Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Ẹ́kísódù 17:1-16

17  Gbogbo àpéjọ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pátá sì bẹ̀rẹ̀ sí jáde kúrò ní aginjù Sínì+ ní ipele-ipele ìrìn, èyí tí wọ́n ṣe ní ìbámu pẹ̀lú àṣẹ ìtọ́ni Jèhófà,+ wọ́n sì dó sí Réfídímù.+ Ṣùgbọ́n kò sí omi fún àwọn ènìyàn náà láti mu.  Àwọn ènìyàn náà sì bẹ̀rẹ̀ sí bá Mósè ṣe aáwọ̀, wọ́n sì ń wí pé:+ “Fún wa ní omi kí a lè mu.” Ṣùgbọ́n Mósè wí fún wọn pé: “Èé ṣe tí ẹ fi ń bá mi ṣe aáwọ̀? Èé ṣe tí ẹ fi ń bá a nìṣó ní dídán Jèhófà wò?”+  Òùngbẹ omi sì bẹ̀rẹ̀ sí gbẹ àwọn ènìyàn náà níbẹ̀, àwọn ènìyàn náà sì ń kùn sí Mósè ṣáá, wọ́n sì ń wí pé: “Èé ṣe tí o fi mú wa gòkè kúrò ní Íjíbítì láti fi ikú òùngbẹ́ pa àwa àti àwọn ọmọ wa àti àwọn ohun ọ̀sìn wa?”+  Níkẹyìn, Mósè ké jáde sí Jèhófà, pé: “Kí ni èmi yóò ti ṣe ti àwọn ènìyàn yìí sí? Ní ìgbà díẹ̀ sí i, wọn yóò sọ mí lókùúta!”+  Nígbà náà ni Jèhófà wí fún Mósè pé: “Kọjá ní iwájú àwọn ènìyàn náà,+ kí o sì mú lára àwọn àgbà ọkùnrin Ísírẹ́lì pẹ̀lú rẹ àti ọ̀pá rẹ tí o fi lu Odò Náílì.+ Mú un dání lọ́wọ́ rẹ kí o sì máa rìn lọ.  Wò ó! Èmi yóò dúró níwájú rẹ níbẹ̀ lórí àpáta ní Hórébù. Kí o sì lu àpáta náà, omi yóò sì jáde láti inú rẹ̀, àwọn ènìyàn náà yóò sì mu ún.”+ Lẹ́yìn náà, Mósè ṣe bẹ́ẹ̀ ní ojú àwọn àgbà ọkùnrin Ísírẹ́lì.  Nítorí náà, ó pe orúkọ ibẹ̀ ní Másà+ àti Mẹ́ríbà,+ nítorí aáwọ̀ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì àti nítorí dídán tí wọ́n dán Jèhófà wò,+ pé: “Jèhófà ha wà ní àárín wa tàbí kò sí?”+  Àwọn ọmọ Ámálékì+ sì bẹ̀rẹ̀ sí wá, wọ́n sì bá Ísírẹ́lì jà ní Réfídímù.+  Látàrí èyí, Mósè wí fún Jóṣúà+ pé: “Yan àwọn ọkùnrin fún wa, kí o sì jáde lọ,+ bá àwọn ọmọ Ámálékì jà. Ní ọ̀la, èmi fúnra mi yóò dúró sí orí òkè kékeré, pẹ̀lú ọ̀pá Ọlọ́run tòótọ́ ní ọwọ́ mi.”+ 10  Nígbà náà ni Jóṣúà ṣe gan-an gẹ́gẹ́ bí Mósè ti wí fún un,+ kí a bàa lè bá àwọn ọmọ Ámálékì jà; Mósè, àti Áárónì àti Húrì+ sì gòkè lọ sí orí òkè kékeré náà. 11  Ó sì ṣẹlẹ̀ pé, gbàrà tí Mósè bá ti gbé ọwọ́ rẹ̀ sókè, ọwọ́ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì a mókè;+ ṣùgbọ́n gbàrà tí ó bá ti gbé ọwọ́ rẹ̀ sílẹ̀, ọwọ́ àwọn ọmọ Ámálékì a mókè. 12  Nígbà tí àwọn ọwọ́ Mósè wúwo, nígbà náà ni wọ́n gbé òkúta kan, wọ́n sì gbé e sábẹ́ rẹ̀, ó sì jókòó lé e; Áárónì àti Húrì sì gbé àwọn ọwọ́ rẹ̀ ró, ọ̀kan ní ìhà ìhín àti èkejì ní ìhà ọ̀hún, tí ó fi jẹ́ pé àwọn ọwọ́ rẹ̀ dúró pa sójú kan títí oòrùn fi wọ̀. 13  Nítorí èyí, Jóṣúà fi ojú idà rẹ́yìn Ámálékì àti àwọn ènìyàn rẹ̀.+ 14  Wàyí o, Jèhófà wí fún Mósè pé: “Kọ èyí sínú ìwé+ gẹ́gẹ́ bí ìrántí, kí o sì sọ ọ́ ní etí Jóṣúà, ‘Èmi yóò nu ìrántí Ámálékì kúrò pátápátá lábẹ́ ọ̀run.’”+ 15  Mósè sì bẹ̀rẹ̀ sí mọ pẹpẹ kan, ó sì pe orúkọ rẹ̀ ní Jèhófá-nisì, 16  pé: “Nítorí ọwọ́ kan lòdì sí ìtẹ́+ Jáà,+ Jèhófà yóò máa ja ogun pẹ̀lú Ámálékì láti ìran dé ìran.”+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé