Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Ẹ́kísódù 39:1-43

39  Láti inú fọ́nrán òwú aláwọ̀ búlúù àti irun àgùntàn tí a fi àwọ̀ àlùkò àdàpọ̀-mọ́-pupa pa láró àti òwú aláwọ̀ rírẹ̀dòdò ti kòkòrò kókọ́sì+ ni wọ́n ti ṣe ẹ̀wù+ tí ó ní iṣẹ́ ọnà àfọwọ́hun fún ṣíṣe ìránṣẹ́ ní ibi mímọ́.+ Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ṣe ẹ̀wù mímọ́+ tí ó wà fún Áárónì, gan-an gẹ́gẹ́ bí Jèhófà ti pàṣẹ fún Mósè.  Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, ó ṣe éfódì+ láti inú wúrà, fọ́nrán òwú aláwọ̀ búlúù àti irun àgùntàn tí a fi àwọ̀ àlùkò àdàpọ̀-mọ́-pupa pa láró àti òwú aláwọ̀ rírẹ̀dòdò ti kòkòrò kókọ́sì àti aṣọ ọ̀gbọ̀ àtàtà lílọ́.  Lẹ́yìn náà, wọ́n fi wúrà pẹlẹbẹ-pẹlẹbẹ rọ àwọn abala fẹ́lẹ́fẹ́lẹ́, ó sì gé àwọn fọ́nrán òwú láti fi sí àárín fọ́nrán òwú aláwọ̀ búlúù àti irun àgùntàn tí a fi àwọ̀ àlùkò àdàpọ̀-mọ́-pupa pa láró àti òwú aláwọ̀ rírẹ̀dòdò ti kòkòrò kókọ́sì àti aṣọ ọ̀gbọ̀ àtàtà, gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ akóṣẹ́-ọnà-sáṣọ.+  Wọ́n ṣe àwọn aṣọ èjìká tí a so pọ̀ fún un. A so ó pọ̀ ní ìkángun rẹ̀ méjèèjì.  Àti àmùrè náà, tí ó wà lórí rẹ̀ fún síso ó pinpin, jẹ́ irú aṣọ kan náà ní ìbámu pẹ̀lú iṣẹ́ ọnà rẹ̀, ti wúrà, fọ́nrán òwú aláwọ̀ búlúù, àti irun àgùntàn tí a fi àwọ̀ àlùkò àdàpọ̀-mọ́-pupa pa láró àti òwú aláwọ̀ rírẹ̀dòdò ti kòkòrò kókọ́sì àti aṣọ ọ̀gbọ̀ àtàtà lílọ́,+ gan-an gẹ́gẹ́ bí Jèhófà ti pàṣẹ fún Mósè.  Lẹ́yìn náà, wọ́n ṣe òkúta ónísì+ tí a lẹ̀ mọ́ ojú ibi ìlẹ̀mọ́ tí a fi wúrà ṣe, tí a fi iṣẹ́ ọ̀nà fífín èdìdì fín ní ìbámu pẹ̀lú orúkọ àwọn ọmọkùnrin Ísírẹ́lì.+  Nípa bẹ́ẹ̀, ó fi wọ́n sára àwọn aṣọ éfódì èjìká gẹ́gẹ́ bí àwọn òkúta ìrántí+ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, gan-an gẹ́gẹ́ bí Jèhófà ti pàṣẹ fún Mósè.  Lẹ́yìn náà, ó fi iṣẹ́ ọnà akóṣẹ́-ọnà-sáṣọ ṣe aṣọ ìgbàyà+ náà, bí iṣẹ́ ọnà éfódì, láti inú wúrà, fọ́nrán òwú aláwọ̀ búlúù àti irun àgùntàn tí a fi àwọ̀ àlùkò àdàpọ̀-mọ́-pupa pa láró àti òwú aláwọ̀ rírẹ̀dòdò ti kòkòrò kókọ́sì àti aṣọ ọ̀gbọ̀ àtàtà lílọ́.+  Ó jẹ́ igun mẹ́rin lọ́gbọọgba nígbà tí a bá ṣẹ́ ẹ po sí méjì. Wọ́n jẹ́ aṣọ ìgbàyà, nígbà tí a bá ṣẹ́ ẹ po sí méjì, ìbú àtẹ́lẹwọ́ ní gígùn rẹ̀ àti ìbú àtẹ́lẹwọ́ ní fífẹ̀ rẹ̀.+ 10  Lẹ́yìn náà, wọ́n fi ẹsẹ mẹ́rin àwọn òkúta dí inú rẹ̀. Ẹsẹ rúbì, tópásì àti émírádì jẹ́ ẹsẹ àkọ́kọ́.+ 11  Ẹsẹ kejì+ sì ni tọ́kọ́ásì, sàfáyà+ àti jásípérì.+ 12  Ẹsẹ kẹta+ ni òkúta léṣémù, ágétì àti ámétísì. 13  Ẹsẹ kẹrin+ sì ni kírísóláítì àti ónísì+ àti jéèdì. A lẹ̀ wọ́n mọ́ ojú ibi ìlẹ̀mọ́ tí a fi wúrà ṣe nínú ihò tí a fi wọ́n dí. 14  Àwọn òkúta náà sì wà ní ìbámu pẹ̀lú orúkọ àwọn ọmọkùnrin Ísírẹ́lì. Wọ́n jẹ́ méjìlá ní ìbámu pẹ̀lú orúkọ wọn, tí a fín ní iṣẹ́ ọ̀nà fífín èdìdì, ọ̀kọ̀ọ̀kan ní ìbámu pẹ̀lú orúkọ rẹ̀ fún àwọn ẹ̀yà méjìlá náà.+ 15  Wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí ṣe ẹ̀wọ̀n kíká sára aṣọ ìgbàyà náà, ní iṣẹ́ ọnà lílọ́, tí a fi ògidì wúrà ṣe.+ 16  Lẹ́yìn náà, wọ́n ṣe ojú ibi ìlẹ̀mọ́ méjì tí a fi wúrà ṣe àti òrùka méjì tí a fi wúrà ṣe, wọ́n sì fi òrùka méjèèjì náà sí ìkángun méjì aṣọ ìgbàyà náà.+ 17  Lẹ́yìn ìyẹn, wọ́n mú ìjàrá méjèèjì tí a fi wúrà ṣe náà gba inú òrùka méjèèjì ní àwọn ìkángun aṣọ ìgbàyà náà.+ 18  Wọ́n sì mú òpin méjì ìjàrá méjèèjì náà gba ojú ibi ìlẹ̀mọ́ méjì náà. Lẹ́yìn náà, wọ́n fi wọ́n sórí àwọn aṣọ éfódì èjìká, ní iwájú rẹ̀.+ 19  Lẹ́yìn èyí, wọ́n ṣe òrùka méjì tí a fi wúrà ṣe, wọ́n sì fi wọ́n sí ìkángun méjì aṣọ ìgbàyà náà ní etí rẹ̀, tí ó wà níhà éfódì ní inú.+ 20  Lẹ́yìn náà, wọ́n ṣe òrùka méjì tí a fi wúrà ṣe, wọ́n sì fi wọ́n sórí aṣọ éfódì èjìká méjèèjì ní ìsàlẹ̀, ní iwájú rẹ̀, nítòsí ibi ìsopọ̀ rẹ̀, lókè àmùrè éfódì náà.+ 21  Níkẹyìn, wọ́n fi okùn tín-ín-rín aláwọ̀ búlúù de àwọn òrùka aṣọ ìgbàyà náà mọ́ àwọn òrùka éfódì náà, kí ó lè máa wà lókè àmùrè éfódì náà, kí aṣọ ìgbàyà náà má bàa yẹ̀ kúrò ní òkè éfódì náà, gan-an gẹ́gẹ́ bí Jèhófà ti pàṣẹ fún Mósè.+ 22  Lẹ́yìn náà, ó ṣe aṣọ àwọ̀lékè tí kò lápá+ tí a ń gbé éfódì lé, iṣẹ́ ọnà olófì, gbogbo rẹ̀ jẹ́ ti fọ́nrán òwú aláwọ̀ búlúù. 23  Ojú ọrùn aṣọ àwọ̀lékè tí kò lápá náà wà ní àárín rẹ̀, bí ojú ọrùn ẹ̀wù tí a fi àdàrọ irin ṣe. Ojú ọrùn rẹ̀ ní ìgbátí yí ká, kí ó má bàa ya.+ 24  Lẹ́yìn náà, sí ìṣẹ́po etí aṣọ àwọ̀lékè tí kò lápá náà, wọ́n ṣe pómégíránétì láti inú fọ́nrán òwú aláwọ̀ búlúù àti irun àgùntàn tí a fi àwọ̀ àlùkò àdàpọ̀-mọ́-pupa pa láró àti òwú aláwọ̀ rírẹ̀dòdò ti kòkòrò kókọ́sì, tí a lọ́pọ̀.+ 25  Síwájú sí i, wọ́n fi ògidì wúrà ṣe àwọn agogo, wọ́n sì fi àwọn agogo náà sáàárín àwọn pómégíránétì+ náà yí ká sí ìṣẹ́po etí aṣọ àwọ̀lékè tí kò lápá náà, láàárín àwọn pómégíránétì náà; 26  agogo kan àti pómégíránétì kan, agogo kan àti pómégíránétì kan yí ká+ sí ìṣẹ́po etí aṣọ àwọ̀lékè tí kò lápá náà, fún ṣíṣe ìránṣẹ́, gan-an gẹ́gẹ́ bí Jèhófà ti pàṣẹ fún Mósè. 27  Lẹ́yìn èyí, wọ́n fi aṣọ ọ̀gbọ̀ àtàtà dá aṣọ,+ iṣẹ́ ọnà olófì, fún Áárónì àti àwọn ọmọkùnrin rẹ̀, 28  àti láwàní+ tí a fi aṣọ ọ̀gbọ̀ àtàtà ṣe àti àwọn gèlè ohun àfiṣẹ̀ṣọ́+ tí a fi aṣọ ọ̀gbọ̀ àtàtà ṣe àti ṣòkòtò àwọ̀tẹ́lẹ̀ ti aṣọ ọ̀gbọ̀+ tí a fi aṣọ ọ̀gbọ̀ àtàtà lílọ́ ṣe, 29  àti ìgbàjá+ tí a fi aṣọ ọ̀gbọ̀ àtàtà lílọ́ ṣe àti fọ́nrán òwú aláwọ̀ búlúù àti irun àgùntàn tí a fi àwọ̀ àlùkò àdàpọ̀-mọ́-pupa pa láró àti òwú aláwọ̀ rírẹ̀dòdò ti kòkòrò kókọ́sì, iṣẹ́ ahunṣọ, gan-an gẹ́gẹ́ bí Jèhófà ti pàṣẹ fún Mósè. 30  Níkẹyìn, wọ́n ṣe àwo dídán, àmì mímọ́ ti ìyàsímímọ́, tí a fi ògidì wúrà ṣe, wọ́n sì fi iṣẹ́ ọnà fífín èdìdì kọ àkọlé kan sára rẹ̀ pé: “Ìjẹ́mímọ́ jẹ́ ti Jèhófà.”+ 31  Lẹ́yìn náà, wọ́n fi okùn tín-ín-rín tí a fi fọ́nrán òwú aláwọ̀ búlúù ṣe sínú rẹ̀ láti fi í sára láwàní lókè,+ gan-an gẹ́gẹ́ bí Jèhófà ti pàṣẹ fún Mósè. 32  Nípa bẹ́ẹ̀, iṣẹ́ fún àgọ́ ìjọsìn ti àgọ́ ìpàdé wá sí àṣeparí rẹ̀, ní ti pé, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ń bá a lọ láti ṣe gẹ́gẹ́ bí gbogbo ohun tí Jèhófà pàṣẹ fún Mósè.+ Wọ́n ṣe bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́. 33  Wọ́n sì tẹ̀ síwájú láti gbé àgọ́ ìjọsìn náà wá+ sọ́dọ̀ Mósè, àgọ́+ náà àti gbogbo nǹkan èlò rẹ̀,+ àwọn ìkọ́ rẹ̀,+ àwọn férémù rẹ̀,+ àwọn ọ̀pá gbọọrọ rẹ̀+ àti àwọn ọwọ̀n rẹ̀ àti àwọn ìtẹ́lẹ̀ oníhò ìtẹ̀bọ̀ rẹ̀,+ 34  àti ìbòrí rẹ̀ tí ó jẹ́ awọ àgbò tí a pa láró+ pupa àti ìbòrí rẹ̀ tí ó jẹ́ awọ séálì+ àti aṣọ ìkélé àtabojú,+ 35  àti àpótí+ gbólóhùn ẹ̀rí àti àwọn ọ̀pá rẹ̀+ àti ìbòrí náà,+ 36  tábìlì,+ gbogbo nǹkan èlò rẹ̀+ àti búrẹ́dì àfihàn, 37  ọ̀pá fìtílà+ tí a fi ògidì wúrà ṣe, àwọn fìtílà rẹ̀, ọ̀wọ́ fìtílà,+ àti gbogbo nǹkan èlò rẹ̀+ àti òróró ìtànmọ́lẹ̀,+ 38  àti pẹpẹ+ wúrà àti òróró àfiyanni+ àti tùràrí onílọ́fínńdà+ àti àtabojú+ fún ẹnu ọ̀nà àgọ́, 39  pẹpẹ+ bàbà àti àgbàyan+ bàbà tí ó jẹ́ tirẹ̀, àwọn ọ̀pá rẹ̀+ àti gbogbo nǹkan èlò rẹ̀,+ bàsíà+ àti ẹsẹ̀ rẹ̀,+ 40  àwọn àsokọ́+ àgbàlá náà, àwọn ọwọ̀n rẹ̀+ àti àwọn ìtẹ́lẹ̀ oníhò ìtẹ̀bọ̀ rẹ̀+ àti àtabojú+ fún ẹnubodè àgbàlá, àwọn okùn àgọ́ rẹ̀+ àti àwọn ìkànlẹ̀ àgọ́ rẹ̀+ àti gbogbo nǹkan èlò+ fún iṣẹ́ ìsìn àgọ́ ìjọsìn náà, fún àgọ́ ìpàdé náà, 41  ẹ̀wù+ tí a fi iṣẹ́ ọnà àfọwọ́hun ṣe fún ṣíṣe ìránṣẹ́ nínú ibùjọsìn, ẹ̀wù+ mímọ́ fún Áárónì àlùfáà àti ẹ̀wù àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ fún ṣíṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí àlùfáà.+ 42  Ní ìbámu pẹ̀lú gbogbo ohun tí Jèhófà pàṣẹ fún Mósè, bẹ́ẹ̀ ni àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣe gbogbo iṣẹ́ ìsìn náà.+ 43  Mósè sì rí gbogbo iṣẹ́ náà, sì wò ó! wọ́n ṣe é gan-an gẹ́gẹ́ bí Jèhófà ti pàṣẹ. Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ṣe. Nítorí náà, Mósè súre fún wọn.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé