Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Ẹ́kísódù 24:1-18

24  Ó sì wí fún Mósè pé: “Gòkè lọ sọ́dọ̀ Jèhófà, ìwọ àti Áárónì, Nádábù àti Ábíhù+ àti àádọ́rin+ lára àwọn àgbà ọkùnrin Ísírẹ́lì, kí ẹ sì tẹrí ba láti òkèèrè.  Kí Mósè nìkan sì sún mọ́ Jèhófà; ṣùgbọ́n àwọn kò gbọ́dọ̀ sún mọ́ tòsí, kí àwọn ènìyàn náà má sì gòkè lọ pẹ̀lú rẹ̀.”+  Lẹ́yìn náà, Mósè dé, ó sì ṣèròyìn gbogbo ọ̀rọ̀ Jèhófà àti gbogbo ìpinnu ìdájọ́+ fún àwọn ènìyàn náà, gbogbo àwọn ènìyàn náà sì dáhùn ní ohùn kan, wọ́n sì wí pé: “Gbogbo ọ̀rọ̀ tí Jèhófà sọ ni àwa múra tán láti ṣe.”+  Nítorí náà, Mósè ṣe àkọsílẹ̀ gbogbo ọ̀rọ̀ Jèhófà.+ Lẹ́yìn náà, ó dìde ní kùtùkùtù òwúrọ̀, ó sì mọ pẹpẹ kan sí ẹsẹ̀ òkè ńlá náà àti ọwọ̀n méjìlá tí ó bá ẹ̀yà méjìlá Ísírẹ́lì ṣe rẹ́gí.+  Lẹ́yìn ìyẹn, ó rán àwọn ọ̀dọ́kùnrin nínú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, wọ́n sì rú àwọn ọrẹ ẹbọ sísun, wọ́n sì fi àwọn akọ màlúù rúbọ gẹ́gẹ́ bí ẹbọ, gẹ́gẹ́ bí àwọn ẹbọ ìdàpọ̀+ sí Jèhófà.  Lẹ́yìn náà, Mósè mú ìdajì ẹ̀jẹ̀ náà, ó sì fi í sínú àwọn àwokòtò,+ ó sì wọ́n ìdajì ẹ̀jẹ̀ náà sára pẹpẹ.+  Níkẹyìn, ó mú ìwé májẹ̀mú,+ ó sì kà á ní etí àwọn ènìyàn náà.+ Nígbà náà, wọ́n wí pé: “Gbogbo ohun tí Jèhófà sọ ni àwa múra tán láti ṣe, a ó sì jẹ́ onígbọràn.”+  Nítorí náà, Mósè mú ẹ̀jẹ̀ náà, ó sì wọ́n ọn sára àwọn ènìyàn naa,+ ó sì wí pé: “Ẹ̀jẹ̀ májẹ̀mú+ náà rèé tí Jèhófà bá yín dá ní ti gbogbo ọ̀rọ̀ wọ̀nyí.”  Mósè àti Áárónì, Nádábù àti Ábíhù àti àádọ́rin lára àwọn àgbà ọkùnrin Ísírẹ́lì sì bẹ̀rẹ̀ sí gòkè lọ, 10  wọ́n sì rí Ọlọ́run Ísírẹ́lì.+ Abẹ́ ẹsẹ̀ rẹ̀ sì ni ohun kan wà tí ó dà bí iṣẹ́ ọnà òkúta sàfáyà palaba-palaba àti ohun tí ó dà bí ọ̀run gan-an ní ti ìmọ́gaara.+ 11  Òun kò sì na ọwọ́ rẹ̀ lòdì sí àwọn sàràkí ọkùnrin lára àwọn ọmọ Ísírẹ́lì,+ ṣùgbọ́n wọ́n rí ìran Ọlọ́run tòótọ́,+ wọ́n sì jẹ, wọ́n sì mu.+ 12  Wàyí o, Jèhófà wí fún Mósè pé: “Gòkè wá sọ́dọ̀ mi lórí òkè ńlá, kí o sì dúró sí ibẹ̀, nítorí mo fẹ́ fún ọ ní àwọn wàláà òkúta àti òfin àti àṣẹ tí èmi yóò kọ láti kọ́ wọn.”+ 13  Nítorí náà, Mósè àti Jóṣúà òjíṣẹ́ rẹ̀ dìde, Mósè sì gòkè lọ sórí òkè ńlá Ọlọ́run tòótọ́.+ 14  Ṣùgbọ́n àwọn àgbà ọkùnrin ni ó wí fún pé: “Ẹ dúró dè wá ní ibí yìí títí a ó fi padà sọ́dọ̀ yín.+ Sì wò ó! Áárónì àti Húrì+ wà pẹ̀lú yín. Ẹnì yòówù tí ó bá ní ẹjọ́ lábẹ́ òfin, kí ó tọ̀ wọ́n lọ.”+ 15  Nípa báyìí, Mósè gòkè lọ sórí òkè ńlá bí àwọsánmà ti bo òkè ńlá náà.+ 16  Ògo Jèhófà+ sì ń bá a lọ láti wà lórí Òkè Ńlá Sínáì,+ àwọsánmà sì ń bá a lọ láti bò ó fún ọjọ́ mẹ́fà. Nígbà tí ó ṣe, ní ọjọ́ keje, ó pe Mósè láti àárín àwọsánmà náà wá.+ 17  Ní ojú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, ìrí ògo Jèhófà sì dà bí iná tí ń jẹni run+ ní orí òkè ńlá náà. 18  Nígbà náà, Mósè wọ àárín àwọsánmà náà, ó sì gòkè lọ sórí òkè ńlá náà.+ Mósè sì ń bá a lọ láti wà ní òkè ńlá náà fún ogójì ọ̀sán àti ogójì òru.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé