Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

Ẹ́kísódù 36:1-38

36  “Kí Bẹ́sálẹ́lì ṣiṣẹ́, bákan náà, Òhólíábù+ àti olúkúlùkù ẹni tí ó ní ọkàn-àyà ọgbọ́n tí Jèhófà fi ọgbọ́n+ àti òye+ fún nínú nǹkan wọ̀nyí láti lè mọ bí a ó ti ṣe gbogbo iṣẹ́ ti iṣẹ́ ìsìn mímọ́ ní ìbámu pẹ̀lú gbogbo ohun tí Jèhófà pa láṣẹ.”+  Mósè sì tẹ̀ síwájú láti pe Bẹ́sálẹ́lì àti Òhólíábù àti olúkúlùkù ẹni tí ó ní ọkàn-àyà ọgbọ́n, àwọn ẹni tí Jèhófà fi ọgbọ́n sínú ọkàn-àyà wọn,+ olúkúlùkù ẹni tí ọkàn-àyà rẹ̀ sún un láti wá sídìí iṣẹ́ náà láti ṣe é.+  Lẹ́yìn náà, wọ́n kó gbogbo ọrẹ+ náà tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì mú wá láti fi ṣe iṣẹ́ ti iṣẹ́ ìsìn mímọ́ kúrò níwájú Mósè, àti pé, ní ti àwọn wọ̀nyí, wọ́n ṣì ń mú ọrẹ àfínnúfíndọ̀ṣe wá fún un síbẹ̀ ní òròòwúrọ̀.  Gbogbo àwọn ọlọ́gbọ́n tí ń ṣe gbogbo iṣẹ́ mímọ́ náà bẹ̀rẹ̀ sí wá, ọ̀kan tẹ̀ lé ìkejì, láti ẹnu iṣẹ́ tí wọ́n ń ṣe,  wọ́n sì wí fún Mósè pé: “Àwọn ènìyàn ń mú púpọ̀púpọ̀ wá ju ohun tí iṣẹ́ ìsìn náà béèrè láti ṣe iṣẹ́ tí Jèhófà pa láṣẹ pé kí a ṣe.”  Nítorí náà, Mósè pàṣẹ pé kí wọ́n ṣe ìkéde la ibùdó náà já, pé: “Ẹ̀yin ọkùnrin àti ẹ̀yin obìnrin, ẹ má ṣe mú ohun èlò wá mọ́ fún ọrẹ mímọ́.” Pẹ̀lú ìyẹn, a dá àwọn ènìyàn náà lẹ́kun mímú un wá.  Ohun èlò náà sì tó fún gbogbo iṣẹ́ tí a ó ṣe, ó tó, ó sì ṣẹ́ kù.  Gbogbo àwọn tí ó ní ọkàn-àyà ọgbọ́n+ láàárín àwọn tí ń ṣe iṣẹ́ náà sì bẹ̀rẹ̀ sí ṣe àgọ́ ìjọsìn,+ aṣọ àgọ́ mẹ́wàá ti aṣọ ọ̀gbọ̀ àtàtà lílọ́ àti fọ́nrán òwú aláwọ̀ búlúù àti irun àgùntàn tí a fi àwọ̀ àlùkò àdàpọ̀-mọ́-pupa pa láró àti òwú aláwọ̀ rírẹ̀dòdò ti kòkòrò kókọ́sì; àwọn kérúbù tí a fi iṣẹ́ akóṣẹ́-ọnà-sáṣọ ṣe, ni ó fi ṣe wọ́n.  Gígùn aṣọ àgọ́ kọ̀ọ̀kan jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ méjìdínlọ́gbọ̀n, fífẹ̀ aṣọ àgọ́ kọ̀ọ̀kan sì jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ mẹ́rin. Ìwọ̀n kan náà ni ó wà fún gbogbo aṣọ àgọ́ náà. 10  Ó wá so aṣọ àgọ́ márùn-ún pọ̀ mọ́ ara wọn,+ aṣọ àgọ́ márùn-ún yòókù ni ó sì so pọ̀ mọ́ ara wọn. 11  Lẹ́yìn ìyẹn, ó fi fọ́nrán òwú aláwọ̀ búlúù ṣe àwọn ihò kóróbójó sí etí aṣọ àgọ́ tí ó wà ní òpin ìsolù náà. Bákan náà ni ó ṣe sí etí aṣọ àgọ́ tí ó wà lóde pátápátá ní ibi ìsolù kejì.+ 12  Ó ṣe àádọ́ta ihò kóróbójó sí aṣọ àgọ́ kan, ó sì ṣe àádọ́ta ihò kóróbójó sí ìkángun aṣọ àgọ́ tí ó wà ní ibi ìsolù kejì, àwọn ihò kóróbójó náà wà ní ìdojúkọ ara wọn.+ 13  Níkẹyìn, ó ṣe àádọ́ta ìkọ́ wúrà, ó sì fi ìkọ́ náà so àwọn aṣọ àgọ́ náà pọ̀ mọ́ ara wọn, tí ó fi di àgọ́ ìjọsìn kan.+ 14  Ó sì tẹ̀ síwájú láti fi irun ewúrẹ́ ṣe aṣọ àgọ́ fún ìbòrí àgọ́ ìjọsìn náà. Aṣọ àgọ́ mọkànlá ni ó ṣe.+ 15  Gígùn aṣọ àgọ́ kọ̀ọ̀kan jẹ́ ọgbọ̀n ìgbọ̀nwọ́, fífẹ̀ aṣọ àgọ́ kọ̀ọ̀kan sì jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ mẹ́rin. Ìwọn kan náà ni ó wà fún aṣọ àgọ́ mọ́kànlá náà.+ 16  Lẹ́yìn náà, ó so aṣọ àgọ́ márùn-ún pọ̀ mọ́ ara wọn àti aṣọ àgọ́ mẹ́fà mìíràn mọ́ ara wọn.+ 17  Lẹ́yìn èyí, ó ṣe àádọ́ta ihò kóróbójó sí etí aṣọ àgọ́ tí ó wà lóde pátápátá ní ibi ìsolù, ó sì ṣe àádọ́ta ihò kóróbójó sí etí aṣọ àgọ́ kejì tí ó so pọ̀ mọ́ ọn.+ 18  Lẹ́yìn ìyẹn, ó ṣe àádọ́ta ìkọ́ bàbà fún síso àgọ́ pọ̀ mọ́ra láti di ẹyọ kan.+ 19  Ó sì bẹ̀rẹ̀ sí ṣe ìbòrí fún àgọ́ náà láti inú awọ àgbò tí a pa láró pupa àti ìbòrí láti inú awọ séálì+ tí ó wà lókè rẹ̀.+ 20  Lẹ́yìn náà, ó fi igi bọn-ọ̀n-ní+ ṣe àwọn férémù fún àgọ́ ìjọsìn, ní ògùródo. 21  Ìgbọ̀nwọ́ mẹ́wàá ni gígùn férémù kan, ìgbọ̀nwọ́ kan àti ààbọ̀ sì ni fífẹ̀ férémù kọ̀ọ̀kan.+ 22  Ọ̀kọ̀ọ̀kan férémù ní ìtẹ̀bọ̀ méjì tí a de ọ̀kan mọ́ ìkejì. Bẹ́ẹ̀ ni ó ṣe sí gbogbo férémù àgọ́ ìjọsìn náà.+ 23  Nípa bẹ́ẹ̀, ó ṣe àwọn férémù fún àgọ́ ìjọsìn náà, ogún férémù fún ìhà tí ó dojú kọ Négébù, ní gúúsù.+ 24  Ó sì fi fàdákà ṣe ogójì ìtẹ́lẹ̀ oníhò ìtẹ̀bọ̀ sí abẹ́ ogún férémù, ìtẹ́lẹ̀ méjì oníhò ìtẹ̀bọ̀ lábẹ́ férémù kan pẹ̀lú ìtẹ̀bọ̀ rẹ̀ méjì àti ìtẹ́lẹ̀ méjì oníhò ìtẹ̀bọ̀ lábẹ́ férémù kejì pẹ̀lú ìtẹ̀bọ̀ rẹ̀ méjì.+ 25  Àti fún ìhà kejì àgọ́ ìjọsìn náà, ìhà àríwá, ó ṣe ogún férémù+ 26  àti ogójì ìtẹ́lẹ̀ oníhò ìtẹ̀bọ̀ wọn tí a fi fàdákà ṣe, ìtẹ́lẹ̀ méjì oníhò ìtẹ̀bọ̀ lábẹ́ férémù kan àti ìtẹ́lẹ̀ méjì oníhò ìtẹ̀bọ̀ lábẹ́ férémù kejì.+ 27  Àti fún àwọn apá ẹ̀yìn àgọ́ ìjọsìn náà, níhà ìwọ̀-oòrùn, ó ṣe férémù mẹ́fà.+ 28  Ó sì ṣe férémù méjì gẹ́gẹ́ bí àwọn arópòódògiri fún igun àgọ́ ìjọsìn náà ní apá ẹ̀yìn rẹ̀ méjèèjì.+ 29  Wọ́n sì jẹ́ ẹ̀dà méjì ní ìsàlẹ̀, wọ́n sì jùmọ̀ jẹ́ ìbejì títí dé orí ọ̀kọ̀ọ̀kan níbi òrùka ti àkọ́kọ́. Ohun tí ó ṣe sí méjèèjì nìyẹn, sí arópòódògiri fún igun méjèèjì náà.+ 30  Nítorí náà, wọ́n jẹ́ férémù mẹ́jọ, ìtẹ́lẹ̀ oníhò ìtẹ̀bọ̀ wọn tí a fi fàdákà ṣe sì jẹ́ mẹ́rìndínlógún, ìtẹ́lẹ̀ méjì oníhò ìtẹ̀bọ̀ tẹ̀ lé ìtẹ́lẹ̀ méjì oníhò ìtẹ̀bọ̀ lábẹ́ férémù kọ̀ọ̀kan.+ 31  Ó sì ń bá a lọ láti fi igi bọn-ọ̀n-ní ṣe àwọn ọ̀pá gbọọrọ, márùn-ún fún àwọn férémù ti ẹ̀gbẹ́ kan àgọ́ ìjọsìn náà+ 32  àti ọ̀pá gbọọrọ márùn-ún fún àwọn férémù ẹ̀gbẹ́ kejì àgọ́ ìjọsìn náà àti ọ̀pá gbọọrọ márùn-ún fún férémù àgọ́ ìjọsìn náà fún apá ẹ̀yìn méjèèjì níhà ìwọ̀-oòrùn.+ 33  Lẹ́yìn náà, ó ṣe ọ̀pá gbọọrọ láti gba àárín àwọn férémù náà láti ìpẹ̀kun kan sí ti èkejì.+ 34  Ó sì fi wúrà bo àwọn férémù náà, ó sì fi wúrà ṣe òrùka wọn gẹ́gẹ́ bí ohun tí yóò di àwọn ọ̀pá gbọọrọ náà mú, ó sì ń bá a lọ láti fi wúrà bo àwọn ọ̀pá gbọọrọ náà.+ 35  Ó sì bẹ̀rẹ̀ sí ṣe aṣọ ìkélé+ láti inú fọ́nrán òwú aláwọ̀ búlúù àti irun àgùntàn tí a fi àwọ̀ àlùkò àdàpọ̀-mọ́-pupa pa láró àti òwú aláwọ̀ rírẹ̀dòdò ti kòkòrò kókọ́sì àti aṣọ ọ̀gbọ̀ àtàtà lílọ́. Àwọn kérúbù tí a fi iṣẹ́ akóṣẹ́-ọnà-sáṣọ ṣe, ni ó fi ṣe é.+ 36  Lẹ́yìn náà, ó ṣe ọwọ̀n igi bọn-ọ̀n-ní mẹ́rin fún un, ó sì fi wúrà bò wọ́n, àwọn èèkàn wọ́n jẹ́ wúrà, ó sì rọ ìtẹ́lẹ̀ mẹ́rin oníhò ìtẹ̀bọ̀ ti fàdákà fún wọn.+ 37  Ó sì ń bá a lọ láti ṣe àtabojú fún ẹnu ọ̀nà àgọ́ láti inú fọ́nrán òwú aláwọ̀ búlúù àti irun àgùntàn tí a fi àwọ̀ àlùkò àdàpọ̀-mọ́-pupa pa láró àti òwú aláwọ̀ rírẹ̀dòdò ti kòkòrò kókọ́sì àti aṣọ ọ̀gbọ̀ àtàtà lílọ́, iṣẹ́ ahunṣọ,+ 38  àti ọwọ̀n rẹ̀ márùn-ún àti àwọn èèkàn wọn. Ó sì fi wúrà bo orí wọn àti ibi ìdè wọn, ṣùgbọ́n ìtẹ́lẹ̀ oníhò ìtẹ̀bọ̀ wọn márààrún jẹ́ bàbà.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé