Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

Ẹ́kísódù 22:1-31

22  “Bí ó bá ṣẹlẹ̀ pé ọkùnrin kan jí akọ màlúù kan tàbí àgùntàn kan, tí ó sì pa á tàbí tí ó tà á, òun yóò fi márùn-ún lára ọ̀wọ́ ẹran san àsanfidípò fún akọ màlúù náà àti mẹ́rin lára agbo ẹran fún àgùntàn náà.+  (“Bí a bá rí olè+ kan tí ń fọ́lé+ tí a sì lù ú, tí ó sì kú, kò sí ẹ̀bi ẹ̀jẹ̀ nítorí rẹ̀.+  Bí oòrùn bá ràn sórí rẹ̀, ẹ̀bi ẹ̀jẹ̀ wà nítorí rẹ̀.) “Òun yóò san àsanfidípò láìkùnà. Bí òun kò bá ní nǹkan kan, nígbà náà, a ó tà á nítorí ohun tí ó jí.+  Bí a bá rí ohun tí ó jí ní ọwọ́ rẹ̀ láìsí àní-àní, láti orí akọ màlúù títí dórí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ àti dórí àgùntàn, tí ó wà láàyè, òun yóò san àsanfidípò ní ìlọ́po méjì.  “Bí ọkùnrin kan bá ṣokùnfà jíjẹko lórí pápá kan tàbí ọgbà àjàrà kan, tí ó sì rán àwọn ẹranko arẹrù rẹ̀ jáde, tí ó sì ṣokùnfà jíjẹ nínú pápá mìíràn, òun yóò fi èyí tí ó dára jù lọ nínú pápá òun fúnra rẹ̀ tàbí èyí tí ó dára jù lọ nínú ọgbà àjàrà òun fúnra rẹ̀ san àsanfidípò.+  “Bí ó bá ṣẹlẹ̀ pé iná kan tàn kálẹ̀, tí ó sì ràn mọ́ àwọn ẹ̀gún, tí àwọn ìtí tàbí ọkà tí ó wà ní ìdúró tàbí pápá kan sì jó run,+ ẹni tí ó dá iná náà yóò san àsanfidípò láìkùnà fún ohun tí ó jó.  “Bí ó bá ṣẹlẹ̀ pé ọkùnrin kan fi owó tàbí ohun èlò fún ọmọnìkejì rẹ̀ láti pa mọ́,+ tí a sì jí i ní ilé ọkùnrin náà, bí a bá wá olè náà rí, òun yóò san àsanfidípò ní ìlọ́po méjì.+  Bí a kò bá wá olè náà rí, nígbà náà, ẹni tí ó ni ilé náà ni a óò mú wá síwájú Ọlọ́run tòótọ́+ láti rí i yálà òun kò gbé ọwọ́ rẹ̀ lé ẹrù ọmọnìkejì rẹ̀.  Ní ti ẹjọ́ ìrélànàkọjá èyíkéyìí,+ nípa akọ màlúù, kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, àgùntàn, ẹ̀wù, ohunkóhun tí ó sọnù tí òun lè sọ nípa rẹ̀ pé, ‘Òun nìyí!’ ẹjọ́ àwọn méjèèjì yóò wá sọ́dọ̀ Ọlọ́run tòótọ́.+ Ẹni tí Ọlọ́run tòótọ́ bá pè ní ẹni burúkú ni yóò san àsanfidípò ní ìlọ́po méjì fún ọmọnìkejì rẹ̀.+ 10  “Bí ó bá ṣẹlẹ̀ pé ọkùnrin kan fún ọmọnìkejì rẹ̀ ní kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ tàbí akọ màlúù tàbí àgùntàn tàbí ẹran agbéléjẹ̀ èyíkéyìí láti tọ́jú, tí ó sì kú tàbí tí ó di aláàbọ̀ ara tàbí tí a mú un lọ nígbà tí ẹnikẹ́ni kò wo ibẹ̀, 11  ìbúra+ nípasẹ̀ Jèhófà ni kí ó wáyé láàárín àwọn méjèèjì pé òun kò gbé ọwọ́ òun lé ẹrù ọmọnìkejì òun;+ kí ẹni tí ó ni wọ́n sì tẹ́wọ́ gbà á, ẹnì kejì kì yóò sì san àsanfidípò. 12  Ṣùgbọ́n bí a bá jí wọn lọ́dọ̀ rẹ̀ ní tòótọ́, òun yóò san àsanfidípò fún ẹni tí ó ni wọ́n.+ 13  Bí ẹranko ẹhànnà bá fà á ya ní tòótọ́,+ òun yóò mú un wá gẹ́gẹ́ bí ẹ̀rí.+ Ohun tí ẹranko ẹhànnà fà ya ni a kì yóò san àsanfidípò fún. 14  “Ṣùgbọ́n bí ó bá ṣẹlẹ̀ pé ẹnikẹ́ni béèrè ohun kan tí ó jẹ́ ti ọmọnìkejì rẹ̀,+ tí ó sì di aláàbọ̀ ara tàbí tí ó kú nígbà tí kò sí lọ́dọ̀ ẹni tí ó ni ín, òun yóò san àsanfidípò láìkùnà.+ 15  Bí ó bá wà lọ́dọ̀ ẹni tí ó ni ín, òun kì yóò san àsanfidípò. Bí a bá háyà rẹ̀, kí ó wá ní ipò ìháyà rẹ̀. 16  “Wàyí o, bí ó bá ṣẹlẹ̀ pé ọkùnrin kan sún wúńdíá kan tí a kò fẹ́ sọ́nà dẹ́ṣẹ̀, tí ó sì sùn tì í ní ti tòótọ́,+ òun yóò san iye owó orí rẹ̀ láìkùnà láti fi í ṣe aya rẹ̀.+ 17  Bí baba rẹ̀ bá kọ̀ jálẹ̀ láti fi í fún un, òun yóò san owó náà ní iye owó tí a ń ra wúńdíá.+ 18  “Ìwọ kò gbọ́dọ̀ pa oníṣẹ́ àjẹ́ mọ́ láàyè.+ 19  “Ẹnikẹ́ni tí ó bá sùn ti ẹranko ni kí a fi ikú pa dájúdájú.+ 20  “Ẹni tí ó bá rúbọ sí àwọn ọlọ́run èyíkéyìí bí kò ṣe sí Jèhófà nìkan ṣoṣo ni a ó yà sọ́tọ̀ fún ìparun.+ 21  “Ìwọ kò gbọ́dọ̀ ṣe àtìpó níkà tàbí kí o ni ín lára,+ nítorí ẹ̀yin jẹ́ àtìpó ní ilẹ̀ Íjíbítì.+ 22  “Ẹ kò gbọ́dọ̀ ṣẹ́ opó èyíkéyìí tàbí ọmọdékùnrin aláìníbaba níṣẹ̀ẹ́.+ 23  Bí o bá ṣẹ́ ẹ níṣẹ̀ẹ́ pẹ́nrẹ́n, tí ó sì ké jáde sí mi pẹ́nrẹ́n, èmi yóò gbọ́ igbe ẹkún rẹ̀ láìkùnà;+ 24  ìbínú mi yóò sì ru ní ti gidi,+ èmi yóò sì fi idà pa yín dájúdájú, àwọn aya yín yóò sì di opó, àwọn ọmọkùnrin yín yóò sì di ọmọdékùnrin aláìníbaba.+ 25  “Bí ìwọ bá fi owó wín àwọn ènìyàn mi, ẹni tí ó sún mọ́ ọ tí ìṣẹ́ ń ṣẹ́,+ ìwọ kò gbọ́dọ̀ dà bí agbẹ̀dá-owó sí i. Ẹ kò gbọ́dọ̀ gbé èlé lé e.+ 26  “Bí ó bá ṣẹlẹ̀ rárá pé o gba ẹ̀wù ọmọnìkejì rẹ gẹ́gẹ́ bí ohun ìdógò,+ kí o dá a padà fún un nígbà tí oòrùn bá ń wọ̀. 27  Nítorí pé èyí ni kìkì ìbora rẹ̀.+ Aṣọ àlàbora rẹ̀ ni ó jẹ́ láti fi bo awọ ara rẹ̀. Kí ni yóò fi bora sùn? Yóò sì ṣẹlẹ̀ pé òun yóò ké jáde sí mi, èmi yóò sì gbọ́ dájúdájú, nítorí pé olóore ọ̀fẹ́ ni mí.+ 28  “Ìwọ kò gbọ́dọ̀ pe ibi wá sórí Ọlọ́run+ tàbí kí o gégùn-ún fún ìjòyè láàárín àwọn ènìyàn rẹ.+ 29  “Ọ̀pọ̀ yanturu àmújáde oko rẹ àti àkúnwọ́sílẹ̀ ti ìfúntí rẹ ni ìwọ kò gbọ́dọ̀ fi fúnni pẹ̀lú ìlọ́tìkọ̀.+ Àkọ́bí nínú àwọn ọmọkùnrin rẹ ni ìwọ yóò fi fún mi.+ 30  Báyìí ni kí o ṣe sí akọ màlúù rẹ àti àgùntàn rẹ:+ Ọjọ́ méje ni kí ó fi wà pẹ̀lú ìyá rẹ̀.+ Ọjọ́ kẹjọ ni kí o fi í fún mi. 31  “Kí ẹ sì fi hàn pé ẹ jẹ́ ènìyàn mímọ́ fún mi;+ ẹ kò sì gbọ́dọ̀ jẹ ẹran inú pápá, tí ó jẹ́ ohun tí ẹranko ẹhànnà fà ya.+ Kí ẹ sọ ọ́ sí àwọn ajá.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé