Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Ẹ́kísódù 32:1-35

32  Láàárín àkókò yìí, àwọn ènìyàn náà rí i pé ó pẹ́ Mósè kí ó tó sọ̀ kalẹ̀ láti orí òkè ńlá náà.+ Nítorí náà, àwọn ènìyàn náà péjọ pọ̀ yí Áárónì ká, wọ́n sì wí fún un pé: “Dìde, ṣe ọlọ́run kan fún wa tí yóò máa ṣáájú wa,+ nítorí, ní ti Mósè yìí, ẹni tí ó mú wa gòkè kúrò ní ilẹ̀ Íjíbítì,+ dájúdájú, àwa kò mọ ohun tí ó ti ṣẹlẹ̀ sí i.”  Látàrí èyí, Áárónì wí fún wọn pé: “Ẹ kán àwọn yẹtí wúrà+ tí ó wà ní etí aya yín, ti àwọn ọmọkùnrin yín àti ti àwọn ọmọbìnrin yín, kí ẹ sì kó wọn wá fún mi.”  Gbogbo àwọn ènìyàn náà sì bẹ̀rẹ̀ sí kán àwọn yẹtí wúrà tí ó wà ní etí wọn, wọ́n sì ń kó wọn wá fún Áárónì.  Nígbà náà, ó gba wúrà náà lọ́wọ́ wọn, ó sì fi irinṣẹ́ tí a fi ń fín nǹkan ṣe é,+ ó sì ṣe ère ọmọ màlúù dídà.+ Wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí sọ pé: “Ìwọ Ísírẹ́lì, èyí ni Ọlọ́run rẹ tí ó mú ọ gòkè kúrò ní ilẹ̀ Íjíbítì.”+  Nígbà tí Áárónì rí èyí, ó bẹ̀rẹ̀ sí mọ pẹpẹ síwájú rẹ̀. Níkẹyìn, Áárónì ké jáde, ó wí pé: “Àjọyọ̀ fún Jèhófà wà lọ́la.”  Nítorí náà, ní ọjọ́ kejì, wọ́n tètè dìde, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí fi ọrẹ ẹbọ sísun rúbọ, wọ́n sì ń mú àwọn ẹbọ ìdàpọ̀ wá. Lẹ́yìn ìyẹn, àwọn ènìyàn náà jókòó láti jẹ àti láti mu. Lẹ́yìn náà, wọ́n dìde láti gbádùn ara wọn.+  Wàyí o, Jèhófà wí fún Mósè pé: “Lọ, sọ̀ kalẹ̀, nítorí pé àwọn ènìyàn rẹ tí o mú gòkè kúrò ní ilẹ̀ Íjíbítì ti gbé ìgbésẹ̀ tí ń fa ìparun.+  Ní kíákíá, wọ́n ti yà kúrò ní ọ̀nà tí mo pa láṣẹ fún wọn láti máa rìn.+ Wọ́n ti ṣe ère ọmọ màlúù dídà fún ara wọn, wọ́n sì ń tẹrí ba fún un, wọ́n sì ń rúbọ sí i, wọ́n sì ń wí pé, ‘Ìwọ Ísírẹ́lì, èyí ni Ọlọ́run rẹ tí ó mú ọ gòkè kúrò ní ilẹ̀ Íjíbítì.’”+  Jèhófà sì ń bá a lọ láti wí fún Mósè pé: “Mo ti bojú wo àwọn ènìyàn yìí, sì kíyè sí i, ọlọ́rùn-líle ènìyàn ni wọ́n.+ 10  Ǹjẹ́ nísinsìnyí, jọ̀wọ́ mi, kí ìbínú mi lè ru sí wọn, kí n lè pa wọ́n run pátápátá,+ kí o sì jẹ́ kí n sọ ìwọ di orílẹ̀-èdè ńlá.”+ 11  Mósè sì bẹ̀rẹ̀ sí tu Jèhófà Ọlọ́run rẹ̀ lójú,+ ó wí pé: “Jèhófà, èé ṣe tí ìbínú rẹ+ yóò fi ru sí àwọn ènìyàn rẹ tí o fi agbára ńlá àti ọwọ́ líle mú jáde kúrò ní ilẹ̀ Íjíbítì? 12  Èé ṣe tí àwọn ará Íjíbítì+ yóò fi wí pe, ‘Ète ibi ni ó fi mú wọn jáde kí ó lè pa wọ́n láàárín àwọn òkè ńlá, kí ó sì lè pa wọ́n run pátápátá kúrò lórí ilẹ̀’?+ Yí padà kúrò nínú ìbínú rẹ jíjófòfò,+ kí o sì pèrò dà+ ní ti ibi sí àwọn ènìyàn rẹ. 13  Rántí Ábúráhámù, Ísákì àti Ísírẹ́lì, àwọn ìránṣẹ́ rẹ, àwọn tí o fi ara rẹ búra fún,+ ní ti pé, o wí fún wọn pé, ‘Èmi yóò sọ irú-ọmọ yín di púpọ̀ bí àwọn ìràwọ̀ ojú ọ̀run,+ gbogbo ilẹ̀ yìí tí mo sì ti tọ́ka sí ni èmi yóò fi fún irú-ọmọ yín,+ kí wọ́n lè gbà á fún àkókò tí ó lọ kánrin.’”+ 14  Jèhófà sì bẹ̀rẹ̀ sí pèrò dà ní ti ibi tí ó sọ pé òun fẹ́ ṣe sí àwọn ènìyàn rẹ̀.+ 15  Lẹ́yìn ìyẹn, Mósè yí padà, ó sì sọ̀ kalẹ̀ láti orí òkè ńlá+ náà pẹ̀lú wàláà méjì ti Gbólóhùn Ẹ̀rí+ ní ọwọ́ rẹ̀, àwọn wàláà tí a kọ̀wé sí ní ìhà méjèèjì. Ìhà kìíní àti ìhà kejì ni a kọ̀wé sí. 16  Àwọn wàláà náà sì jẹ́ iṣẹ́ ọnà Ọlọ́run, ìkọ̀wé náà sì jẹ́ ìkọ̀wé Ọlọ́run tí a fín sórí àwọn wàláà.+ 17  Jóṣúà sì bẹ̀rẹ̀ sí gbọ́ ariwo àwọn ènìyàn nítorí igbe wọn, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí wí fún Mósè pé: “Ariwo ìjà ogun+ ń bẹ ní ibùdó.” 18  Ṣùgbọ́n ó wí pé: “Kì í ṣe ìró orin nítorí iṣẹ́ agbára ńlá,+ Kì í sì í ṣe ìró orin àwọn tí a ṣẹ́gun; Ìró orin mìíràn ni mo ń gbọ́.” 19  Ó ṣẹlẹ̀ pé, gbàrà tí ó sún mọ́ ibùdó, tí ó sì rí ọmọ màlúù+ àti ijó, ìbínú Mósè bẹ̀rẹ̀ sí ru, lójú-ẹsẹ̀, ó sọ àwọn wàláà náà sílẹ̀ kúrò ní ọwọ́ rẹ̀, ó sì fọ́ wọn túútúú sí ẹsẹ̀ òkè ńlá náà.+ 20  Lẹ́yìn náà, ó mú ọmọ màlúù tí wọ́n ṣe, ó sì fi iná jó o, ó sì fọ́ ọ túútúú títí ó fi di lẹ́búlẹ́bú,+ lẹ́yìn èyí, ó tú u ká sórí omi,+ ó sì mú kí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì mu ún.+ 21  Lẹ́yìn náà, Mósè sọ fún Áárónì pé: “Kí ni àwọn ènìyàn yìí fi ṣe ọ tí o fi mú ẹ̀ṣẹ̀ ńlá wá sórí rẹ̀?” 22  Áárónì fèsì pé: “Má ṣe jẹ́ kí ìbínú olúwa mi ru. Ìwọ fúnra rẹ mọ àwọn ènìyàn náà dáadáa, pé wọ́n ní ìtẹ̀sí èrò ibi.+ 23  Nítorí náà, wọ́n wí fún mi pé, ‘Ṣe ọlọ́run kan fún wa tí yóò máa ṣáájú wa,+ nítorí, ní ti Mósè yìí, ẹni tí ó mú wa gòkè kúrò ní ilẹ̀ Íjíbítì, dájúdájú, àwa kò mọ ohun tí ó ti ṣẹlẹ̀ sí i.’ 24  Nítorí náà, mo sọ fún wọn pé, ‘Ta ni ó ní wúrà èyíkéyìí? Kí wọ́n kán an kúrò lára wọn, kí wọ́n lè fi í fún mi.’ Mo sì bẹ̀rẹ̀ sí i sọ ọ́ sínú iná, ọmọ màlúù yìí sì jáde wá.” 25  Mósè sì rí i pé àwọn ènìyàn náà wà láìníjàánu, nítorí pé Áárónì ti jẹ́ kí wọ́n wà láìníjàánu+ kí ojú lè tì wọ́n láàárín àwọn alátakò wọn.+ 26  Nígbà náà, Mósè mú ìdúró rẹ̀ ní ẹnubodè ibùdó, ó sì wí pé: “Ta ni ó wà ní ìhà ọ̀dọ̀ Jèhófà? Kí ó wá sọ́dọ̀ mi!”+ Gbogbo àwọn ọmọ Léfì sì bẹ̀rẹ̀ sí kó ara wọn jọ sọ́dọ̀ rẹ̀. 27  Wàyí o, ó wí fún wọn pé: “Èyí ni ohun tí Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì wí, ‘Kí olúkúlùkù yín fi idà rẹ̀ sí ẹ̀gbẹ́ ara rẹ̀. Ẹ là á kọjá, kí ẹ sì padà láti ẹnubodè sí ẹnubodè nínú ibùdó, kí olúkúlùkù sì pa arákùnrin rẹ̀, kí olúkúlùkù sì pa ọmọnìkejì rẹ̀, kí olúkúlùkù sì pa ojúlùmọ̀ rẹ̀ tímọ́tímọ́.’”+ 28  Àwọn ọmọ Léfì+ sì bẹ̀rẹ̀ sí ṣe gẹ́gẹ́ bí Mósè ti wí, tí ó fi jẹ́ pé nǹkan bí ẹgbẹ̀ẹ́dógún ènìyàn ṣubú nínú àwọn ènìyàn náà ní ọjọ́ yẹn. 29  Mósè sì ń bá a lọ láti wí pé: “Ẹ fi agbára kún ọwọ́ yín lónìí fún Jèhófà,+ nítorí pé olúkúlùkù yín dojú ìjà kọ ọmọ rẹ̀ àti arákùnrin rẹ̀,+ kí ó sì lè fi ìbùkún dá yín lọ́lá lónìí.”+ 30  Ó sì ṣẹlẹ̀ ní ọjọ́ kejì gan-an pé Mósè bẹ̀rẹ̀ sí wí fún àwọn ènìyàn náà pé: “Ẹ̀yin—ẹ ti ṣẹ ẹ̀ṣẹ̀ ńlá,+ èmi yóò sì gòkè tọ Jèhófà lọ nísinsìnyí. Bóyá mo lè rí àtúnṣe sí ẹ̀ṣẹ̀ yín.”+ 31  Nítorí náà, Mósè padà sọ́dọ̀ Jèhófà, ó sì wí pé: “Áà, ṣùgbọ́n àwọn ènìyàn yìí ti ṣẹ ẹ̀ṣẹ̀ ńlá, ní ti pé wọ́n fi wúrà ṣe ọlọ́run fún ara wọn!+ 32  Ǹjẹ́ nísinsìnyí, bí ìwọ yóò bá dárí ẹ̀ṣẹ̀ wọn jì,+—bí bẹ́ẹ̀ sì kọ́, jọ̀wọ́, pa mi rẹ́+ kúrò nínú ìwé rẹ+ tí o ti kọ.” 33  Bí ó ti wù kí ó rí, Jèhófà wí fún Mósè pé: “Ẹnì yòówù tí ó ti ṣẹ̀ mí, ni èmi yóò pa rẹ́ kúrò nínú ìwé mi.+ 34  Wàyí o, wá, ṣamọ̀nà àwọn ènìyàn náà lọ sí ibi tí mo sọ fún ọ nípa rẹ̀. Wò ó! Áńgẹ́lì mi yóò lọ ṣáájú rẹ,+ ní ọjọ́ tí èmi yóò sì mú ìyà wá, èmi yóò mú ìyà wá sórí wọn dájúdájú fún ẹ̀ṣẹ̀ wọn.”+ 35  Jèhófà sì bẹ̀rẹ̀ sí mú ìyọnu àjàkálẹ̀ bá àwọn ènìyàn náà nítorí pé wọ́n ṣe ọmọ màlúù, èyí tí Áárónì ṣe.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé