Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Ẹ́kísódù 7:1-25

7  Nítorí náà, Jèhófà wí fún Mósè pé: “Wò ó, mo fi ọ́ ṣe Ọlọ́run fún Fáráò,+ Áárónì arákùnrin rẹ gan-an yóò sì di wòlíì rẹ.+  Ìwọ—ìwọ ni yóò sọ gbogbo èyí tí èmi yóò pa láṣẹ fún ọ;+ Áárónì arákùnrin rẹ ni yóò sì máa bá Fáráò sọ̀rọ̀,+ òun yóò sì rán àwọn ọmọ Ísírẹ́lì lọ kúrò ní ilẹ̀ rẹ̀.+  Ní tèmi, èmi yóò jẹ́ kí ọkàn-àyà Fáráò di èyí tí ó ṣoríkunkun,+ dájúdájú, èmi yóò sì sọ àwọn àmì mi àti àwọn iṣẹ́ ìyanu mi di púpọ̀ ní ilẹ̀ Íjíbítì.+  Fáráò kì yóò sì fetí sí yín;+ àti pé èmi yóò ní láti gbé ọwọ́ mi lé Íjíbítì, èmi yóò sì mú àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun mi,+ àwọn ènìyàn mi,+ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì,+ jáde kúrò ní ilẹ̀ Íjíbítì pẹ̀lú àwọn ìdájọ́ ńlá.+  Àwọn ará Íjíbítì yóò sì mọ̀ dájúdájú pé èmi ni Jèhófà nígbà tí mo bá na ọwọ́ mi jáde lòdì sí Íjíbítì,+ ní ti gidi, èmi yóò sì mú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì jáde kúrò ní àárín wọn.”+  Mósè àti Áárónì sì tẹ̀ síwájú ní ṣíṣe gẹ́gẹ́ bí Jèhófà ti pàṣẹ fún wọn.+ Wọ́n ṣe bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́.+  Mósè sì jẹ́ ẹni ọgọ́rin ọdún, tí Áárónì sì jẹ́ ẹni ọdún mẹ́tàlélọ́gọ́rin ní ìgbà tí wọ́n ń bá Fáráò sọ̀rọ̀.+  Wàyí o, Jèhófà wí fún Mósè àti Áárónì pé:  “Bí ó bá ṣẹlẹ̀ pé Fáráò sọ fún yín, pé, ‘Ẹ ṣe iṣẹ́ ìyanu kan fún ara yín,’+ nígbà náà, kí o wí fún Áárónì pé, ‘Mú ọ̀pá rẹ,+ kí o sì sọ ọ́ sílẹ̀ níwájú Fáráò.’ Yóò di ejò ńlá.”+ 10  Nítorí náà, Mósè àti Áárónì wọlé lọ bá Fáráò, wọ́n sì ṣe gan-an gẹ́gẹ́ bí Jèhófà ti pàṣẹ. Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, Áárónì sọ ọ̀pá rẹ̀ sílẹ̀ níwájú Fáráò àti àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀, ó sì di ejò ńlá. 11  Bí ó ti wù kí ó rí, Fáráò pẹ̀lú pe àwọn ọlọ́gbọ́n àti àwọn oníṣẹ́ oṣó;+ àwọn àlùfáà pidánpidán Íjíbítì fúnra wọn pẹ̀lú sì bẹ̀rẹ̀ sí fi idán pípa+ wọn ṣe ohun kan náà. 12  Nítorí náà, olúkúlùkù wọn sọ ọ̀pá rẹ̀ sílẹ̀, wọ́n sì di ejò ńlá; ṣùgbọ́n ọ̀pá Áárónì gbé ọ̀pá wọn mì. 13  Síbẹ̀síbẹ̀, ọkàn-àyà Fáráò di èyí tí ó ṣoríkunkun,+ kò sì fetí sí wọn, gan-an gẹ́gẹ́ bí Jèhófà ti wí. 14  Nígbà náà ni Jèhófà wí fún Mósè pé: “Ọkàn-àyà Fáráò ti gíràn-án.+ Ó ti kọ̀ láti rán àwọn ènìyàn náà lọ.+ 15  Lọ bá Fáráò ní òwúrọ̀. Wò ó! Ó ń jáde lọ síbi omi!+ Kí o sì fi ara rẹ sí ipò láti pàdé rẹ̀ ní etí Odò Náílì,+ ọ̀pá tí ó yí padà di ejò ni kí o sì mú dání ní ọwọ́ rẹ.+ 16  Kí o sì sọ fún un pé, ‘Jèhófà Ọlọ́run àwọn Hébérù rán mi sí ọ,+ pé: “Rán àwọn ènìyàn mi lọ kí wọ́n lè sìn mí ní aginjù,”+ ṣùgbọ́n kíyè sí i, ìwọ kò tíì ṣègbọràn títí di ìsinsìnyí. 17  Èyí ni ohun tí Jèhófà wí:+ “Nípa èyí ni ìwọ yóò fi mọ̀ pé èmi ni Jèhófà.+ Kíyè sí i, èmi yóò fi ọ̀pá tí ó wà ní ọwọ́ mi lu orí omi tí ó wà nínú Odò Náílì,+ dájúdájú, yóò sì yí padà di ẹ̀jẹ̀.+ 18  Àwọn ẹja tí ó wà nínú Odò Náílì yóò sì kú,+ Odò Náílì ní ti gidi yóò sì máa ṣíyàn-án,+ àpòlúkù àwọn ará Íjíbítì yóò sì wulẹ̀ kọ mímu omi Odò Náílì.”’”+ 19  Lẹ́yìn náà, Jèhófà wí fún Mósè pé: “Sọ fún Áárónì pé, ‘Mú ọ̀pá rẹ kí o sì na ọwọ́ rẹ+ sórí omi Íjíbítì, sórí àwọn odò wọn, sórí àwọn ipa odò Náílì wọn àti sórí àwọn odò adágún wọn tí ó kún fún esùsú+ àti sórí gbogbo ìkójọpọ̀ omi wọn, kí wọ́n lè di ẹ̀jẹ̀.’ Dájúdájú, ẹ̀jẹ̀ yóò sì wà ní gbogbo ilẹ̀ Íjíbítì àti nínú àwọn ohun èlò igi àti àwọn ohun èlò òkúta.” 20  Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, Mósè àti Áárónì ṣe bẹ́ẹ̀,+ gan-an gẹ́gẹ́ bí Jèhófà ti pàṣẹ,+ ó sì gbé ọ̀pá náà sókè, ó sì lu omi tí ó wà nínú Odò Náílì ní ojú Fáráò àti àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀,+ gbogbo omi tí ó wà nínú Odò Náílì sì yí padà di ẹ̀jẹ̀.+ 21  Àwọn ẹja tí ó wà nínú Odò Náílì sì kú,+ Odò Náílì sì bẹ̀rẹ̀ sí ṣíyàn-án; àwọn ara Íjíbítì kò sì lè mu omi Odò Náílì;+ ẹ̀jẹ̀ sì wá wà ní gbogbo ilẹ̀ Íjíbítì. 22  Síbẹ̀síbẹ̀, àwọn àlùfáà pidánpidán Íjíbítì bẹ̀rẹ̀ sí fi iṣẹ́ òkùnkùn+ wọn ṣe ohun kan náà; tí ó fi jẹ́ pé ọkàn-àyà Fáráò ń bá a lọ láti jẹ́ èyí tí ó ṣoríkunkun,+ kò sì fetí sí wọn, gan-an gẹ́gẹ́ bí Jèhófà ti wí.+ 23  Nítorí náà, Fáráò yí padà, ó sì lọ sí ilé rẹ̀, kò sì jẹ́ kí ọkàn-àyà rẹ̀ ṣàníyàn láti ka èyí sí nǹkan kan pẹ̀lú.+ 24  Gbogbo àwọn ará Íjíbítì sì bẹ̀rẹ̀ sí walẹ̀ yí ká Odò Náílì fún omi mímu, nítorí pé wọn kò lè mu omi kankan láti inú Odò Náílì.+ 25  Ọjọ́ méje sì wá pé lẹ́yìn tí Jèhófà lu Odò Náílì.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé