  Nígbà náà ni Jèhófà wí fún Mósè pé: “Dìde ní kùtùkùtù òwúrọ̀, kí o sì mú ìdúró ní iwájú Fáráò.+ Wò ó! Ó ń jáde bọ̀ wá síbi omi! Ìwọ yóò sì sọ fún un pé, ‘Èyí ni ohun tí Jèhófà wí: “Rán àwọn ènìyàn mi lọ kí wọ́n lè sìn mí.+ 21  Ṣùgbọ́n bí ìwọ kò bá ní rán àwọn ènìyàn mi lọ, kíyè sí i, èmi yóò rán eṣinṣin mùjẹ̀mùjẹ̀+ sára ìwọ àti àwọn ìránṣẹ́ rẹ àti àwọn ènìyàn rẹ àti sínú àwọn ilé rẹ; àwọn ilé Íjíbítì yóò sì wulẹ̀ kún fún eṣinṣin mùjẹ̀mùjẹ̀, àti orí ilẹ̀ tí wọ́n wà pẹ̀lú. 22  Ní ọjọ́ yẹn, èmi yóò sì mú ilẹ̀ Góṣénì tí àwọn ènìyàn mi dúró sí, dá yàtọ̀ dájúdájú, kí eṣinṣin mùjẹ̀mùjẹ̀ kankan má bàa sí níbẹ̀;+ kí ìwọ bàa lè mọ̀ pé èmi ni Jèhófà láàárín ilẹ̀ ayé.+ 23  Ní tòótọ́, èmi yóò sì pààlà sáàárín àwọn ènìyàn mi àti àwọn ènìyàn rẹ.+ Ọ̀la ni àmì yìí yóò ṣẹlẹ̀.”’” 24  Jèhófà sì bẹ̀rẹ̀ sí ṣe bẹ́ẹ̀; ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ àwọn eṣinṣin mùjẹ̀mùjẹ̀ bíbùáyà sì bẹ̀rẹ̀ sí gbógun ti ilé Fáráò àti ilé àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ àti gbogbo ilẹ̀ Íjíbítì.+ Ilẹ̀ náà run nítorí àwọn eṣinṣin mùjẹ̀mùjẹ̀.+ 25  Níkẹyìn, Fáráò pe Mósè àti Áárónì, ó sì wí pé: “Ẹ lọ, ẹ rúbọ sí Ọlọ́run yín ní ilẹ̀ yìí.”+ 26  Ṣùgbọ́n Mósè wí pé: “Kò ṣeé gbà wọlé pé kí a ṣe bẹ́ẹ̀, nítorí pé àwa yóò fi ohun tí ó jẹ́ ìṣe-họ́ọ̀-sí lójú àwọn ará Íjíbítì+ rúbọ sí Jèhófà Ọlọ́run wa. Ká ní àwa yóò fi ohun tí ó jẹ́ ìṣe-họ́ọ̀-sí lójú àwọn ará Íjíbítì rúbọ lójú wọn; ṣé wọn kò ní sọ wá lókùúta? 27  Àwa yóò lọ ìrìn àjò ọlọ́jọ́ mẹ́ta sí aginjù, láìsí àní-àní, àwa yóò sì rúbọ sí Jèhófà Ọlọ́run wa gan-an gẹ́gẹ́ bí ó ti wí fún wa.”+ 28  Wàyí o, Fáráò wí pé: “Èmi—èmi yóò rán yín lọ,+ ní tòótọ́, ẹ ó sì rúbọ sí Jèhófà Ọlọ́run yín ní aginjù.+ Kìkì pé kí ẹ má ṣe jẹ́ kí ibi tí ẹ ó lọ jìnnà réré tó bẹ́ẹ̀. Kí ẹ pàrọwà nítorí mi.”+ 29  Nígbà náà ni Mósè wí pé: “Kíyè sí i, mo ń jáde lọ kúrò lọ́dọ̀ rẹ, èmi yóò sì pàrọwà ní ti gidi sí Jèhófà, dájúdájú, àwọn eṣinṣin mùjẹ̀mùjẹ̀ náà yóò sì lọ kúrò lọ́dọ̀ Fáráò, àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ àti àwọn ènìyàn rẹ̀ ní ọ̀la. Kìkì pé kí Fáráò má ṣe tún kà á sí ohun ṣeréṣeré mọ́ ní ṣíṣaláìrán àwọn ènìyàn náà lọ láti rúbọ sí Jèhófà.”+ 30  Lẹ́yìn ìyẹn, Mósè jáde kúrò lọ́dọ̀ Fáráò, ó sì pàrọwà sí Jèhófà.+ 31  Nítorí náà, Jèhófà ṣe gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ Mósè,+ àwọn eṣinṣin mùjẹ̀mùjẹ̀ náà sì lọ kúrò lọ́dọ̀ Fáráò, àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ àti àwọn ènìyàn rẹ̀.+ Kò sí ọ̀kan tí ó ṣẹ́ kù. 32  Bí ó ti wù kí ó rí, Fáráò mú ọkàn-àyà rẹ̀ gíràn-án lọ́tẹ̀ yìí pẹ̀lú, kò sì rán àwọn ènìyàn náà lọ.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé