Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Ẹ́kísódù 16:1-36

16  Lẹ́yìn náà, wọ́n kúrò ní Élímù,+ níkẹyìn gbogbo àpéjọ ọmọ Ísírẹ́lì pátá sì dé aginjù Sínì,+ èyí tí ó wà láàárín Élímù àti Sínáì, ní ọjọ́ kẹẹ̀ẹ́dógún oṣù kejì lẹ́yìn tí wọ́n jáde kúrò ní ilẹ̀ Íjíbítì.  Gbogbo àpéjọ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pátá sì bẹ̀rẹ̀ sí kùn sí Mósè àti Áárónì ní aginjù.+  Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sì ń wí fún wọn ṣáá pé: “Àwa ì bá kúkú ti kú+ láti ọwọ́ Jèhófà ní ilẹ̀ Íjíbítì nígbà tí àwa jókòó ti ìkòkò ẹran,+ nígbà tí a ń jẹ oúnjẹ ní àjẹtẹ́rùn, nítorí ẹ̀yin ti mú wa jáde wá sínú aginjù yìí láti fi ìyàn pa gbogbo ìjọ yìí.”+  Nígbà náà ni Jèhófà wí fún Mósè pé: “Kíyè sí i, èmi yóò rọ̀jò oúnjẹ fún yín láti ọ̀run;+ àwọn ènìyàn náà yóò sì jáde, olúkúlùkù yóò sì kó iye tirẹ̀ ti òòjọ́ fún òòjọ́,+ kí èmi bàa lè dán wọn wò ní ti yálà wọn yóò rìn nínú òfin mi tàbí bẹ́ẹ̀ kọ́.+  Yóò sì ṣẹlẹ̀ ní ọjọ́ kẹfà+ pé wọ́n ní láti pèsè ohun tí wọn yóò kó wọlé sílẹ̀, yóò sì jẹ́ ìlọ́po méjì ohun tí wọ́n ń kó ní ọjọ́ dé ọjọ́.”+  Nítorí náà, Mósè àti Áárónì sọ fún gbogbo ọmọ Ísírẹ́lì pé: “Ní alẹ́, ẹ ó mọ̀ dájúdájú pé Jèhófà ni ẹni tí ó mú yín jáde kúrò ní ilẹ̀ Íjíbítì.+  Àti ní òwúrọ̀, ní tòótọ́ ẹ óò rí ògo Jèhófà,+ nítorí ó ti gbọ́ ìkùnsínú yín sí Jèhófà. Kí sì ni àwa tí ẹ ó fi máa kùn sí wa?”  Mósè sì ń bá a lọ pé: “Yóò jẹ́ nígbà tí Jèhófà bá fún yín ní ẹran láti jẹ́ ní alẹ́ àti ní òwúrọ̀ oúnjẹ láti jẹ́ ní àjẹtẹ́rùn, nítorí pé Jèhófà ti gbọ́ ìkùnsínú yín tí ẹ ń kùn sí i. Kí sì ni àwa? Ìkùnsínú yín kì í ṣe sí wa, bí kò ṣe sí Jèhófà.”+  Mósè sì ń bá a lọ láti wí fún Áárónì pé: “Sọ fún gbogbo àpéjọ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pátá pé, ‘Ẹ wá síwájú Jèhófà, nítorí pé ó ti gbọ́ ìkùnsínú yín.’”+ 10  Ó wá ṣẹlẹ̀ pé gbàrà tí Áárónì ti bá gbogbo àpéjọ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pátá sọ̀rọ̀, wọ́n yí padà, wọ́n sì dojú kọ aginjù, sì wò ó! ògo Jèhófà fara hàn ní àwọsánmà.+ 11  Jèhófà sì bá Mósè sọ̀rọ̀ síwájú sí i, pé: 12  “Mo ti gbọ́ ìkùnsínú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì.+ Sọ fún wọn, pé, ‘Láàárín ìrọ̀lẹ́ méjèèjì, ẹ̀yin yóò jẹ ẹran àti ní òwúrọ̀, ẹ̀yin yóò jẹ oúnjẹ ní àjẹyó;+ ẹ ó sì mọ̀ dájúdájú pé èmi ni Jèhófà Ọlọ́run yín.’”+ 13  Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, ó ṣẹlẹ̀ pé ní alẹ́, àwọn àparò+ bẹ̀rẹ̀ sí jáde wá, wọ́n sì bo ibùdó, ní òwúrọ̀ pẹ̀lú, ipele ìrì sì ti gbára jọ yí ká ibùdó náà.+ 14  Nígbà tí ó ṣe, ipele ìrì náà gbẹ, sì kíyè sí i, lórí ilẹ̀ aginjù ni ohun fúlẹ́fúlẹ́ kíkúnná+ kan wà, ó kúnná bí ìrì dídì wínníwínní+ lórí ilẹ̀. 15  Nígbà tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì rí i, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí wí fún ara wọn lẹ́nì kìíní-kejì pé: “Kí ni èyí?” Nítorí pé wọn kò mọ ohun tí ó jẹ́. Nítorí náà, Mósè wí fún wọn pé: “Oúnjẹ tí Jèhófà fi fún yín láti jẹ ni.+ 16  Èyí ni ọ̀rọ̀ tí Jèhófà pa láṣẹ, ‘Ẹ kó lára rẹ̀, olúkúlùkù ní ìwọ̀n bí ó ti lè jẹun tó. Kí ẹ mú òṣùwọ̀n ómérì+ kan fún ẹnì kọ̀ọ̀kan ní iye ọkàn tí ọ̀kọ̀ọ̀kan yín ní nínú àgọ́ rẹ̀.’” 17  Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sì bẹ̀rẹ̀ sí ṣe bẹ́ẹ̀; wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí kó o, àwọn kan kó púpọ̀, àwọn kan sì kó díẹ̀. 18  Nígbà tí wọn bá fi òṣùwọ̀n ómérì wọ̀n ọ́n, ẹni tí ó kó púpọ̀ kò ní àṣẹ́kùsílẹ̀, ẹni tí ó sì kó díẹ̀ kò ṣe aláìnító.+ Wọ́n kó o, olúkúlùkù ní ìwọ̀n bí ó ti lè jẹun tó. 19  Nígbà náà ni Mósè wí fún wọn pé: “Kí ẹnikẹ́ni má ṣe fi èyíkéyìí lára rẹ̀ sílẹ̀ títí di òwúrọ̀.”+ 20  Ṣùgbọ́n wọn kò fetí sí Mósè. Nígbà tí àwọn kan bá fi lára rẹ̀ sílẹ̀ títí di òwúrọ̀, yóò yọ kòkòrò mùkúlú, yóò sì máa ṣíyàn-án;+ tó bẹ́ẹ̀ tí ìkannú Mósè fi ru sí wọn.+ 21  Wọ́n a sì máa kó o ní òròòwúrọ̀,+ olúkúlùkù ní ìwọ̀n bí ó ti lè jẹun tó. Nígbà tí oòrùn mú, ó yọ́. 22  Ó sì ṣẹlẹ̀ ní ọjọ́ kẹfà pé wọ́n kó ìlọ́po méjì oúnjẹ náà,+ òṣùwọ̀n ómérì méjì fún ẹnì kan. Nítorí náà, gbogbo ìjòyè àpéjọ náà wá, wọ́n sì ròyìn rẹ̀ fún Mósè. 23  Látàrí èyí, ó wí fún wọn pé: “Ohun tí Jèhófà ti sọ ni. Ní ọ̀la, pípa sábáàtì mọ́ yóò wà, sábáàtì mímọ́ fún Jèhófà.+ Ohun tí ẹ bá lè yan, ẹ yan án, ohun tí ẹ bá sì lè sè, ẹ sè é,+ gbogbo àṣẹ́kùsílẹ̀ tí ó bá sì wà, ẹ ṣẹ́ ẹ kù sílẹ̀ fún ara yín gẹ́gẹ́ bí ohun tí a ní láti pa mọ́ títí di òwúrọ̀.” 24  Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, wọ́n ṣẹ́ ẹ kù sílẹ̀ títí di òwúrọ̀, gan-an gẹ́gẹ́ bí Mósè ti pàṣẹ; kò ṣíyàn-án, bẹ́ẹ̀ ni ìdin kò sì yọ nínú rẹ̀.+ 25  Nígbà náà ni Mósè wí pé: “Ẹ jẹ ẹ́ lónìí, nítorí òní jẹ́ sábáàtì+ fún Jèhófà. Lónìí, ẹ kì yóò rí i nínú pápá. 26  Ọjọ́ mẹ́fà ni ẹ ó fi kó o, ṣùgbọ́n ní ọjọ́ keje, sábáàtì+ ni. Ní ọjọ́ náà, ìkankan kì yóò kóra jọ.” 27  Bí ó ti wù kí ó rí, ó ṣẹlẹ̀ ní ọjọ́ keje pé àwọn kan lára àwọn ènìyàn náà jáde lọ ní ti gidi láti kó o, ṣùgbọ́n wọn kò rí ìkankan. 28  Nítorí náà, Jèhófà wí fún Mósè pé: “Yóò ti pẹ́ tó tí ẹ ó fi máa kọ̀ láti pa àwọn àṣẹ mi àti àwọn òfin mi mọ́?+ 29  Kíyè sí òtítọ́ náà pé Jèhófà ti fún yín ní sábáàtì.+ Ìdí nìyẹn tí ó fi ń fún yín ní oúnjẹ ọjọ́ méjì ní ọjọ́ kẹfà. Kí ẹ wà ní ìjókòó olúkúlùkù ní àyè rẹ̀.+ Kí ẹnikẹ́ni má ṣe jáde kúrò ní àdúgbò rẹ̀ ní ọjọ́ keje.” 30  Àwọn ènìyàn náà sì bẹ̀rẹ̀ sí pa sábáàtì mọ́ ní ọjọ́ keje.+ 31  Ilé Ísírẹ́lì sì bẹ̀rẹ̀ sí pe orúkọ rẹ̀ ní “mánà.” Ó sì funfun bí irúgbìn ewéko kọriáńdà, adùn rẹ̀ sì dà bí ti àkàrà pẹlẹbẹ olóyin.+ 32  Nígbà náà ni Mósè wí pé: “Èyí ni ọ̀rọ̀ tí Jèhófà pa láṣẹ, ‘Ẹ fi í kún òṣùwọ̀n ómérì kan gẹ́gẹ́ bí ohun tí a ní láti pa mọ́ jálẹ̀ ìran-ìran yín,+ kí wọ́n bàa lè rí oúnjẹ tí mo mú kí ẹ jẹ ní aginjù nígbà tí mo mú yín jáde kúrò ní ilẹ̀ Íjíbítì.’”+ 33  Nítorí náà, Mósè wí fún Áárónì pé: “Mú ìṣà kan, kí o sì fi mánà ẹ̀kún òṣùwọ̀n ómérì kan sínú rẹ̀, kí o sì gbé e kalẹ̀ níwájú Jèhófà gẹ́gẹ́ bí ohun tí a ní láti pa mọ́ jálẹ̀ ìran-ìran yín.”+ 34  Gan-an gẹ́gẹ́ bí Jèhófà ti pàṣẹ fún Mósè, Áárónì sì bẹ̀rẹ̀ sí gbé e kalẹ̀ síwájú Gbólóhùn Ẹ̀rí+ gẹ́gẹ́ bí ohun tí a ní láti pa mọ́. 35  Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sì jẹ mánà fún ogójì ọdún,+ títí wọ́n fi dé ilẹ̀ kan tí a ń gbé.+ Mánà ni ohun tí wọ́n jẹ títí wọ́n fi dé ààlà ilẹ̀ Kénáánì.+ 36  Wàyí o, òṣùwọ̀n ómérì jẹ́ ìdá mẹ́wàá òṣùwọ̀n eéfà.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé