Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Ẹ́kísódù 38:1-31

38  Ó sì ń bá a lọ láti fi igi bọn-ọ̀n-ní ṣe pẹpẹ ọrẹ ẹbọ sísun. Ìgbọ̀nwọ́ márùn-ún ni gígùn rẹ̀, ìgbọ̀nwọ́ márùn-ún sì ni fífẹ̀ rẹ̀,+ ó jẹ́ igun mẹ́rin lọ́gbọọgba, ìgbọ̀nwọ́ mẹ́ta sì ni gíga rẹ̀.  Lẹ́yìn náà, ó ṣe àwọn ìwo rẹ̀+ sórí igun rẹ̀ mẹ́rẹ̀ẹ̀rin. Àwọn ìwo rẹ̀ yọ jáde lára rẹ̀. Lẹ́yìn náà, ó fi bàbà bò ó.+  Lẹ́yìn ìyẹn, ó ṣe gbogbo nǹkan èlò pẹpẹ náà, àwọn garawa àti àwọn ṣọ́bìrì àti àwọn àwokòtò, àwọn àmúga àti àwọn ìkóná. Gbogbo nǹkan èlò rẹ̀ ni ó fi bàbà ṣe.+  Síwájú sí i, ó ṣe àgbàyan kan fún pẹpẹ náà, tí ó rí bí àwọ̀n, èyí tí a fi bàbà ṣe, sábẹ́ etí rẹ̀, sí ìsàlẹ̀ ní àárín rẹ̀.+  Lẹ́yìn náà, ó rọ òrùka mẹ́rin sí ìkángun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin nítòsí àgbàyan bàbà, gẹ́gẹ́ bí ohun tí yóò di àwọn ọ̀pá náà mú.  Lẹ́yìn ìyẹn, ó fi igi bọn-ọ̀n-ní ṣe àwọn ọ̀pá, ó sì fi bàbà bò wọ́n.+  Lẹ́yìn náà, ó ti àwọn ọ̀pá náà bọ inú àwọn òrùka tí ó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ pẹpẹ náà láti máa fi wọ́n gbé e.+ Ó ṣe é ní àpótí abinú-kótópó tí a fi pátákó ṣe.+  Lẹ́yìn náà, ó ṣe bàsíà bàbà,+ ó sì fi bàbà ṣe ẹsẹ̀ rẹ̀, nípa lílo dígí àwọn ìránṣẹ́bìnrin tí ń ṣe iṣẹ́ ìsìn àfètòṣe ní ẹnu ọ̀nà àgọ́ ìpàdé.+  Ó sì bẹ̀rẹ̀ sí ṣe àgbàlá.+ Fún ìhà tí ó dojú kọ Négébù, ní gúúsù, àwọn àsokọ́ àgbàlá náà jẹ́ aṣọ ọ̀gbọ̀ àtàtà lílọ́, fún ọgọ́rùn-ún ìgbọ̀nwọ́.+ 10  Ogún ọwọ̀n tí wọ́n ní àti ogún ìtẹ́lẹ̀ oníhò ìtẹ̀bọ̀ wọn ni a fi bàbà ṣe. Èèkàn àwọn ọwọ̀n náà àti ibi ìdè wọn ni a fi fàdákà ṣe.+ 11  Pẹ̀lúpẹ̀lù, fún ìhà àríwá, ọgọ́rùn-ún ìgbọ̀nwọ́ ni ó wà níbẹ̀. Ogún ọwọ̀n tí wọ́n ní àti ogún ìtẹ́lẹ̀ oníhò ìtẹ̀bọ̀ wọn ni a fi bàbà ṣe. Èèkàn àwọn ọwọ̀n náà àti ibi ìdè wọn ni a fi fàdákà ṣe.+ 12  Ṣùgbọ́n ní ti ìhà ìwọ̀-oòrùn, àwọn àsokọ́ náà jẹ́ àádọ́ta ìgbọ̀nwọ́. Ọwọ̀n wọn jẹ́ mẹ́wàá, ìtẹ́lẹ̀ oníhò ìtẹ̀bọ̀ wọn sì jẹ́ mẹ́wàá.+ Èèkàn àwọn ọwọ̀n náà àti ibi ìdè wọn jẹ́ fàdákà. 13  Àádọ́ta ìgbọ̀nwọ́ sì wà fún ìhà ìlà-oòrùn ní ìdojúkọ yíyọ oòrùn.+ 14  Àwọn àsokọ́ náà jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ mẹ́ẹ̀ẹ́dógún ní apá tí ó yọ síta. Ọwọ̀n wọn jẹ́ mẹ́ta, ìtẹ́lẹ̀ oníhò ìtẹ̀bọ̀ wọn sì jẹ́ mẹ́ta.+ 15  Fún apá kejì tí ó yọ síta, ní ìhà ìhín àti ọ̀hún, ti ẹnubodè àgbàlá náà, àwọn àsokọ́ náà jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ mẹ́ẹ̀ẹ́dógún. Ọwọ̀n wọn jẹ́ mẹ́ta, ìtẹ́lẹ̀ oníhò ìtẹ̀bọ̀ wọn sì jẹ́ mẹ́ta.+ 16  Gbogbo àsokọ́ àgbàlá náà yíká-yíká jẹ́ aṣọ ọ̀gbọ̀ àtàtà lílọ́. 17  Àwọn ìtẹ́lẹ̀ oníhò ìtẹ̀bọ̀ fún àwọn ọwọ̀n náà ni a fi bàbà ṣe. Èèkàn àwọn ọwọ̀n náà àti ibi ìdè wọn ni a fi fàdákà ṣe, ohun tí a fi bo orí wọn ni a sì fi fàdákà ṣe, àwọn fàdákà asohunpọ̀ sì wà fún gbogbo ọwọ̀n àgbàlá náà.+ 18  Àtabojú ẹnubodè àgbàlá náà sì jẹ́ iṣẹ́ ahunṣọ, láti inú fọ́nrán òwú aláwọ̀ búlúù àti ti irun àgùntàn tí a fi àwọ̀ àlùkò àdàpọ̀-mọ́-pupa pa láró àti òwú aláwọ̀ rírẹ̀dòdò ti kòkòrò kókọ́sì àti aṣọ ọ̀gbọ̀ àtàtà lílọ́,+ ó sì jẹ́ ogún ìgbọ̀nwọ́ ní gígùn, gíga rẹ̀ ní ibi tí ó gùn dé sì jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ márùn-ún, ó jẹ́ ọgbọọgba pẹ̀lú àwọn àsokọ́ àgbàlá náà.+ 19  Ọwọ̀n wọn mẹ́rẹ̀ẹ̀rin àti ìtẹ́lẹ̀ oníhò ìtẹ̀bọ̀ wọn mẹ́rẹ̀ẹ̀rin ni a fi bàbà ṣe. Àwọn èèkàn wọn ni a fi fàdákà ṣe, ohun tí a sì fi bo orí wọn àti ibi ìdè wọn ni a fi fàdákà ṣe. 20  Gbogbo ìkànlẹ̀ àgọ́ fún àgọ́ ìjọsìn náà àti fún àgbàlá náà yíká-yíká ni a fi bàbà ṣe.+ 21  Àwọn ohun tí ó tẹ̀ lé e yìí jẹ́ ohun tí a kà lẹ́sẹẹsẹ pé ó wà nínú àgọ́ ìjọsìn, àgọ́ ìjọsìn Gbólóhùn Ẹ̀rí,+ èyí tí a kà lẹ́sẹẹsẹ nípa àṣẹ Mósè, gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ ìsìn àwọn ọmọ Léfì+ lábẹ́ ìdarí Ítámárì+ ọmọkùnrin Áárónì àlùfáà. 22  Bẹ́sálẹ́lì+ ọmọkùnrin Úráì ọmọkùnrin Húrì láti inú ẹ̀yà Júdà sì ṣe gbogbo ohun tí Jèhófà pa láṣẹ fún Mósè. 23  Ẹni tí ó sì pẹ̀lú rẹ̀ ni Òhólíábù+ ọmọkùnrin Áhísámákì ti ẹ̀yà Dánì, oníṣẹ́ ọnà àti akóṣẹ́-ọnà-sáṣọ àti olùhun fọ́nrán òwú aláwọ̀ búlúù àti irun àgùntàn tí a fi àwọ̀ àlùkò àdàpọ̀-mọ́-pupa pa láró àti òwú aláwọ̀ rírẹ̀dòdò ti kòkòrò kókọ́sì àti aṣọ ọ̀gbọ̀ àtàtà. 24  Gbogbo wúrà tí a lò fún iṣẹ́ náà nínú gbogbo iṣẹ́ ibi mímọ́ jẹ́ iye ìwọ̀n wúrà ọrẹ ẹbọ fífì,+ tálẹ́ńtì mọ́kàndínlọ́gbọ̀n àti ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rin ó lé ọgbọ̀n ṣékélì gẹ́gẹ́ bí ṣékélì+ ibi mímọ́.+ 25  Fàdákà àwọn tí a forúkọ wọn sílẹ̀ nínú àpéjọ náà sì jẹ́ ọgọ́rùn-ún tálẹ́ńtì àti ẹgbẹ̀sán ó dín mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n ṣékélì gẹ́gẹ́ bí ṣékélì ibi mímọ́. 26  Ìlàjì ṣékélì fún ẹnì kọ̀ọ̀kan jẹ́ ìlàjì ṣékélì gẹ́gẹ́ bí ṣékélì ibi mímọ́, fún olúkúlùkù ẹni tí ó kọjá sọ́dọ̀ àwọn tí a forúkọ wọn sílẹ̀ láti ẹni ogún ọdún sókè,+ iye wọn jẹ́ ọgbọ̀n ọ̀kẹ́ ó lé egbèjìdínlógún dín àádọ́ta.+ 27  Ọgọ́rùn-ún tálẹ́ńtì fàdákà sì lọ fún rírọ àwọn ìtẹ́lẹ̀ oníhò ìtẹ̀bọ̀ ti ibi mímọ́ àti àwọn ìtẹ́lẹ̀ oníhò ìtẹ̀bọ̀ ti aṣọ ìkélé. Ọgọ́rùn-ún ìtẹ́lẹ̀ oníhò ìtẹ̀bọ̀ jẹ́ ọgọ́rùn-ún tálẹ́ńtì, tálẹ́ńtì kan fún ìtẹ́lẹ̀ oníhò ìtẹ̀bọ̀ kan.+ 28  Lára ẹgbẹ̀sán ó dín mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n ṣékélì ni ó sì ṣe àwọn èèkàn fún àwọn ọwọ̀n, ó sì bo orí wọn, ó sì so wọ́n pọ̀. 29  Bàbà ọrẹ ẹbọ fífì sì jẹ́ àádọ́rin tálẹ́ńtì àti egbèjìlá ṣékélì. 30  Pẹ̀lú èyí ni ó bẹ̀rẹ̀ sí ṣe àwọn ìtẹ́lẹ̀ oníhò ìtẹ̀bọ̀ ti ẹnu ọ̀nà àgọ́ ìpàdé àti pẹpẹ bàbà àti àgbàyan bàbà tí ó wà lára rẹ̀, àti gbogbo nǹkan èlò pẹpẹ, 31  àti àwọn ìtẹ́lẹ̀ oníhò ìtẹ̀bọ̀ àgbàlá yí ká, àti ìtẹ́lẹ̀ oníhò ìtẹ̀bọ̀ ti ẹnubodè àgbàlá, àti gbogbo ìkànlẹ̀ àgọ́+ ti àgọ́ ìjọsìn náà àti gbogbo ìkànlẹ̀ àgọ́ ti àgbàlá náà yíká-yíká.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé