Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Ẹ́kísódù 18:1-27

18  Wàyí o, Jẹ́tírò àlùfáà Mídíánì, baba ìyàwó Mósè,+ wá gbọ́ nípa gbogbo ohun tí Ọlọ́run ti ṣe fún Mósè àti fún Ísírẹ́lì àwọn ènìyàn rẹ̀, bí Jèhófà ṣe mú Ísírẹ́lì jáde kúrò ní Íjíbítì.+  Nítorí náà, Jẹ́tírò, baba ìyàwó Mósè, mú Sípórà, aya Mósè, lẹ́yìn rírán an lọ,  pẹ̀lú àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ méjèèjì,+ tí orúkọ ọ̀kan nínú wọn ń jẹ́ Gẹ́ṣómù,+ ó wí pé, “nítorí mo wá di àtìpó ní ilẹ̀ òkèèrè”;  orúkọ èkejì sì ni Élíésérì,+ “nítorí,” láti fa ọ̀rọ̀ rẹ̀ yọ, “Ọlọ́run baba mi ni olùrànlọ́wọ́ mi ní ti pé ó dá mi nídè kúrò lọ́wọ́ idà Fáráò.”+  Nítorí náà, Jẹ́tírò, baba ìyàwó Mósè, àti àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ àti aya rẹ̀ wá bá Mósè nínú aginjù níbi tí ó dó sí, ní òkè ńlá Ọlọ́run tòótọ́.+  Nígbà náà ni ó fi ọ̀rọ̀ ránṣẹ́ sí Mósè pé: “Èmi, Jẹ́tírò,+ baba ìyàwó rẹ, ni mo wá bá ọ, àti aya rẹ pẹ̀lú àti àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ méjèèjì pẹ̀lú rẹ̀.”  Ní kíá, Mósè jáde lọ pàdé baba ìyàwó rẹ̀, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí wólẹ̀, ó sì fi ẹnu kò ó lẹ́nu;+ olúkúlùkù wọn sì bẹ̀rẹ̀ sí béèrè bí ẹnì kìíní-kejì ṣe ń ṣe sí. Lẹ́yìn ìyẹn, wọ́n lọ sínú àgọ́.  Mósè sì ṣèròyìn fún baba ìyàwó rẹ̀ nípa gbogbo ohun tí Jèhófà ti ṣe sí Fáráò àti Íjíbítì ní tìtorí Ísírẹ́lì,+ àti gbogbo ìnira tí ó ti ṣẹlẹ̀ sí wọn ní ọ̀nà,+ síbẹ̀ tí Jèhófà sì ń dá wọn nídè.+  Nígbà náà ni Jẹ́tírò yọ̀ ṣẹ̀ṣẹ̀ lórí gbogbo ire tí Jèhófà ti ṣe fún Ísírẹ́lì ní ti pé ó dá wọn nídè kúrò lọ́wọ́ Íjíbítì.+ 10  Nítorí náà, Jẹ́tírò wí pé: “Ìbùkún ni fún Jèhófà, ẹni tí ó dá yín nídè kúrò lọ́wọ́ Íjíbítì àti kúrò lọ́wọ́ Fáráò, ẹni tí ó sì dá àwọn ènìyàn náà nídè kúrò lábẹ́ ọwọ́ Íjíbítì.+ 11  Nísinsìnyí, mo mọ̀ ní ti gidi pé Jèhófà tóbi ju gbogbo ọlọ́run+ yòókù nítorí àlámọ̀rí yìí nínú èyí tí wọ́n fi ìkùgbù gbé ìgbésẹ̀ lòdì sí wọn.” 12  Lẹ́yìn náà ni Jẹ́tírò, baba ìyàwó Mósè, mú ọrẹ ẹbọ sísun àti àwọn ẹbọ fún Ọlọ́run;+ Áárónì àti gbogbo àgbà ọkùnrin Ísírẹ́lì sì wá bá baba ìyàwó Mósè jẹ oúnjẹ, níwájú Ọlọ́run tòótọ́.+ 13  Ó sì ṣẹlẹ̀ ní ọjọ́ kejì pé Mósè jókòó bí ìṣe rẹ̀ láti ṣe onídàájọ́ fún àwọn ènìyàn,+ àwọn ènìyàn náà sì ń dúró níwájú Mósè láti òwúrọ̀ títí di alẹ́. 14  Baba ìyàwó Mósè sì wá rí gbogbo ohun tí ó ń ṣe fún àwọn ènìyàn náà. Nítorí náà, ó wí pé: “Irú iṣẹ́ àmójútó wo ni èyí tí ìwọ ń ṣe fún àwọn ènìyàn? Èé ṣe tí ìwọ nìkan ṣoṣo fi ń bá a lọ ní jíjókòó, tí gbogbo ènìyàn sì ń bá a lọ ní mímú ìdúró wọn níwájú rẹ láti òwúrọ̀ títí di alẹ́?” 15  Nígbà náà ni Mósè wí fún baba ìyàwó rẹ̀ pé: “Nítorí pé àwọn ènìyàn náà ń wá sọ́dọ̀ mi ṣáá láti ṣe ìwádìí lọ́dọ̀ Ọlọ́run.+ 16  Bí ó bá ṣẹlẹ̀ pé wọ́n ní ẹjọ́ kan tí ó dìde,+ yóò wá sọ́dọ̀ mi, èmi yóò sì ṣe ìdájọ́ láàárín ìhà kìíní àti èkejì, èmi yóò sì sọ àwọn ìpinnu Ọlọ́run tòótọ́ àti àwọn òfin rẹ̀ di mímọ̀.”+ 17  Látàrí èyí, baba ìyàwó Mósè wí fún un pé: “Bí o ṣe ń ṣe yìí kò dára. 18  Dájúdájú, agara yóò dá ọ, àti ìwọ àti àwọn ènìyàn yìí tí ó wà pẹ̀lú rẹ, nítorí pé iṣẹ́ àmójútó yìí jẹ́ ẹrù tí ó tóbi jù fún ọ.+ Ìwọ kò lè dá a ṣe.+ 19  Wàyí o, fetí sí ohùn mi.+ Èmi yóò fún ọ ní àmọ̀ràn, Ọlọ́run yóò sì wà pẹ̀lú rẹ.+ Kí ìwọ fúnra rẹ jẹ́ aṣojú fún àwọn ènìyàn náà níwájú Ọlọ́run tòótọ́,+ kí ìwọ fúnra rẹ sì máa mú àwọn ẹjọ́ wá sọ́dọ̀ Ọlọ́run tòótọ́.+ 20  Kí o sì kìlọ̀ fún wọn nípa ohun tí àwọn ìlànà àti àwọn òfin jẹ́,+ kí o sì sọ ọ̀nà tí wọ́n ní láti máa rìn di mímọ̀ fún wọn àti iṣẹ́ tí wọ́n ní láti máa ṣe.+ 21  Ṣùgbọ́n kí ìwọ fúnra rẹ yàn nínú gbogbo àwọn ènìyàn náà, àwọn ọkùnrin dídáńgájíá,+ tí ó bẹ̀rù Ọlọ́run,+ àwọn ọkùnrin tí ó ṣeé gbẹ́kẹ̀ lé,+ tí ó kórìíra èrè aláìbá ìdájọ́ òdodo mu;+ kí o sì yan àwọn wọ̀nyí lé wọn lórí gẹ́gẹ́ bí olórí lórí ẹgbẹẹgbẹ̀rún,+ olórí lórí ọgọ́rọ̀ọ̀rún, olórí lórí àràádọ́ta àti olórí lórí ẹ̀wẹ̀ẹ̀wá.+ 22  Kí wọ́n sì máa ṣe ìdájọ́ àwọn ènìyàn náà ní gbogbo ìgbà tí ó bẹ́tọ̀ọ́ mu; yóò sì ṣẹlẹ̀ pé gbogbo ẹjọ́ tí ó tóbi ni kí wọ́n máa mú wá sọ́dọ̀ rẹ,+ ṣùgbọ́n gbogbo ẹjọ́ tí ó kéré ni kí àwọn fúnra wọn bójú tó gẹ́gẹ́ bí onídàájọ́. Nítorí náà, mú un fúyẹ́ fún ara rẹ, kí wọ́n sì bá ọ rù nínú ẹrù náà.+ 23  Bí ìwọ bá ṣe ohun yìí gan-an, tí Ọlọ́run sì ti páṣẹ fún ọ, nígbà náà, dájúdájú, ìwọ yóò lè kojú rẹ̀ àti pé, ní àfikún, gbogbo ènìyàn yìí yóò dé àyè tiwọn fúnra wọn ní àlàáfíà.”+ 24  Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, Mósè fetí sí ohùn baba ìyàwó rẹ̀, ó sì ṣe gbogbo ohun tí ó wí.+ 25  Mósè sì bẹ̀rẹ̀ sí yan àwọn ọkùnrin dídáńgájíá nínú gbogbo Ísírẹ́lì, ó sì fún wọn ní ipò gẹ́gẹ́ bí olórí lórí àwọn ènìyàn náà,+ gẹ́gẹ́ bí olórí ẹgbẹẹgbẹ̀rún, olórí ọgọ́rọ̀ọ̀rún, olórí àràádọ́ta àti olórí ẹ̀wẹ̀ẹ̀wá. 26  Wọ́n sì ń ṣe ìdájọ́ àwọn ènìyàn náà ní gbogbo ìgbà tí ó bẹ́tọ̀ọ́ mu. Ẹjọ́ líle ni wọn a mú wá sọ́dọ̀ Mósè,+ ṣùgbọ́n gbogbo ẹjọ́ tí ó kéré ni àwọn fúnra wọn a bójútó gẹ́gẹ́ bí onídàájọ́. 27  Lẹ́yìn ìyẹn, Mósè pẹ́ baba ìyàwó rẹ̀ lẹ́sẹ̀,+ ó sì bá ọ̀nà rẹ̀ lọ sí ilẹ̀ rẹ̀.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé