Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Ẹ́kísódù 26:1-37

26  “Àgọ́ ìjọsìn náà ni kí o fi aṣọ àgọ́ mẹ́wàá ṣe,+ aṣọ ọ̀gbọ̀ àtàtà lílọ́ àti fọ́nrán òwú aláwọ̀ búlúù àti irun àgùntàn tí a fi àwọ̀ àlùkò àdàpọ̀-mọ́-pupa pa láró àti òwú aláwọ̀ rírẹ̀dòdò ti kòkòrò kókọ́sì.+ Àwọn kérúbù+ tí a fi iṣẹ́ akóṣẹ́-ọnà-sáṣọ ṣe, ni kí o ṣe sí wọ́n.  Gígùn aṣọ àgọ́ kọ̀ọ̀kan jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ méjìdínlọ́gbọ̀n, fífẹ̀ aṣọ àgọ́ kọ̀ọ̀kan sì jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ mẹ́rin. Ìwọ̀n kan náà ni ó wà fún gbogbo aṣọ àgọ́ náà.+  Aṣọ àgọ́ márùn-ún ni kí ó para pọ̀ di ọ̀wọ́ kan tí a so ọ̀kan pọ̀ mọ́ ìkejì, àti ọ̀wọ́ kan aṣọ àgọ́ márùn-ún tí a so ọ̀kan pọ̀ mọ́ ìkejì.+  Kí o sì fi fọ́nrán òwú aláwọ̀ búlúù ṣe ihò kóróbójó sí etí aṣọ àgọ́ kan ní òpin ọ̀wọ́ náà; kí o sì ṣe bákan náà sí etí aṣọ àgọ́ tí ó wà lóde pátápátá ní ibi ìsolù kejì.+  Ìwọ yóò ṣe àádọ́ta ihò kóróbójó sí aṣọ àgọ́ kan, àádọ́ta ihò kóróbójó ni ìwọ yóò sì ṣe sí ìkángun aṣọ àgọ́ tí ó wà ní ibi ìsolù kejì, tí àwọn ihò kóróbójó náà wà ní ìdojúkọ ara wọn.+  Kí o sì fi wúrà ṣe àádọ́ta ìkọ́, kí o sì fi àwọn ìkọ́ náà so àwọn aṣọ àgọ́ náà pọ̀, ọ̀kan mọ́ ìkejì, kí ó sì di àgọ́ ìjọsìn kan.+  “Kí o sì fi aṣọ tí a fi irun ewúrẹ́+ ṣe ṣe ìbòrí àgọ́ ìjọsìn náà. Ìwọ yóò ṣe aṣọ àgọ́ mọ́kànlá.  Gígùn aṣọ àgọ́ kọ̀ọ̀kan jẹ́ ọgbọ̀n ìgbọ̀nwọ́,+ fífẹ̀ aṣọ àgọ́ kọ̀ọ̀kan sì jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ mẹ́rin. Ìwọ̀n kan náà ni ó wà fún aṣọ àgọ́ mọ́kànlá náà.  Kí o sì so aṣọ àgọ́ márùn-ún pọ̀ mọ́ra wọn àti aṣọ àgọ́ mẹ́fà pọ̀ mọ́ra wọn,+ kí o sì ṣẹ́ aṣọ àgọ́ kẹfà po sí méjì ní iwájú àgọ́. 10  Kí o sì ṣe àádọ́ta ihò kóróbójó sí etí aṣọ àgọ́ náà, èyí tí ó wà lóde pátápátá nínú ọ̀wọ́ náà, àti àádọ́ta ihò kóróbójó sí etí aṣọ àgọ́ ní ibi ìsolù kejì. 11  Kí o sì fi bàbà+ ṣe àádọ́ta ìkọ́, kí o sì ti àwọn ìkọ́ náà bọ àwọn ihò kóróbójó náà, kí o sì so àgọ́ náà pọ̀ mọ́ra, kí ó sì di ọ̀kan.+ 12  Ohun tí ó sì ṣẹ́ kù lára aṣọ àgọ́ náà jẹ́ àsorọ̀. Ìdajì lára aṣọ àgọ́ tí ó ṣẹ́ kù yóò so rọ̀ sórí ẹ̀yìn àgọ́ ìjọsìn náà. 13  Ìgbọ̀nwọ́ ní ìhà ìhín àti ìgbọ̀nwọ́ ní ìhà ọ̀hún lára ohun tí ó ṣẹ́ kù nínú gígùn aṣọ àgọ́ náà yóò sì jẹ́ àsorọ̀ sí àwọn ẹ̀gbẹ́ àgọ́ ìjọsìn náà, láti bò ó ní ìhà ìhín àti ọ̀hún. 14  “Kí o sì fi awọ àgbò tí a pa láró pupa ṣe ìbòrí fún àgọ́ náà àti ìbòrí awọ séálì sí òkè. 15  “Kí o sì fi igi bọn-ọ̀n-ní ṣe àwọn férémù+ fún àgọ́ ìjọsìn náà, ní ògùródo. 16  Ìgbọ̀nwọ́ mẹ́wàá ni gígùn férémù kan, ìgbọ̀nwọ́ kan àti ààbọ̀ sì ni fífẹ̀ férémù kọ̀ọ̀kan. 17  Ọ̀kọ̀ọ̀kan férémù náà ní ìtẹ̀bọ̀ méjì tí a so ọ̀kan pọ̀ mọ́ ìkejì. Bẹ́ẹ̀ ni ìwọ yóò ṣe sí gbogbo férémù àgọ́ ìjọsìn náà. 18  Kí o sì ṣe àwọn férémù fún àgọ́ ìjọsìn náà, ogún férémù fún ìhà tí ó dojú kọ Négébù, níhà gúúsù. 19  “Ìwọ yóò sì fi fàdákà ṣe ogójì ìtẹ́lẹ̀ oníhò ìtẹ̀bọ̀+ sábẹ́ ogún férémù náà; ìtẹ́lẹ̀ méjì oníhò ìtẹ̀bọ̀ sábẹ́ férémù kan pẹ̀lú ìtẹ̀bọ̀ rẹ̀ méjì, àti ìtẹ́lẹ̀ méjì oníhò ìtẹ̀bọ̀ sábẹ́ férémù kejì pẹ̀lú ìtẹ̀bọ̀ rẹ̀ méjì. 20  Àti fún ẹ̀gbẹ́ kejì àgọ́ ìjọsìn náà, ti ìhà àríwá, ogún férémù,+ 21  àti ogójì ìtẹ́lẹ̀ oníhò ìtẹ̀bọ̀ wọn tí a fi fàdákà ṣe, ìtẹ́lẹ̀ méjì oníhò ìtẹ̀bọ̀ sábẹ́ férémù kan àti ìtẹ́lẹ̀ méjì oníhò ìtẹ̀bọ̀ sábẹ́ férémù kejì.+ 22  Àti fún àwọn apá ẹ̀yìn àgọ́ ìjọsìn náà níhà ìwọ̀-oòrùn, ìwọ yóò ṣe férémù mẹ́fà.+ 23  Ìwọ yóò sì ṣe férémù méjì gẹ́gẹ́ bí arópòódògiri fún igun àgọ́ ìjọsìn+ náà ní apá ẹ̀yìn rẹ̀ méjèèjì. 24  Kí wọ́n sì jẹ́ ẹ̀dà méjì ní ìsàlẹ̀, kí wọ́n sì jùmọ̀ jẹ́ ẹ̀dà méjì títí dé òkè ọ̀kọ̀ọ̀kan níbi òrùka ti àkọ́kọ́. Bẹ́ẹ̀ ni yóò rí ní ti àwọn méjèèjì. Wọn yóò jẹ́ arópòódògiri fún igun méjèèjì. 25  Kí ó sì jẹ́ férémù mẹ́jọ àti ìtẹ́lẹ̀ oníhò ìtẹ̀bọ̀ wọn tí a fi fàdákà ṣe, ìtẹ́lẹ̀ mẹ́rìndínlógún, ìtẹ́lẹ̀ méjì oníhò ìtẹ̀bọ̀ lábẹ́ férémù kan àti ìtẹ́lẹ̀ méjì oníhò ìtẹ̀bọ̀ lábẹ́ férémù kejì. 26  “Kí o sì fi igi bọn-ọ̀n-ní+ ṣe àwọn ọ̀pá gbọọrọ, márùn-ún fún àwọn férémù ti ẹ̀gbẹ́ kan àgọ́ ìjọsìn náà, 27  àti ọ̀pá gbọọrọ márùn-ún fún àwọn férémù ẹ̀gbẹ́ kejì àgọ́ ìjọsìn náà àti ọ̀pá gbọọrọ márùn-ún fún àwọn férémù ẹ̀gbẹ́ àgọ́ ìjọsìn náà fún apá ẹ̀yìn méjèèjì níhà ìwọ̀-oòrùn.+ 28  Ọ̀pá gbọọrọ àárín àwọn férémù náà sì kọjá lọ láti ìpẹ̀kun dé ìpẹ̀kun. 29  “Ìwọ yóò sì fi wúrà bo àwọn férémù náà,+ àwọn òrùka wọn ni ìwọ yóò sì fi wúrà ṣe gẹ́gẹ́ bí ohun tí yóò di àwọn ọ̀pá gbọọrọ náà mú; kí o sì fi wúrà bo àwọn ọ̀pá gbọọrọ náà. 30  Kí o sì kọ́ àgọ́ ìjọsìn náà ní ìbámu pẹ̀lú àwòrán ilé kíkọ́ rẹ̀ tí a ti fi hàn ọ́ ní òkè ńlá náà.+ 31  “Kí o sì ṣe aṣọ ìkélé+ láti inú fọ́nrán òwú aláwọ̀ búlúù àti irun àgùntàn tí a fi àwọ̀ àlùkò àdàpọ̀-mọ́-pupa pa láró àti òwú aláwọ̀ rírẹ̀dòdò ti kòkòrò kókọ́sì àti aṣọ ọ̀gbọ̀ àtàtà lílọ́. Òun yóò sì ṣe àwọn kérúbù sí i,+ iṣẹ́ akóṣẹ́-ọnà-sáṣọ. 32  Kí o sì fi í sórí ọwọ̀n mẹ́rin tí a fi igi bọn-ọ̀n-ní ṣe, tí a fi wúrà bò. Èèkàn wọn ni a fi wúrà ṣe. Wọ́n wà lórí ìtẹ́lẹ̀ mẹ́rin oníhò ìtẹ̀bọ̀ tí a fi fàdákà ṣe. 33  Kí o sì fi aṣọ ìkélé sábẹ́ àwọn ìkọ́, kí o sì gbé àpótí gbólóhùn ẹ̀rí+ wá síbẹ̀ láàárín aṣọ ìkélé náà; kí aṣọ ìkélé náà ṣe ìpínyà fún yín láàárín Ibi Mímọ́+ àti Ibi Mímọ́ Jù Lọ.+ 34  Kí o sì fi ìbòrí bo àpótí gbólóhùn ẹ̀rí náà nínú Ibi Mímọ́ Jù Lọ. 35  “Kí o sì gbé tábìlì kalẹ̀ lẹ́yìn aṣọ ìkélé náà, àti ọ̀pá fìtílà+ ní ìdojúkọ tábìlì ní ẹ̀gbẹ́ àgọ́ ìjọsìn náà níhà gúúsù; tábìlì náà ni ìwọ yóò sì gbé sí ìhà àríwá. 36  Kí o sì ṣe àtabojú+ fún ẹnu ọ̀nà àgọ́ náà láti inú fọ́nrán òwú aláwọ̀ búlúù àti irun àgùntàn tí a fi àwọ̀ àlùkò àdàpọ̀-mọ́-pupa pa láró àti òwú aláwọ̀ rírẹ̀dòdò ti kòkòrò kókọ́sì àti aṣọ ọ̀gbọ̀ àtàtà lílọ́, iṣẹ́ ahunṣọ. 37  Kí o sì fi igi bọn-ọ̀n-ní ṣe ọwọ̀n márùn-ún fún àtabojú náà, kí o sì fi wúrà bò wọ́n. Èèkàn wọn ni a fi wúrà ṣe. Kí o sì fi bàbà rọ ìtẹ́lẹ̀ márùn-ún oníhò ìtẹ̀bọ̀ fún wọn.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé