Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

Ẹ́kísódù 2:1-25

2  Láàárín àkókò náà, ọkùnrin kan ní ilé Léfì lọ, ó sì fẹ́ ọmọbìnrin Léfì kan.+  Obìnrin náà sì lóyún, ó sì bí ọmọkùnrin kan. Nígbà tí ó rí bí ọmọ náà ti dára tó ní ìrìsí, ó pa á mọ́+ fún oṣù òṣùpá mẹ́ta.+  Nígbà tí kò tún lè pa á mọ́ mọ́,+ nítorí rẹ̀, ó wá mú àpótí tí a fi òrépèté ṣe, ó sì fi ọ̀dà bítúmẹ́nì dídì àti ọ̀dà bítúmẹ́nì rírọ̀+ rẹ́ ẹ, ó sì gbé ọmọ náà sínú rẹ̀, ó sì gbé e sáàárín àwọn esùsú+ ní bèbè Odò Náílì.  Síwájú sí i, arábìnrin rẹ̀ dúró ní òkèèrè láti rí ohun tí yóò ṣẹlẹ̀ sí i.+  Láìpẹ́, ọmọbìnrin Fáráò sọ̀ kalẹ̀ wá láti wẹ̀ nínú Odò Náílì, àwọn ẹmẹ̀wà rẹ̀ tí ó jẹ́ obìnrin sì ń rìn létí Odò Náílì. Ó sì tajú kán rí àpótí náà ní àárín àwọn esùsú. Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, ó rán ẹrúbìnrin rẹ̀ kí ó lè gbé e wá.+  Nígbà tí ó ṣí i, ó wá rí ọmọ náà, kíyè sí i, ọmọdékùnrin náà ń sunkún. Látàrí èyí, ó yọ́nú sí i,+ bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ó wí pé: “Ọ̀kan lára àwọn ọmọ Hébérù nìyí.”  Nígbà náà ni arábìnrin rẹ̀ sọ fún ọmọbìnrin Fáráò pé: “Ṣé kí n lọ bá ọ dìídì pe obìnrin olùṣètọ́jú kan láti inú àwọn obìnrin Hébérù kí ó lè máa bá ọ ṣètọ́jú ọmọ náà?”  Nítorí náà, ọmọbìnrin Fáráò sọ fún un pé: “Lọ!” Lójú-ẹsẹ̀, omidan náà lọ pe ìyá ọmọ náà.+  Nígbà náà ni ọmọbìnrin Fáráò sọ fún un pé: “Gbé ọmọ yìí dání lọ, kí o sì máa bá mi ṣètọ́jú rẹ̀, èmi fúnra mi yóò sì fún ọ ní owó ọ̀yà rẹ.”+ Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, obìnrin náà gbé ọmọ náà, ó sì ṣètọ́jú rẹ̀. 10  Ọmọ náà sì dàgbà. Lẹ́yìn náà, ó mú un wá fún ọmọbìnrin Fáráò, ó sì tipa báyìí di ọmọkùnrin rẹ̀;+ ó sì bẹ̀rẹ̀ sí pe orúkọ rẹ̀ ní Mósè, ó sì wí pé: “Nítorí pé mo fà á jáde láti inú omi.”+ 11  Wàyí o, ó ṣẹlẹ̀ pé ní ọjọ́ wọnnì, bí Mósè tí ń di alágbára, ó jáde lọ sọ́dọ̀ àwọn arákùnrin rẹ̀ kí ó lè wo ẹrù ìnira tí wọ́n ń rù;+ ó sì tajú kán rí ọmọ Íjíbítì kan tí ń lu Hébérù kan tí ó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn arákùnrin rẹ̀.+ 12  Nítorí náà, ó yíjú síhìn-ín sọ́hùn-ún, ó sì rí i pé kò sí ẹnikẹ́ni ní àyíká. Nígbà náà ni ó ṣá ọmọ Íjíbítì náà balẹ̀, ó sì pa á mọ́ sínú iyanrìn.+ 13  Bí ó ti wù kí ó rí, ó jáde lọ ní ọjọ́ tí ó tẹ̀ lé e, sì kíyè sí i, àwọn ọkùnrin Hébérù méjì ń bá ara wọn jìjàkadì. Nítorí náà, ó sọ fún ẹni tí ó jẹ̀bi pé: “Èé ṣe tí o fi ń lu alábàákẹ́gbẹ́ rẹ?”+ 14  Látàrí èyí, ó wí pé: “Ta ní yàn ọ́ ṣe ọmọ aládé àti onídàájọ́ lórí wa?+ Ìwọ ha ń pète-pèrò láti pa mí gẹ́gẹ́ bí o ti pa ọmọ Íjíbítì náà?”+ Àyà wá fo Mósè wàyí, ó sì wí pé: “Dájúdájú, nǹkan yìí ti di mímọ̀!”+ 15  Lẹ́yìn náà, Fáráò wá gbọ́ nípa nǹkan yìí, ó sì gbìdánwò láti pa Mósè;+ ṣùgbọ́n Mósè fẹsẹ̀ fẹ+ kúrò lọ́dọ̀ Fáráò kí ó lè máa gbé ní ilẹ̀ Mídíánì;+ ó sì mú ìjókòó lẹ́bàá kànga kan. 16  Wàyí o, àlùfáà+ Mídíánì ní ọmọbìnrin méje, bí ìṣe wọn, wọ́n wá fa omi, wọ́n sì kún àwọn kòtò ìmumi láti fi omi fún agbo ẹran baba wọn.+ 17  Bí ìṣe wọn, àwọn olùṣọ́ àgùntàn wá, wọ́n sì lé wọn lọ. Látàrí èyí, Mósè dìde, ó sì ran àwọn obìnrin náà lọ́wọ́, ó sì fi omi fún agbo ẹran wọn.+ 18  Nítorí náà, nígbà tí wọ́n dé ilé lọ́dọ̀ Réúẹ́lì+ baba wọn, ó wí tìyanu-tìyanu pé: “Báwo ló ti jẹ́ tí ẹ fi tètè dé ilé lónìí?” 19  Wọ́n fèsì pé: “Ará Íjíbítì kan+ ni ó dá wa nídè kúrò lọ́wọ́ àwọn olùṣọ́ àgùntàn àti pé, ní àfikún, ó fa omi fún wa ní ti gidi, kí ó lè fi omi fún agbo ẹran.” 20  Nígbà náà ni ó wí fún àwọn ọmọbìnrin rẹ̀ pé: “Ṣùgbọ́n òun dà? Èé ṣe tí ẹ fi fi ọkùnrin náà sílẹ̀ sẹ́yìn? Ẹ pè é wá, kí ó lè jẹ oúnjẹ.”+ 21  Lẹ́yìn náà, Mósè fi ẹ̀mí ìmúratán hàn láti máa gbé pẹ̀lú ọkùnrin náà, ó sì fi Sípórà+ ọmọbìnrin rẹ̀ fún Mósè. 22  Lẹ́yìn náà, obìnrin náà bí ọmọkùnrin kan, ó sì pe orúkọ rẹ̀ ní Gẹ́ṣómù,+ nítorí, ó wí pé: “Mo wá di àtìpó ní ilẹ̀ òkèèrè.”+ 23  Ó sì ṣẹlẹ̀ láàárín ọ̀pọ̀ ọjọ́ wọnnì pé ọba Íjíbítì kú níkẹyìn,+ ṣùgbọ́n àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ń bá a lọ láti mí ìmí ẹ̀dùn nítorí ìsìnrú náà, wọ́n sì ń ké jáde nínú ìráhùn,+ igbe wọn fún ìrànlọ́wọ́ sì ń gòkè lọ sọ́dọ̀ Ọlọ́run tòótọ́ ṣáá nítorí ìsìnrú náà.+ 24  Nígbà tí ó ṣe, Ọlọ́run gbọ́+ ìkérora+ wọn, Ọlọ́run sì rántí májẹ̀mú rẹ̀ pẹ̀lú Ábúráhámù, Ísákì àti Jékọ́bù.+ 25  Nítorí náà, Ọlọ́run bojú wo àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, Ọlọ́run sì kíyè sí i.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé