Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

Ẹ́kísódù 29:1-46

29  “Èyí sì ni ohun tí ìwọ yóò ṣe fún wọn láti sọ wọ́n di mímọ́ fún ṣíṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí àlùfáà fún mi: Mú ẹgbọrọ akọ màlúù kan, àti àgbò méjì,+ tí ara wọ́n dá ṣáṣá,+  àti búrẹ́dì aláìwú àti àkàrà aláìwú onírìísí òrùka tí a fi òróró rin fẹ́ẹ́rẹ́fẹ́ àti àdíngbẹ àkàrà pẹlẹbẹ aláìwú tí a fi òróró pa.+ Ìyẹ̀fun àlìkámà kíkúnná ni ìwọ yóò fi ṣe wọ́n.  Kí o sì fi wọ́n sínú apẹ̀rẹ̀, kí o sì gbé wọn wá nínú apẹ̀rẹ̀,+ àti akọ màlúù àti àgbò méjì náà pẹ̀lú.  “Ìwọ yóò sì mú Áárónì àti àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ wá síwájú ẹnu ọ̀nà+ àgọ́ ìpàdé, kí o sì fi omi wẹ̀ wọ́n.+  Lẹ́yìn náà, kí o kó àwọn ẹ̀wù náà,+ kí o sì wọ Áárónì ní aṣọ náà àti aṣọ àwọ̀lékè tí kò lápá tí a ń gbé éfódì lé àti éfódì àti aṣọ ìgbàyà, kí o sì fi àmùrè éfódì+ so ó mọ́ ọn pinpin.  Kí o sì fi láwàní wé orí rẹ̀, kí o sì fi àmì mímọ́ ti ìyàsímímọ́ sára láwàní náà.+  Kí o sì mú òróró àfiyanni,+ kí o sì dà á sí orí rẹ̀, kí o sì fòróró yàn án.+  “Lẹ́yìn náà, kí ìwọ mú àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ sún mọ́ tòsí, kí o sì fi aṣọ wọ̀ wọ́n.+  Kí o sì fi ìgbàjá dì wọ́n lámùrè, Áárónì àti àwọn ọmọkùnrin rẹ̀, kí o sì fi gèlè wé wọn lórí; iṣẹ́ àlùfáà yóò sì di tiwọn gẹ́gẹ́ bí ìlànà àgbékalẹ̀ fún àkókò tí ó lọ kánrin.+ Nípa báyìí, ìwọ yóò fi agbára kún ọwọ́ Áárónì àti ọwọ́ àwọn ọmọkùnrin rẹ̀.+ 10  “Wàyí o, kí ìwọ mú akọ màlúù wá síwájú àgọ́ ìpàdé, kí Áárónì àti àwọn ọmọ rẹ̀ sì gbé ọwọ́ wọn lé orí akọ màlúù náà.+ 11  Kí o sì pa akọ màlúù náà níwájú Jèhófà, ní ẹnu ọ̀nà àgọ́ ìpàdé.+ 12  Kí o sì mú lára ẹ̀jẹ̀ akọ màlúù náà,+ kí o sì fi ìka rẹ fi í sára àwọn ìwo pẹpẹ,+ gbogbo ìyókù ẹ̀jẹ̀ náà ni kí o sì dà sí ìhà ìsàlẹ̀ pẹpẹ.+ 13  Kí o sì mú gbogbo ọ̀rá+ tí ó bo ìfun,+ àti àmọ́ ara ẹ̀dọ̀,+ àti kíndìnrín méjèèjì àti ọ̀rá tí ó wà lára wọn, kí o sì mú wọn rú èéfín lórí pẹpẹ.+ 14  Ṣùgbọ́n ẹran akọ màlúù náà àti awọ ara rẹ̀ àti imí rẹ̀ ni kí o fi iná jó ní òde ibùdó.+ Ọrẹ ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ ni. 15  “Lẹ́yìn náà, ìwọ yóò mú àgbò kan,+ kí Áárónì àti àwọn ọmọ rẹ̀ sì gbé ọwọ́ wọn lé orí àgbò náà.+ 16  Kí o sì pa àgbò náà, kí o sì mú ẹ̀jẹ̀ rẹ̀, kí o sì fi í wọ́n pẹpẹ yíká-yíká.+ 17  Ìwọ yóò sì gé àgbò náà sí àwọn ègé rẹ̀, kí o sì fọ ìfun rẹ̀+ àti tete rẹ̀, kí o sì to àwọn ègé rẹ̀ mọ́ ara wọn títí kan orí rẹ̀. 18  Kí o sì mú odindi àgbò náà rú èéfín lórí pẹpẹ. Ọrẹ ẹbọ sísun+ sí Jèhófà ni, òórùn amáratuni.+ Ọrẹ ẹbọ àfinásun sí Jèhófà ni. 19  “Lẹ́yìn èyí, kí ìwọ mú àgbò kejì, kí Áárónì àti àwọn ọmọ rẹ̀ sì gbé ọwọ́ wọn lé orí àgbò náà.+ 20  Kí o sì pa àgbò náà, kí o sì mú lára ẹ̀jẹ̀ rẹ̀, kí o sì fi í sí ìsàlẹ̀ etí ọ̀tún Áárónì àti sí ìsàlẹ̀ etí ọ̀tún àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ àti sí àtàǹpàkò ọwọ́ ọ̀tún wọn àti sí àtàǹpàkò ẹsẹ̀ ọ̀tún wọn,+ kí o sì fi ẹ̀jẹ̀ wọ́n pẹpẹ náà yíká-yíká. 21  Kí o sì mú lára ẹ̀jẹ̀ tí ó wà lórí pẹpẹ náà àti lára òróró àfiyanni náà,+ kí o sì wọ́n ọn ṣẹ̀rẹ̀ṣẹ̀rẹ̀ sára Áárónì àti ẹ̀wù rẹ̀ àti sára àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ àti ẹ̀wù àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ pẹ̀lú rẹ̀, kí òun àti ẹ̀wù rẹ̀ àti àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ àti ẹ̀wù àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ pẹ̀lú rẹ̀ lè jẹ́ mímọ́ ní ti gidi.+ 22  “Kí o sì mú ọ̀rá àti ìrù ọlọ́ràá+ àti ọ̀rá tí ó bo ìfun, àti àmọ́ ara ẹ̀dọ̀, àti kíndìnrín méjèèjì àti ọ̀rá tí ó wà lára wọn, àti ẹsẹ̀ ọ̀tún+ kúrò lára àgbò náà, nítorí ó jẹ́ àgbò ìfinijoyè;+ 23  àti pẹ̀lú ìṣù búrẹ́dì ribiti kan àti àkàrà kan onírìísí òrùka tí a fi búrẹ́dì olóròóró ṣe àti àdíngbẹ àkàrà pẹlẹbẹ kan láti inú apẹ̀rẹ̀ àkàrà aláìwú tí ó wà níwájú Jèhófà.+ 24  Kí o sì fi gbogbo wọn sí àtẹ́lẹwọ́ Áárónì àti sí àtẹ́lẹwọ́ àwọn ọmọkùnrin rẹ̀,+ kí o sì fì wọ́n síwá-sẹ́yìn gẹ́gẹ́ bí ọrẹ ẹbọ fífì níwájú Jèhófà.+ 25  Kí o sì gbà wọ́n kúrò ní ọwọ́ wọn, kí o sì mú wọn rú èéfín lórí pẹpẹ lórí ọrẹ ẹbọ sísun náà gẹ́gẹ́ bí òórùn amáratuni níwájú Jèhófà.+ Ọrẹ ẹbọ àfinásun sí Jèhófà ni.+ 26  “Kí o sì mú igẹ̀ àgbò ìfinijoyè náà,+ tí ò wà fún Áárónì, kí o sì fì í síwá-sẹ́yìn gẹ́gẹ́ bí ọrẹ ẹbọ fífì níwájú Jèhófà, kí ó sì di ìpín tìrẹ. 27  Kí o sì sọ igẹ̀+ ọrẹ ẹbọ fífì náà di mímọ́ àti ẹsẹ̀ ìpín ọlọ́wọ̀ náà tí a fì, tí a sì fi ṣe ìtìlẹyìn láti inú àgbò ìfinijoyè náà,+ láti inú ohun tí ó wà fún Áárónì àti ohun tí ó wà fún àwọn ọmọkùnrin rẹ̀. 28  Kí ó sì di ti Áárónì àti ti àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ nípa ìlànà fún àkókò tí ó lọ kánrin fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì láti máa ṣe, nítorí ó jẹ́ ìpín ọlọ́wọ̀;+ yóò sì di ìpín ọlọ́wọ̀ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì láti máa san. Láti inú ẹbọ ìdàpọ̀ wọn,+ ìpín ọlọ́wọ̀ fún Jèhófà ni. 29  “Ẹ̀wù mímọ́+ tí ó jẹ́ ti Áárónì yóò wà fún àwọn ọmọkùnrin rẹ̀+ lẹ́yìn rẹ̀ láti fòróró yàn+ wọ́n nínú wọn àti láti fi agbára kún ọwọ́ wọn nínú wọn.+ 30  Ọjọ́ méje+ ni àlùfáà tí ó rọ́pò rẹ̀ lára àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ tí ó sì wá sínú àgọ́ ìpàdé láti ṣe ìránṣẹ́ ní ibi mímọ́ yóò fi wọ̀ wọ́n. 31  “Ìwọ yóò sì mú àgbò ìfinijoyè, ìwọ yóò sì se ẹran rẹ̀ ní ibi mímọ́.+ 32  Kí Áárónì àti àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ sì jẹ+ ẹran àgbò náà àti búrẹ́dì tí ó wà nínú apẹ̀rẹ̀ ní ẹnu ọ̀nà àgọ́ ìpàdé. 33  Kí wọ́n sì jẹ àwọn nǹkan tí a fi ṣe ètùtù láti fi agbára kún ọwọ́ wọn, kí a bàa lè sọ wọ́n di mímọ́.+ Ṣùgbọ́n àjèjì kò gbọ́dọ̀ jẹ wọ́n, nítorí pé wọ́n jẹ́ ohun mímọ́.+ 34  Bí èyíkéyìí nínú ẹran ẹbọ ìfinijoyè àti nínú búrẹ́dì náà bá sì ṣẹ́ kù títí di òwúrọ̀, nígbà náà, kí o fi iná jó ohun tí ó ṣẹ́ kù náà.+ A kò gbọ́dọ̀ jẹ ẹ́, nítorí ohun mímọ́ ni. 35  “Báyìí ni kí o ṣe fún Áárónì àti àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ ní ìbámu pẹ̀lú gbogbo ohun tí mo ti pa láṣẹ fún ọ.+ Ìwọ yóò lo ọjọ́ méje láti fi agbára kún ọwọ́ wọn.+ 36  Ìwọ yóò sì máa fi akọ màlúù ọrẹ ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ rúbọ lójoojúmọ́ fún ètùtù,+ kí o sì máa wẹ pẹpẹ náà mọ́ gaara kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ nípa ṣíṣe ètùtù ní tìtorí rẹ̀, kí o sì fòróró yàn+ án láti sọ ọ́ di mímọ́. 37  Ìwọ yóò lo ọjọ́ méje láti fi ṣe ètùtù ní tìtorí pẹpẹ náà, kí o sì sọ ọ́ di mímọ́,+ kí ó lè di pẹpẹ mímọ́ jù lọ+ ní tòótọ́. Ẹnikẹ́ni tí ó bá fara kan pẹpẹ náà ní láti jẹ́ mímọ́.+ 38  “Èyí sì ni ohun tí ìwọ yóò fi rúbọ lórí pẹpẹ náà: àwọn ẹgbọrọ àgbò, tí ọ̀kọ̀ọ̀kan jẹ́ ọlọ́dún kan, méjì ní ọjọ́ kọ̀ọ̀kan nígbà gbogbo.+ 39  Ìwọ yóò sì fi ẹgbọrọ àgbò kan rúbọ ní òwúrọ̀,+ ìwọ yóò sì fi ẹgbọrọ àgbò kejì rúbọ láàárín ìrọ̀lẹ́ méjèèjì.+ 40  Ìdá mẹ́wàá òṣùwọ̀n eéfà ìyẹ̀fun kíkúnná+ tí a fi ìlàrin òṣùwọ̀n hínì òróró tí a fún rin fẹ́ẹ́rẹ́fẹ́, àti ọrẹ ẹbọ ohun mímu+ ti wáìnì ìlàrin òṣùwọ̀n hínì, yóò lọ fún ẹgbọrọ àgbò àkọ́kọ́. 41  Ìwọ yóò sì fi ẹgbọrọ àgbò kejì rúbọ láàárín ìrọ̀lẹ́ méjèèjì. Pẹ̀lú ọrẹ ẹbọ ọkà+ bí ti òwúrọ̀ àti pẹ̀lú ọrẹ ẹbọ ohun mímu bí tirẹ̀, ni ìwọ yóò fi í rúbọ gẹ́gẹ́ bí òórùn amáratuni, ọrẹ ẹbọ àfinásun sí Jèhófà. 42  Ó jẹ́ ọrẹ ẹbọ sísun ìgbà gbogbo+ jálẹ̀ ìran-ìran yín ní ẹnu ọ̀nà àgọ́ ìpàdé níwájú Jèhófà, níbi tí èmi yóò ti pàdé yín láti bá ọ sọ̀rọ̀ níbẹ̀.+ 43  “Èmi yóò sì pàdé àwọn ọmọ Ísírẹ́lì níbẹ̀, a ó sì fi ògo mi sọ ọ́ di mímọ́+ dájúdájú. 44  Èmi yóò sì sọ àgọ́ ìpàdé àti pẹpẹ di mímọ́; èmi yóò sì sọ Áárónì àti àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ di mímọ́,+ kí wọ́n bàa lè ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí àlùfáà fún mi. 45  Èmi yóò sì pàgọ́ sí àárín àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, èmi yóò sì jẹ́ Ọlọ́run wọn.+ 46  Wọn yóò sì mọ̀ dájúdájú pé èmi ni Jèhófà Ọlọ́run wọn, tí ó mú wọn jáde kúrò ní ilẹ̀ Íjíbítì kí n lè pàgọ́ sáàárín wọn.+ Èmi ni Jèhófà Ọlọ́run wọn.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé