Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Ẹ́kísódù 5:1-23

5  Lẹ́yìn náà, Mósè àti Áárónì sì wọlé, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí wí fún Fáráò pé:+ “Èyí ni ohun tí Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì wí, ‘Rán àwọn ènìyàn mi lọ, kí wọ́n lè ṣe àjọyọ̀ fún mi ní aginjù.’”+  Ṣùgbọ́n Fáráò wí pé: “Ta ni Jèhófà,+ tí èmi yóò fi ṣègbọràn sí ohùn rẹ̀ láti rán Ísírẹ́lì lọ?+ Èmi kò mọ Jèhófà rárá+ àti pé, jù bẹ́ẹ̀ lọ, èmi kì yóò rán Ísírẹ́lì lọ.”+  Bí ó ti wù kí ó rí, wọ́n ń bá a lọ láti wí pé: “Ọlọ́run àwọn Hébérù ti kàn sí wa.+ Jọ̀wọ́, àwa fẹ́ lọ ìrìn àjò ọlọ́jọ́ mẹ́ta sí aginjù, kí a sì rúbọ sí Jèhófà Ọlọ́run wa;+ bí bẹ́ẹ̀ kọ́, ó lè fi àjàkálẹ̀ àrùn tàbí idà kọlù wá.”+  Látàrí èyí, ọba Íjíbítì wí fún wọn pé: “Èé ṣe, Mósè àti Áárónì, tí ẹ fi mú kí àwọn ènìyàn náà kúrò nídìí iṣẹ́ wọn?+ Ẹ lọ máa ru ẹrù ìnira yín!”+  Fáráò sì ń bá a lọ pé: “Wò ó! Àwọn ènìyàn ilẹ̀ náà ti pọ̀ nísinsìnyí,+ ẹ̀yin ní ti gidi sì mú kí wọ́n ṣíwọ́ lẹ́nu rírù tí wọ́n ń ru ẹrù ìnira.”+  Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, ní ọjọ́ yẹn, Fáráò pàṣẹ fún àwọn tí ń kó àwọn ènìyàn náà ṣiṣẹ́ àti àwọn onípò àṣẹ láàárín wọn,+ pé:  “Ẹ kò gbọ́dọ̀ kó èérún pòròpórò jọ láti fún àwọn ènìyàn náà láti fi ṣe bíríkì+ bí ti tẹ́lẹ̀ rí. Ẹ jẹ́ kí àwọn fúnra wọn lọ máa kó èérún pòròpórò jọ fún ara wọn.  Jù bẹ́ẹ̀ lọ, iye bíríkì tí a béèrè, tí wọn ń ṣe tẹ́lẹ̀ rí, ni ẹ óò gbé kà wọ́n lórí síwájú sí i. Ẹ kò gbọ́dọ̀ dín nǹkan kan kù fún wọn, nítorí wọ́n ń dẹwọ́.+ Ìdí nìyẹn tí wọ́n fi ń ké jáde, pé, ‘Àwa fẹ́ lọ, àwa fẹ́ rúbọ sí Ọlọ́run wa!’+  Ẹ jẹ́ kí iṣẹ́ ìsìn wúwo lórí àwọn ọkùnrin náà, ẹ sì jẹ́ kí wọ́n máa ṣiṣẹ́ kára lórí rẹ̀, ẹ má sì jẹ́ kí wọ́n fiyè sí àwọn ọ̀rọ̀ èké.”+ 10  Nítorí náà, àwọn tí ń kó àwọn ènìyàn náà ṣiṣẹ́+ àti àwọn onípò àṣẹ láàárín wọn jáde lọ, wọ́n sì wí fún àwọn ènìyàn náà pé: “Ohun tí Fáráò wí nìyí, ‘Èmi kò ní fún yín ní èérún pòròpórò kankan mọ́. 11  Ẹ̀yin fúnra yín ẹ lọ, ẹ wá èérún pòròpórò fún ara yín ní ibikíbi tí ẹ bá ti lè rí i, nítorí a kò ní dín bíńtín kankan kù nínú iṣẹ́ ìsìn yín.’”+ 12  Nítorí náà, àwọn ènìyàn náà tú káàkiri gbogbo ilẹ̀ Íjíbítì láti kó àgékù pòròpórò jọ fún ṣíṣe èérún pòròpórò. 13  Àwọn tí ń kó wọn ṣiṣẹ́ sì ń kán wọ́n lójú ṣáá,+ pé: “Ẹ parí iṣẹ́ yín, olúkúlùkù iṣẹ́ rẹ̀, ti òòjọ́ fún òòjọ́, gan-an bí ìgbà tí èérún pòròpórò wà lárọ̀ọ́wọ́tó.”+ 14  Lẹ́yìn náà, a lu+ àwọn onípò àṣẹ+ láàárín àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, àwọn tí àwọn akóniṣiṣẹ́ Fáráò yàn lé wọ́n lórí, àwọn wọ̀nyí wí pé: “Èé ṣe tí ẹ kò fi parí iṣẹ́ ìmúnisìn tí a lànà sílẹ̀ fún yín ní ṣíṣe àwọn bíríkì+ bí ti tẹ́lẹ̀ rí, ní àná àti òní?”+ 15  Nítorí náà, àwọn onípò àṣẹ+ láàárín àwọn ọmọ Ísírẹ́lì wọlé, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí ké jáde sí Fáráò, pé: “Èé ṣe tí o fi bá àwọn ìránṣẹ́ rẹ lò lọ́nà yìí? 16  A kò fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ ní èérún pòròpórò, síbẹ̀ wọ́n sì ń sọ fún wa pé, ‘Ẹ máa ṣe bíríkì!’ sì kíyè sí i, a lu àwọn ìránṣẹ́ rẹ, nígbà tí ó jẹ́ pé àléébù náà jẹ́ ti àwọn ènìyàn rẹ.”+ 17  Ṣùgbọ́n, ó wí pé: “Ẹ ń dẹwọ́, ẹ ń dẹwọ́!+ Ìdí nìyẹn tí ẹ fi ń wí pé, ‘A fẹ́ lọ, a fẹ́ rúbọ sí Jèhófà.’+ 18  Ẹ lọ nísinsìnyí, kí ẹ sì sìn! Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé a kì yóò fún yín ní èérún pòròpórò, síbẹ̀ ẹ ní láti fúnni ní iye bíríkì tí a fi lélẹ̀ pàtó.”+ 19  Nígbà náà ni àwọn onípò àṣẹ láàárín àwọn ọmọ Ísírẹ́lì rí ara wọn nínú ipò ìṣòro tí ó burú nítorí àsọjáde náà pé:+ “Ẹ kò gbọ́dọ̀ yọ bíńtín kankan kúrò nínú iye bíríkì ojoojúmọ́ ẹnikẹ́ni nínú yín.”+ 20  Lẹ́yìn ìyẹn, wọ́n pàdé Mósè àti Áárónì,+ tí wọ́n ń dúró níbẹ̀ láti pàdé wọn bí wọ́n ti jáde kúrò lọ́dọ̀ Fáráò. 21  Lójú-ẹsẹ̀, wọ́n wí fún wọn pé: “Kí Jèhófà bojú wò yín kí ó sì ṣe ìdájọ́,+ níwọ̀n bí ẹ ti sọ wá di òórùn burúkú+ níwájú Fáráò àti níwájú àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ láti lè fi idà lé wọn lọ́wọ́ láti pa wá.”+ 22  Nígbà náà ni Mósè yíjú sí Jèhófà,+ ó sì wí pé: “Jèhófà, èé ṣe tí o fi mú ibi bá àwọn ènìyàn yìí?+ Èé ṣe tí o fi rán mi?+ 23  Nítorí láti ìgbà tí mo ti wọlé wá síwájú Fáráò láti sọ̀rọ̀ ní orúkọ rẹ,+ ni ó ti ń ṣe ibi sí àwọn ènìyàn yìí,+ ìwọ kò sì dá àwọn ènìyàn rẹ nídè lọ́nàkọnà.”+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé