Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

Ẹ́kísódù 31:1-18

31  Jèhófà sì ń bá a lọ láti sọ fún Mósè, pé:  “Wò ó, mo fi orúkọ pe Bẹ́sálẹ́lì+ ọmọkùnrin Úráì ọmọkùnrin Húrì ti ẹ̀yà Júdà.+  Èmi yóò sì fi ẹ̀mí Ọlọ́run kún inú rẹ̀ ní ti ọgbọ́n àti ní ti òye àti ní ti ìmọ̀ àti ní ti gbogbo onírúurú ọgbọ́n iṣẹ́ ọnà,+  fún ṣíṣe iṣẹ́ ọnà àwọn nǹkan àfọgbọ́nrọ, fún ṣíṣe iṣẹ́ wúrà àti fàdákà àti bàbà,+  àti fún ṣíṣe iṣẹ́ òkúta láti tò wọ́n+ àti fún ṣíṣe iṣẹ́ igi láti ṣe onírúurú nǹkan jáde.+  Ní tèmi, wò ó! mo fi Òhólíábù ọmọkùnrin Áhísámákì ti ẹ̀yà Dánì+ pẹ̀lú rẹ̀, àti ọkàn-àyà olúkúlùkù ẹni tí ó gbọ́n ní ọkàn-àyà ni mo fi ọgbọ́n sí, kí àwọn ní tòótọ́ lè ṣe ohun gbogbo tí mo pa láṣẹ fún ọ:+  àgọ́ ìpàdé+ àti Àpótí+ fún gbólóhùn ẹ̀rí àti ìbòrí tí ó wà lórí+ rẹ̀, àti gbogbo nǹkan èlò àgọ́ náà,  àti tábìlì àti àwọn nǹkan èlò rẹ̀,+ àti ọ̀pá fìtílà tí a fi ògidì wúrà ṣe àti gbogbo nǹkan èlò rẹ̀,+ àti pẹpẹ tùràrí.+  àti pẹpẹ ọrẹ ẹbọ sísun àti gbogbo nǹkan èlò rẹ̀,+ àti bàsíà àti ẹsẹ̀ rẹ̀,+ 10  àti ẹ̀wù iṣẹ́ ọnà àfọwọ́hun àti ẹ̀wù mímọ́ fún Áárónì àlùfáà àti ẹ̀wù àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ fún ṣíṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí àlùfáà;+ 11  àti òróró àfiyanni àti tùràrí onílọ́fínńdà fún ibùjọsìn.+ Ní ìbámu pẹ̀lú ohun gbogbo tí mo pa láṣẹ fún ọ ni wọn yóò ṣe.” 12  Jèhófà sì sọ fún Mósè síwájú sí i pé: 13  “Ní tìrẹ, sọ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, pé, ‘Ní pàtàkì àwọn sábáàtì mi ni kí ẹ pa mọ́,+ nítorí ó jẹ́ àmì láàárín èmi àti ẹ̀yin ní ìran-ìran yín, kí ẹ lè mọ̀ pé èmi Jèhófà ní ń sọ yín di mímọ́.+ 14  Kí ẹ sì pa sábáàtì náà mọ́, nítorí ó jẹ́ ohun mímọ́ lójú yín.+ Ẹni tí ó bá sọ ọ́ di aláìmọ́ ni a ó fi ikú pa+ dájúdájú. Bí ó bá ṣẹlẹ̀ pé ẹnikẹ́ni ń ṣe iṣẹ́ nínú rẹ̀, nígbà náà, ọkàn yẹn ni a óò ké kúrò láàárín àwọn ènìyàn rẹ̀.+ 15  Ọjọ́ mẹ́fà ni kí a fi ṣe iṣẹ́, ṣùgbọ́n ọjọ́ keje ni sábáàtì ìsinmi pátápátá.+ Ohun mímọ́ ni lójú Jèhófà. Ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣe iṣẹ́ ní ọjọ́ sábáàtì ni a ó fi ikú pa dájúdájú. 16  Kí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sì máa pa sábáàtì mọ́, láti máa mú sábáàtì ṣẹ ní ìran-ìran wọn. Májẹ̀mú ni fún àkókò tí ó lọ kánrin.+ 17  Láàárín èmi àti àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, àmì ni fún àkókò tí ó lọ kánrin,+ nítorí pé ní ọjọ́ mẹ́fà, Jèhófà ṣe ọ̀run àti ilẹ̀ ayé àti pé ní ọjọ́ keje, ó sinmi, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí tu ara rẹ̀ lára.’”+ 18  Wàyí o, gbàrà tí ó ti parí bíbá a sọ̀rọ̀ lórí Òkè Ńlá Sínáì, ó tẹ̀ síwájú láti fún Mósè ní wàláà méjì ti Gbólóhùn Ẹ̀rí,+ àwọn wàláà òkúta tí ìka Ọlọ́run+ kọ̀wé sára rẹ̀.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé