Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Ẹ́kísódù 19:1-25

19  Ní oṣù kẹta lẹ́yìn tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì jáde kúrò ní ilẹ̀ Íjíbítì,+ ní ọjọ́ kan náà, wọ́n dé aginjù Sínáì.+  Wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí ṣí kúrò ní Réfídímù,+ wọ́n sì wá sí aginjù Sínáì, wọ́n sì dó sí aginjù;+ Ísírẹ́lì sì dó síbẹ̀ ní iwájú òkè ńlá náà.+  Mósè sì gòkè lọ bá Ọlọ́run tòótọ́, Jèhófà sì bẹ̀rẹ̀ sí pè é láti òkè ńlá náà+ wá, pé: “Èyí ni ohun tí ìwọ yóò wí fún ilé Jékọ́bù, tí ìwọ yóò sì sọ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì,  ‘Ẹ̀yin fúnra yín ti rí ohun tí mo ṣe sí àwọn ará Íjíbítì,+ kí èmi lè gbé yín lórí ìyẹ́ apá àwọn idì, kí n sì mú yín wá sọ̀dọ̀ ara mi.+  Wàyí o, bí ẹ̀yin yóò bá ṣègbọràn délẹ̀délẹ̀+ sí ohùn mi, tí ẹ ó sì pa májẹ̀mú mi mọ́ ní ti gidi,+ dájúdájú, nígbà náà, ẹ̀yin yóò di àkànṣe dúkìá mi nínú gbogbo àwọn ènìyàn yòókù,+ nítorí pé, gbogbo ilẹ̀ ayé jẹ́ tèmi.+  Ẹ̀yin fúnra yín yóò sì di ìjọba àwọn àlùfáà àti orílẹ̀-èdè mímọ́+ fún mi.’ Ìwọ̀nyí ni ọ̀rọ̀ tí ìwọ yóò sọ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì.”  Nítorí náà, Mósè wá, ó sì pe àwọn àgbà ọkùnrin+ àwọn ènìyàn náà, ó sì gbé gbogbo ọ̀rọ̀ wọ̀nyí tí Jèhófà pa láṣẹ fún un kalẹ̀ níwájú wọn.+  Lẹ́yìn ìyẹn, gbogbo àwọn ènìyàn náà ní ìfìmọ̀ṣọ̀kan dáhùn, wọ́n sì wí pé: “Gbogbo ohun tí Jèhófà sọ ni àwa ti múra tán láti ṣe.”+ Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, Mósè mú ọ̀rọ̀ àwọn ènìyàn náà padà lọ bá Jèhófà.+  Látàrí èyí, Jèhófà wí fún Mósè pé: “Wò ó! Èmi yóò wá sọ́dọ̀ rẹ nínú àwọsánmà ṣíṣú,+ kí àwọn ènìyàn náà bàa lè gbọ́ nígbà tí mo bá ń bá ọ sọ̀rọ̀,+ àti pé kí wọ́n lè ní ìgbàgbọ́ nínú ìwọ pẹ̀lú fún àkókò tí ó lọ kánrin.”+ Lẹ́yìn náà, Mósè ròyìn ọ̀rọ̀ àwọn ènìyàn náà fún Jèhófà. 10  Jèhófà sì ń bá a lọ láti wí fún Mósè pé: “Lọ bá àwọn ènìyàn náà, kí o sì sọ wọ́n di mímọ́ lónìí àti lọ́la, kí wọ́n sì fọ aṣọ àlàbora wọn.+ 11  Kí wọ́n sì wà ní sẹpẹ́ de ọjọ́ kẹta, nítorí pé ní ọjọ́ kẹta, Jèhófà yóò sọ̀ kalẹ̀ lójú gbogbo àwọn ènìyàn náà sórí Òkè Ńlá Sínáì.+ 12  Kí o sì pa ààlà fún àwọn ènìyàn náà yí ká, pé, ‘Ẹ ṣọ́ ara yín láti má ṣe gòkè lọ sórí òkè ńlá náà, kí ẹ má sì fara kan etí rẹ̀. Ẹnikẹ́ni tí ó bá fara kan òkè ńlá náà ni a ó fikú pa dájúdájú.+ 13  Ọwọ́ kankan kò gbọ́dọ̀ kan ẹni náà, nítorí pé sísọ ni a ó sọ ọ́ lókùúta tàbí gígún ni a óò gún un ní àgúnyọ. Yálà ẹranko ni tàbí ènìyàn, òun kì yóò wà láàyè.’+ Nígbà tí a bá fun ìwo àgbò,+ kí àwọn fúnra wọn gòkè wá sí òkè ńlá náà.” 14  Lẹ́yìn náà, Mósè sọ̀ kalẹ̀ láti orí òkè ńlá náà wá sọ́dọ̀ àwọn ènìyàn náà, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí sọ àwọn ènìyàn náà di mímọ́; wọ́n sì ń fọ aṣọ àlàbora wọn.+ 15  Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, ó wí fún àwọn ènìyàn náà pé: “Ẹ múra sílẹ̀+ ní ọjọ́ mẹ́ta. Kí ẹ̀yin ọkùnrin má ṣe sún mọ́ obìnrin.”+ 16  Ní ọjọ́ kẹta, nígbà tí ó di òwúrọ̀, ó sì ṣẹlẹ̀ pé ààrá sán, mànàmáná sì bẹ̀rẹ̀ sí kọ,+ àti àwọsánmà ṣíṣú dùdù+ lórí òkè ńlá náà àti ìró ìwo adúnròkè lálá,+ tó bẹ́ẹ̀ tí gbogbo ènìyàn tí ó wà nínú ibùdó fi bẹ̀rẹ̀ sí wárìrì.+ 17  Wàyí o, Mósè mú àwọn ènìyàn náà jáde kúrò ní ibùdó láti pàdé Ọlọ́run tòótọ́, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí mú ìdúró wọn ní ìsàlẹ̀ òkè ńlá náà.+ 18  Òkè Ńlá Sínáì sì rú èéfín káríkárí,+ nítorí òtítọ́ náà pé Jèhófà sọ̀ kalẹ̀ sórí rẹ̀ nínú iná;+ èéfín rẹ̀ sì ń gòkè bí èéfín ẹbu,+ gbogbo òkè ńlá náà sì ń wárìrì gidigidi.+ 19  Nígbà tí ìró ìwo náà túbọ̀ ń dún kíkankíkan láìdáwọ́ dúró, Mósè bẹ̀rẹ̀ sí sọ̀rọ̀, Ọlọ́run tòótọ́ sì bẹ̀rẹ̀ sí fi ohùn dá a lóhùn.+ 20  Nítorí náà, Jèhófà sọ̀ kalẹ̀ sórí Òkè Ńlá Sínáì, sí orí òkè ńlá náà. Nígbà náà ni Jèhófà pe Mósè wá sí orí òkè ńlá náà, Mósè sì gòkè lọ.+ 21  Wàyí o, Jèhófà wí fún Mósè pé: “Sọ̀ kalẹ̀, kìlọ̀ fún àwọn ènìyàn náà, pé kí wọ́n má ṣe já wá sọ́dọ̀ Jèhófà láti bojú wò ó, tí ọ̀pọ̀ lára wọn yóò sì fi ṣubú.+ 22  Kí o sì jẹ́ kí àwọn àlùfáà pẹ̀lú tí wọ́n ń sún mọ́ Jèhófà déédéé sọ ara wọn di mímọ́,+ kí Jèhófà má bàa kọlù wọ́n.”+ 23  Látàrí èyí, Mósè wí fún Jèhófà pé: “Àwọn ènìyàn náà kò lè gòkè wá sí Òkè Ńlá Sínáì, nítorí pé ìwọ fúnra rẹ ti kìlọ̀ fún wa ṣáájú, pé, ‘Pa ààlà fún òkè ńlá náà, kí o sì ṣe é ní ọlọ́wọ̀.’”+ 24  Bí ó ti wù kí ó rí, Jèhófà wí fún un pé: “Lọ, sọ̀ kalẹ̀, kí o sì gòkè wá, ìwọ àti Áárónì pẹ̀lú rẹ; ṣùgbọ́n má ṣe jẹ́ kí àwọn àlùfáà àti àwọn ènìyàn náà já gòkè wá sọ́dọ̀ Jèhófà, kí ó má bàa kọlù wọ́n.”+ 25  Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, Mósè sọ̀ kalẹ̀ lọ bá àwọn ènìyàn náà, ó sì sọ fún wọn.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé