Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

Ẹ́kísódù 40:1-38

40  Nígbà náà ni Jèhófà sọ fún Mósè, pé:  “Ní ọjọ́ oṣù àkọ́kọ́,+ ọjọ́ kìíní oṣù náà, ni kí o gbé àgọ́ ìjọsìn ti àgọ́ ìpàdé nà ró.+  Kí o sì gbé àpótí gbólóhùn ẹ̀rí+ sínú rẹ̀, kí o sì ta aṣọ ìkélé dí ọ̀nà àbáwọlé síbi Àpótí náà.+  Kí o sì gbé tábìlì+ náà wọlé, kí o sì ṣètò àwọn ohun tí ó yẹ ní títò sórí rẹ̀, kí o gbé ọ̀pá fìtílà+ wọlé, kí o sì tan àwọn fìtílà rẹ̀.+  Kí o sì gbé pẹpẹ wúrà kalẹ̀ fún tùràrí+ níwájú àpótí gbólóhùn ẹ̀rí, kí o sì fi àtabojú ẹnu ọ̀nà fún àgọ́ ìjọsìn sí àyè rẹ̀.+  “Kí o gbé pẹpẹ+ ọrẹ ẹbọ sísun síwájú ẹnu ọ̀nà àgọ́ ìjọsìn ti àgọ́ ìpàdé,  kí o sì gbé bàsíà sáàárín àgọ́ ìpàdé àti pẹpẹ, kí o sì bu omi sínú rẹ̀.+  Kí o sì ṣe àgbàlá+ yí ká, kí o sì ta àtabojú+ ẹnubodè àgbàlá náà.  Kí o sì bu òróró àfiyanni,+ kí o sì fòróró yan àgọ́ ìjọsìn náà àti gbogbo ohun tí ó wà nínú rẹ̀,+ kí o sì sọ ọ́ di mímọ́ àti gbogbo nǹkan èlò rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni kí ó sì di ohun mímọ́. 10  Kí o sì fòróró yan pẹpẹ ọrẹ ẹbọ sísun àti gbogbo nǹkan èlò rẹ̀, kí o sì sọ pẹpẹ náà di mímọ́,+ bẹ́ẹ̀ ni kí ó sì di pẹpẹ mímọ́ jù lọ.+ 11  Kí o sì fòróró yan bàsíà àti ẹsẹ̀ rẹ̀, kí o sì sọ ọ́ di mímọ́. 12  “Lẹ́yìn náà, kí o mú Áárónì àti àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ sún mọ́ ẹnu ọ̀nà àgọ́ ìpàdé, kí o sì fi omi wẹ̀ wọ́n.+ 13  Kí o sì fi ẹ̀wù mímọ́+ wọ Áárónì, kí o sì fòróró yàn án,+ kí o sì sọ ọ́ di mímọ́, nípa bẹ́ẹ̀, kí ó sì máa ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí àlùfáà fún mi. 14  Lẹ́yìn ìyẹn, ìwọ yóò mú àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ sún mọ́ tòsí, kí o sì fi aṣọ wọ̀ wọ́n.+ 15  Kí o sì fòróró yàn wọ́n gan-an gẹ́gẹ́ bí o ti fòróró yan baba wọn,+ bẹ́ẹ̀ ni kí wọ́n sì ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí àlùfáà fún mi, kí ìfòróróyàn wọ́n sì wà títí lọ fún wọn gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ àlùfáà fún àkókò tí ó lọ kánrin ní ìran-ìran wọn.”+ 16  Mósè sì bẹ̀rẹ̀ sí ṣe gẹ́gẹ́ bí gbogbo ohun tí Jèhófà pa láṣẹ fún un.+ Ó ṣe bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́. 17  Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, ó ṣẹlẹ̀ pé ní oṣù kìíní, ní ọdún kejì, ní ọjọ́ kìíní oṣù náà, a gbé àgọ́ ìjọsìn náà nà ró.+ 18  Nígbà tí Mósè bẹ̀rẹ̀ sí gbé àgọ́ ìjọsìn náà nà ró, ó ń fi àwọn ìtẹ́lẹ̀ oníhò ìtẹ̀bọ̀ rẹ̀+ sọlẹ̀, ó sì ń fi àwọn férémù rẹ̀+ sí i, ó sì ń fi àwọn ọ̀pá gbọọrọ rẹ̀+ sí i, ó sì ń gbé àwọn ọwọ̀n rẹ̀+ nà ró. 19  Lẹ́yìn náà, ó na ìbòrí+ náà lé àgọ́ ìjọsìn lórí, ó sì fi ìbòrí ìta+ bò ó lókè, gan-an gẹ́gẹ́ bí Jèhófà ti pàṣẹ fún Mósè. 20  Lẹ́yìn ìyẹn, ó mú Gbólóhùn Ẹ̀rí+ náà, ó sì fi í sínú Àpótí,+ ó sì kó àwọn ọ̀pá+ sórí Àpótí náà, ó sì fi ìbòrí+ bo Àpótí+ náà. 21  Lẹ́yìn náà, ó gbé Àpótí náà wá sínú àgọ́ ìjọsìn, ó sì fi aṣọ ìkélé+ àtabojú sí àyè rẹ̀, ó sì dí ọ̀nà àbáwọlé síbi àpótí gbólóhùn ẹ̀rí,+ gan-an gẹ́gẹ́ bí Jèhófà ti pàṣẹ fún Mósè. 22  Lẹ́yìn náà, ó gbé tábìlì+ sínú àgọ́ ìpàdé lẹ́gbẹ̀ẹ́ àgọ́ ìjọsìn ní apá àríwá lẹ́yìn aṣọ ìkélé náà, 23  ó sì ṣètò búrẹ́dì+ lẹ́sẹẹsẹ sórí rẹ̀ níwájú Jèhófà, gan-an gẹ́gẹ́ bí Jèhófà ti pàṣẹ fún Mósè. 24  Lẹ́yìn náà, ó gbé ọ̀pá fìtílà+ sínú àgọ́ ìpàdé ní iwájú tábìlì náà, lẹ́gbẹ̀ẹ́ àgọ́ ìjọsìn náà ní apá gúúsù. 25  Lẹ́yìn náà, ó tan àwọn fìtílà+ náà níwájú Jèhófà, gan-an gẹ́gẹ́ bí Jèhófà ti pàṣẹ fún Mósè. 26  Lẹ́yìn náà, ó gbé pẹpẹ wúrà+ sínú àgọ́ ìpàdé níwájú aṣọ ìkélé, 27  kí ó lè mú tùràrí onílọ́fínńdà rú èéfín lórí rẹ̀,+ gan-an gẹ́gẹ́ bí Jèhófà ti pàṣẹ fún Mósè. 28  Níkẹyìn, ó fi àtabojú+ ẹnu ọ̀nà àgọ́ ìjọsìn náà sí àyè rẹ̀. 29  Ó sì gbé pẹpẹ+ ọrẹ ẹbọ sísun sí ẹnu ọ̀nà àgọ́ ìjọsìn ti àgọ́ ìpàdé, kí ó lè fi ọrẹ ẹbọ sísun+ àti ọrẹ ẹbọ ọkà rúbọ lórí rẹ̀, gan-an gẹ́gẹ́ bí Jèhófà ti pàṣẹ fún Mósè. 30  Lẹ́yìn náà, ó gbé bàsíà sáàárín àgọ́ ìpàdé àti pẹpẹ, ó sì bu omi sínú rẹ̀ fún wíwẹ̀.+ 31  Mósè àti Áárónì àti àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ sì wẹ ọwọ́ wọn àti ẹsẹ̀ wọn níbẹ̀. 32  Nígbà tí wọ́n bá ń lọ sínú àgọ́ ìpàdé àti nígbà tí wọ́n bá ń sún mọ́ pẹpẹ, wọ́n a wẹ̀,+ gan-an gẹ́gẹ́ bí Jèhófà ti pàṣẹ fún Mósè. 33  Níkẹyìn, ó ṣe àgbàlá+ yí ká àgọ́ ìjọsìn àti pẹpẹ, ó sì fi àtabojú ẹnubodè àgbàlá+ sí i. Nípa bẹ́ẹ̀, Mósè parí iṣẹ́ náà. 34  Àwọsánmà+ sì bẹ̀rẹ̀ sí bo àgọ́ ìpàdé, ògo Jèhófà sì kún inú àgọ́ ìjọsìn náà. 35  Mósè kò sì lè lọ sínú àgọ́ ìpàdé náà, nítorí pé, àwọsánmà+ wà lórí rẹ̀, ògo Jèhófà sì kún inú àgọ́ ìjọsìn náà.+ 36  Nígbà tí àwọsánmà bá sì gbéra sókè kúrò lórí àgọ́ ìjọsìn náà, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì yóò ṣí ibùdó ní gbogbo ipele ìrìn àjò wọn.+ 37  Bí ó ti wù kí ó rí, bí àwọsánmà náà kò bá gbéra sókè, nígbà náà, wọn kì yóò ṣí ibùdó títí di ọjọ́ tí ó bá gbéra sókè.+ 38  Nítorí àwọsánmà Jèhófà wà lórí àgọ́ ìjọsìn náà ní ọ̀sán, iná sì máa ń wà lórí rẹ̀ ní òru lójú gbogbo ilé Ísírẹ́lì ní gbogbo ipele ìrìn àjò wọn.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé