Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

Ẹ́kísódù 6:1-30

6  Nítorí náà, Jèhófà sọ fún Mósè pé: “Nísinsìnyí, ìwọ yóò rí ohun tí èmi yóò ṣe sí Fáráò,+ nítorí pé tìtorí ọwọ́ líle ni òun yóò fi rán wọn lọ, tìtorí ọwọ́ líle sì ni òun yóò fi lé wọn jáde kúrò ní ilẹ̀ rẹ̀.”+  Ọlọ́run sì ń bá a lọ láti bá Mósè sọ̀rọ̀, ó sì wí fún un pé: “Èmi ni Jèhófà.+  Èmi sì ti máa ń fara han Ábúráhámù,+ Ísákì+ àti Jékọ́bù+ ní Ọlọ́run Olódùmarè,+ ṣùgbọ́n ní ti orúkọ mi Jèhófà+ èmi ko sọ ara mi di mímọ̀+ fún wọn.  Mo sì tún fìdí májẹ̀mú mi múlẹ̀ pẹ̀lú wọn láti fún wọn ní ilẹ̀ Kénáánì, ilẹ̀ àtìpó wọn níbi tí wọ́n ti ṣe àtìpó.+  Èmi, àní èmi, sì ti gbọ́ ìkérora àwọn ọmọ Ísírẹ́lì,+ tí àwọn ará Íjíbítì sọ di ẹrú, mo sì rántí májẹ̀mú mi.+  “Nítorí náà, sọ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé, ‘Èmi ni Jèhófà, èmi yóò sì mú yín jáde dájúdájú kúrò lábẹ́ ẹrù ìnira àwọn ará Íjíbítì, èmi yóò sì dá yín nídè kúrò nínú ìsìnrú wọn,+ èmi yóò sì tún gbà yín padà ní ti gidi pẹ̀lú apá nínà jáde àti pẹ̀lú àwọn ìdájọ́ ńlá.+  Dájúdájú, èmi yóò sì mú yín sọ́dọ̀ ara mi gẹ́gẹ́ bí àwọn ènìyàn kan,+ èmi yóò sì jẹ́ Ọlọ́run fún yín ní ti tòótọ́+; dájúdájú, ẹ ó sì mọ̀ pé èmi ni Jèhófà Ọlọ́run yín tí ó mú yín jáde kúrò lábẹ́ ẹrù ìnira Íjíbítì.+  Dájúdájú, èmi yóò sì mú yín wá sí ilẹ̀ tí mo gbé ọwọ́ mi sókè ní ìbúra+ láti fi fún Ábúráhámù, Ísákì àti Jékọ́bù; èmi yóò sì fi í fún yín ní tòótọ́ gẹ́gẹ́ bí ohun ìní.+ Èmi ni Jèhófà.’”+  Lẹ́yìn náà, Mósè sọ̀rọ̀ nípa èyí fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, ṣùgbọ́n wọn kò fetí sí Mósè nítorí ìrẹ̀wẹ̀sì àti nítorí ìsìnrú nínira náà.+ 10  Nígbà náà ni Jèhófà sọ fún Mósè, pé: 11  “Wọlé, sọ fún Fáráò, ọba Íjíbítì,+ pé kí ó rán àwọn ọmọ Ísírẹ́lì lọ kúrò ní ilẹ̀ rẹ̀.”+ 12  Bí ó ti wù kí ó rí, Mósè sọ̀rọ̀ níwájú Jèhófà, pé: “Wò ó! Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kò tíì fetí sí mi;+ báwo sì ni Fáráò yóò ṣe fetí sí mi láé,+ níwọ̀n bí mo ti jẹ́ aláìdádọ̀dọ́ ètè?”+ 13  Ṣùgbọ́n Jèhófà ń bá a lọ láti bá Mósè àti Áárónì sọ̀rọ̀ àti láti pa àṣẹ nípasẹ̀ wọn fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì àti fún Fáráò, ọba Íjíbítì, kí a bàa lè mú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì jáde kúrò ní ilẹ̀ Íjíbítì.+ 14  Ìwọ̀nyí ni àwọn olórí ilé àwọn baba wọn: Àwọn ọmọkùnrin Rúbẹ́nì, àkọ́bí Ísírẹ́lì,+ ni Hánókù àti Pálù, Hésírónì àti Kámì.+ Ìwọ̀nyí ni àwọn ìdílé Rúbẹ́nì.+ 15  Àwọn ọmọkùnrin Síméónì sì ni Jémúélì àti Jámínì àti Óhádì àti Jákínì àti Sóhárì àti Ṣọ́ọ̀lù ọmọkùnrin obìnrin ará Kénáánì.+ Ìwọ̀nyí ni àwọn ìdílé Síméónì.+ 16  Ìwọ̀nyí sì ni orúkọ àwọn ọmọkùnrin Léfì,+ ní ìbámu pẹ̀lú orírun ìdílé wọn:+ Gẹ́ṣónì àti Kóhátì àti Mérárì.+ Ọdún ìgbésí ayé Léfì sì jẹ́ ọdún mẹ́tà-dín-lógóje. 17  Àwọn ọmọkùnrin Gẹ́ṣónì ni Líbínì àti Ṣíméì,+ ní ìbámu pẹ̀lú ìdílé wọn.+ 18  Àwọn ọmọkùnrin Kóhátì ni Ámúrámù àti Ísárì àti Hébúrónì àti Úsíélì.+ Ọdún ìgbésí ayé Kóhátì sì jẹ́ ọdún mẹ́tà-lé-láàádóje. 19  Àwọn ọmọkùnrin Mérárì sì ni Máhílì àti Múṣì.+ Ìwọ̀nyí ni ìdílé àwọn ọmọ Léfì, ní ìbámu pẹ̀lú orírun ìdílé wọn.+ 20  Wàyí o, Ámúrámù fi Jókébédì arábìnrin baba rẹ̀ ṣe aya rẹ̀.+ Lẹ́yìn náà, ó bí Áárónì àti Mósè fún un.+ Ọdún ìgbésí ayé Ámúrámù sì jẹ́ ọdún mẹ́tà-dín-lógóje. 21  Àwọn ọmọkùnrin Ísárì sì ni Kórà+ àti Néfégì àti Síkírì. 22  Àwọn ọmọkùnrin Úsíélì sì ni Míṣáẹ́lì àti Élísáfánì àti Sítírì.+ 23  Wàyí o, Áárónì fi Élíṣébà, ọmọbìnrin Ámínádábù, arábìnrin Náṣónì,+ ṣe aya rẹ̀. Lẹ́yìn náà, ó bí Nádábù àti Ábíhù, Élíásárì àti Ítámárì fún un.+ 24  Àwọn ọmọkùnrin Kórà sì ni Ásírì àti Ẹlikénà àti Ábíásáfù.+ Ìwọ̀nyí ni àwọn ìdílé ọmọ Kórà.+ 25  Élíásárì, ọmọkùnrin Áárónì,+ sì mú ọ̀kan nínú àwọn ọmọbìnrin Pútíélì fún ara rẹ̀ láti fi ṣe aya rẹ̀. Lẹ́yìn náà, ó bí Fíníhásì fún un.+ Ìwọ̀nyí ni àwọn olórí baba àwọn ọmọ Léfì, ní ìbámu pẹ̀lú ìdílé wọn.+ 26  Áárónì àti Mósè náà nìyí, àwọn ẹni tí Jèhófà sọ fún pé:+ “Ẹ mú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì jáde kúrò ní ilẹ̀ Íjíbítì ní ìbámu pẹ̀lú ẹgbẹ́ ọmọ ogun wọn.”+ 27  Àwọn ni wọ́n ń bá Fáráò, ọba Íjíbítì sọ̀rọ̀, láti mú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì jáde kúrò ní Íjíbítì.+ Mósè àti Áárónì náà nìyí. 28  Ó sì ṣẹlẹ̀ ní ọjọ́ tí Jèhófà bá Mósè sọ̀rọ̀ ní ilẹ̀ Íjíbítì,+ 29  pé Jèhófà ń bá a lọ láti sọ fún Mósè, pé: “Èmi ni Jèhófà.+ Sọ gbogbo ohun tí mo ń sọ fún ọ fún Fáráò ọba Íjíbítì.” 30  Nígbà náà ni Mósè wí níwájú Jèhófà pé: “Wò ó! Mo jẹ́ aláìdádọ̀dọ́ ètè, nítorí náà, báwo ni Fáráò yóò ṣe fetí sí mi láé?”+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé