Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Ẹ́kísódù 27:1-21

27  “Kí o sì fi igi bọn-ọ̀n-ní ṣe pẹpẹ, ìgbọ̀nwọ́ márùn-ún ni gígùn rẹ̀, ìgbọ̀nwọ́ márùn-ún sì ni fífẹ̀ rẹ̀. Kí pẹpẹ+ náà jẹ́ igun mẹ́rin lọ́gbọọgba, kí gíga rẹ̀ sì jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ mẹ́ta.  Kí o sì ṣe àwọn ìwo+ rẹ̀ sórí igun rẹ̀ mẹ́rẹ̀ẹ̀rin. Àwọn ìwo rẹ̀ yóò yọ jáde lára rẹ̀, kí o sì fi bàbà bò ó.+  Kí o sì ṣe àwọn garawa rẹ̀ fún kíkó àwọn eérú rẹ̀ ọlọ́ràá dànù, àti àwọn ṣọ́bìrì rẹ̀, àti àwọn àwokòtò rẹ̀, àti àwọn àmúga rẹ̀, àti àwọn ìkóná rẹ̀; ìwọ yóò sì fi bàbà ṣe gbogbo nǹkan èlò rẹ̀.+  Kí o sì ṣe àgbàyan fún un, tí ó rí bí àwọ̀n,+ èyí tí a fi bàbà ṣe; kí o sì ṣe òrùka bàbà mẹ́rin sára àwọ̀n náà ní ìkángun rẹ̀ mẹ́rẹ̀ẹ̀rin.  Kí o sì fi í sábẹ́ etí pẹpẹ náà nísàlẹ̀ láàárín, kí àwọ̀n náà sì wà níhà àárín pẹpẹ náà.+  Kí o sì ṣe àwọn ọ̀pá fún pẹpẹ náà, kí àwọn ọ̀pá rẹ̀ jẹ́ igi bọn-ọ̀n-ní, kí o sì fi bàbà bò wọ́n.+  Kí a sì ti àwọn ọ̀pá náà bọ àwọn òrùka náà, kí àwọn ọ̀pá náà sì wà ní ẹ̀gbẹ́ méjèèjì pẹpẹ náà nígbà tí a bá ń gbé e.+  Kí o ṣe é ní àpótí abinú-kótópó tí a fi pátákó ṣe. Gan-an gẹ́gẹ́ bí ó ti fi hàn ọ́ ní òkè ńlá náà, bẹ́ẹ̀ ni wọn yóò ṣe é.+  “Kí o sì ṣe àgbàlá+ àgọ́ ìjọsìn náà. Fún ìhà tí ó dojú kọ Négébù, níhà gúúsù, àgbàlá náà ní àwọn àsokọ́ aṣọ ọ̀gbọ̀ àtàtà lílọ́,+ ọgọ́rùn-ún ìgbọ̀nwọ́ ni gígùn ti ìhà kan. 10  Ogún ọwọ̀n rẹ̀ àti ogún ìtẹ́lẹ̀ oníhò ìtẹ̀bọ̀ wọn sì ni a fi bàbà ṣe. Èèkàn àwọn ọwọ̀n náà àti ibi ìdè wọn ni a fi fàdákà ṣe.+ 11  Bákan náà, pẹ̀lú, ni ó rí ní gígùn fún ìhà àríwá, àwọn àsokọ́ náà jẹ́ ọgọ́rùn-ún ìgbọ̀nwọ́ ní gígùn, àti ogún ọwọ̀n rẹ̀ àti ogún ìtẹ́lẹ̀ oníhò ìtẹ̀bọ̀ wọn ni a fi bàbà ṣe, èèkàn àwọn ọwọ̀n náà àti ibi ìdè wọn ni a fi fàdákà ṣe.+ 12  Ní ti fífẹ̀ àgbàlá náà, ní ìhà ìwọ̀-oòrùn, àwọn àsokọ́ náà jẹ́ àádọ́ta ìgbọ̀nwọ́, ọwọ̀n wọn jẹ́ mẹ́wàá, ìtẹ́lẹ̀ oníhò ìtẹ̀bọ̀ wọn sì jẹ́ mẹ́wàá.+ 13  Fífẹ̀ àgbàlá náà ní ìhà ìlà-oòrùn tí ó dojú kọ yíyọ-oòrùn jẹ́ àádọ́ta ìgbọ̀nwọ́.+ 14  Àwọn àsokọ́ tí ó jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ mẹ́ẹ̀ẹ́dógún sì wà ní ìhà kan, ọwọ̀n wọn jẹ́ mẹ́ta, ìtẹ́lẹ̀ oníhò ìtẹ̀bọ̀ wọn sì jẹ́ mẹ́ta.+ 15  Àti ní ìhà kejì ni àwọn àsokọ́ tí ó jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ mẹ́ẹ̀ẹ́dógún wà, ọwọ̀n wọn jẹ́ mẹ́ta, ìtẹ́lẹ̀ oníhò ìtẹ̀bọ̀ wọn sì jẹ́ mẹ́ta.+ 16  “Àti ní ẹnubodè àgbàlá náà ni àtabojú kan tí gígùn rẹ̀ jẹ́ ogún ìgbọ̀nwọ́ wà, tí a ṣe láti inú fọ́nrán òwú aláwọ̀ búlúù àti irun àgùntàn tí a fi àwọ̀ àlùkò àdàpọ̀-mọ́-pupa pa láró àti òwú aláwọ̀ rírẹ̀dòdò ti kòkòrò kókọ́sì àti aṣọ ọ̀gbọ̀ àtàtà lílọ́, iṣẹ́ ahunṣọ,+ ọwọ̀n wọn jẹ́ mẹ́rin, ìtẹ́lẹ̀ oníhò ìtẹ̀bọ̀ wọn sì jẹ́ mẹ́rin.+ 17  Gbogbo ọwọ̀n àgbàlá náà yíká-yíká ní ìdehunpọ̀ tí a fi fàdákà ṣe, èèkàn wọn sì ni a fi fàdákà ṣe, ṣùgbọ́n bàbà ni a fi ṣe ìtẹ́lẹ̀ oníhò ìtẹ̀bọ̀ wọn.+ 18  Gígùn àgbàlá náà jẹ́ ọgọ́rùn-ún ìgbọ̀nwọ́,+ fífẹ̀ rẹ̀ sì jẹ́ àádọ́ta ìgbọ̀nwọ́, gíga rẹ̀ sì jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ márùn-ún, tí a fi aṣọ ọ̀gbọ̀ àtàtà lílọ́ ṣe, ìtẹ́lẹ̀ oníhò ìtẹ̀bọ̀ wọn sì ni a fi bàbà ṣe. 19  Gbogbo nǹkan èlò àgọ́ ìjọsìn náà nínú gbogbo iṣẹ́ ìsìn rẹ̀, àti gbogbo ìkànlẹ̀ àgọ́ rẹ̀, àti gbogbo ìkànlẹ̀ àgbàlá náà ni a fi bàbà ṣe.+ 20  “Ní tìrẹ, kí o pàṣẹ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé kí wọ́n bá ọ wá ògidì òróró ólífì tí a fún, tí ó wà fún orísun ìmọ́lẹ̀, láti lè máa tan fìtílà nígbà gbogbo.+ 21  Nínú àgọ́ ìpàdé, lẹ́yìn aṣọ ìkélé+ tí ó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ Gbólóhùn Ẹ̀rí, ni Áárónì àti àwọn ọmọ rẹ̀ yóò ṣètò rẹ̀ sí láti alẹ́ títí di òwúrọ̀ níwájú Jèhófà.+ Ó jẹ́ ìlànà àgbékalẹ̀ fún ìran-ìran wọn+ fún àkókò tí ó lọ kánrin, kí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì máa ṣe é.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé