Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

Ẹ́kísódù 28:1-43

28  “Ní tìrẹ, mú Áárónì arákùnrin rẹ àti àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ pẹ̀lú rẹ̀ wá sọ́dọ̀ ara rẹ láti àárín àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kí ó lè ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí àlùfáà fún mi,+ Áárónì,+ Nádábù àti Ábíhù,+ Élíásárì àti Ítámárì,+ àwọn ọmọkùnrin Áárónì.  Kí o sì ṣe ẹ̀wù mímọ́ fún Áárónì arákùnrin rẹ, fún ògo àti ẹwà.+  Kí ìwọ fúnra rẹ sì sọ fún gbogbo ọlọ́gbọ́n tí ó ní ọkàn-àyà tí mo ti fi ẹ̀mí ọgbọ́n+ kún, kí wọ́n sì ṣe ẹ̀wù Áárónì fún sísọ ọ́ di mímọ́, kí ó lè ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí àlùfáà fún mi.+  “Ìwọ̀nyí sì ni ẹ̀wù tí wọn yóò ṣe: aṣọ ìgbàyà,+ àti éfódì+ àti aṣọ àwọ̀lékè tí kò lápá+ àti aṣọ oníbátànì igun mẹ́rin, láwàní+ àti ìgbàjá;+ kí wọ́n sì ṣe ẹ̀wù mímọ́ fún Áárónì arákùnrin rẹ àti àwọn ọmọkùnrin rẹ̀, kí wọ́n lè ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí àlùfáà fún mi.  Àwọn fúnra wọn yóò sì mú wúrà àti fọ́nrán òwú aláwọ̀ búlúù àti irun àgùntàn tí a fi àwọ̀ àlùkò àdàpọ̀-mọ́-pupa pa láró àti òwú aláwọ̀ rírẹ̀dòdò ti kòkòrò kókọ́sì àti aṣọ ọ̀gbọ̀ àtàtà.  “Kí wọ́n sì ṣe éfódì láti inú wúrà, fọ́nrán òwú aláwọ̀ búlúù àti irun àgùntàn tí a fi àwọ̀ àlùkò àdàpọ̀-mọ́-pupa pa láró, òwú aláwọ̀ rírẹ̀dòdò ti kòkòrò kókọ́sì àti aṣọ ọ̀gbọ̀ àtàtà lílọ́, iṣẹ́ akóṣẹ́-ọnà-sáṣọ.+  Yóò sì ní aṣọ méjì ní èjìká tí a so pọ̀ ní ìkángun rẹ̀ méjèèjì, kí a sì so ó pọ̀.+  Àti àmùrè,+ tí ó wà lórí rẹ̀ fún síso ó pinpin, bí iṣẹ́ ọnà rẹ̀ ti rí ni kí àwọn ohun tí a fi ṣe é rí, láti inú wúrà, fọ́nrán òwú aláwọ̀ búlúù àti irun àgùntàn tí a fi àwọ̀ àlùkò àdàpọ̀-mọ́-pupa pa láró àti òwú aláwọ̀ rírẹ̀dòdò ti kòkòrò kókọ́sì àti aṣọ ọ̀gbọ̀ àtàtà lílọ́.  “Kí o sì mú òkúta ónísì+ méjì, kí o sì fín+ orúkọ àwọn ọmọkùnrin Ísírẹ́lì sára wọn,+ 10  mẹ́fà nínú orúkọ wọn sára òkúta kan àti orúkọ mẹ́fà tí ó ṣẹ́ kù sára òkúta kejì ní ìtòtẹ̀léra bí a ṣe bí wọn.+ 11  Bí iṣẹ́ oníṣẹ́ ọnà òkúta, bí iṣẹ́ ọnà fífín èdìdì, ni ìwọ yóò fín òkúta méjèèjì pẹ̀lú orúkọ àwọn ọmọkùnrin Ísírẹ́lì.+ Bí lílẹ̀ ti àwọn ojú ibi ìlẹ̀mọ́ tí a fi wúrà ṣe ni ìwọ yóò ṣe wọ́n.+ 12  Kí o sì fi òkúta méjèèjì sórí àwọn aṣọ éfódì èjìká gẹ́gẹ́ bí àwọn òkúta ìrántí fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì;+ kí Áárónì sì ru orúkọ wọn níwájú Jèhófà lórí aṣọ èjìká rẹ̀ méjèèjì gẹ́gẹ́ bí ìrántí. 13  Kí o sì ṣe àwọn ojú ibi ìlẹ̀mọ́ tí a fi wúrà ṣe, 14  àti ẹ̀wọ̀n méjì tí a fi ògidì wúrà ṣe.+ Ìwọ yóò ṣe wọ́n bí okùn, pẹ̀lú iṣẹ́ ọnà ìjàrá; kí o sì so àwọn ẹ̀wọ̀n tí ó dà bí ìjàrá náà mọ́ àwọn ojú ibi ìlẹ̀mọ́ náà.+ 15  “Kí o sì fi iṣẹ́ ọnà akóṣẹ́-ọnà-sáṣọ ṣe aṣọ ìgbàyà ìdájọ́.+ Bí iṣẹ́ ọnà éfódì ni ìwọ yóò ṣe é. Wúrà, fọ́nrán òwú aláwọ̀ búlúù àti irun àgùntàn tí a fi àwọ̀ àlùkò àdàpọ̀-mọ́-pupa pa láró àti òwú aláwọ̀ rírẹ̀dòdò ti kòkòrò kókọ́sì àti aṣọ ọ̀gbọ̀ àtàtà lílọ́ ni ìwọ yóò fi ṣe é.+ 16  Kí ó jẹ́ igun mẹ́rin lọ́gbọọgba nígbà tí a bá ṣẹ́ ẹ po sí méjì, ìbú àtẹ́lẹwọ́ ni gígùn rẹ̀ àti ìbú àtẹ́lẹwọ́ ni fífẹ̀ rẹ̀.+ 17  Kí o sì fi àwọn òkúta dí i, ẹsẹ mẹ́rin àwọn òkúta ni.+ Ẹsẹ rúbì,+ tópásì+ àti émírádì+ ni ẹsẹ àkọ́kọ́. 18  Ẹsẹ kejì sì ni tọ́kọ́ásì,+ sàfáyà+ àti jásípérì.+ 19  Ẹsẹ kẹta sì ni òkúta léṣémù, ágétì+ àti ámétísì.+ 20  Ẹsẹ kẹrin ni kírísóláítì+ àti ónísì+ àti jéèdì. Kí àwọn ihò ìtẹ̀bọ̀ tí a fi wúrà ṣe wà nínú ihò tí a fi wọ́n dí.+ 21  Kí àwọn òkúta náà sì wà ní ìbámu pẹ̀lú orúkọ àwọn ọmọkùnrin Ísírẹ́lì, àwọn méjìlá náà ní ìbámu pẹ̀lú orúkọ wọn.+ Iṣẹ́ ọ̀nà fífín èdìdì ni kí wọ́n jẹ́, ọ̀kọ̀ọ̀kan ní ìbámu pẹ̀lú orúkọ rẹ̀, fún ẹ̀yà méjìlá náà.+ 22  “Kí o sì ṣe ẹ̀wọ̀n kíká sára aṣọ ìgbàyà náà, ní iṣẹ́ ọnà lílọ́, tí a fi ògidì wúrà ṣe.+ 23  Kí o sì ṣe òrùka méjì tí a fi wúrà ṣe+ sára aṣọ ìgbàyà náà, kí o sì fi òrùka méjèèjì sí ìkángun méjì aṣọ ìgbàyà náà. 24  Kí o sì mú ìjàrá méjèèjì tí a fi wúrà ṣe náà gba inú òrùka méjèèjì ní àwọn ìkángun aṣọ ìgbàyà náà.+ 25  Ìwọ yóò sì mú òpin méjì ìjàrá méjèèjì gba ojú ibi ìlẹ̀mọ́ méjì náà, kí o sì fi wọ́n sórí àwọn aṣọ éfódì èjìká náà, ní iwájú rẹ̀.+ 26  Kí o sì ṣe òrùka méjì tí a fi wúrà ṣe, kí o sì fi wọ́n sí ìkángun méjì aṣọ ìgbàyà náà ní etí rẹ̀, tí ó wà níhà éfódì ní inú.+ 27  Kí o sì ṣe òrùka méjì tí a fi wúrà ṣe, kí o sì fi wọ́n sórí aṣọ éfódì èjìká méjèèjì ní ìsàlẹ̀, ní iwájú rẹ̀, nítòsí ibi ìsopọ̀ rẹ̀, lókè àmùrè éfódì náà.+ 28  Wọn yóò sì fi okùn tín-ín-rín aláwọ̀ búlúù de àwọn òrùka aṣọ ìgbàyà mọ́ àwọn òrùka éfódì, kí ó lè máa wà lókè àmùrè éfódì náà àti kí aṣọ ìgbàyà náà má bàa yẹ̀ kúrò ní òkè éfódì náà.+ 29  “Kí Áárónì sì máa ru orúkọ àwọn ọmọkùnrin Ísírẹ́lì lára aṣọ ìgbàyà ìdájọ́ lórí ọkàn-àyà rẹ̀ nígbà tí ó bá wá sínú Ibi Mímọ́ gẹ́gẹ́ bí ìrántí níwájú Jèhófà nígbà gbogbo. 30  Kí o sì fi Úrímù+ àti Túmímù sínú aṣọ ìgbàyà ìdájọ́ náà, kí wọ́n sì máa wà lórí ọkàn-àyà Áárónì nígbà tí ó bá wọlé síwájú Jèhófà; kí Áárónì sì máa ru ìdájọ́+ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ní ọkàn-àyà rẹ̀ níwájú Jèhófà nígbà gbogbo. 31  “Kí o sì fi fọ́nrán òwú aláwọ̀ búlúù+ látòkè délẹ̀ ṣe aṣọ àwọ̀lékè tí kò lápá tí a ń gbé éfódì lé. 32  Kí ojú ọrùn sì wà ní òkè rẹ̀ ní àárín rẹ̀. Kí ojú ọrùn rẹ̀ ní ìgbátí yí ká, ohun tí olófì ṣe. Bí ojú ọrùn ẹ̀wù tí a fi àdàrọ irin ṣe ni kí ó jẹ́ lára rẹ̀, kí ó má bàa ya.+ 33  Àti sí ìṣẹ́po etí rẹ̀, kí o ṣe pómégíránétì láti inú fọ́nrán òwú aláwọ̀ búlúù àti irun àgùntàn tí a fi àwọ̀ àlùkò àdàpọ̀-mọ́-pupa pa láró àti òwú aláwọ̀ rírẹ̀dòdò ti kòkòrò kókọ́sì, sí ìṣẹ́po etí rẹ̀ yí ká, àti àwọn agogo+ wúrà sáàárín wọn yí ká; 34  agogo wúrà kan àti pómégíránétì kan, agogo wúrà kan àti pómégíránétì kan sí ìṣẹ́po etí aṣọ àwọ̀lékè tí kò lápá náà yí ká.+ 35  Kí ó sì wà lára Áárónì, kí ó lè ṣe ìránṣẹ́, kí a sì máa gbọ́ ìró láti ara rẹ̀ nígbà tí ó bá ń lọ sínú ibùjọsìn níwájú Jèhófà àti nígbà tí ó bá ń jáde, kí ó má bàa kú.+ 36  “Kí o sì fi ògidì wúrà ṣe àwo dídán, kí o sì fi iṣẹ́ ọnà fífín èdìdì fín ‘Ìjẹ́mímọ́ jẹ́ ti Jèhófà’+ sí i lára. 37  Kí o sì fi okùn tín-ín-rín aláwọ̀ búlúù dè é, kí ó sì wà lára láwàní.+ Iwájú láwàní náà ni kí ó wà. 38  Kí ó sì wà ní iwájú orí Áárónì, kí Áárónì sì máa dáhùn fún ìṣìnà lòdì sí ohun mímọ́, èyí tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì yóò sọ di mímọ́, èyíinì ni, gbogbo ẹ̀bùn mímọ́ wọn;+ kí ó sì máa wà ní iwájú orí rẹ̀ nígbà gbogbo, láti rí ìtẹ́wọ́gbà fún wọn+ níwájú Jèhófà. 39  “Kí o sì fi aṣọ ọ̀gbọ̀ àtàtà hun aṣọ oníbátànì igun mẹ́rin, kí o sì fi aṣọ ọ̀gbọ̀ àtàtà+ ṣe láwàní, ìwọ yóò sì ṣe ìgbàjá,+ iṣẹ́ ahunṣọ. 40  “Kí o sì dá aṣọ fún àwọn ọmọkùnrin Áárónì,+ kí ìwọ sì ṣe ìgbàjá fún wọn, ìwọ yóò sì ṣe gèlè+ fún wọn fún ògo àti ẹwà.+ 41  Kí o sì fi wọ́n wọ Áárónì arákùnrin rẹ láṣọ àti àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ pẹ̀lú rẹ̀, kí o sì fòróró yàn wọ́n,+ kí o sì fi agbára kún ọwọ́ wọn,+ kí o sì sọ wọ́n di mímọ́, kí wọ́n sì ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí àlùfáà fún mi. 42  Kí o sì fi aṣọ ọ̀gbọ̀ ṣe ṣòkòtò àwọ̀tẹ́lẹ̀ fún wọn láti bo ara tí ó wà ní ìhòòhò.+ Kí wọ́n gùn láti ìgbáròkó dé itan. 43  Kí wọ́n sì wà lára Áárónì àti àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ nígbà tí wọ́n bá wá sínú àgọ́ ìpàdé tàbí nígbà tí wọ́n bá sún mọ́ pẹpẹ láti ṣe ìránṣẹ́ ní ibi mímọ́, kí wọ́n má bàa fa ìṣìnà wá sórí ara wọn, kí wọ́n sì kú dájúdájú. Ìlànà àgbékalẹ̀ fún àkókò tí ó lọ kánrin ni fún òun àti àwọn ọmọ rẹ̀ lẹ́yìn rẹ̀.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé