Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Ẹ́kísódù 25:1-40

25  Jèhófà sì bẹ̀rẹ̀ sí sọ fún Mósè,+ pé:  “Bá àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sọ̀rọ̀, kí wọ́n lè gba ọrẹ fún mi: Ọwọ́ olúkúlùkù ènìyàn tí ọkàn-àyà rẹ̀ ru ú sókè ni kí ẹ ti gba ọrẹ mi.+  Èyí sì ni ọrẹ tí ẹ̀yin yóò gbà lọ́wọ́ wọn: wúrà+ àti fàdákà+ àti bàbà,+  àti fọ́nrán òwú aláwọ̀ búlúù, àti irun àgùntàn tí a fi àwọ̀ àlùkò àdàpọ̀-mọ́-pupa pa láró, àti òwú aláwọ̀ rírẹ̀dòdò ti kòkòrò kókọ́sì, àti aṣọ ọ̀gbọ̀ àtàtà, àti irun ewúrẹ́,+  àti awọ àgbò tí a pa láró pupa, àti awọ séálì, àti igi bọn-ọ̀n-ní;+  òróró fún orísun ìmọ́lẹ̀,+ òróró básámù+ fún òróró àfiyanni+ àti fún tùràrí onílọ́fínńdà;+  àti àwọn òkúta ónísì àti àwọn òkúta lílẹ̀ mọ́ ara éfódì+ àti fún aṣọ ìgbàyà.+  Kí wọ́n sì ṣe ibùjọsìn fún mi, nítorí èmi yóò gbé inú àgọ́ ní àárín wọn.+  Ní ìbámu pẹ̀lú gbogbo ohun tí èmi yóò fi hàn ọ́ gẹ́gẹ́ bí àwòṣe àgọ́ ìjọsìn àti àwòṣe gbogbo ohun èlò inú rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni kí ẹ ṣe é.+ 10  “Kí wọ́n sì fi igi bọn-ọ̀n-ní+ ṣe Àpótí, ìgbọ̀nwọ́ méjì àti ààbọ̀ ni gígùn rẹ̀, ìgbọ̀nwọ́ kan àti ààbọ̀ sì ni fífẹ̀ rẹ̀, ìgbọ̀nwọ́ kan àti ààbọ̀ sì ni gíga rẹ̀. 11  Kí o sì fi ògidì wúrà bò ó.+ Kí o bò ó nínú àti lóde, kí o sì ṣe ìgbátí wúrà sórí rẹ̀ yí ká.+ 12  Kí o sì rọ òrùka wúrà mẹ́rin fún un, kí o sì fi wọ́n sókè ẹsẹ̀ rẹ̀ mẹ́rẹ̀ẹ̀rin, pẹ̀lú òrùka méjì ní ẹ̀gbẹ́ rẹ̀ kan àti òrùka méjì ní ẹ̀gbẹ́ rẹ̀ kejì.+ 13  Kí o sì fi igi bọn-ọ̀n-ní ṣe àwọn ọ̀pá, kí o sì fi wúrà bò wọ́n.+ 14  Kí o sì ti àwọn ọ̀pá náà bọ àwọn òrùka ara àwọn ẹ̀gbẹ́ Àpótí náà láti máa fi wọ́n ru Àpótí náà. 15  Inú àwọn òrùka Àpótí náà ni àwọn ọ̀pá náà yóò wà. A kò ní yọ wọ́n kúrò nínú rẹ̀.+ 16  Kí o sì fi gbólóhùn ẹ̀rí tí èmi yóò fún ọ sínú Àpótí náà.+ 17  “Kí o sì fi ògidì wúrà ṣe ìbòrí, ìgbọ̀nwọ́ méjì àti ààbọ̀ ni gígùn rẹ̀, ìgbọ̀nwọ́ kan àti ààbọ̀ sì ni fífẹ̀ rẹ̀.+ 18  Kí o sì fi wúrà ṣe kérúbù méjì. Iṣẹ́ òòlù ni kí o fi ṣe wọ́n sí ìkángun méjèèjì ìbòrí náà.+ 19  Kí o sì ṣe kérúbù kan sí ìkángun yìí àti kérúbù kan sí ìkángun yẹn.+ Orí ìbòrí ni kí ẹ ṣe àwọn kérúbù náà sí ní ìkángun rẹ̀ méjèèjì. 20  Kí àwọn kérúbù náà sì na ìyẹ́ apá wọn méjèèjì sókè, ní fífi ìyẹ́ apá wọn bo ìbòrí náà lórí, tí wọ́n sì dojú kọ ara wọn.+ Kí àwọn kérúbù náà dojú kọ ìbòrí náà. 21  Kí o sì gbé ìbòrí náà+ lé Àpótí náà, inú Àpótí náà ni ìwọ yóò sì fi gbólóhùn ẹ̀rí tí èmi yóò fún ọ sí. 22  Èmi yóò sì pàdé rẹ níbẹ̀, èmi yóò sì bá ọ sọ̀rọ̀ láti orí ìbòrí náà,+ láti àárín àwọn kérúbù méjì tí ó wà lórí àpótí gbólóhùn ẹ̀rí náà, àní gbogbo ohun tí èmi yóò pa láṣẹ fún ọ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì.+ 23  “Kí o sì fi igi bọn-ọ̀n-ní ṣe tábìlì,+ ìgbọ̀nwọ́ méjì ni gígùn rẹ̀, ìgbọ̀nwọ́ kan sì ni fífẹ̀ rẹ̀, ìgbọ̀nwọ́ kan àti ààbọ̀ sì ni gíga rẹ̀. 24  Kí o sì fi ògidì wúrà bò ó, kí o sì ṣe ìgbátí wúrà sí i yí ká.+ 25  Kí o sì ṣe etí tí ó fẹ̀ tó ìbú ọwọ́ kan sí i yí ká, kí o sì ṣe ìgbátí wúrà sí etí rẹ̀ yí ká.+ 26  Kí o sì ṣe òrùka wúrà mẹ́rin fún un, kí o sì fi àwọn òrùka náà sí igun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin tí ó wà fún ẹsẹ̀ mẹ́rẹ̀ẹ̀rin náà.+ 27  Kí àwọn òrùka náà sún mọ́ etí náà gẹ́gẹ́ bí ohun tí yóò di àwọn ọ̀pá náà mú láti máa fi gbé tábìlì náà.+ 28  Kí o sì fi igi bọn-ọ̀n-ní ṣe àwọn ọ̀pá, kí o sì fi wúrà bò wọ́n, kí wọ́n sì máa fi wọ́n gbé tábìlì náà.+ 29  “Kí o sì ṣe àwọn àwo ìjẹun rẹ̀ àti àwọn ife rẹ̀ àti àwọn orù rẹ̀ àti àwọn àwokòtò rẹ̀ tí wọn yóò fi da ẹbọ ìtasílẹ̀. Kí o fi ògidì wúrà ṣe wọ́n.+ 30  Kí o sì fi búrẹ́dì àfihàn sórí tábìlì níwájú mi nígbà gbogbo.+ 31  “Kí o sì fi ògidì wúrà ṣe ọ̀pá fìtílà. Iṣẹ́ òòlù ni kí o fi ṣe ọ̀pá fìtílà náà.+ Ìhà ìsàlẹ̀ rẹ̀, àwọn ẹ̀ka rẹ̀, àwọn ife rẹ̀, àwọn kókó rubutu rẹ̀ àti àwọn ìtànná rẹ̀ yóò jáde láti ara rẹ̀. 32  Ẹ̀ka mẹ́fà ni ó sì yọ jáde ní àwọn ẹ̀gbẹ́ rẹ̀, ẹ̀ka mẹ́ta ọ̀pá fìtílà ní ẹ̀gbẹ́ rẹ̀ kan àti ẹ̀ka mẹ́ta ọ̀pá fìtílà ní ẹ̀gbẹ́ rẹ̀ kejì.+ 33  Ife mẹ́ta tí ó ní ìrísí òdòdó álímọ́ńdì wà ní ọ̀wọ́ kan àwọn ẹ̀ka náà, pẹ̀lú àwọn kókó rubutu àti àwọn ìtànná tí ọ̀kan tẹ̀ lé ìkejì, ife mẹ́ta tí ó ní ìrísí òdòdó álímọ́ńdì sì wà ní ọ̀wọ́ kejì àwọn ẹ̀ka náà, pẹ̀lú àwọn kókó rubutu àti àwọn ìtànná tí ọ̀kan tẹ̀ lé ìkejì.+ Bí ẹ̀ka mẹ́fẹ̀ẹ̀fà tí ó yọ jáde lára ọ̀pá fìtílà náà ti rí nìyí. 34  Ara ọ̀pá fìtílà náà sì ni ife mẹ́rin wà tí ó ní ìrísí òdòdó álímọ́ńdì, pẹ̀lú àwọn kókó rubutu àti àwọn ìtànná rẹ̀ tí ọ̀kan tẹ̀ lé ìkejì.+ 35  Kókó rubutu tí ó wà lábẹ́ ẹ̀ka méjì náà sì wá láti ara rẹ̀ àti kókó rubutu tí ó wà lábẹ́ ẹ̀ka méjì mìíràn wá láti ara rẹ̀ àti kókó rubutu tí ó wà lábẹ́ ẹ̀ka méjì sí i wá láti ara rẹ̀, fún ẹ̀ka mẹ́fẹ̀ẹ̀fà tí ó yọ jáde láti ara ọ̀pá fìtílà náà.+ 36  Kí kókó rubutu wọn àti ẹ̀ka wọn yọ jáde lára rẹ̀. Gbogbo rẹ̀ jẹ́ ẹyọ kan lódindi tí a fi iṣẹ́ òòlù ṣe, tí a fi ògidì wúrà ṣe.+ 37  Kí o sì ṣe fìtílà méje fún un; kí a sì tan àwọn fìtílà náà, kí wọ́n sì tàn sí àyè ilẹ̀ tí ó wà ní iwájú rẹ̀.+ 38  Kí àwọn ẹ̀mú rẹ̀ àti àwọn ìkóná rẹ̀ sì jẹ́ ògidì wúrà.+ 39  Tálẹ́ńtì kan ògidì wúrà ni kí ó fi ṣe é pẹ̀lú gbogbo nǹkan èlò rẹ̀ wọ̀nyí. 40  Kí o sì rí i pé o ṣe wọ́n ní ìbámu pẹ̀lú àwòṣe wọn tí a fi hàn ọ́ ní òkè ńlá náà.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé