Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Ẹ́kísódù 37:1-29

37  Wàyí o, Bẹ́sálẹ́lì+ fi igi bọn-ọ̀n-ní ṣe Àpótí.+ Ìgbọ̀nwọ́ méjì àti ààbọ̀ ni gígùn rẹ̀, ìgbọ̀nwọ́ kan àti ààbọ̀ sì ni fífẹ̀ rẹ̀, ìgbọ̀nwọ́ kan àti ààbọ̀ sì ni gíga rẹ̀.+  Lẹ́yìn náà, ó fi ògidì wúrà bò ó nínú àti lóde, ó sì ṣe ìgbátí wúrà sí i yí ká.+  Lẹ́yìn ìyẹn, ó rọ òrùka wúrà mẹ́rin fún un, sí òkè ẹsẹ̀ rẹ̀ mẹ́rẹ̀ẹ̀rin, pẹ̀lú òrùka méjì ní ẹ̀gbẹ́ rẹ̀ kan àti òrùka méjì ní ẹ̀gbẹ́ rẹ̀ kejì.+  Lẹ́yìn èyí, ó fi igi bọn-ọ̀n-ní ṣe àwọn ọ̀pá, ó sì fi wúrà bò wọ́n.+  Lẹ́yìn náà, ó ti àwọn ọ̀pá náà bọ àwọn òrùka náà ní àwọn ẹ̀gbẹ́ Àpótí fún ríru Àpótí náà.+  Ó sì fi ògidì wúrà ṣe ìbòrí.+ Ìgbọ̀nwọ́ méjì àti ààbọ̀ ni gígùn rẹ̀, ìgbọ̀nwọ́ kan àti ààbọ̀ sì ni fífẹ̀ rẹ̀.+  Síwájú sí i, ó fi wúrà ṣe kérúbù méjì. Iṣẹ́ òòlù ni ó fi ṣe wọ́n sí àwọn ìkángun méjèèjì ìbòrí náà.+  Kérúbù kan wà ní ìkángun ọ̀hún, kérúbù kejì sì wà ní ìkángun ìhín. Ó ṣe àwọn kérúbù náà sórí ìbòrí náà ní àwọn ìkángun rẹ̀ méjèèjì.+  Wọ́n sì jẹ́ àwọn kérúbù tí wọ́n na ìyẹ́ apá méjèèjì sókè, tí wọ́n fi ìyẹ́ apá wọn bo ìbòrí náà,+ wọ́n sì dojú kọ ara wọn. Àwọn kérúbù náà dojú kọ ìbòrí náà.+ 10  Ó sì bẹ̀rẹ̀ sí fi igi bọn-ọ̀n-ní+ ṣe tábìlì. Ìgbọ̀nwọ́ méjì ni gígùn rẹ̀, ìgbọ̀nwọ́ kan sì ni fífẹ̀ rẹ̀, ìgbọ̀nwọ́ kan àti ààbọ̀ sì ni gíga rẹ̀.+ 11  Lẹ́yìn náà, ó fi ògidì wúrà bò ó, ó sì ṣe ìgbátí wúrà sí i yí ká.+ 12  Lẹ́yìn èyí, ó ṣe etí tí ó fẹ̀ tó ìbú ọwọ́ kan sí i yí ká, ó sì ṣe ìgbátí wúrà sí etí rẹ̀ yí ká.+ 13  Síwájú sí i, ó rọ òrùka wúrà mẹ́rin fún un, ó sì fi àwọn òrùka náà sí igun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin tí ó wà fún ẹsẹ̀ mẹ́rẹ̀ẹ̀rin náà.+ 14  Àwọn òrùka náà sún mọ́ etí náà, gẹ́gẹ́ bí ohun tí yóò di àwọn ọ̀pá náà mú fún gbígbé tábìlì náà.+ 15  Lẹ́yìn náà, ó fi igi bọn-ọ̀n-ní ṣe àwọn ọ̀pá, ó sì fi wúrà bò wọ́n fún gbígbé tábìlì náà.+ 16  Lẹ́yìn ìyẹn, ó fi ògidì wúrà ṣe àwọn nǹkan èlò tí ó wà lórí tábìlì, àwọn àwo ìjẹun rẹ̀ àti àwọn ife rẹ̀ àti àwọn àwokòtò rẹ̀ àti àwọn orù rẹ̀ tí a o fi máa da ẹbọ ìtasílẹ̀.+ 17  Lẹ́yìn náà, ó fi ògidì wúrà ṣe ọ̀pá fìtílà. Iṣẹ́ òòlù ni ó fi ṣe ọ̀pá fìtílà náà.+ Àwọn ẹ̀gbẹ́ rẹ̀ àti àwọn ẹ̀ka rẹ̀, àwọn ife rẹ̀, àwọn kókó rubutu rẹ̀ àti àwọn ìtànná rẹ̀ jáde láti ara rẹ̀.+ 18  Ẹ̀ka mẹ́fà sì yọ jáde láti àwọn ẹ̀gbẹ́ rẹ̀, ẹ̀ka mẹ́ta ọ̀pá fìtílà náà jáde láti ẹ̀gbẹ́ rẹ̀ kan àti ẹ̀ka mẹ́ta ọ̀pá fìtílà náà jáde láti ẹ̀gbẹ́ rẹ̀ kejì.+ 19  Ife mẹ́ta tí ó ní ìrísí òdòdó álímọ́ńdì wà ní ọ̀wọ́ kan àwọn ẹ̀ka náà, pẹ̀lú àwọn kókó rubutu àti àwọn ìtànná tí ọ̀kan tẹ̀ lé ìkejì; ife mẹ́ta tí ó ní ìrísí òdòdó álímọ́ńdì sì wà ní ọ̀wọ́ kejì àwọn ẹ̀ka náà, pẹ̀lú àwọn kókó rubutu àti àwọn ìtànná tí ọ̀kan tẹ̀ lé ìkejì. Bí ẹ̀ka mẹ́fẹ̀ẹ̀fà tí ó yọ jáde lára ọ̀pá fìtílà náà ti rí nìyí.+ 20  Àti lára ọ̀pá fìtílà náà ni ife mẹ́rin wà tí ó ní ìrísí òdòdó álímọ́ńdì, pẹ̀lú àwọn kókó rubutu rẹ̀ àti àwọn ìtànná rẹ̀ tí ọ̀kan tẹ̀ lé ìkejì.+ 21  Kókó rubutu tí ó wà lábẹ́ ẹ̀ka méjì náà sì wá láti ara rẹ̀, kókó rubutu tí ó wà lábẹ́ ẹ̀ka méjì mìíràn sì wá láti ara rẹ̀, àti kókó rubutu tí ó wà lábẹ́ ẹ̀ka méjì sí i wá láti ara rẹ̀, fún ẹ̀ka mẹ́fẹ̀ẹ̀fà tí ó yọ jáde láti ara ọ̀pá fìtílà náà.+ 22  Kókó rubutu wọn àti ẹ̀ka wọn yọ jáde lára rẹ̀. Gbogbo rẹ̀ jẹ́ ẹyọ kan lódindi tí a fi iṣẹ́ òòlù ṣe, ti ògidì wúrà.+ 23  Lẹ́yìn náà, ó fi ògidì wúrà ṣe fìtílà rẹ̀ méje àti ẹ̀mú rẹ̀ àti ìkóná rẹ̀.+ 24  Tálẹ́ńtì kan ògidì wúrà ni ó fi ṣe é, àti gbogbo nǹkan èlò rẹ̀. 25  Wàyí o, ó fi igi bọn-ọ̀n-ní+ ṣe pẹpẹ tùràrí.+ Ìgbọ̀nwọ́ kan ni gígùn rẹ̀, ìgbọ̀nwọ́ kan sì ni fífẹ̀ rẹ̀, ó jẹ́ igun mẹ́rin lọ́gbọọgba, ìgbọ̀nwọ́ méjì sì ni gíga rẹ̀. Àwọn ìwo rẹ̀ yọ jáde lára rẹ̀.+ 26  Lẹ́yìn náà, ó fi ògidì wúrà bò ó, òkè orí rẹ̀ àti ẹ̀gbẹ́ rẹ̀ yí ká àti àwọn ìwo rẹ̀, ó sì ṣe ìgbátí wúrà sí i yí ká.+ 27  Ó sì ṣe òrùka wúrà sí i nísàlẹ̀ ìgbátí rẹ̀, sí ẹ̀gbẹ́ rẹ̀ méjèèjì, sí ẹ̀gbẹ́ rẹ̀ méjì tí ó dojú kọra, gẹ́gẹ́ bí ohun tí yóò di àwọn ọ̀pá náà mú, tí a ó fi máa gbé e.+ 28  Lẹ́yìn ìyẹn, ó fi igi bọn-ọ̀n-ní ṣe àwọn ọ̀pá, ó sì fi wúrà bò wọ́n.+ 29  Ní àfikún sí i, ó ṣe òróró mímọ́ àfiyanni+ àti ògidì tùràrí onílọ́fínńdà,+ iṣẹ́ olùṣe òróró ìkunra.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé