Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Ẹ́kísódù 20:1-26

20  Ọlọ́run sì bẹ̀rẹ̀ sí sọ gbogbo ọ̀rọ̀ wọ̀nyí, pé:+  “Èmi ni Jèhófà Ọlọ́run rẹ,+ tí ó mú ọ jáde kúrò ní ilẹ̀ Íjíbítì, kúrò ní ilé ẹrú.+  Ìwọ kò gbọ́dọ̀ ní àwọn ọlọ́run èyíkéyìí mìíràn+ níṣojú mi.  “Ìwọ kò gbọ́dọ̀ ṣe ère gbígbẹ́ fún ara rẹ tàbí ìrísí tí ó dà bí ohunkóhun tí ó wà nínú ọ̀run lókè tàbí tí ó wà lábẹ́ ilẹ̀ tàbí tí ó wà nínú omi lábẹ́ ilẹ̀.+  Ìwọ kò gbọ́dọ̀ tẹrí ba fún wọn tàbí kí a sún ọ láti sìn wọ́n,+ nítorí èmi Jèhófà Ọlọ́run rẹ jẹ́ Ọlọ́run tí ń béèrè ìfọkànsìn tí a yà sọ́tọ̀ gedegbe,+ tí ń mú ìyà ìṣìnà àwọn baba wá sórí àwọn ọmọ, sórí ìran kẹta àti sórí ìran kẹrin, ní ti àwọn tí ó kórìíra mi;+  ṣùgbọ́n tí ó ń ṣe inú-rere-onífẹ̀ẹ́ sí ìran ẹgbẹ̀rún ní ti àwọn tí ó nífẹ̀ẹ́ mi, tí wọ́n sì ń pa àwọn àṣẹ mi mọ́.+  “Ìwọ kò gbọ́dọ̀ lo orúkọ Jèhófà Ọlọ́run rẹ lọ́nà tí kò ní láárí,+ nítorí Jèhófà kò ní ṣàìfi ìyà jẹ ẹni tí ó lo orúkọ rẹ̀ lọ́nà tí kò ní láárí.+  “Máa rántí ọjọ́ sábáàtì láti kà á sí ọlọ́wọ̀,+  kí ìwọ ṣe iṣẹ́ ìsìn, kí o sì ṣe gbogbo iṣẹ́ rẹ ní ọjọ́ mẹ́fà.+ 10  Ṣùgbọ́n ọjọ́ keje jẹ́ sábáàtì fún Jèhófà Ọlọ́run rẹ.+ Ìwọ kò gbọ́dọ̀ ṣe iṣẹ́ èyíkéyìí, ìwọ tàbí ọmọkùnrin rẹ tàbí ọmọbìnrin rẹ, ẹrúkùnrin rẹ tàbí ẹrúbìnrin rẹ tàbí ẹran agbéléjẹ̀ rẹ tàbí àtìpó rẹ tí ó wà nínú àwọn ẹnubodè rẹ.+ 11  Nítorí ọjọ́ mẹ́fà ni Jèhófà ṣe ọ̀run àti ilẹ̀ ayé, òkun àti ohun gbogbo tí ó wà nínú wọn,+ ó sì bẹ̀rẹ̀ sí sinmi ní ọjọ́ keje.+ Ìdí nìyẹn tí Jèhófà fi bù kún ọjọ́ sábáàtì, tí ó sì bẹ̀rẹ̀ sí ṣe é ní ọlọ́wọ̀.+ 12  “Bọlá fún baba rẹ àti ìyá rẹ+ kí àwọn ọjọ́ rẹ bàa lè gùn lórí ilẹ̀ tí Jèhófà Ọlọ́run rẹ yóò fi fún ọ.+ 13  “Ìwọ kò gbọ́dọ̀ ṣìkà pànìyàn.+ 14  “Ìwọ kò gbọ́dọ̀ ṣe panṣágà.+ 15  “Ìwọ kò gbọ́dọ̀ jalè.+ 16  “Ìwọ kò gbọ́dọ̀ jẹ́rìí lọ́nà èké gẹ́gẹ́ bí ẹlẹ́rìí lòdì sí ọmọnìkejì rẹ.+ 17  “Ojú rẹ kò gbọ́dọ̀ wọ ilé ọmọnìkejì rẹ. Ojú rẹ kò gbọ́dọ̀ wọ aya ọmọnìkejì rẹ,+ tàbí ẹrúkùnrin rẹ̀ tàbí ẹrúbìnrin rẹ̀ tàbí akọ màlúù rẹ̀ tàbí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ̀ tàbí ohunkóhun tí ó jẹ́ ti ọmọnìkejì rẹ.”+ 18  Wàyí o, gbogbo àwọn ènìyàn náà rí ààrá àti ìkọyẹ̀rì mànàmáná àti ìró ìwo àti òkè ńlá tí ń rú èéfín. Nígbà tí àwọn ènìyàn náà rí i, nígbà náà ni wọ́n gbọ̀n pẹ̀pẹ̀, tí wọ́n sì dúró ní òkèèrè.+ 19  Wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí wí fún Mósè pé: “Ìwọ ni kí ó máa bá wa sọ̀rọ̀, kí a sì máa fetí sílẹ̀; ṣùgbọ́n má ṣe jẹ́ kí Ọlọ́run bá wa sọ̀rọ̀ kí àwa má bàa kú.”+ 20  Nítorí náà, Mósè wí fún àwọn ènìyàn náà pé: “Ẹ má fòyà, nítorí pé tìtorí dídán yín wò ni Ọlọ́run tòótọ́ fi wá,+ àti kí ìbẹ̀rù rẹ̀ bàa lè máa wà nìṣó níwájú yín kí ẹ má bàa ṣẹ̀.”+ 21  Àwọn ènìyàn náà sì ń bá a lọ ní dídúró ní òkèèrè, ṣùgbọ́n Mósè sún mọ́ ìwọ́jọpọ̀ àwọsánmà ṣíṣú náà níbi tí Ọlọ́run tòótọ́ wà.+ 22  Jèhófà sì ń bá a lọ láti wí fún Mósè pé:+ “Èyí ni ohun tí ìwọ yóò wí fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, ‘Ẹ̀yin fúnra yín rí i pé láti ọ̀run wá ni mo ti bá yín sọ̀rọ̀.+ 23  Ẹ kò gbọ́dọ̀ ṣe àwọn ọlọ́run fàdákà pẹ̀lú mi, ẹ kò sì gbọ́dọ̀ ṣe àwọn ọlọ́run wúrà fún ara yín.+ 24  Pẹpẹ ilẹ̀+ ni kí o sì ṣe fún mi, orí rẹ̀ sì ni kí o ti máa rú àwọn ọrẹ ẹbọ sísun rẹ àti àwọn ẹbọ ìdàpọ̀ rẹ, agbo ẹran rẹ àti ọ̀wọ́ ẹran rẹ.+ Ibi gbogbo tí èmi yóò ti mú kí a rántí orúkọ mi ni èmi yóò ti wá bá ọ, èmi yóò sì bù kún ọ dájúdájú.+ 25  Bí ìwọ bá sì fi àwọn òkúta ṣe pẹpẹ fún mi, ìwọ kò gbọ́dọ̀ mọ wọ́n gẹ́gẹ́ bí àwọn òkúta gbígbẹ́. Bí ó bá ṣẹlẹ̀ pé o lo ẹyá rẹ lára rẹ̀ ní ti gidi, nígbà náà, ìwọ yóò sọ ọ́ di aláìmọ́.+ 26  Ìwọ kò sì gbọ́dọ̀ fi àtẹ̀gùn gun pẹpẹ mi, kí abẹ́ rẹ má bàa hàn lórí rẹ̀.’

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé