Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

Ẹ́kísódù 4:1-31

4  Bí ó ti wù kí ó rí, ní dídáhùn, Mósè wí pé: “Ṣùgbọ́n ká ní wọn kò gbà mí gbọ́ tí wọn kò sì fetí sí ohùn mi,+ nítorí wọn yóò wí pé, ‘Jèhófà kò fara hàn ọ́.’”  Nígbà náà ni Jèhófà sọ fún un pé: “Kí ni ó wà ní ọwọ́ rẹ yẹn?” ó dáhùn pé: “Ọ̀pá.”+  Lẹ́yìn èyí, ó wí pé: “Sọ ọ́ sí ilẹ̀.” Nítorí náà, ó sọ ọ́ sí ilẹ̀, ó sì di ejò;+ Mósè sì bẹ̀rẹ̀ sí sá fún un.  Wàyí o, Jèhófà sọ fún Mósè pé: “Na ọwọ́ rẹ jáde, kí o sì gbá a ní ìrù mú.” Nítorí náà, ó na ọwọ́ rẹ̀ jáde, ó sì gbá a mú, ó sì di ọ̀pá ní àtẹ́lẹwọ́ rẹ̀.  Láti fa ọ̀rọ̀ rẹ̀ yọ pé, “Kí wọ́n bàa lè gbà gbọ́ pé Jèhófà Ọlọ́run àwọn baba ńlá wọn,+ Ọlọ́run Ábúráhámù,+ Ọlọ́run Ísákì+ àti Ọlọ́run Jékọ́bù,+ ti fara hàn ọ́.”+  Nígbà náà ni Jèhófà sọ fún un lẹ́ẹ̀kan sí i pé: “Jọ̀wọ́, ki ọwọ́ rẹ bọ ibi tí ẹ̀wù rẹ ti ṣẹ́po lókè.” Nítorí náà, ó ki ọwọ́ rẹ̀ bọ ibi tí ẹ̀wù rẹ̀ ti ṣẹ́po lókè. Nígbà tí ó fà á yọ, họ́wù, kíyè sí i, ẹ̀tẹ̀ bo ọwọ́ rẹ̀ bí ìrì dídì!+  Lẹ́yìn ìyẹn, ó sọ pé: “Dá ọwọ́ rẹ padà sí ibi tí ẹ̀wù rẹ ti ṣẹ́po lókè.” Nítorí náà, ó dá ọwọ́ rẹ̀ padà sí ibi tí ẹ̀wù rẹ̀ ti ṣẹ́po lókè. Nígbà tí ó fà á yọ láti ibi tí ẹ̀wù rẹ̀ ti ṣẹ́po lókè, họ́wù, kíyèsí i, a ti mú un padà bọ̀ sípò bí ìyókù ara rẹ̀!+  Láti fa ọ̀rọ̀ rẹ̀ yọ pé, “Yóò sì ṣẹlẹ̀ pé bí wọn kò bá ní gbà ọ́ gbọ́, tí wọn kò sì ní fetí sí ohùn iṣẹ́ àmì àkọ́kọ́, dájúdájú, nígbà náà, wọn yóò gba ohùn iṣẹ́ àmì ìkẹ́yìn gbọ́.+  Síbẹ̀síbẹ̀, yóò sì ṣẹlẹ̀ pé, bí wọn kò bá ní gba iṣẹ́ àmì méjì wọ̀nyí pàápàá gbọ́, tí wọn kò sì ní fetí sí ohùn rẹ,+ nígbà náà, ìwọ yóò ní láti bu omi díẹ̀ láti inú Odò Náílì, kí o sì dà á sórí ilẹ̀ gbígbẹ;+ omi tí ìwọ yóò sì bù láti inú Odò Náílì yóò di, bẹ́ẹ̀ ni, dájúdájú, yóò di ẹ̀jẹ̀ ní ti gidi lórí ilẹ̀ gbígbẹ.” 10  Wàyí o, Mósè wí fún Jèhófà pé: “Dákun, Jèhófà, ṣùgbọ́n èmi kì í ṣe ẹni tí ń sọ̀rọ̀ lọ́nà tí ó já geere, kì í ṣe láti àná, bẹ́ẹ̀ ni kì í ṣe ṣáájú ìgbà yẹn tàbí láti ìgbà tí o ti ń bá ìránṣẹ́ rẹ sọ̀rọ̀, nítorí ẹnu mi wúwo, ahọ́n mi sì wúwo.”+ 11  Látàrí ìyẹn, Jèhófà sọ fún un pé: “Ta ní yan ẹnu fún ènìyàn tàbí ta ní yan ẹni tí kò lè sọ̀rọ̀ tàbí adití tàbí ẹni tí ó ríran kedere tàbí afọ́jú? Èmi Jèhófà ha kọ́ ni?+ 12  Nítorí náà, lọ nísinsìnyí, èmi alára yóò sì wà pẹ̀lú ẹnu rẹ, èmi yóò sì kọ́ ọ ní ohun tí ó yẹ kí o sọ.”+ 13  Ṣùgbọ́n òun wí pé: “Dákun, Jèhófà, ṣùgbọ́n, jọ̀wọ́, ránṣẹ́ nípa ọwọ́ ẹni tí ìwọ yóò rán.” 14  Nígbà náà ni ìbínú Jèhófà gbóná sí Mósè, ó sì wí pé: “Áárónì ọmọ Léfì kì í ha ṣe arákùnrin rẹ?+ Mo mọ̀ ní tòótọ́ pé ó lè sọ̀rọ̀ ní ti gidi. Àti pé, ní àfikún, kíyè sí i, ó ti mú ọ̀nà rẹ̀ pọ̀n láti wá pàdé rẹ. Nígbà tí ó bá rí ọ, dájúdájú, òun yóò yọ̀ nínú ọkàn-àyà rẹ̀.+ 15  Ìwọ yóò sì bá a sọ̀rọ̀, kí o sì fi ọ̀rọ̀ sí ẹnu rẹ̀;+ èmi alára yóò sì wà pẹ̀lú ẹnu rẹ àti ẹnu rẹ̀,+ dájúdájú, èmi yóò sì kọ́ yín ní ohun tí ẹ ó ṣe.+ 16  Òun yóò sì bá àwọn ènìyàn náà sọ̀rọ̀ fún ọ; yóò sì ṣẹlẹ̀ pé òun yóò ṣe bí ẹnu fún ọ,+ ìwọ yóò sì ṣe bí Ọlọ́run fún un.+ 17  Ọ̀pá yìí ni ìwọ yóò sì mú ní ọwọ́ rẹ kí o lè máa fi ṣe iṣẹ́ àmì.”+ 18  Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, Mósè lọ, ó sì padà sọ́dọ̀ Jẹ́tírò baba ìyàwó rẹ̀, ó sì wí fún un pé:+ “Jọ̀wọ́, mo fẹ́ lọ, kí n sì padà sọ́dọ̀ àwọn arákùnrin mi tí ń bẹ ní Íjíbítì kí n lè rí bóyá wọ́n ṣì wà láàyè.”+ Nítorí náà, Jẹ́tírò wí fún Mósè pé: “Máa lọ ní àlàáfíà.”+ 19  Lẹ́yìn ìyẹn, Jèhófà wí fún Mósè ní Mídíánì pé: “Lọ, padà sí Íjíbítì, nítorí pé, gbogbo ènìyàn tí ń dọdẹ ọkàn rẹ ti kú.”+ 20  Nígbà náà ni Mósè mú aya àti àwọn ọmọkùnrin rẹ̀, ó sì mú wọn gun kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, ó sì tẹ̀ síwájú láti padà sí ilẹ̀ Íjíbítì. Jù bẹ́ẹ̀ lọ, Mósè mú ọ̀pá Ọlọ́run tòótọ́ dání ní ọwọ́ rẹ̀.+ 21  Jèhófà sì ń bá a lọ láti sọ fún Mósè pé: “Lẹ́yìn tí o bá ti lọ, tí o sì ti padà sí Íjíbítì, rí i pé ní ti gidi gbogbo iṣẹ́ ìyanu tí mo ti fi sí ọwọ́ rẹ ni o ṣe níwájú Fáráò.+ Ní tèmi, èmi yóò jẹ́ kí ọkàn-àyà rẹ̀ di èyí tí ó ṣoríkunkun;+ òun kì yóò sì rán àwọn ènìyàn náà lọ.+ 22  Ìwọ yóò sì sọ fún Fáráò pé, ‘Èyí ni ohun tí Jèhófà wí: “Ọmọkùnrin mi ni Ísírẹ́lì, àkọ́bí mi.+ 23  Mo sì wí fún ọ: Rán ọmọ mi lọ kí ó lè sìn mí. Ṣùgbọ́n bí ìwọ bá kọ̀ láti rán an lọ, kíyè sí i èmi yóò pa ọmọkùnrin rẹ, àkọ́bí rẹ.”’”+ 24  Wàyí o, ó ṣẹlẹ̀ lójú ọ̀nà ní ibùwọ̀+ pé Jèhófà pàdé rẹ̀,+ ó sì ń wá ọ̀nà láti fi ikú pa á.+ 25  Níkẹyìn, Sípórà+ mú akọ òkúta, ó sì dá adọ̀dọ́+ ọmọkùnrin rẹ̀, ó sì mú kí ó kan ẹsẹ̀ rẹ̀, ó sì wí pé: “Nítorí pé ọkọ ìyàwó ẹ̀jẹ̀ ni o jẹ́ fún mi.” 26  Nítorí náà, ó jẹ́ kí ó lọ. Ní àkókò yẹn, obìnrin náà wí pé: “Ọkọ ìyàwó ẹ̀jẹ̀,” nítorí ìdádọ̀dọ́. 27  Nígbà náà ni Jèhófà sọ fún Áárónì pé: “Lọ pàdé Mósè ní aginjù.”+ Pẹ̀lú ìyẹn, ó lọ, ó sì pàdé rẹ̀ ní òkè ńlá Ọlọ́run tòótọ́,+ ó sì fi ẹnu kò ó lẹ́nu. 28  Mósè sì bẹ̀rẹ̀ sí sọ gbogbo ọ̀rọ̀ Jèhófà, ẹni tí ó rán an,+ fún Áárónì àti gbogbo iṣẹ́ àmì tí ó ti pa láṣẹ fún un pé kí ó ṣe.+ 29  Lẹ́yìn ìyẹn, Mósè àti Áárónì lọ, wọ́n sì kó gbogbo àgbà ọkùnrin àwọn ọmọ Ísírẹ́lì jọ.+ 30  Nígbà náà ni Áárónì sọ gbogbo ọ̀rọ̀ tí Jèhófà sọ fún Mósè,+ ó sì ṣe àwọn iṣẹ́ àmì+ lójú àwọn ènìyàn náà. 31  Látàrí èyí, àwọn ènìyàn náà gbà gbọ́.+ Nígbà tí wọ́n gbọ́ pé Jèhófà ti yí àfiyèsí+ rẹ̀ sí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì àti pé ó ti rí ṣíṣẹ́ tí a ń ṣẹ́ wọn níṣẹ̀ẹ́,+ nígbà náà ni wọ́n tẹrí ba, wọ́n sì wólẹ̀.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé