Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Ẹ́kísódù 21:1-36

21  “Ìwọ̀nyí sì ni ìpinnu ìdájọ́ tí ìwọ yóò gbé kalẹ̀ níwájú wọn:+  “Bí ó bá ṣẹlẹ̀ pé o ra Hébérù kan ṣe ẹrú,+ yóò jẹ́ ẹrú fún ọdún mẹ́fà, ṣùgbọ́n ní ọdún keje, yóò jáde lọ gẹ́gẹ́ bí ẹni tí a dá sílẹ̀ láìsanwó.+  Bí ó bá wá ní òun nìkan, yóò jáde lọ ní òun nìkan. Bí ó bá jẹ́ ẹni tí ó ní aya, nígbà náà, kí aya rẹ̀ jáde lọ pẹ̀lú rẹ̀.  Bí ọ̀gá rẹ̀ bá fún un ní aya, tí ó sì bí àwọn ọmọkùnrin tàbí àwọn ọmọbìnrin fún un, aya náà àti àwọn ọmọ rẹ̀ yóò di ti ọ̀gá obìnrin náà,+ ọkùnrin náà yóò sì jáde lọ ní òun nìkan.+  Ṣùgbọ́n bí ẹrú náà bá fi ìtẹpẹlẹmọ́ wí pé, ‘Mo nífẹ̀ẹ́ ọ̀gá mi, aya mi àti àwọn ọmọ mi ní ti gidi; èmi kò fẹ́ jáde lọ gẹ́gẹ́ bí ẹni tí a dá sílẹ̀ lómìnira,’+  nígbà náà, kí ọ̀gá rẹ̀ mú un sún mọ́ Ọlọ́run tòótọ́, kí ó sì mú un wá síbi ilẹ̀kùn tàbí òpó ilẹ̀kùn; kí ọ̀gá rẹ̀ sì fi òòlu lu etí rẹ̀, kí ó sì jẹ́ ẹrú rẹ̀ fún àkókò tí ó lọ kánrin.+  “Bí ó bá sì ṣẹlẹ̀ pé ọkùnrin kan ta ọmọbìnrin rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ẹrúbìnrin,+ òun kì yóò jáde lọ lọ́nà tí àwọn ẹrúkùnrin gbà ń jáde.  Bí obìnrin náà bá jẹ́ okùnfà ìbìnújẹ́ ní ojú ọ̀gá rẹ̀ tí ó fi jẹ́ pé kò yàn án gẹ́gẹ́ bí wáhàrì,+ ṣùgbọ́n tí ó mú kí a tún un rà padà, òun kì yóò lẹ́tọ̀ọ́ sí títà á fún àwọn ènìyàn ilẹ̀ òkèèrè nínú àdàkàdekè tí ó ṣe sí i.  Bí ó bá sì jẹ́ pé ọmọkùnrin rẹ̀ ni ó yàn án fún, òun yóò ṣe sí i gẹ́gẹ́ bí ẹ̀tọ́ àwọn ọmọbìnrin.+ 10  Bí ó bá mú aya mìíràn fún ara rẹ̀, ohun ìgbẹ́mìíró rẹ̀, aṣọ rẹ̀+ àti ẹ̀tọ́ ìgbéyàwó rẹ̀+ kì yóò dínkù. 11  Bí òun kì yóò bá ṣe nǹkan mẹ́ta wọ̀nyí fún un, nígbà náà, kí obìnrin náà jáde lọ́fẹ̀ẹ́, láìsan owó. 12  “Ẹni tí ó lu ènìyàn tí ó fi kú ní ti gidi ni kí a fi ikú pa láìkùnà.+ 13  Ṣùgbọ́n bí ó bá jẹ́ pé ẹnì kan kò lúgọ deni, tí Ọlọ́run tòótọ́ sì jẹ́ kí ó ṣẹlẹ̀ ní ọwọ́ rẹ̀,+ nígbà náà, èmi yóò yan ibì kan fún ọ tí òun lè sá lọ sí.+ 14  Bí ó bá sì ṣẹlẹ̀ pé ènìyàn kan gbaná jẹ mọ́ ọmọnìkejì rẹ̀ débi pé ó fi àrékérekè pa á,+ kí ìwọ mú un kúrò láti kú, àní bí ó tilẹ̀ wà níbi pẹpẹ+ mi. 15  Ẹnikẹ́ni tí ó bá sì lu baba rẹ̀ àti ìyá rẹ̀ ni kí a fi ikú pa láìkùnà.+ 16  “Ẹni tí ó bá sì jí ènìyàn gbé,+ tí ó sì tà á+ tàbí ẹni tí a rí i lọ́wọ́ rẹ̀ ni kí a fi ikú pa láìkùnà.+ 17  “Ẹni tí ó bá sì pe ibi wá sórí baba rẹ̀ àti ìyá rẹ̀ ni a ó fi ikú pa láìkùnà.+ 18  “Bí ó bá sì ṣẹlẹ̀ pé àwọn ọkùnrin kó wọnú aáwọ̀, tí ọ̀kan sì fi òkúta tàbí ọkọ́ lu ọmọnìkejì rẹ̀, tí òun kò sì kú, ṣùgbọ́n tí ó di dandan pé kí ó wà lórí ibùsùn rẹ̀; 19  bí ó bá dìde tí ó sì rìn káàkiri níta lórí àwọn ohun tí ó fi ń tilẹ̀ rìn, nígbà náà, ẹni tí ó lù ú yóò bọ́ lọ́wọ́ ìyà; òun yóò san àsanfidípò kìkì fún àkókò tí ẹni yẹn pàdánù nídìí iṣẹ́ rẹ̀ títí yóò fi mú un lára dá pátápátá. 20  “Bí ó bá sì ṣẹlẹ̀ pé ọkùnrin kan fi ọ̀pá lu+ ẹrúkùnrin rẹ̀ tàbí ẹrúbìnrin rẹ̀, tí ẹni yẹn sì kú ní ti gidi ní ọwọ́ rẹ̀, a ó gbẹ̀san ẹni yẹn láìkùnà.+ 21  Àmọ́ ṣá o, bí ó bá dúró pẹ́ fún ọjọ́ kan tàbí ọjọ́ méjì, a kì yóò gbẹ̀san rẹ̀, nítorí pe owó rẹ̀ ni òun jẹ́. 22  “Bí ó bá sì ṣẹlẹ̀ pé àwọn ọkùnrin bá ara wọn jìjàkadì, tí wọ́n sì ṣe obìnrin tí ó lóyún lọ́ṣẹ́ ní ti gidi, tí àwọn ọmọ rẹ̀ sì jáde+ ṣùgbọ́n tí jàǹbá aṣekúpani kò ṣẹlẹ̀, a ó bu ìtanràn lé e láìkùnà ní ìbámu pẹ̀lú ohun tí ẹni tí ó ni obìnrin náà bá bù lé e; kí òun sì fi í fúnni nípasẹ̀ àwọn adájọ́.+ 23  Ṣùgbọ́n bí jàǹbá aṣekúpani bá ṣẹlẹ̀, nígbà náà, kí ìwọ fi ọkàn fún ọkàn,+ 24  ojú fún ojú, eyín fún eyín, ọwọ́ fún ọwọ́, ẹsẹ̀ fún ẹsẹ̀,+ 25  àmì ìjóni fún àmì ìjóni, ọgbẹ́ fún ọgbẹ́, ẹ̀ṣẹ́ fún ẹ̀ṣẹ́.+ 26  “Bí ó bá sì ṣẹlẹ̀ pé ọkùnrin kan gbá ojú ẹrúkùnrin rẹ̀ tàbí ojú ẹrúbìnrin rẹ̀, tí ó sì bà á jẹ́ ní ti gidi, òun yóò rán an lọ gẹ́gẹ́ bí ẹni tí a dá sílẹ̀ lómìnira ní ìsanfidípò fún ojú rẹ̀.+ 27  Bí ó bá sì jẹ́ eyín ẹrúkùnrin rẹ̀ tàbí eyín ẹrúbìnrin rẹ̀ ni ó gbá yọ, òun yóò rán an lọ gẹ́gẹ́ bí ẹni tí a dá sílẹ̀ lómìnira ní ìsanfidípò fún eyín rẹ̀. 28  “Bí ó bá sì ṣẹlẹ̀ pé ọkùnrin kan tàbí obìnrin kan ni akọ màlúù kàn, tí ẹni yẹn sì kú ní ti tòótọ́, akọ màlúù náà ni a ó sọ lókùúta+ láìkùnà, ṣùgbọ́n ẹran rẹ̀ ni a kì yóò jẹ; ẹni tí ó ni akọ màlúù náà sì bọ́ lọ́wọ́ ìyà. 29  Ṣùgbọ́n bí ó bá jẹ́ ìṣe akọ màlúù kan láti máa kàn tẹ́lẹ̀, tí a sì ti fún ẹni tí ó ni ín ní ìkìlọ̀, ṣùgbọ́n tí òun kò sì sé e mọ́, tí ó sì fi ikú pa ọkùnrin kan tàbí obìnrin kan, akọ màlúù náà ni a ó sọ lókùúta, a ó sì tún fi ikú pa ẹni tí ó ni ín. 30  Bí a bá gbé ìràpadà kà á lórí, nígbà náà, kí ó fi iye owó ìtúnràpadà fúnni fún ọkàn rẹ̀ ní ìbámu pẹ̀lú gbogbo ohun tí a óò gbé kà á lórí.+ 31  Yálà ó kan ọmọkùnrin kan tàbí ó kan ọmọbìnrin kan, a ó ṣe sí i ní ìbámu pẹ̀lú ìpinnu ìdájọ́ yìí.+ 32  Bí ó bá jẹ́ ẹrúkùnrin kan tàbí ẹrúbìnrin kan ni akọ màlúù náà kàn, òun yóò fi iye owó ọgbọ̀n ṣékélì+ fún ọ̀gá ẹni yẹn, akọ màlúù náà ni a ó sì sọ lókùúta. 33  “Bí ó bá sì ṣẹlẹ̀ pé ọkùnrin kan ṣí kòtò kan sílẹ̀ tàbí bí ó bá ṣẹlẹ̀ pé ọkùnrin kan gbẹ́ kòtò kan tí kò sì bò ó, tí akọ màlúù kan tàbí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ kan sì já sínú rẹ̀,+ 34  ẹni tí ó ni kòtò náà yóò san àsanfidípò.+ Iye owó náà ni òun yóò dá padà fún ẹni tí ó ni ín, òkú ẹran náà yóò sì di tirẹ̀. 35  Bí ó bá sì ṣẹlẹ̀ pé akọ màlúù ọkùnrin kan ṣe akọ màlúù ẹlòmíràn lọ́ṣẹ́, tí ó sì kú, nígbà náà, kí wọ́n ta ààyè akọ màlúù náà, kí wọ́n sì pín iye owó tí a san fún un; kí wọ́n sì tún pín èyí tí ó kú.+ 36  Tàbí bí a bá mọ̀ pé ó jẹ́ ìṣe akọ màlúù kan láti máa kàn tẹ́lẹ̀, ṣùgbọ́n tí ẹni tí ó ni ín kò sé e mọ́,+ kí ó san àsanfidípò+ ní akọ màlúù fún akọ màlúù láìkùnà, èyí tí ó kú yóò sì di tirẹ̀.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé