Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Ẹ́kísódù 33:1-23

33  Jèhófà sì wí fún Mósè síwájú sí i, pé: “Lọ, gòkè láti ìhín, ìwọ àti àwọn ènìyàn tí o mú gòkè kúrò ní ilẹ̀ Íjíbítì,+ lọ sí ilẹ̀ tí mo búra nípa rẹ̀ fún Ábúráhámù, Ísákì àti Jékọ́bù pé, ‘Irú-ọmọ rẹ ni èmi yóò fi í fún.’+  Èmi yóò sì rán áńgẹ́lì kan ṣáájú rẹ,+ èmi yóò sì lé àwọn ọmọ Kénáánì, àwọn Àmórì, àti àwọn ọmọ Hétì àti àwọn Pérísì, àwọn Hífì àti àwọn ará Jébúsì+ jáde;  sí ilẹ̀ tí ń ṣàn fún wàrà àti oyin,+ nítorí èmi kì yóò gòkè lọ láàárín rẹ, nítorí pé ìwọ jẹ́ ọlọ́rùn-líle,+ kí èmi má bàa pa ọ́ run pátápátá lójú ọ̀nà.”+  Nígbà tí àwọn ènìyàn náà wá gbọ́ ọ̀rọ̀ ibi yìí, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí ṣọ̀fọ̀;+ kò sì sí ọ̀kan nínú wọn tí ó fi àwọn ohun ọ̀ṣọ́ rẹ̀ sára rẹ̀.  Jèhófà sì ń bá a lọ láti wí fún Mósè pé: “Sọ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé, ‘Ọlọ́rùn-líle+ ni yín. Ní ìṣẹ́jú kan+ mo lè gòkè lọ sáàárín rẹ, kí n sì pa ọ́ run pátápátá ní tòótọ́. Ǹjẹ́ nísinsìnyí, bọ́ àwọn ohun ọ̀ṣọ́ rẹ kúrò lára rẹ, nítorí mo fẹ́ mọ ohun tí èmi yóò ṣe sí ọ.’”+  Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sì bẹ̀rẹ̀ sí bọ́ àwọn ohun ọ̀ṣọ́ wọn kúrò lára wọn láti Òkè Ńlá Hórébù+ lọ.  Ní ti Mósè, ó bẹ̀rẹ̀ sí ká àgọ́ rẹ̀ kúrò, ó sì pa á sóde ibùdó, jìnnà réré sí ibùdó náà; ó sì pè é ní àgọ́ ìpàdé. Ó sì ṣẹlẹ̀ pé olúkúlùkù tí ń ṣe ìwádìí+ lọ́dọ̀ Jèhófà yóò jáde lọ sí àgọ́ ìpàdé, tí ó wà ní òde ibùdó náà.  Ó sì ṣẹlẹ̀ pé gbàrà tí Mósè bá jáde lọ sí àgọ́, gbogbo ènìyàn yóò dìde dúró,+ wọn a sì dúró, olúkúlùkù ní ẹnu ọ̀nà àgọ́ rẹ̀, wọn yóò sì tẹjú mọ́ Mósè títí yóò fi wọnú àgọ́.  Ó sì tún ṣẹlẹ̀ pé gbàrà tí Mósè bá ti wọnú àgọ́, ọwọ̀n àwọsánmà+ a sọ̀ kalẹ̀, a sì dúró ní ẹnu ọ̀nà àgọ́, òun a sì bá Mósè sọ̀rọ̀.+ 10  Gbogbo ènìyàn sì rí ọwọ̀n àwọsánmà+ tí ó dúró ní ẹnu ọ̀nà àgọ́, gbogbo ènìyàn sì dìde, wọ́n sì tẹrí ba, olúkúlùkù ní ẹnu ọ̀nà àgọ́ rẹ̀.+ 11  Jèhófà sì bá Mósè sọ̀rọ̀ ní ojúkojú,+ gan-an gẹ́gẹ́ bí ènìyàn kan yóò ti bá ọmọnìkejì rẹ̀ sọ̀rọ̀. Nígbà tí ó bá padà sí ibùdó, Jóṣúà, ọmọkùnrin Núnì,+ òjíṣẹ́ rẹ̀,+ gẹ́gẹ́ bí ẹmẹ̀wà, kì yóò kúrò nínú àgọ́ náà. 12  Wàyí o, Mósè wí fún Jèhófà pé: “Wò ó, ìwọ sọ fún mi pé, ‘Mú àwọn ènìyàn yìí gòkè lọ,’ ṣùgbọ́n ìwọ fúnra rẹ kò tíì jẹ́ kí n mọ ẹni tí ìwọ yóò rán pẹ̀lú mi. Jù bẹ́ẹ̀ lọ, ìwọ fúnra rẹ ti wí pé, ‘Èmi fi orúkọ mọ̀ ọ́,+ àti pé, ní àfikún sí i, ìwọ ti rí ojú rere lójú mi.’ 13  Wàyí o, jọ̀wọ́, bí mo bá rí ojú rere lójú rẹ,+ jọ̀wọ́, jẹ́ kí n mọ àwọn ọ̀nà rẹ,+ kí n lè mọ̀ ọ́, kí n lè rí ojú rere lójú rẹ. Kí o sì gbà á rò pé orílẹ̀-èdè yìí jẹ́ àwọn ènìyàn rẹ.”+ 14  Nítorí náà, ó wí pé: “Èmi alára yóò bá ọ lọ,+ èmi yóò sì fún ọ ní ìsinmi+ dájúdájú.” 15  Látàrí èyí, ó wí fún un pé: “Bí ìwọ alára kò bá bá wa lọ, má ṣe mú wa gòkè lọ láti ìhín. 16  Wàyí o, kí sì ni ohun tí a ó fi mọ̀ pé mo ti rí ojú rere lójú rẹ, èmi àti àwọn ènìyàn rẹ? Kì í ha ṣe bíbá tí o bá ń bá wa lọ,+ ní ti pé, èmi àti àwọn ènìyàn rẹ ni a ti mú dáyàtọ̀ sí gbogbo ènìyàn yòókù tí ó wà lórí ilẹ̀?”+ 17  Jèhófà sì ń bá a lọ láti wí fún Mósè pé: “Ohun yìí tí ìwọ sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ pẹ̀lú, ni èmi yóò ṣe,+ nítorí ìwọ ti rí ojú rere lójú mi, mo sì fi orúkọ mọ̀ ọ́.” 18  Látàrí èyí, ó wí pé: “Jọ̀wọ́, jẹ́ kí n rí ògo rẹ.”+ 19  Ṣùgbọ́n òun wí pé: “Èmi fúnra mi yóò mú kí gbogbo oore mi kọjá níwájú rẹ,+ èmi yóò sì polongo orúkọ Jèhófà níwájú rẹ;+ èmi yóò sì ṣe ojú rere sí ẹni tí èmi yóò ṣe ojú rere sí, èmi yóò sì fi àánú hàn sí ẹni tí èmi yóò fi àánú hàn sí.”+ 20  Ó sì fi kún un pé: “Ìwọ kò lè rí ojú mi, nítorí pé kò sí ènìyàn tí ó lè rí mi kí ó sì wà láàyè síbẹ̀.”+ 21  Jèhófà sì sọ síwájú sí i pé: “Kíyè sí i, àyè kan nìyí lọ́dọ̀ mi, kí o sì dúró lórí àpáta yìí. 22  Yóò sì ṣẹlẹ̀ pé, nígbà tí ògo mi bá ń kọjá, èmi yóò fi ọ́ sínú ihò nínú àpáta, èmi yóò sì fi àtẹ́lẹwọ́ mi bò ọ́ gẹ́gẹ́ bí àtabojú títí èmi yóò fi kọjá. 23  Lẹ́yìn ìyẹn, èmi yóò mú àtẹ́lẹwọ́ mi kúrò, ìwọ yóò sì rí ẹ̀yìn mi ní tòótọ́. Ṣùgbọ́n ojú mi ni a kò lè rí.”+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé