Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

Ẹ́kísódù 23:1-33

23  “Ìwọ kò gbọ́dọ̀ dara pọ̀ nínú sísọ ìròyìn tí kò jóòótọ́.+ Má fọwọ́ sowọ́ pọ̀ pẹ̀lú ẹni burúkú nípa dídi ẹlẹ́rìí tí ń pète-pèrò ohun àìtọ́.+  Ìwọ kò gbọ́dọ̀ tẹ̀ lé ogunlọ́gọ̀ fún ète ibi;+ ìwọ kò sì gbọ́dọ̀ jẹ́rìí lórí ẹjọ́ kan láti lè tẹ̀ sí ọ̀dọ̀ ogunlọ́gọ̀ láti yí ìdájọ́ òdodo po.+  Ní ti àwọn ẹni rírẹlẹ̀, ìwọ kò gbọ́dọ̀ fi ojúsàájú hàn nínú ẹjọ́ rẹ̀.+  “Bí ìwọ bá ṣàdédé rí akọ màlúù tàbí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ ọ̀tá rẹ tí ń ṣáko lọ, kí o dá a padà fún un láìkùnà.+  Bí ìwọ bá rí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ ẹni tí ó kórìíra rẹ tí ó dùbúlẹ̀ lábẹ́ ẹrù tí ó gbé, nígbà náà, kí ìwọ má ṣe yẹra láti fi ẹni náà sílẹ̀. Láìkùnà, kí ìwọ àti òun tú u sílẹ̀.+  “Kí o má ṣe yí ìpinnu ìdájọ́ òtòṣì rẹ po nínú ẹjọ́ rẹ̀.+  “Kí o jìnnà réré sí ọ̀rọ̀ èké.+ Kí o má sì pa àwọn aláìmọwọ́-mẹsẹ̀ àti àwọn olódodo, nítorí èmi kì yóò polongo ẹni burúkú ní olódodo.+  “Kí o má gba àbẹ̀tẹ́lẹ̀, nítorí àbẹ̀tẹ́lẹ̀ a máa fọ́ ojú àwọn tí ó ríran kedere, ó sì lè fi èrú yí ọ̀rọ̀ àwọn olódodo po.+  “Ìwọ kò sì gbọ́dọ̀ ni àtìpó lára,+ níwọ̀n bí ẹ̀yin fúnra yín ti mọ ọkàn àtìpó, nítorí ẹ̀yin jẹ́ àtìpó ní ilẹ̀ Íjíbítì.+ 10  “Ọdún mẹ́fà ni ìwọ yóò sì fi fún irúgbìn sí ilẹ̀ rẹ, kí ìwọ sì kó èso rẹ̀ jọ.+ 11  Ṣùgbọ́n ní ọdún keje ìwọ yóò fi í sílẹ̀ láìro,+ kí o sì jẹ́ kí ó wà láìfi dá oko, kí àwọn òtòṣì nínú àwọn ènìyàn rẹ sì jẹ nínú rẹ̀; ohun tí wọ́n sì ṣẹ́ kù ni àwọn ẹranko inú pápá yóò jẹ.+ Bẹ́ẹ̀ ni ìwọ yóò ṣe sí ọgbà àjàrà rẹ àti oko ólífì rẹ. 12  “Ọjọ́ mẹ́fà ni ìwọ yóò máa fi ṣe iṣẹ́ rẹ;+ ṣùgbọ́n ní ọjọ́ keje, kí ìwọ ṣíwọ́, kí akọ màlúù rẹ àti kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ lè sinmi, kí ọmọ ẹrúbìnrin rẹ àti àtìpó sì lè tu ara wọn lára.+ 13  “Kí ẹ sì máa ṣọ́ra nípa gbogbo ohun tí mo ti sọ fún yín;+ ẹ kò sì gbọ́dọ̀ mẹ́nu kan orúkọ àwọn ọlọ́run mìíràn. Kí a má ṣe gbọ́ ọ ní ẹnu rẹ.+ 14  “Ìgbà mẹ́ta lọ́dún ni kí o máa ṣe àjọyọ̀ fún mi.+ 15  Ìwọ yóò pa àjọyọ̀ àkàrà aláìwú mọ́.+ Ìwọ yóò jẹ àkàrà aláìwú+ fún ọjọ́ méje, gan-an gẹ́gẹ́ bí mo ti pàṣẹ fún ọ, ní àkókò tí a yàn kalẹ̀ nínú oṣù Ábíbù,+ nítorí pé inú rẹ̀ ni o jáde kúrò ní Íjíbítì. Wọn kò sì gbọ́dọ̀ fara hàn níwájú mi lọ́wọ́ òfo.+ 16  Pẹ̀lúpẹ̀lù, àjọyọ̀ ìkórè ti àkọ́pọ́n èso+ iṣẹ́ òpò rẹ, ti ohun tí ìwọ fúnrúgbìn nínú pápá;+ àti àjọyọ̀ ìkórèwọlé nígbà tí ọdún ń parí lọ, nígbà tí ìwọ bá kó àmújáde iṣẹ́ òpò rẹ jọ láti inú pápá.+ 17  Ní ìgbà mẹ́ta nínú ọdún, gbogbo ọkùnrin tí ó jẹ́ tìrẹ yóò fara hàn níwájú Olúwa tòótọ́, Jèhófà.+ 18  “Ìwọ kò gbọ́dọ̀ fi ẹ̀jẹ̀ ìrúbọ mi rúbọ pa pọ̀ pẹ̀lú ohun tí ó ní ìwúkàrà. Kí ọ̀rá àjọyọ̀ mi má sì wà láti òru títí di òwúrọ̀.+ 19  “Èyí tí ó dára jù lọ nínú àkọ́pọ́n àwọn èso ilẹ̀ rẹ ni kí o mú wá sí ilé Jèhófà Ọlọ́run rẹ.+ “Ìwọ kò gbọ́dọ̀ se ọmọ ẹran nínú wàrà ìyá rẹ̀.+ 20  “Kíyè sí i, èmi yóò rán áńgẹ́lì kan+ ṣáájú rẹ láti pa ọ́ mọ́ ní ojú ọ̀nà àti láti mú ọ wá sí ibi tí mo ti pèsè sílẹ̀.+ 21  Ṣọ́ ara rẹ nítorí rẹ̀ kí o sì ṣègbọràn sí ohùn rẹ̀. Má ṣọ̀tẹ̀ sí i, nítorí kì yóò dárí ìrélànàkọjá yín jì;+ nítorí orúkọ mi wà lára rẹ̀. 22  Bí ó ti wù kí ó rí, bí ìwọ bá ṣègbọràn délẹ̀délẹ̀ sí ohùn rẹ̀, tí o sì ṣe gbogbo ohun tí èmi yóò sọ,+ nígbà náà, èmi yóò bá àwọn ọ̀tá rẹ jà dájúdájú, èmi yóò sì fòòró àwọn tí ń fòòró rẹ.+ 23  Nítorí áńgẹ́lì mi yóò lọ ṣáájú rẹ, yóò sì mú ọ wá ní tòótọ́ sọ́dọ̀ àwọn Ámórì àti àwọn ọmọ Hétì àti àwọn Pérísì àti àwọn ọmọ Kénáánì, àwọn Hífì àti àwọn ará Jébúsì, èmi yóò sì pa wọ́n rẹ́ dájúdájú.+ 24  Ìwọ kò gbọ́dọ̀ tẹrí ba fún àwọn ọlọ́run wọn, tàbí kí a sún ọ láti sìn wọ́n, ìwọ kò sì gbọ́dọ̀ ṣe ohunkóhun tí ó dà bí iṣẹ́ wọn,+ bí kò ṣe kí o wó wọn palẹ̀ láìkùnà, kí o sì wó àwọn ọwọ̀n ọlọ́wọ̀ wọn lulẹ̀ láìkùnà.+ 25  Kí ẹ sì sin Jèhófà Ọlọ́run yín,+ òun yóò sì bù kún oùnjẹ rẹ àti omi rẹ dájúdájú;+ èmi yóò sì mú àrùn kúrò ní àárín rẹ ní ti gidi.+ 26  Obìnrin tí oyún rẹ̀ ṣẹ́ tàbí àgàn kì yóò sí ní ilẹ̀ rẹ.+ Èmi yóò mú iye àwọn ọjọ́ rẹ kún.+ 27  “Èmi yóò sì rán jìnnìjìnnì mi ṣáájú rẹ,+ dájúdájú, èmi yóò kó gbogbo àwọn ènìyàn tí ìwọ yóò dé àárín wọn sínú ìdàrúdàpọ̀, èmi yóò sì fi ẹ̀yìn ọrùn gbogbo ọ̀tá rẹ fún ọ ní ti gidi.+ 28  Èmi yóò sì rán ẹ̀mí ìrẹ̀wẹ̀sì ṣáájú rẹ,+ yóò sì wulẹ̀ lé àwọn Hífì, àwọn ọmọ Kénáánì àti àwọn ọmọ Hétì kúrò níwájú rẹ.+ 29  Èmi kò ní lé wọn jáde kúrò níwájú rẹ ní ọdún kan, kí ilẹ̀ náà má bàa di ahoro, tí ẹranko inú pápá yóò sì di púpọ̀ lòdì sí ọ.+ 30  Díẹ̀díẹ̀ ni èmi yóò lé wọn jáde kúrò níwájú rẹ, títí ìwọ yóò fi so èso, tí ìwọ yóò sì gba ilẹ̀ náà ní tòótọ́.+ 31  “Èmi yóò sì pa ààlà rẹ láti Òkun Pupa dé òkun àwọn Filísínì àti láti aginjù dé Odò;+ nítorí èmi yóò fi àwọn olùgbé ilẹ̀ náà lé yín lọ́wọ́, ìwọ yóò sì lé wọn jáde kúrò níwájú ara rẹ dájúdájú.+ 32  Kí ìwọ má ṣe bá wọn dá májẹ̀mú tàbí àwọn ọlọ́run wọn.+ 33  Kí wọ́n má ṣe gbé ní ilẹ̀ rẹ, kí wọ́n má bàa mú ọ ṣẹ̀ sí mi. Bí ó bá ṣẹlẹ̀ pé o sin àwọn ọlọ́run wọn, yóò di ìdẹkùn fún ọ.”+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé